Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà Ọlọ́run

 ORÍ 31

“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò sì Sún Mọ́ Yín”

“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò sì Sún Mọ́ Yín”

1-3. (a) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nípa ìwà ẹ̀dá, bá a bá kíyè sí àjọṣe àárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn jòjòló? (b) Kí ló sábà ń jẹ́ ìṣarasíhùwà wa nígbà tẹ́nì kan bá fìfẹ́ hàn sí wa, ìbéèrè pàtàkì wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

INÚ àwọn òbí máa ń dùn láti rí ẹ̀rín lẹ́nu ọmọ wọn jòjòló. Ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n á dìídì gbójú sún mọ́ ojú ìkókó náà, wọ́n á fohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bá a ṣeré, wọ́n á sì fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà rẹ́rìn-ín sí i. Wọ́n á wá máa retí kí ọmọ náà rẹ́rìn-ín padà. Kò sì ní pẹ́ tí wọ́n á fi rí i tí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ náà á ṣe mùkẹ́, tí yóò wá rọra la ẹnu pẹ̀ẹ́, tí yóò sì rẹ́rìn-ín músẹ́. Ńṣe ló jọ pé ẹ̀rín tó rín yẹn jẹ́ ọ̀nà tirẹ̀ láti gbà fìfẹ́ hàn. Ìyẹn ni pé ọmọ ọwọ́ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn sáwọn òbí rẹ̀ tó kọ́kọ́ fìfẹ́ hàn sí i.

2 Ẹ̀rín músẹ́ ọmọ náà rán wa létí ohun pàtàkì kan nípa ìwà ẹ̀dá. Ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá láti fìfẹ́ hàn sáwọn tó fìfẹ́ hàn sí wa. Ẹ̀dá tiwa nìyẹn. (Sáàmù 22:9) Bá a ṣe ń dàgbà, a dẹni tó túbọ̀ ń mọ bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó fìfẹ́ hàn sí wa. Ó ṣeé ṣe kó o rántí ìgbà tó o wà ní kékeré, tí àwọn òbí, ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ rẹ fìfẹ́ hàn sí ọ. Èyí gbin ìfẹ́ ọlọ́yàyà sí ọ lọ́kàn, èyí tó gbèrú débi pé ó ń hàn nínú ìṣe rẹ. Ó di pé ìwọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn padà. Ṣé bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ náà nìyẹn nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run?

3 Bíbélì sọ pé: “Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Láti Ìsọ̀rí 1 dé Ìsọ̀rí 3 ìwé yìí, a rán ọ létí pé Jèhófà Ọlọ́run ti fìfẹ́ lo agbára rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ lónírúurú ọ̀nà fún àǹfààní rẹ. Nígbà tá a sì dé Ìsọ̀rí 4, o rí i pé ó fìfẹ́ rẹ̀ hàn ní tààràtà sọ́mọ aráyé, àti sí ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, lọ́nà tó bùáyà. Ìbéèrè kan rèé wàyí. Lọ́nà kan, èyí ni ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kó o bi ara rẹ, ìyẹn ni pé: ‘Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà mi sí ìfẹ́ Jèhófà?’

 Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

4. Ọ̀nà wo ni ohun tí nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí fi ń rú àwọn èèyàn lójú?

4 Jèhófà, Ẹni tó ṣẹ̀dá ìfẹ́, mọ̀ dájú pé ìfẹ́ lágbára tó ga tó fi lè sún àwọn èèyàn láti lo àwọn ànímọ́ wọn lọ́nà tó dára jù lọ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, pẹ̀lú bí àwọn ẹ̀dá èèyàn aláìṣòótọ́ ṣe jingíri sínú ìwà ọ̀tẹ̀ tó, ó dá a lójú pé àwọn kan lára ọmọ aráyé yóò kọbi ara sí ìfẹ́ òun. Ọ̀kẹ́ àìmọye sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ẹ̀sìn inú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí ti mú kí ohun tí nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí rú àwọn èèyàn lójú. Àìmọye èèyàn ló ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ lójú tiwọn kéèyàn sáà ti sọ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ jáde lọ́rọ̀ ẹnu lásán ti tó. Èèyàn lè fi ìyẹn bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ tí ọmọ ọwọ́ ní fún àwọn òbí rẹ̀ ti lè kọ́kọ́ hàn nínú ẹ̀rín músẹ́ ọmọ náà. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ àwọn tó ti dàgbà dénú tún rìn jìnnà jùyẹn lọ.

5. Kí ni Bíbélì sọ pé ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí, kí sì nìdí tó fi yẹ kí àlàyé yẹn fà wá lọ́kàn mọ́ra?

5 Jèhófà ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ òun. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Fún ìdí yìí, ìfẹ́ fún Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Ó yẹ kí ó hàn nínú ìwà wa. Òótọ́ ni pé ṣíṣe ìgbọràn kò bá ọ̀pọ̀ èèyàn lára mu. Ṣùgbọ́n ẹsẹ yìí kan náà fi kún un lọ́nà tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé: “Síbẹ̀ àwọn àṣẹ [Ọlọ́run] kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Àǹfààní wa làwọn òfin àti ìlànà Jèhófà wà fún, kì í ṣe láti ni wá lára. (Aísáyà 48:17, 18) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún fún àwọn ìlànà tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ ọn. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká gbé apá mẹ́ta lára àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run yẹ̀ wò. Ìwọ̀nyí wé mọ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, ìjọsìn àti àfarawé.

Bíbá Jèhófà Sọ̀rọ̀

6-8. (a) Ọ̀nà wo la lè gbà fetí sí Jèhófà? (b) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe lè máa ta wá jí nígbà tá a bá ń kà á?

6 Orí Kìíní bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè náà, “Ká ní o ṣàdédé gbóhùn Olódùmarè látọ̀run, tó ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí lo máa ṣe ná?” A rí i  pé irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ. Ohun tó jọ ọ́ wáyé nígbà ayé Mósè. Lóde òní ńkọ́? Lọ́jọ́ tiwa yìí, Jèhófà kì í rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti wá bá àwa ẹ̀dá èèyàn sọ̀rọ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n Jèhófà ní ọ̀nà tó gbámúṣé tó gbà ń bá wa sọ̀rọ̀ lóde òní. Báwo la ṣe lè fetí sí Jèhófà?

7 Nítorí pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,” à ń fetí sí Jèhófà nípa kíka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Ìdí nìyẹn tí onísáàmù náà fi rọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pé kí wọ́n máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “tọ̀sán-tòru.” (Sáàmù 1:1, 2) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń béèrè pé ká sapá gidigidi. Ṣùgbọ́n gbogbo ìsapá tá a bá ṣe tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i ní Orí 18, ńṣe ni Bíbélì dà bí lẹ́tà pàtàkì kan tí Baba wa ọ̀run kọ sí wa. Nítorí náà, kò yẹ kó máa ro wá lójú láti kà á. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ máa ta wá jí nígbà tá a bá ń kà á. Báwo la ṣe lè ṣe é?

8 Máa fojú inú bá ìtàn Bíbélì tí ò ń kà lọ. Máa fojú ẹni gidi wo àwọn èèyàn tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú Bíbélì. Gbìyànjú láti mọ ipò tó yí wọn ká àtohun tó sún wọn ṣe ohun tí wọ́n ṣe. Lẹ́yìn náà, wá ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ nípa ohun tó o kà, kí o máa bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ni ìtàn yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? Èwo lára ànímọ́ rẹ̀ ni ìtàn yìí gbé yọ? Kí ni ìlànà tí Jèhófà fẹ́ fi kọ́ mi, báwo sì ni mo ṣe lè mú un lò nínú ìgbésí ayé mi?’ Máa kà á, máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀, kí o sì máa fi í sílò. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á máa ta ọ́ jí.—Sáàmù 77:12; Jákọ́bù 1:23-25.

9. Ta ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà, èé sì ti ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa sí “ẹrú” yẹn?

9 Jèhófà tún ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a yan àwùjọ àwọn ọkùnrin kéréje kan tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró yìí láti máa pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn oníyánpọnyánrin yìí. (Mátíù 24:45-47) Ẹrú yẹn ló ń bọ́ wa nígbà tá a bá ń ka àwọn ìwé tó wà fún ríràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì àti nígbà tá a bá lọ sáwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ Kristẹni. Níwọ̀n  bí ó ti jẹ́ pé ẹrú Kristi ni ẹrú yìí, ohun tó bọ́gbọ́n mu pé ká ṣe ni pé ká tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) À ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ nítorí a gbà pé ẹrú olóòótọ́ náà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá wa sọ̀rọ̀.

10-12. (a) Kí nìdí tí àǹfààní gbígbàdúrà fi jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu látọ̀dọ̀ Jèhófà? (b) Báwo la ṣe lè gbàdúrà lọ́nà tí yóò dùn mọ́ Jèhófà nínú, èé sì ti ṣe tí ọkàn wa fi lè balẹ̀ pé ó ń fi ojú pàtàkì wo àdúrà wa?

10 Àmọ́, bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ńkọ́? Ṣé a lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ ni? Èrò tó ń ró kìì lọ́kàn ẹni rèé o. Ká sọ pé o fẹ́ lọ sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún olórí orílẹ̀-èdè rẹ, ǹjẹ́ o rò pé wàá lè rí i bá sọ̀rọ̀? Pé o tiẹ̀ gbìyànjú ẹ̀ rárá lè dà bíi fífi ikú ṣeré! Nígbà ayé Ẹ́sítérì àti Módékáì, wọ́n lè pààyàn torí pé ó lọ yọjú sí ọba Páṣíà láìjẹ́ pé kábíyèsí fúnra rẹ̀ ké sí i. (Ẹ́sítérì 4:10, 11) Wàyí o, fojú inú wo wíwá síwájú Olúwa Ọba Aláṣẹ ọ̀run òun ayé, ẹni tó jẹ́ pé àwọn èèyàn tó wà ní ipò gíga jù lọ “dà bí tata” lójú rẹ̀. (Aísáyà 40:22) Ṣé ìyẹn wá sọ pé kí ẹ̀rù àtibá Jèhófà sọ̀rọ̀ máa bà wá? Rárá o!

11 Jèhófà ti ṣí ọ̀nà rírọrùn sílẹ̀ gbayawu fún gbogbo èèyàn láti gbà bá òun sọ̀rọ̀. Àdúrà ni ọ̀nà yẹn. Kódà ọmọ kékeré lè fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà sí Jèhófà, lórúkọ Jésù. (Jòhánù 14:6; Hébérù 11:6) Láfikún sí i, àdúrà ń fún wa láǹfààní láti sọ èrò tó díjú jù lọ, tó wà nísàlẹ̀ ikùn wa jáde, títí kan àwọn àròdùn tó ṣòroó sọ jáde pàápàá. (Róòmù 8:26) Tá a bá ń gbàdúrà, dída ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwu tàbí ká di ẹnú-dùn-juyọ̀ tó ń gba àdúrà gígùn jàn-ànràn jan-anran, tó ń ṣàròyé lọ bí ilẹ̀ bí ẹní, kọ́ ni Jèhófà ń fẹ́. (Mátíù 6:7, 8) Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ṣòfin pé àdúrà wa ò gbọ́dọ̀ gùn o, tàbí pé àdúrà wa ò gbọ́dọ̀ ju iye ìgbà báyìí lọ. Rárá o, ṣe ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ rọ̀ wá pé ká “máa gbàdúrà láìdabọ̀.”—1 Tẹsalóníkà 5:17.

12 Rántí pé Jèhófà nìkan ni a pè ní “Olùgbọ́ àdúrà,” ó sì máa ń fetí sílẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. (Sáàmù 65:2) Ṣé ó kàn ń rọ́jú gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ni? Ó  tì o, àní ó máa ń wù ú gbọ́ ni pàápàá. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi irú àdúrà bẹ́ẹ̀ wé tùràrí olóòórùn dídùn, tó máa ń rú èéfín amáratuni nígbà tí wọ́n bá ń sun ún. (Sáàmù 141:2; Ìṣípayá 5:8; 8:4) Ǹjẹ́ kò tuni nínú láti mọ̀ pé bí àdúrà wa àtọkànwá ṣe ń gòkè tọ Ọlọ́run lọ nìyẹn àti pé ó ń dùn mọ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ? Nítorí náà, bó o bá fẹ́ sún mọ́ Jèhófà, máa fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí i lemọ́lemọ́, lójoojúmọ́. Máa tú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn rẹ jáde fún un; má ṣe ṣẹ́ nǹkan kan kù. (Sáàmù 62:8) Sọ gbogbo ohun tó ń jà gùdù lọ́kàn rẹ, àti ayọ̀ rẹ àti ọpẹ́ rẹ àti ìyìn rẹ fún Baba rẹ ọ̀run. Èyí á jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àtòun túbọ̀ máa lágbára sí i.

Sísin Jèhófà

13, 14. Kí ló túmọ̀ sí láti sin Jèhófà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

13 Nígbà tá a bá ń bá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀, kì í kàn-án ṣe bí ìgbà téèyàn ń fetí sí ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí rẹ̀ kan tàbí bí ìgbà téèyàn ń bá irú àwọn bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Ní ti gidi, ńṣe là ń jọ́sìn Jèhófà, tí à ń fún un ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tó yẹ ẹ́. Ìjọsìn tòótọ́ kan gbogbo ìgbésí ayé wa látòkèdélẹ̀. Ìjọsìn wa jẹ́ ọ̀nà tá a gbà ń fi ìfẹ́ àtọkànwá àti ìfọkànsìn wa hàn sí Jèhófà. Ìjọsìn tòótọ́ yìí sì so gbogbo ẹ̀dá tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, láyé lọ́run, pọ̀ ṣọ̀kan. Lójú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù gbọ́ tí áńgẹ́lì kan ń kéde àṣẹ náà fáyé gbọ́, pé: “Ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.”—Ìṣípayá 14:7.

14 Kí nìdí tó fi yẹ ká sin Jèhófà? Ronú nípa àwọn ànímọ́ tá a ti jíròrò nínú ìwé yìí, bí ìjẹ́mímọ́, agbára, ìkóra-ẹni-níjàánu, ìdájọ́ òdodo, ìgboyà, àánú, ọgbọ́n, ìrẹ̀lẹ̀, ìfẹ́, ìyọ́nú, ìdúróṣinṣin àti ìṣoore. A ti rí i pé Jèhófà gan-an ni àwòkọ́ṣe gíga jù lọ nínú gbogbo ànímọ́ àtàtà wọ̀nyí. Nígbà tá a bá ń gbìyànjú láti lóye àpapọ̀ ànímọ́ rẹ̀, a máa ń rí i pé Jèhófà ga fíìfíì ju Ẹni tá a kàn lè fi oríkì rẹ̀ mọ sí ẹni iyì tàbí ẹni ọlá lásán. Ọ̀gá ògo ni, tó ga fíofío jù wá lọ. (Aísáyà 55:9) Láìsí  àní-àní, Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ wa, ó sì yẹ ní ẹni tí à á sìn. Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe yẹ ká máa sin Jèhófà?

15. Báwo la ṣe lè sin Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́,” àǹfààní wo sì la ní láti ṣe èyí nínú àwọn ìpàdé Kristẹni?

15 Jésù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Èyí túmọ̀ sí sísin Jèhófà lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí rẹ̀, pẹ̀lú ọkàn tó kún fún ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́. Ó tún túmọ̀ sí jíjọ́sìn níbàámu pẹ̀lú òtítọ́, ìyẹn ìmọ̀ pípéye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A ní àǹfààní gíga lọ́lá láti sin Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” nígbàkigbà tá a bá pé jọ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa. (Hébérù 10:24, 25) Nígbà tá a bá ń kọrin ìyìn sí Jèhófà, tá a dara pọ̀ nínú àdúrà sí i, tá a sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ìjíròrò nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tá a sì kópa nínú irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń tipa ìjọsìn mímọ́ bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ àkókò aláyọ̀ láti sin Jèhófà

16. Kí ni ọ̀kan lára àṣẹ gíga jù lọ tá a pa fáwọn Kristẹni tòótọ́, kí sì nìdí tí ọkàn wa fi ń sún wa láti rí i pé a pa á mọ́?

 16 A tún ń sin Jèhófà nígbà tá a bá ń sọ fáwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀, tí à ń yìn ín ní gbangba. (Hébérù 13:15) Ní tòótọ́, ọ̀kan lára àṣẹ gíga jù lọ tí àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ pa mọ́ ní pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Jèhófà. (Mátíù 24:14) À ń fi tọkàntara pa àṣẹ yìí mọ́ nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Tá a bá rántí bí Sátánì Èṣù, “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” ṣe “fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú,” nípa irọ́ ńláńlá tó ń pa mọ́ Jèhófà, ǹjẹ́ a kì í hára gàgà láti dúró bí Ẹlẹ́rìí fún Ọlọ́run wa, láti já irú irọ́ burúkú bẹ́ẹ̀? (2 Kọ́ríńtì 4:4; Aísáyà 43:10-12) Nígbà tá a bá sì ronú nípa àwọn àgbàyanu ànímọ́ Jèhófà, ǹjẹ́ ọkàn wa kì í gún wa ní kẹ́sẹ́ láti sọ fáwọn èèyàn nípa rẹ̀? Àní sẹ́, kò sí àǹfààní tó ga tó ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n mọ Baba wa ọ̀run bá a ṣe mọ̀ ọ́n, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

17. Kí ni jíjọ́sìn Jèhófà wé mọ́, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìwà títọ́ sìn ín?

17 Sísin Jèhófà kò mọ síbẹ̀ yẹn o. Ó kan gbogbo apá ìgbésí ayé wa. (Kólósè 3:23) Bó bá jẹ́ lóòótọ́ la gbà pé Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ wa, a óò máa wá ọ̀nà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nínú ohun gbogbo, ìyẹn nínú agbo ìdílé wa, níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, títí kan ohun tí à ń fi àkókò ìsinmi wa ṣe pàápàá. A óò máa sapá láti “fi ọkàn-àyà pípé pérépéré” sin Jèhófà, nínú ìwà títọ́. (1 Kíróníkà 28:9) Irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ kò fàyè gba ọkàn tó pínyà tàbí gbígbé ìgbésí ayé méjì, ìyẹn ni híhu ìwà àgàbàgebè, ká máa ṣojú ayé pé à ń sin Jèhófà, ká tún máa yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì dá ní kọ̀rọ̀. Ìwà títọ́ kò ní jẹ́ kéèyàn hu irú ìwà àgàbàgebè bẹ́ẹ̀; ìfẹ́ á jẹ́ kí irú ìwà bẹ́ẹ̀ kóni nírìíra. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú. Bíbélì fi hàn pé irú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ wé mọ́ níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.—Sáàmù 25:14.

 Fífarawé Jèhófà

18, 19. Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti ronú pé ẹ̀dá ènìyàn aláìpé lásánlàsàn lè fara wé Jèhófà Ọlọ́run?

18 Àkòrí tó gbẹ̀yìn ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan inú ìwé yìí dá lórí bá a ṣe lè “di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Ó ṣe kókó láti rántí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe ní ti gidi láti fara wé ọ̀nà pípé tí Jèhófà gbà ń lo agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Báwo la ṣe mọ̀ pé ó ṣeé ṣe ní tòótọ́ láti fara wé Olódùmarè? Ẹ jẹ́ ká rántí pé ìtumọ̀ orúkọ Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé ó lè sọ ara rẹ̀ di ohunkóhun tó bá fẹ́ láti lè mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Agbára yẹn ń jẹ́ kí ẹ̀rù Ọlọ́run bani, ó sì tọ́ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò ṣeé ṣe rárá láti fara wé Jèhófà ni? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀.

19 Àwòrán Ọlọ́run ni a dá wa. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ìyẹn làwa èèyàn fi yàtọ̀ sáwọn ẹ̀dá yòókù lórí ilẹ̀ ayé. Kì í ṣe ìwà àdánidá nìkan tàbí àwọn èròjà tí ń pilẹ̀ àbùdá tàbí àyíká wa ló ń tì wá ṣe àwọn ohun tí à ń ṣe. Jèhófà fún wa ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn ni òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá. Láìka àìlera àti àìpé wa sí, a lómìnira láti yan irú ẹ̀dá tí a fẹ́ láti jẹ́. Ṣé o fẹ́ jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ọlọgbọ́n, olódodo tó ń lo agbára bó ti tọ́? Lọ́lá ẹ̀mí Jèhófà, o lè jẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́! Ronú nípa ohun rere tó o lè tipa bẹ́ẹ̀ gbé ṣe.

20. Ohun rere wo ni a óò gbé ṣe bá a bá ń fara wé Jèhófà?

20 Inú Baba rẹ ọ̀run yóò máa dùn sí ọ, wàá sì mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) O tilẹ̀ lè ‘wu Jèhófà ní kíkún,’ nítorí pé ó mọ ibi tí agbára rẹ mọ. (Kólósè 1:9, 10) Bó o sì ṣe ń fi àwọn ànímọ́ rere kọ́ra ní àfarawé Baba rẹ ọ̀wọ́n, wàá ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan. Nínú ayé tó ṣókùnkùn biribiri, tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run yìí, wàá di atànmọ́lẹ̀. (Mátíù 5:1, 2, 14) Wàá wà lára àwọn tí ń gbé ànímọ́ ológo Jèhófà yọ kárí ayé. Ọlá kankan ò mà tún lè jùyẹn lọ o!

 “Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò sì Sún Mọ́ Yín”

Ǹjẹ́ kí o máa bá a lọ ní sísúnmọ́ Jèhófà

21, 22. Ọ̀nà wo ni àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà yóò máa tọ̀ títí ayé?

21 Ọ̀rọ̀ ìyànjú tá a sọ wẹ́rẹ́ nínú ìwé Jákọ́bù 4:8 yìí kì í kàn-án ṣe góńgó téèyàn ń lépa nìkan. Ipa ọ̀nà téèyàn ń tọ̀ ni. Bí a bá ń jẹ́ olóòótọ́ nìṣó, ọ̀nà yẹn ò ní pin láé. A ò ní yéé máa sún mọ́ Jèhófà nìṣó, síwájú àti síwájú sí i títí láé. Ó ṣe tán, kò sígbà tí a ò ní máa túbọ̀ rí nǹkan kọ́ nípa rẹ̀. Ká má rò pé ìwé yìí ti kọ́ wa ní gbogbo ohun tó yẹ ní mímọ̀ nípa Jèhófà o. A tiẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mẹ́yẹ bọ̀ lápò ni, torí pé kékeré la tíì sọ nípa gbogbo ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run wa! Bíbélì pàápàá kò sọ gbogbo ohun tá a lè mọ̀ nípa Jèhófà fún wa tán. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé bí a bá ní ká ṣe àkọọ́lẹ̀ gbogbo ohun tí Jésù ṣe nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, “ayé tìkára rẹ̀ kò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ.” (Jòhánù 21:25) Bí a bá sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa Ọmọ Ọlọ́run, mélòómélòó wá ni ti Bàbá fúnra rẹ̀!

22 Pẹ̀lú ìyè ayérayé pàápàá, a ò ní lè mọ gbogbo ohun tó  ṣeé mọ̀ nípa Jèhófà tán. (Oníwàásù 3:11) Wá fi ìyẹn ronú nípa ìrètí tí ń bẹ níwájú wa. Lẹ́yìn tá a bá wà láàyè fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ọ̀kẹ́ àìmọye, kódà fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún, ohun tí a ó mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run á pọ̀ púpọ̀ ju ohun tá a mọ̀ báyìí. Ṣùgbọ́n a óò rí i pé àwọn ohun àgbàyanu tó ṣì yẹ ní mímọ̀ kò lóǹkà. A óò máa hára gàgà láti mọ̀ sí i, nítorí pé títí ayé la óò máa ní irú èrò tí onísáàmù náà ní, nígbà tó kọ ọ́ lórin pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.” (Sáàmù 73:28) Ìyè ayérayé yóò kún fún ohun mériyìírí lóríṣiríṣi tó ń mú ayé dùn mọ́ni. Sísúnmọ́ Jèhófà sì ni apá tí yóò mérè wá jù lọ nínú rẹ̀.

23. Kí la gbà ọ́ níyànjú láti ṣe?

23 Ǹjẹ́ kí o kọbi ara sí ìfẹ́ Jèhófà nísinsìnyí, nípa fífi gbogbo ọkàn-àyà rẹ, ọkàn rẹ, èrò inú àti okun rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Máàkù 12:29, 30) Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ rẹ jẹ́ ìfẹ́ dídúróṣinṣin, tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ǹjẹ́ kí àwọn ìpinnu tí ò ń ṣe lójoojúmọ́, látorí ìpinnu tó kéré jù lọ dórí èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ, máa tẹ̀ lé ìlànà pàtàkì kan náà, èyíinì ni pé wàá máa tọ ipa ọ̀nà tí yóò mú kí àjọṣe àárín ìwọ àti Baba rẹ ọ̀run túbọ̀ máa ṣe tímọ́tímọ́ sí i títí láé. Lékè gbogbo rẹ̀, ǹjẹ́ kí o túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, kí òun náà sì túbọ̀ máa sún mọ́ ọ, títí láé fáàbàdà!