Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì kú. Jẹ́nẹ́sísì 3:6, 23

Éfà tẹ́tí sí ejò yìí, ó sì jẹ nínú èso igi náà. Nígbà tó yá, ó fún Ádámù lára rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.

Ohun tí wọ́n ṣe yẹn kò dára, ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n dá. Ọlọ́run lé wọn jáde nínu Párádísè tí wọ́n ń gbé.

Nǹkan wá le koko fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn. Wọ́n di arúgbó wọ́n sì kú. Wọn ò lọ sí ibi táwọn ẹni ẹ̀mí ń gbé o; ṣe ni wọn kò sí mọ́.

 Àwọn tó ti kú dà bí erùpẹ̀ tó jẹ́ aláìlẹ́mìí. Jẹ́nẹ́sísì 3:19

Àwa èèyàn ń kú nítorí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà ni gbogbo wa. Àwọn òkú kò lè ríran, wọn ò lè gbọ́ràn, wọn kò sì lè ṣe ohunkóhun.—Oníwàásù 9:5, 10.

Jèhófà kò fẹ́ kí èèyàn máa kú. Láìpẹ́ yóò jí àwọn tó ti kú dìde. Tí wọ́n bá tẹ́tí sí i, wọn yóò wà láàyè títí láé.