Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé

 Apá 14

Báwo Lo Ṣe Lè Fi Hàn Pé O Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà?

Báwo Lo Ṣe Lè Fi Hàn Pé O Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà?

Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni kó o dúró sí. 1 Pétérù 5:6-9

Má ṣe bá àwọn èèyàn lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Ó gba ìgboyà láti lè ṣe èyí.

Má ṣe bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú; òṣèlú ò fara mọ́ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn.

 Yan ohun tó tọ́, ìyẹn ni pé kó o tẹ́tí sí Ọlọ́run. Mátíù 7:24, 25

Máa dára pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà; wọ́n á ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè sún mọ́ Ọlọ́run.

Máa bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kó o sì máa sapá láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.

Tí ìgbàgbọ́ rẹ bá ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, o ní láti ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi.—Mátíù 28:19.

Máa tẹ́tí sí Ọlọ́run. Máa ka Bíbélì, kó o sì ní káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé rẹ̀ fún ọ. Lẹ́yìn náà, kó o máa fi àwọn ohun tó ò ń kọ́ sílò. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá wà láàyè títí láé.—Sáàmù 37:29.