Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà Ọlọ́run

 ORÍ 2

Ǹjẹ́ O Lè “Sún Mọ́ Ọlọ́run” Ní Tòótọ́?

Ǹjẹ́ O Lè “Sún Mọ́ Ọlọ́run” Ní Tòótọ́?

1, 2. (a) Kí ni ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé kò lè ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kí ni ohun tí Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú? (b) Àǹfààní wo ni Jèhófà fún Ábúráhámù, kí sì nìdí rẹ̀?

KÍ LÓ ti máa rí lára rẹ bí Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé bá tọ́ka sí ọ tó sì sọ pé, “Ọ̀rẹ́ mi nìyí”? Ọ̀pọ̀ èèyàn kò rò pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ láé. Àbí, báwo lọmọ adáríhurun tiẹ̀ ṣe máa bá Jèhófà Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́ pàápàá? Síbẹ̀, Bíbélì mú kó dá wa lójú pé a lè sún mọ́ Ọlọ́run ní tòótọ́.

2 Ábúráhámù tó gbé láyé àtijọ́ sún mọ́ Ọlọ́run lọ́nà bẹ́ẹ̀. “Ọ̀rẹ́ mi” sì ni Jèhófà pe baba ńlá ìgbàanì yìí. (Aísáyà 41:8) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ka Ábúráhámù sí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ohun tó sì jẹ́ kí Jèhófà fún Ábúráhámù láǹfààní yẹn ni pé ó “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” (Jákọ́bù 2:23) Lóde òní bákan náà, Jèhófà máa ń wá bó ṣe máa “fà mọ́” àwọn tó bá ń sìn ín tìfẹ́tìfẹ́. (Diutarónómì 10:15) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Bí gbólóhùn yìí ṣe rọ̀ wá láti ṣe nǹkan kan ló sì tún ṣèlérí nǹkan kan fún wa pẹ̀lú.

3. Kí ni Jèhófà rọ̀ wá láti ṣe, ìlérí wo ló sì ṣe fún wa tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀?

3 Jèhófà ń rọ̀ wá pé ká sún mọ́ òun. Ó ṣe tán láti gbà wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún ṣèlérí pé bí a bá gbé ìgbésẹ̀ láti sún mọ́ òun, òun náà yóò sún mọ́ wa pẹ̀lú. Nípa bẹ́ẹ̀, a óò dẹni tó wọnú àjọṣe kan tó ṣe pàtàkì, ìyẹn “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.” * (Sáàmù 25:14) Ọ̀rọ̀ náà “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́” máa ń fúnni ní èrò pé àwọn ẹni tí à ń wí jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ àfinúhàn.

4. Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan, ọ̀nà wo sì ni Jèhófà gbà jẹ́ irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ fún àwọn tó bá sún mọ́ ọn?

 4 Ǹjẹ́ o ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan tó o lè finú hàn? Irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ẹni tí kì í fọ̀rọ̀ rẹ ṣeré. Yóò jẹ́ ẹni tó o fọkàn tán nítorí pé ó jẹ́ ojúlówó ọ̀rẹ́. Ẹni tó jẹ́ pé tó o bá sọ ohun tó dùn mọ́ ọ fún un ayọ̀ rẹ á tún pọ̀ sí i. Tó jẹ́ pé ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn tó fi máa ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ máa ń jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ fúyẹ́. Òun ni ẹni tó jẹ́ pé, báwọn èèyàn ò tiẹ̀ mọ ohun tó ń dà ọ́ láàmú, òun á mọ̀ ọ́n. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run, wàá dẹni tó ní Ọ̀rẹ́ kan tó ju ọ̀rẹ́ lọ. Ọ̀rẹ́ tó kà ọ́ sí gidigidi, tí kì í fọ̀ràn rẹ ṣeré, tí ọ̀rọ̀ rẹ sì máa ń tètè yé e dáadáa. (Sáàmù 103:14; 1 Pétérù 5:7) Ẹni tó jẹ́ pé gbogbo ọ̀rọ̀ àṣírí rẹ lo lè sọ fún un pátá, nítorí o mọ̀ pé ó jẹ́ ojúlówó ọ̀rẹ́ fún àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin. (Sáàmù 18:25) Àmọ́ ṣá o, kí á mọ̀ pé ohun tó mú kí á lè láǹfààní láti bá Ọlọ́run rẹ́ tímọ́tímọ́ lọ́nà yìí ni pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣí ọ̀nà yẹn sílẹ̀.

Jèhófà Ṣí Ọ̀nà Sílẹ̀

5. Kí ni Jèhófà ṣe láti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ ọn?

5 Bí a bá fi dá kìkìdá ti àwa ẹlẹ́ṣẹ̀, a ò ní lè sún mọ́ Ọlọ́run láéláé. (Sáàmù 5:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ṣètò pé kí Jésù “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Lílò tí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà yẹn ni yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Ọlọ́run. Nígbà tó sì jẹ́ pé Ọlọ́run “ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa,” òun ló fi ìpìlẹ̀ bí a ó ṣe di ọ̀rẹ́ rẹ̀ lélẹ̀.—1 Jòhánù 4:19.

6, 7. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣe Ọlọ́run tó fara sin tá ò lè mọ̀? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà ṣí ara rẹ̀ payá?

6 Jèhófà sì tún gbé ìgbésẹ̀ mìíràn pẹ̀lú: Ó ṣí ara rẹ̀ payá fún wa. Bí o bá ń bá ẹnì kan ṣọ̀rẹ́, ohun tí yóò mú ọ fà mọ́ onítọ̀hún tímọ́tímọ́ ni pé kí o mọ̀ ọ́n dáadáa, kí àwọn ànímọ́ àti ìwà rẹ̀ sì wù ọ́. Nítorí náà, bí Jèhófà bá jẹ́ Ọlọ́run tó fara  sin, tí kò ṣeé mọ̀, a ò ní lè fà mọ́ ọn rárá. Ó sì hàn kedere pé Ọlọ́run kò fara rẹ̀ pa mọ́ rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń fẹ́ ká mọ òun. (Aísáyà 45:19) Síwájú sí i, gbangba gbàǹgbà ni ohun tó ṣí payá nípa ara rẹ̀ wà fún aráyé láti rí, àní fún àwa táráyé lè kà sí aláìjámọ́ nǹkan kan pàápàá.—Mátíù 11:25.

Jèhófà lo àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fi ṣí ara rẹ̀ payá fún wa

7 Ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà ṣí ara rẹ̀ payá fún wa? Àwọn ìṣẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ mú ká mọ àwọn apá kan lára ànímọ́ rẹ̀, irú bí agbára rẹ̀ ṣe ga tó, bí ọgbọ́n rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó àti bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó. (Róòmù 1:20) Ṣùgbọ́n kì í ṣe kìkì àwọn nǹkan tí Jèhófà dá nìkan ni ó lò láti fi ṣí ara rẹ̀ payá. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọ̀gá ni Jèhófà jẹ́ ní ti ká fúnni ní ìsọfúnni, ó pèsè àkọsílẹ̀ kan tó fi ṣí ara rẹ̀ payá sínú Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Rírí “Adùn Jèhófà”

8. Kí nìdí tí a fi lè sọ pé Bíbélì gan-an jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà fẹ́ràn wa?

8 Wíwà tí Bíbélì wà pàápàá jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Àwọn nǹkan tó lè yé wa ni Ọlọ́run lò nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fi ṣí ara rẹ̀ payá fún wa, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí pé yàtọ̀ sí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń fẹ́ ká mọ òun ká sì nífẹ̀ẹ́ òun pẹ̀lú. Ohun tí a rí kà nínú ìwé iyebíye yìí mú ká lè rí “adùn Jèhófà,” ó sì ń mú ká fẹ́ láti sún mọ́ ọn. (Sáàmù 90:17) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà dídùnmọ́ni tí Jèhófà ti gbà ṣí ara rẹ̀ payá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

9. Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa àwọn gbólóhùn pàtó kan nínú Bíbélì tó fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run hàn?

9 Onírúurú àwọn gbólóhùn pàtó tó fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run hàn ló wà nínú Ìwé Mímọ́. Kíyè sí àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan. “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.” (Sáàmù 37:28) Ọlọ́run “ga ní agbára.” (Jóòbù 37:23) “‘Adúróṣinṣin ni mí,’ ni àsọjáde Jèhófà.” (Jeremáyà 3:12) “Ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ọkàn-àyà.” (Jóòbù 9:4) Ó jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) “Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Gẹ́gẹ́ bí a sì ṣe sọ ní orí kìíní ìwé yìí, ànímọ́ kan  wà to gba iwájú gbogbo àwọn ìyókù, òun sì ni pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Bí o ṣe ń ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ànímọ́ tó wuni yìí, ǹjẹ́ ọkàn rẹ̀ kò túbọ̀ fà mọ́ Ọlọ́run tí kò láfiwé yìí?

Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà

10, 11. (a) Kí ni Jèhófà tún kọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí a bàa lè rí ànímọ́ rẹ̀ lọ́nà tó túbọ̀ ṣe kedere? (b) Àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló ràn wá lọ́wọ́ láti lè fojú inú rí bí agbára Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́?

10 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà sọ ohun tí àwọn ànímọ́ yìí jẹ́ fún wa, ó tún fi tìfẹ́tìfẹ́ kọ àwọn àpẹẹrẹ pàtó nípa bí òun ṣe ń lo àwọn ànímọ́ yìí sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wá. Irú àwọn àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká rí àwọn àpẹẹrẹ tó ṣe kedere tó sì túbọ̀ fi bí apá kọ̀ọ̀kan nínú ànímọ́ rẹ̀ yìí ṣe jẹ́ hàn wá. Ìyẹn pẹ̀lú tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ ọn. Wo àpẹẹrẹ kan.

11 Lóòótọ́ a ti lè máa kà á pé Ọlọ́run “ní okun inú nínú agbára.” (Aísáyà 40:26) Ṣùgbọ́n tí a bá ka ìtàn bí ó ṣe gba Ísírẹ́lì là nínú Òkun Pupa tó sì tọ́jú orílẹ̀ èdè yẹn nínú aginjù fún ogójì ọdún, òye ohun tí ànímọ́ yẹn jẹ́ gan-an á wá yé wa. Nítorí pé àá lè fojú inú rí bí omi òkun tó ń rọ́ gìdì yẹn ṣe ń pínyà. Àá lè fojú inú rí bí orílẹ̀-èdè yẹn, tí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta [3,000,000], ṣe rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ la àárín òkun kọjá, tí omi rẹ̀ tó ti dì yẹn wá dà bí ògiri gàgàrà lọ́tùn-ún lósì. (Ẹ́kísódù 14:21; 15:8) Àá lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run tọ́jú wọn ó sì dáàbò bò wọ́n nínú aginjù. Omi ṣàn jáde látinú àpáta. Oúnjẹ tó dà bí irúgbìn funfun wà káàkiri lórí ilẹ̀. (Ẹ́kísódù 16:31; Númérì 20:11) Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi hàn pé yàtọ̀ sí pé òun ní agbára, òun tún máa ń lò ó fún ìrànlọ́wọ́ àwọn èèyàn òun. Ǹjẹ́ èyí kò mú kí ọkàn wa balẹ̀ pé Ọlọ́run alágbára tó “jẹ́ ibi ìsádi  àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà” ni à ń gbàdúrà sí bí?—Sáàmù 46:1.

12. Báwo ni Jèhófà ṣe mú ká lè “rí” òun ní àwọn ọ̀nà tí yóò lè yé wa?

12 Jèhófà, tó jẹ́ ẹni ẹ̀mí, tún ṣe ohun púpọ̀ sí i láti jẹ́ kí á lè mọ òun. Ó níbi tí agbára ìríran àwa èèyàn mọ, nítorí kìkì ohun tó hàn sí ojú ìyójú wa nìkan la lè rí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé a kò lè rí ibi tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wà. Bí Ọlọ́run bá wá lo orúkọ àwọn nǹkan tẹ̀mí láti fi ṣàpèjúwe ara rẹ̀ fún wa ńṣe ni yóò dà bí ìgbà tó o fẹ́ máa ṣàlàyé ìrísí ara rẹ, títí kan àwọ̀ ojú rẹ tàbí àwọn ibi tó hun jọ lára rẹ fún ẹnì kan tí a bí ní afọ́jú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà fi inúure jẹ́ kí á lè “rí” òun lọ́nà tó lè yé wa. Nígbà mìíràn ó máa ń lo àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ àti àfiwé tààrà láti fi ṣàlàyé ara rẹ̀, yóò fi ara rẹ̀ wé àwọn nǹkan tí a mọ̀ dáadáa. Ó tiẹ̀ ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní àwọn ẹ̀yà kan tí ọmọ ènìyàn ní lára. *

13. Irú àpèjúwe téèyàn lè fojú inú rí wo ni Aísáyà 40:11 ṣe, báwo ni ìyẹn sì ṣe nípa lórí rẹ?

13 Ṣàkíyèsí àpèjúwe tí a ṣe nípa Jèhófà nínú Aísáyà 40:11, pé: “Bí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí.” Ibí yìí fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ pé ó máa ń fi “apá rẹ̀” kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀. Bí Ọlọ́run ṣe lágbára láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, títí kan àwọn aláìlágbára pàápàá, àti pé ó tún ń tì wọ́n lẹ́yìn, ni ohun tí ibí yìí ń fi hàn. Dájúdájú, ọkàn wa lè balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ lábẹ́ ààbò ọwọ́ rẹ̀ alágbára, nítorí bí a bá dúró ṣinṣin tì í kò ní kọ̀ wá sílẹ̀ láé. (Róòmù 8:38, 39) Olùṣọ́ Àgùntàn ńlá náà máa ń gbé àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn sí “oókan àyà rẹ̀,” ìyẹn ibi ìṣẹ́po ẹ̀wù lápá òkè, tí  olùṣọ́ àgùntàn máa ń gbé àṣẹ̀ṣẹ̀bí ọ̀dọ́ àgùntàn sí nígbà mìíràn. Èyí tipa báyìí mú un dá wa lójú pé Jèhófà kà wá sí iyebíye, ó sì ń fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tọ́jú wa. Kò mà sí bí èèyàn ò ṣe ní fẹ́ fà mọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ o.

‘Ọmọ Ń Fẹ́ Láti Ṣí I Payá’

14. Kí nìdí tí a fi lè sọ pé Jèhófà tipasẹ̀ Jésù ṣí ara rẹ̀ payá fún wa lọ́nà tó jinlẹ̀ jù lọ?

14 Jèhófà tipasẹ̀ Jésù, ààyò Ọmọ rẹ̀, ṣí ara rẹ̀ payá fún wa lọ́nà tó jinlẹ̀ jù lọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kò sí ẹni tó lè gbé ìrònú àti bí nǹkan ṣe ń rí lára Ọlọ́run yọ lọ́nà tó sún mọ́ bó ṣe jẹ́ gan-an tàbí tó lè ṣàlàyé nípa Ọlọ́run lọ́nà tó ṣe kedere bíi ti Jésù. Ó ṣe tán, Ọmọ àkọ́bí yìí kúkú ti wà lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ṣáájú kí ẹ̀dá ẹ̀mí èyíkéyìí tó wà, àti kí a tó dá ayé òun ìsálú ọ̀run pàápàá. (Kólósè 1:15) Jésù mọ Jèhófà dunjú. Ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé: “Kò sì sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́ bí kò ṣe Baba; ẹni tí Baba sì jẹ́, kò sí ẹni tí ó mọ̀ bí kò ṣe Ọmọ, àti ẹni tí Ọmọ bá fẹ́ láti ṣí i payá fún.” (Lúùkù 10:22) Nígbà tí Jésù jẹ́ ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀nà méjì pàtàkì ló gbà fi Bàbá rẹ̀ hàn.

15, 16. Ọ̀nà méjì wo ni Jésù gbà fi Bàbá rẹ̀ hàn?

 15 Àkọ́kọ́, àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni jẹ́ kí á mọ Bàbá rẹ̀. Ọ̀nà tí Jésù gbà ṣàpèjúwe Jèhófà wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù fẹ́ ṣàpèjúwe fún wa pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú tó máa ń tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà padà, ó fi Jèhófà wé bàbá adáríjini kan tí àánú ṣe gidigidi bó ṣe tajú kán rí ọmọ rẹ̀ onínàákúnàá lókèèrè tó ń padà bọ̀ wálé. Bàbá yìí sáré pàdé ọmọ rẹ̀, ó sì rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. (Lúùkù 15:11-24) Jésù tún fi Jèhófà hàn pé ó jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń “fa” àwọn olóòótọ́ ọkàn mọ́ra nítorí pé ó fẹ́ràn wọn. (Jòhánù 6:44) Kódà bí ẹyẹ ológoṣẹ́ kékeré bá já bọ́ pàápàá ó máa ń mọ̀. Jésù wá ṣàlàyé pé: “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29, 31) Ó dájú pé, ọkàn wa yóò fà mọ́ irú Ọlọ́run tó ń ṣìkẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀.

16 Ìkejì, àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Jésù fìwà jọ Bàbá rẹ̀ láìkù síbì kan débi tó fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:9) Nípa bẹ́ẹ̀ tí a bá ń ka ọ̀rọ̀ nípa Jésù nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, ìyẹn nípa ìṣarasíhùwà rẹ̀ àti bí ó ṣe bá àwọn èèyàn lò, ohun tí Bàbá rẹ̀ ń ṣe gẹ́lẹ́ là ń rí yẹn, torí ẹní bá ti rí ìṣe Jésù, ó ti mọ irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́. Bóyá lọ̀nà mìíràn tún wà tí Jèhófà lè gbà ṣí àwọn ànímọ́ rẹ̀ payá fún wa kedere ju ìyẹn lọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

17. Ṣàpèjúwe ohun tí Jèhófà ti ṣe láti mú kí òye irú ẹni tí òun jẹ́ yé wa.

17 Àpẹẹrẹ kan rèé: Fojú inú wò ó pé ò ń gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tí à ń pè ní inú rere fúnni. Ó ṣeé ṣe kí o lo onírúurú ọ̀rọ̀ láti fi sọ ìtumọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n tí o bá lè tọ́ka sí ẹnì kan tó ń ṣe inúure síni lọ́wọ́, tó o ní, “Àpẹẹrẹ inú rere tí à ń wí gan-an nìyí,” ọ̀rọ̀ náà “inú rere” á túbọ̀ nítumọ̀ sí ẹni tí ò ń ṣàlàyé rẹ̀ fún á sì tètè yé e dáadáa. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe kí òye irú ẹni tí òun jẹ́ lè yé wa. Láfikún sí bí ó ṣe fi ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe ara rẹ̀, ó tún jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ wá fi àpẹẹrẹ ohun tí òun ń wí hàn wá nínú ìṣe rẹ̀. Ìṣe Jésù jẹ́ ká rí ọ̀nà tí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run gbà ń ṣiṣẹ́. Bí ìwé Ìhìn Rere ṣe ń sọ àwọn ìtàn nípa Jésù, ńṣe  ni Jèhófà ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ fún wa pé: “Bí mo ṣe jẹ́ gan-an lẹ̀ ń rí yìí o.” Báwo ni àkọsílẹ̀ onímìísí ṣe ṣàpèjúwe Jésù nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé?

18. Báwo ni Jésù ṣe fi ànímọ́ agbára, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n hàn?

18 Jésù gbé àwọn ànímọ́ pàtàkì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí Ọlọ́run ní yọ gan-an ni. Ó ní agbára lórí àìsàn, ebi àti lórí ikú pàápàá. Síbẹ̀, kò lo agbára yìí bíi ti àwọn èèyàn onímọtara-ẹni-nìkan tó máa ń ṣi agbára lò, kò lo agbára iṣẹ́ ìyanu tó ní láti fi gbọ́ tara rẹ̀ tàbí láti fi ṣe àwọn ẹlòmíràn níkà. (Mátíù 4:2-4) Ó fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo. Inú rẹ̀ ru nítorí ìbínú òdodo nígbà tó rí bí àwọn oníṣòwò àbòsí ṣe ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. (Mátíù 21:12, 13) Kò ṣe ojúsàájú nínú ọ̀ràn àwọn aláìní àtàwọn tá a tẹ̀ lórí ba, ńṣe ló ṣèrànwọ́ fún wọn kí wọ́n lè “rí ìtura” fún ọkàn wọn. (Mátíù 11:4, 5, 28-30) Ọgbọ́n tó tayọ wà nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù, ẹni tó “ju Sólómọ́nì lọ,” kọ́ni. (Mátíù 12:42) Síbẹ̀ Jésù kò fi ọgbọ́n ṣe fọ́ńté rárá. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn gbáàtúù lọ́kàn ṣinṣin nítorí pé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣe kedere, ó rọrùn, ó sì ṣe é múlò.

19, 20. (a) Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ ní ti pé ká ní ìfẹ́? (b) Bí a ṣe ń kà nípa àpẹẹrẹ tí Jésù fi hàn, kí ni ká má ṣe gbàgbé?

19 Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ nípa kéèyàn ní ìfẹ́. Ní gbogbo ìgbà tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, gbogbo onírúurú ọ̀nà téèyàn lè gbà fi ìfẹ́ hàn ló ti fi í hàn, títí kan níní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò àti ìyọ́nú. Àánú èèyàn kì í pẹ́ẹ́ ṣe é. Àìmọye ìgbà ni ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn yẹn sì ti sún un láti ṣe nǹkan kan láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (Mátíù 14:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù wo àwọn aláìsàn sàn tó sì foúnjẹ bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ọ̀nà kan tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ wà tí Jésù tún gbà fi ìyọ́nú hàn. Ó ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó mú kí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́ ọ̀hún kí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀, nítorí pé Ìjọba yẹn ni yóò ṣe aráyé ní àǹfààní tó máa wà títí gbére. (Máàkù 6:34; Lúùkù 4:43) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jésù fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn nípa pé ó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn èèyàn.—Jòhánù 15:13.

 20 Abájọ tí ọkàn tọmọdé tàgbà láti onírúurú ipò ìgbésí ayé fi fà mọ́ ọkùnrin ọlọ́yàyà àti olójú àánú yìí. (Máàkù 10:13-16) Àmọ́, bí a ṣe ń kà nípa àpẹẹrẹ tí Jésù fi hàn lọ́rọ̀ àti ní ìṣe, tí a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé ohun tí à ń rí tí Ọmọ Ọlọ́run ń ṣe yìí jẹ́ bí ìwà Bàbá rẹ̀ ṣe rí gan-an.—Hébérù 1:3.

Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Kan Tí Yóò Ràn Wá Lọ́wọ́

21, 22. Kí ni wíwá Jèhófà wé mọ́, kí ló sì wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe àwárí yẹn?

21 Bí Jèhófà ṣe ṣí ara rẹ̀ payá gbangba gbàǹgbà fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ńṣe ló ń mú kí ó dá wa lójú pé àní sẹ́, òun fẹ́ ká sún mọ́ òun. Àmọ́ ṣá o, kò fipá mú wa láti bá òun wọ àjọṣe o. Kálukú wa ni yóò pinnu fúnra rẹ̀ láti wá Jèhófà ‘nígbà tí a lè rí i.’ (Aísáyà 55:6) Wíwá Jèhófà wé mọ́ pé kí á dẹni tó mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi í hàn. A ṣe ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ò ń kà lọ́wọ́ yìí kí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí yẹn.

22 Wàá kíyè sí i pé a pín ìwé yìí sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí tó bá àwọn ànímọ́ mẹ́rin tó gbawájú jù lọ mu, tí Jèhófà ń lò, ìyẹn: agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, wàá kọ́kọ́  rí àkópọ̀ ọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ tí a fẹ́ kọ́. Lẹ́yìn náà, orí mélòó kan lábẹ́ ìsọ̀rí yẹn yóò wá ṣàlàyé nípa bí Jèhófà ṣe lo ànímọ́ yẹn lóríṣiríṣi ọ̀nà. Ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan tún máa ń ní àkòrí kan tó ń sọ bí Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ ìlò ànímọ́ náà hàn, ó sì tún máa ń ní orí kan tó máa ń ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí a lè gbà gbé ànímọ́ yẹn yọ nígbèésí ayé wa.

23, 24. (a) Ṣàlàyé nípa ẹ̀ka àkànṣe náà “Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò.” (b) Báwo ni ṣíṣe àṣàrò ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?

23 Bẹ̀rẹ̀ láti orí tí a wà yìí, a óò máa gbé ẹ̀ka àkànṣe kan yọ tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò.” Bí àpẹẹrẹ, wo àpótí tó wà lójú ewé 24. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti ìbéèrè tó wà níbẹ̀ kò wà fún ṣíṣe àtúnyẹ̀wò orí tí a so ó mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n wà fún ni pé kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn apá pàtàkì mìíràn nínú kókó tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán. Báwo ni wàá ṣe wá lo ẹ̀ka yìí lọ́nà tó múná dóko? Ṣí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí níbẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan kí o sì fara balẹ̀ kà wọ́n. Wá gbé ìbéèrè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ Bíbélì yẹn yẹ̀ wò. Ronú nípa ohun tó lè jẹ́ ìdáhùn rẹ̀. O lè ṣe ìwádìí nípa rẹ̀. Bi ara rẹ̀ ní àfikún ìbéèrè bíi: ‘Kí ni ọ̀rọ̀ yìí ń sọ fún mi nípa Jèhófà? Báwo ló ṣe kan ìgbésí ayé mi? Báwo ni mo ṣe lè lò ó láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?’

24 Ṣíṣe irú àṣàrò yìí lè túbọ̀ mú wa máa sún mọ́ Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì so àṣàrò pọ̀ mọ́ ọkàn ẹni. (Sáàmù 19:14) Nígbà tí a bá fi ẹ̀mí ìmoore tó jinlẹ̀ ronú lórí ohun tí a kọ́ nípa Ọlọ́run, ìsọfúnni yẹn yóò túbọ̀ wọ inú ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa jinlẹ̀-jinlẹ̀, yóò sì nípa lórí ìrònú wa, yóò ta wá jí, yóò sì sún wa ṣiṣẹ́ lé e lórí níkẹyìn. Ìfẹ́ tí a ní sí Ọlọ́run yóò túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, yóò sì mú kí á fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wù ú nítorí pé òun ni Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ jù lọ. (1 Jòhánù 5:3) Kí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ tó lè wà, a ní láti dẹni tó mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. Àmọ́, lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ kí á sọ̀rọ̀ nípa apá kan nínú ànímọ́ Ọlọ́run tó mú ká rí ìdí tó fi di dandan fún wa láti sún mọ́ ọn. Ìyẹn ni jíjẹ́ tó jẹ́ mímọ́.

^ ìpínrọ̀ 3 Ó yẹ fún àfiyèsí pé, ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí a túmọ̀ sí “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́” ni wọ́n lò nínú Ámósì 3:7, èyí tó sọ pé Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa ń ṣí “ọ̀ràn àṣírí” rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí wọ́n ti mọ ohun tó fẹ́ ṣe ṣáájú kó tó ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 12 Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ojú, etí, imú, ẹnu, apá àti ẹsẹ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 18:15; 27:8; 44:3; Aísáyà 60:13; Mátíù 4:4; 1 Pétérù 3:12) Kò túmọ̀ sí pé irú ẹ̀yà ojú, imú, etí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí àwa ní yìí gan-an ni ti Jèhófà, àní bí pípè tí a pe Jèhófà ní “Àpáta náà” tàbí pé ó jẹ́ “apata” kò ṣe túmọ̀ sí pé ara rẹ̀ rí bí nǹkan wọ̀nyẹn gangan.—Diutarónómì 32:4; Sáàmù 84:11.