1, 2. “Àṣírí ọlọ́wọ̀” wo ló yẹ kó wù wá láti mọ̀, kí sì nìdí rẹ̀?

ÀṢÍRÍ! Torí pé ó máa ń gbani láfiyèsí, tó máa ń fani mọ́ra, tó sì máa ń ta kókó, ni kì í jẹ́ kí ọmọ aráyé lè fi ṣe mọ̀ọ́nú. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé: “Ògo Ọlọ́run ni pípa ọ̀ràn mọ́ ní àṣírí.” (Òwe 25:2) Òótọ́ sì ni, nítorí lọ́nà ẹ̀tọ́, Jèhófà Olùṣàkóso àti Ẹlẹ́dàá, Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, pa àwọn ọ̀ràn kan mọ́ láṣìírí fọ́mọ aráyé títí tí àkókò á fi tó lójú rẹ̀ láti ṣí i payá.

2 Àmọ́, àṣírí kan wà tó fani mọ́ra, tó gbani láfiyèsí tí Jèhófà ṣí payá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíbélì pè é ní “àṣírí ọlọ́wọ̀ ìfẹ́” Ọlọ́run. (Éfésù 1:9) Bó o bá mọ̀ ọ́n, á tẹ́ ẹ̀mí ìtọpinpin rẹ lọ́rùn kódà á tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìmọ̀ nípa àṣírí yìí lè mú ọ rí ìgbàlà, ó sì lè jẹ́ kó o ní ìjìnlẹ̀ òye nípa àwámárìídìí ọgbọ́n Jèhófà.

A Ṣí Àṣírí Náà Payá Ní Ṣísẹ̀ntẹ̀lé

3, 4. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣe fúnni nírètí, àdììtú tàbí “àṣírí ọlọ́wọ̀” wo ló sì wé mọ́ ọn?

3 Nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, ó lè dà bí pé ète Jèhófà pé kí ilẹ̀ ayé jẹ́ Párádísè tí ẹ̀dá èèyàn pípé ń gbé ti wọmi. Ṣùgbọ́n ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ọlọ́run bójú tó ìṣòro yìí. Ó ní: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ [ejò náà] àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.

4 Ọ̀rọ̀ yìí ta kókó, kódà àdììtú ni. Ta ni obìnrin yìí? Ta ni ejò náà? Ta ni “irú-ọmọ” tí yóò fọ́ orí ejò yìí? Ádámù àti Éfà ò lè mọ̀ ọ́n, wọ́n kàn lè máa méfò nípa rẹ̀ ni. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ yìí fún àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ nínú àtọmọdọ́mọ tọkọtaya aláìṣòótọ́ yẹn nírètí. Ìyẹn ni pé òdodo yóò lékè. Ète Jèhófà  yóò ṣẹ dandan. Àmọ́ báwo ni yóò ṣe ṣẹ? Àṣírí ńlá gbáà nìyẹn o! Bíbélì pè é ní “ọgbọ́n Ọlọ́run nínú àṣírí ọlọ́wọ̀ kan, ọgbọ́n tí a fi pa mọ́.”—1 Kọ́ríńtì 2:7.

5. Ṣàpèjúwe ìdí tí Jèhófà fi máa ń ṣí àṣírí rẹ̀ payá ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé.

5 Bópẹ́bóyá, Jèhófà tó jẹ́ “Olùṣí àwọn àṣírí payá,” yóò ṣí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àṣírí yìí payá ṣáá ni. (Dáníẹ́lì 2:28) Àmọ́, wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé ni yóò máa fi í hàn. A lè lo àpèjúwe irú ìdáhùn tí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan máa fún ọmọkùnrin rẹ̀ kékeré, tí ọmọ náà bá bi í pé, “Bàbá, báwo ni mo ṣe dáyé?” Bàbá tó jẹ́ ọlọgbọ́n ò kàn ní tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ìwọ̀nba àlàyé díẹ̀ tó lè yé ọmọ náà ni yóò ṣe mọ. Bí ọmọ yìí bá ṣe ń dàgbà sí i ni Bàbá rẹ̀ yóò máa ṣàlàyé yòókù fún un díẹ̀díẹ̀. Bákan náà, Jèhófà máa ń dúró di ìgbà táwọn èèyàn rẹ̀ á lè gba ìṣípayá ìfẹ́ rẹ̀ àti ète rẹ̀ kí ó tó ṣí i payá.—Òwe 4:18; Dáníẹ́lì 12:4.

6. (a) Kí ni májẹ̀mú, tàbí àdéhùn, wà fún? (b) Kí nìdí tó fí jọni lójú pé Jèhófà tún ń bá ọmọ aráyé wọ májẹ̀mú?

6 Ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà ṣí wọn payá? Ó lo onírúurú májẹ̀mú, tàbí àdéhùn, láti fi ṣí ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ payá. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ alára ti fọwọ́ sí ìwé àdéhùn kan rí, yálà láti ra ilé, tàbí láti yáwó, tàbí láti yáni lówó. Irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ máa ń pèsè ẹ̀rí lábẹ́ òfin pé ẹ máa mú àdéhùn tẹ́ ẹ jọ ṣe ṣẹ. Ṣùgbọ́n kí nìdí tí Jèhófà fi ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ń bá ọmọ aráyé wọ májẹ̀mú, tàbí àdéhùn? Ṣebí Awímáyẹhùn ni, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ lásán sì tó ẹ̀rí pé á mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Òótọ́ ni, síbẹ̀síbẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, inúure Ọlọ́run máa ń mú kó fi àdéhùn lábẹ́ òfin ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn. Irú àwọn àdéhùn bẹ́ẹ̀, tí ẹ̀rí wà pé ó di dandan fúnni láti mú ṣẹ, máa ń fún àwa ẹ̀dá aláìpé ní ẹ̀rí tó dájú láti lè gbọ́kàn lé àwọn ìlérí Jèhófà.—Hébérù 6:16-18.

 Májẹ̀mú Pẹ̀lú Ábúráhámù

7, 8. (a) Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Ábúráhámù dá, ìjìnlẹ̀ òye wo sì ni èyí fúnni nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ náà? (b) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe darí àfiyèsí sí ìlà kan pàtó tí Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà yóò ti wá?

7 Ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́yìn tí Jèhófà lé ènìyàn jáde kúrò nínú Párádísè, ó sọ fún Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Èmi yóò . . . sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ dájúdájú bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run . . . nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Ọ̀rọ̀ yìí ju ìlérí lásán lọ; ńṣe ni Jèhófà sọ ọ́ bí ẹní ń dá májẹ̀mú lọ́nà òfin, tó sì tún fi ìbúra tí kò lè yẹ̀ tì í lẹ́yìn. (Jẹ́nẹ́sísì 17:1, 2; Hébérù 6:13-15) Ó mà wúni lórí gan-an o pé Olúwa Ọba Aláṣẹ ṣe àdéhùn láti bù kún aráyé!

“Èmi yóò . . . sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ dájúdájú bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run”

8 Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá ṣí i payá pé ènìyàn ni Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí yìí yóò jẹ́, nítorí àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ni. Àmọ́ ta lonítọ̀hún? Ìgbà tó yá ni Jèhófà ṣí i payá pé láàárín àwọn ọmọ Ábúráhámù, Ísákì ni yóò jẹ́ baba ńlá Irú-Ọmọ yìí. Nínú ọmọkùnrin méjì tí Ísákì sì bí, Jékọ́bù la mú. (Jẹ́nẹ́sísì 21:12; 28:13, 14) Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù súre fún ọ̀kan nínú ọmọ méjìlá tó bí, pé: “Ọ̀pá aládé kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ kì yóò yà kúrò ní àárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣílò [“Ẹni Tó Ni Ín”] yóò fi dé; ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:10) Ìgbà yìí la mọ̀ pé ọba ni Irú-Ọmọ yìí yóò jẹ́, pé láti Júdà ni yóò sì ti wá!

Májẹ̀mú Pẹ̀lú Ísírẹ́lì

9, 10. (a) Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá, ààbò wo ni májẹ̀mú yẹn sì pèsè? (b) Báwo ni Òfin Mósè ṣe fi hàn pé aráyé nílò ìràpadà?

9 Lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà ṣe ìpèsè kan tó tún la ọ̀nà sílẹ̀ fún ìṣípayá síwájú sí i nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ náà. Ó bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù dá májẹ̀mú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé májẹ̀mú yẹn, tí í ṣe Òfin Mósè, kò ṣiṣẹ́ mọ́  báyìí, apá pàtàkì ló jẹ́ nínú ète Jèhófà láti mú Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà wá. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Wo ọ̀nà mẹ́ta tó gbà rí bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, Òfin Mósè dà bí ògiri ààbò kan. (Éfésù 2:14) Àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ dà bí ògiri tó pààlà sáàárín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí. Nípa bẹ́ẹ̀, Òfin Mósè kò jẹ́ kí ìlà tí Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà yóò ti wá dà rú. Ààbò yìí ló mú kí orílẹ̀-èdè yẹn ṣì wà di ìgbà tí àkókò tó lójú Ọlọ́run pé ká bí Mèsáyà ọ̀hún sí ìlà Júdà.

10 Ìkejì, Òfin Mósè jẹ́ kó hàn gbangba gbàǹgbà pé aráyé nílò ìràpadà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ Òfin pípé, ó tú ọmọ aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ fó pé wọn ò lè pa á mọ́ délẹ̀délẹ̀. Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ ń “mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere, títí irú-ọmọ tí a ṣe ìlérí fún yóò fi dé.” (Gálátíà 3:19) Òfin Mósè lànà fífi ẹran rúbọ láti fi ṣètùtù ìgbà díẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ ṣe fi hàn, níwọ̀n bí “kò [ti] ṣeé ṣe fún ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,” òjìji ni wọ́n kàn jẹ́ fún ẹbọ ìràpadà Kristi tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Hébérù 10:1-4) Nítorí náà, fún àwọn Júù tó jẹ́ olóòótọ́, májẹ̀mú yẹn jẹ́ “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ . . . tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.”—Gálátíà 3:24.

11. Ohun ológo wo ni májẹ̀mú Òfin mú kí Ísírẹ́lì máa retí, ṣùgbọ́n kí nìdí tí orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ fi pàdánù rẹ̀?

11 Ìkẹta, májẹ̀mú yẹn mú kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa retí ohun ológo kan. Jèhófà sọ fún wọn pé bí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí májẹ̀mú yẹn, wọ́n á di “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Lóòótọ́, inú Ísírẹ́lì nípa ti ara ni àwọn tá a kọ́kọ́ yàn pé yóò wà nínú ìjọba àwọn àlùfáà ní ọ̀run ti wá. Àmọ́, Ísírẹ́lì lápapọ̀ da májẹ̀mú Òfin yẹn, wọ́n kọ Mèsáyà tó jẹ́ Irú-Ọmọ yìí, wọ́n sì pàdánù àǹfààní tí wọn ì bá ní yẹn. Nígbà náà, ibo ni ìyókù àwọn tí yóò di ìjọba àwọn àlùfáà náà yóò ti wá? Báwo sì ni orílẹ̀-èdè oníbùkún yìí yóò ṣe tan mọ́ Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà? Ìgbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run ni yóò tó ṣí ìhà yẹn payá nínú àṣírí ọlọ́wọ̀ yìí.

 Májẹ̀mú Ìjọba ní Ìlà Dáfídì

12. Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Dáfídì dá, ojútùú síwájú sí i wo ló sì pèsè nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run?

12 Ní ọ̀rúndún kọkànlá ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà túbọ̀ pèsè ojútùú sí àṣírí ọlọ́wọ̀ náà nígbà tó dá májẹ̀mú mìíràn. Ó ṣèlérí fún Dáfídì olóòótọ́ ọba pé: “Èmi yóò gbé irú-ọmọ rẹ dìde lẹ́yìn rẹ dájúdájú, . . . èmi yóò fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. . . . Dájúdájú, èmi yóò fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (2 Sámúẹ́lì 7:12, 13; Sáàmù 89:3) Wàyí o, ó ti wá hàn pé ìlà tí Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà yóò ti wá ni ilé Dáfídì. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ èèyàn ẹlẹ́ran ara lè máa ṣàkóso “fún àkókò tí ó lọ kánrin”? (Sáàmù 89:20, 29, 34-36) Ǹjẹ́ irú ọba tó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn yìí á wá lè gba ìran ènìyàn lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú bí?

13, 14. (a) Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 110 ṣe fi hàn, ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún ẹni tó fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí Ọba? (b) Àwọn nǹkan mìíràn síwájú sí i wo nípa Irú-Ọmọ tó ń bọ̀ náà ni Jèhófà gbẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ ṣí payá?

13 Dáfídì kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Àsọjáde Jèhófà fún Olúwa mi ni pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.’ Jèhófà ti búra (kì yóò sì pèrò dà) pé: ‘Ìwọ jẹ́ àlùfáà fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì!’” (Sáàmù 110:1, 4) Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà, tàbí Mèsáyà, ni ọ̀rọ̀ Dáfídì yìí kàn ní tààràtà. (Ìṣe 2:35, 36) Kì í ṣe Jerúsálẹ́mù ni Ọba yìí yóò jókòó sí láti máa ṣàkóso, rárá o, “ọwọ́ ọ̀tún” Jèhófà lọ́run ni. Ìyẹn á jẹ́ kí ọlá àṣẹ rẹ̀ kárí gbogbo ayé dípò kó mọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìkan. (Sáàmù 2:6-8) Ohun mìíràn tún wà tí ibí yìí tún ṣí payá síwájú sí i. Ṣàkíyèsí pé Jèhófà ṣe ìbúra pàtàkì kan pé Mèsáyà yóò jẹ́ “àlùfáà . . . ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.” Bíi ti Melikisédékì, tó jẹ́ ọba àti àlùfáà láyé ìgbà Ábúráhámù, ni ọ̀ràn Irú-Ọmọ tó ń bọ̀ yìí yóò ṣe rí. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò fi jẹ Ọba àti Àlùfáà!—Jẹ́nẹ́sísì 14:17-20.

14 Nínú ọ̀pọ̀ ọdún tó tẹ̀ lé e, Jèhófà lo àwọn wòlíì rẹ̀ láti ṣí àṣírí ọlọ́wọ̀ rẹ̀ payá síwájú sí i. Bí àpẹẹrẹ, Aísáyà fi hàn pé Irú-Ọmọ  yìí yóò kú ikú ìfara-ẹni-rúbọ. (Aísáyà 53:3-12) Míkà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ibi tí wọ́n ti máa bí Mèsáyà. (Míkà 5:2) Dáníẹ́lì tilẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ àkókò pàtó tí Irú-Ọmọ yẹn yóò fara hàn àti ìgbà ikú rẹ̀.—Dáníẹ́lì 9:24-27.

Ọlọ́run Ṣí Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Náà Payá!

15, 16. (a) Báwo ni Ọmọ Jèhófà ṣe dẹni tó “ti ara obìnrin jáde wá”? (b) Kí ni Jésù jogún láti ara àwọn òbí rẹ̀ ẹlẹ́ran ara, ìgbà wo ló dé gẹ́gẹ́ bí Irú-Ọmọ tá a ṣèlérí náà?

15 Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí yóò ṣe ní ìmúṣẹ jẹ́ àdììtú títí Irú-Ọmọ yìí fi fara hàn ní ti gidi. Gálátíà 4:4 sọ pé: “Nígbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò dé, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde, ẹni tí ó ti ara obìnrin jáde wá.” Lọ́dún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa, áńgẹ́lì kan sọ fún wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà pé: “Wò ó! ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un . . . Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.”—Lúùkù 1:31, 32, 35.

16 Nígbà tó yá, Jèhófà ta àtaré ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, tí Ọmọ yìí fi wá dẹni tó ti ara obìnrin jáde wá. Aláìpé ni Màríà jẹ́. Síbẹ̀, Jésù kò jogún àìpé lára rẹ̀, nítorí “Ọmọ Ọlọ́run” ló jẹ́. Àmọ́ níwọ̀n bí àwọn òbí ẹlẹ́ran ara tí Jésù ní ti jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì, ìyẹn mú kó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà àbínibí àti lọ́nà òfin láti jogún ìtẹ́ Dáfídì. (Ìṣe 13:22, 23) Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, ó sì wí pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:16, 17) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Irú-Ọmọ tá à ń wí dé! (Gálátíà 3:16) Ó wá tó àkókò wàyí láti tún ṣí àwọn nǹkan payá síwájú sí i nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ náà.—2 Tímótì 1:10.

17. Báwo la ṣe mú kí ìtumọ̀ Jẹ́nẹ́sísì 3:15 túbọ̀ ṣe kedere?

17 Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó fi hàn pé Sátánì ni ejò inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, àti pé àwọn ọmọlẹ́yìn Sátánì ni irú ọmọ ejò  náà. (Mátíù 23:33; Jòhánù 8:44) Nígbà tó yá, a ṣí ọ̀nà tí gbogbo wọn yóò gbà di àtẹ̀rẹ́ láéláé payá. (Ìṣípayá 20:1-3, 10, 15) A sì wá fi hàn pé obìnrin náà ni “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” ìyẹn ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run, tí í ṣe àpapọ̀ ẹ̀dá ẹ̀mí tó dà bí aya fún un. *Gálátíà 4:26; Ìṣípayá 12:1-6.

Májẹ̀mú Tuntun

18. Kí ni ète “májẹ̀mú tuntun”?

18 Ó jọ pé alẹ́ ìkẹyìn kí Jésù tó kú ni ìṣípayá tó gbàfiyèsí jù lọ wáyé, ìyẹn ìgbà tó sọ̀rọ̀ nípa “májẹ̀mú tuntun” fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́. (Lúùkù 22:20) Májẹ̀mú tuntun yìí dà bíi ti májẹ̀mú Òfin Mósè tó wà ṣáájú rẹ̀ ní ti pé yóò mú “ìjọba àwọn àlùfáà” jáde wá. (Ẹ́kísódù 19:6; 1 Pétérù 2:9) Àmọ́, kì í ṣe orílẹ̀-èdè nípa tí ara ni májẹ̀mú yìí yóò mú jáde bí kò ṣe orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tí yóò jẹ́ kìkì àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi. (Gálátíà 6:16) Dájúdájú, àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun yìí yóò bá Jésù kópa nínú bíbùkún ìran ènìyàn!

19. (a) Kí nìdí tó fi ṣeé ṣe fún májẹ̀mú tuntun láti mú “ìjọba àwọn àlùfáà” jáde? (b) Kí nìdí tá a fi pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní “ìṣẹ̀dá tuntun,” ẹni mélòó sì ni yóò bá Kristi ṣàkóso lọ́run?

19 Ṣùgbọ́n kí nìdí tó fi ṣeé ṣe fún májẹ̀mú tuntun láti mú “ìjọba àwọn àlùfáà” tí yóò bù kún ìran ènìyàn jáde? Ìdí ni pé kàkà kí májẹ̀mú yẹn máa dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi lẹ́jọ́ pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ńṣe ló mú kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. (Jeremáyà 31:31-34) Bí Jèhófà bá sì ti lè kà wọ́n sí olódodo, yóò gbà wọ́n ṣọmọ, wọn yóò di apá kan ìdílé rẹ̀ ọ̀run, yóò sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. (Róòmù 8:15-17; 2 Kọ́ríńtì 1:21) Wọn yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tó ‘ní ìbí tuntun  sí ìrètí tí ó wà láàyè tí a fi pa mọ́ ní ọ̀run.’ (1 Pétérù 1:3, 4) Nǹkan tuntun ni irú ìgbéga yìí jẹ́ fún ìran ènìyàn, ìdí nìyẹn tá a fi pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tá a fẹ̀mí bí ní “ìṣẹ̀dá tuntun.” (2 Kọ́ríńtì 5:17) Bíbélì ṣí i payá pé, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ènìyàn ni yóò ti ọ̀run máa kópa nínú ṣíṣàkóso ìran ènìyàn tá a rà padà.—Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-4.

20. (a) Kí ni ohun tí a ṣí payá nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ yẹn lọ́dún 36 Sànmánì Tiwa? (b) Àwọn wo ni yóò gba ìbùkún tí a ṣèlérí fún Ábúráhámù?

20 Àwọn ẹni àmì òróró yìí àti Jésù yóò pa pọ̀ di “irú ọmọ Ábúráhámù.” * (Gálátíà 3:29) Àwọn Júù nípa ti ara la kọ́kọ́ yàn láti jẹ́ ara wọn. Ṣùgbọ́n lọ́dún 36 Sànmánì Tiwa, a ṣí ìhà mìíràn nínú àṣírí ọlọ́wọ̀ yẹn payá, ìyẹn ni pé: Àwọn Kèfèrí, tàbí àwọn tí kì í ṣe Júù, yóò nípìn-ín nínú ìrètí ti ọ̀run yìí pẹ̀lú. (Róòmù 9:6-8; 11:25, 26; Éfésù 3:5, 6) Ṣé kìkì àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni yóò gba ìbùkún tá a ṣèlérí fún Ábúráhámù yìí ni? Rárá o, nítorí gbogbo ayé ni ẹbọ Jésù ṣàǹfààní fún. (1 Jòhánù 2:2) Bí àkókò ti ń lọ Jèhófà ṣí i payá pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí a kò sọ iye wọn yóò la òpin ètò àwọn nǹkan ti Sátánì yìí já. (Ìṣípayá 7:9, 14) Ògìdìgbó ènìyàn sí i la óò jí dìde, wọn yóò sì máa retí láti gbé títí láé nínú Párádísè!—Lúùkù 23:43; Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 20:11-15; 21:3, 4.

Ọgbọ́n Ọlọ́run àti Àṣírí Ọlọ́wọ̀

21, 22. Àwọn ọ̀nà wo ni àṣírí ọlọ́wọ̀ Jèhófà gbà fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn?

21 Àṣírí ọlọ́wọ̀ yìí jẹ́ ọ̀nà kan tí “ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ọgbọ́n Ọlọ́run” gbà fara hàn lọ́nà ìyanu. (Éfésù 3:8-10) Áà, àgbà ọgbọ́n ni Jèhófà fi gbé àṣírí yìí kalẹ̀, ọba ọgbọ́n ló sì fi ń ṣí i payá wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́! Ó ń fi ọgbọ́n gba ti ìwọ̀n òye ọmọ aráyé rò, ó sì ń fún wọn láyè láti fi ohun tí ń bẹ nísàlẹ̀ ọkàn wọn hàn.—Sáàmù 103:14.

 22 Ọgbọ́n tí kò láfiwé sì ni Jèhófà lò ní yíyàn tó yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba. Nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ láyé lọ́run, Ọmọ Jèhófà ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé jù lọ. Gbígbé tí Jésù gbé láyé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀ ti jẹ́ kó fojú winá onírúurú ìṣòro. Ó mọ ìṣòro tí ọmọ ènìyàn ń dojú kọ lámọ̀dunjú. (Hébérù 5:7-9) Àwọn tí yóò bá Jésù jọba wá ńkọ́? Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá la ti ń fàmì òróró yan àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin, látinú gbogbo ẹ̀yà, èdè, àti onírúurú ipò wá. Kò sí ìṣòro kankan tá ò ní rí lára wọn tó ti fojú winá rẹ̀ rí tí wọ́n sì ti borí rẹ̀. (Éfésù 4:22-24) Áà, èèyàn á mà gbádùn lábẹ́ àkóso àwọn ọba àti àlùfáà aláàánú wọ̀nyí o!

23. Àǹfààní wo làwọn Kristẹni ní nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ Jèhófà?

23 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àṣírí ọlọ́wọ̀ tí a fi pa mọ́ láti àwọn ètò àwọn nǹkan tí ó ti kọjá . . . a ti fi í hàn kedere fún àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.” (Kólósè 1:26) Òtítọ́ ni, àwọn ẹni mímọ́ tó jẹ́ ẹni àmì òróró Jèhófà ti mọ púpọ̀ nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ yẹn, wọ́n sì ti fi ìmọ̀ wọn yìí han ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn pẹ̀lú. Àǹfààní tí gbogbo wa ní yìí mà ga lọ́lá o! Jèhófà ti “sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa.” (Éfésù 1:9) Ẹ jẹ́ ká fi àṣírí ọlọ́wọ̀ yìí han àwọn ẹlòmíràn, ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí àwọn náà lè yọjú wo àwámárìídìí ọgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run!

^ ìpínrọ̀ 17 A tún ṣí “àṣírí ọlọ́wọ̀ . . . ti fífọkànsin Ọlọ́run” payá lára Jésù pẹ̀lú. (1 Tímótì 3:16) Tipẹ́tipẹ́ ni ọ̀ràn bóyá á ṣeé ṣe láti rí ẹni tó máa pàwà títọ́ mọ́ sí Jèhófà lọ́nà pípé ti jẹ́ àṣírí, ohun àdììtú. Jésù ló pèsè ìdáhùn rẹ̀. Ó pa ìwà títọ́ mọ́ nínú gbogbo àdánwò tí Sátánì gbé kò ó lójú.—Mátíù 4:1-11; 27:26-50.

^ ìpínrọ̀ 20 Àwùjọ kan náà yìí ni Jésù bá “dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba.” (Lúùkù 22:29, 30) Jésù wá ń tipa bẹ́ẹ̀ bá “agbo kékeré” yìí ṣe àdéhùn pé wọ́n á bá òun ṣàkóso ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àwọn tó jẹ́ onípò kejì nínú irú ọmọ Ábúráhámù.—Lúùkù 12:32.