Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà Ọlọ́run

 Orí 23

“Òun Ni Ó Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”

“Òun Ni Ó Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”

1-3. Kí làwọn nǹkan tó mú kí ikú Jésù jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn?

LỌ́JỌ́ kan nígbà ìrúwé, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, wọ́n ṣẹjọ́ ọkùnrin aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan, wọ́n dá a lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀, wọ́n sì dá a lóró títí ó fi kú. Ìyẹn kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn, tọ́mọ aráyé máa pànìyàn nípa ìkà; ó sì bani nínú jẹ́ pé èyí kọ́ ni ìgbẹ̀yìn irú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ikú tirẹ̀ yẹn jẹ́ àrà ọ̀tọ̀.

2 Bí ọkùnrin yẹn ṣe ń joró ikú nínú ìrora gógó, ojú ọ̀run pàápàá jẹ́rìí sí i pé nǹkan pàtàkì ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀sán ganrínganrín ni, ṣe ni òkùnkùn ṣàdédé ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà. Òpìtàn kan tó ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sọ pé “ìmọ́lẹ̀ oòrùn kùnà.” (Lúùkù 23:44, 45) Àmọ́, gẹ́rẹ́ ṣáájú kí ọkùnrin náà tó gbẹ́mìí mì, ó sọ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé kan, ó ní: “A ti ṣe é parí!” Àní sẹ́, nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, ó ti ṣe ohun àgbàyanu kan láṣeparí. Ẹbọ tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rú yìí ni ìfẹ́ tó ga jù lọ tí ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tíì fi hàn.—Jòhánù 15:13; 19:30.

3 Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, Jésù Kristi lọkùnrin tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Àwọn èèyàn níbi gbogbo ló mọ̀ nípa ìjìyà àti ikú tó kú lọ́jọ́ tí gọngọ sọ yẹn, ìyẹn ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, àwọn èèyàn sábà máa ń gbójú fo kókó pàtàkì kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà ńlá jẹ Jésù, síbẹ̀ ẹnì kan tún wà tó jẹ́ pé ohun tó mú mọ́ra ju ti Jésù lọ. Àní sẹ́, ẹnì kan tún wà tó fi ohun ńláǹlà du ara rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Èyí sì ni ìfẹ́ tó ga jù lọ tí ẹnikẹ́ni tíì fi hàn láyé lọ́run. Ìfẹ́ wo nìyẹn? Ìdáhùn ìbéèrè yìí la ó fi nasẹ̀ kókó ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ, èyíinì ni: ìfẹ́ Jèhófà.

Ìgbésẹ̀ Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ

4. Báwo ni ọmọ ogun ará Róòmù kan ṣe wá rí i pé Jésù kì í kàn-án ṣe èèyàn lásán, kí sì ni ìparí èrò rẹ̀?

4 Kàyéfì gbáà ni òkùnkùn tó ṣáájú ikú Jésù àti ilẹ̀ tó sẹ̀ lọ́nà  bíbùáyà lẹ́yìn ikú rẹ̀ jẹ́ fún balógun ọ̀rún ará Róòmù tó bójú tó ètò pípa Jésù. Ó sọ pé: “Dájúdájú, Ọmọ Ọlọ́run ni èyí.” (Mátíù 27:54) Ó ṣe kedere pé Jésù kì í kàn-án ṣe èèyàn lásán. Áà, ọmọ ogun yẹn bá wọn lọ́wọ́ sí pípa Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo! Báwo gan-an ni Ọmọ yẹn àti Bàbá rẹ̀ ṣe ṣe tímọ́tímọ́ tó?

5. Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe ọdún gbọ́nhan tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ti jọ wà?

5 Bíbélì pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Sáà rò ó wò ná, àní Ọmọ Jèhófà ti wà kí ayé òun ìsálú ọ̀run tó wà. Báwo wá ni ó ti pẹ́ tó tí Bàbá àti Ọmọ rẹ̀ yìí ti jọ wà? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan fojú bù ú pé á ti tó bílíọ̀nù mẹ́tàlá ọdún tí ayé òun ìsálú ọ̀run ti wà. Ǹjẹ́ o tilẹ̀ lè mòye àkókò tó gùn tóyẹn? Káwọn èèyàn lè lóye iye ọdún táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ayé òun ìsálú ọ̀run ti wà, wọ́n ya àwòrán ọ̀wọ́ àwọn pílánẹ́ẹ̀tì, wọ́n wá ṣe àtẹ kan tó fi bí ìgbà ṣe ń lọ sí hàn, èyí tó gùn ní àádọ́fà [110] mítà. Bí àwọn tó wá wo àtẹ ìsọfúnni fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ yìí ti ń gba ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kọjá, ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá gbé dúró fún nǹkan bí mílíọ̀nù márùnléláàádọ́rin [75] ọdún tí ayé òun ìsálú ọ̀run ti wà. Lápá ìparí àtẹ náà, àmì bíńtín kan, tí kò fẹ̀ ju fọ́nrán irun kan ṣoṣo, ló dúró fún gbogbo ìtàn ẹ̀dá ènìyàn! Ká tiẹ̀ sọ pé ohun tí wọ́n fojú bù yìí tọ̀nà, àtẹ ìsọfúnni náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin kò lè gùn tó ọdún gbọ́nhan tí Ọmọ Jèhófà ti wà! Iṣẹ́ wo ló ń ṣe ní gbogbo ìgbà tó lọ bí òréré yẹn?

6. (a) Iṣẹ́ wo ni Ọmọ Jèhófà ń ṣe kó tó di èèyàn ẹlẹ́ran ara? (b) Irú ìdè wo ló wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀?

6 Ńṣe ni Ọmọ ń fi tayọ̀tayọ̀ sin Bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30) Bíbélì sọ pé: “Láìsí [Ọmọ], àní ohun kan kò di wíwà.” (Jòhánù 1:3) Nítorí náà Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jọ ṣiṣẹ́ dídá gbogbo nǹkan yòókù. Ẹ wo àkókò alárinrin, tó kún fún ayọ̀ tí wọ́n gbádùn pa pọ̀! A sì mọ̀ pè ìfẹ́ alọ́májàá sábà máa ń wà láàárín òbí àtọmọ. Ìfẹ́ sì rèé, “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” ni. (Kólósè 3:14) Ta ló lè sọ bí ìdè àárín wọ́n ṣe lágbára tó ní  gbogbo ọdún gbọ́nhan tí wọ́n ti jọ wà? Ní kedere, ìdè ìfẹ́ tó lágbára jù lọ láyé lọ́run ló wà láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀.

7. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, kí ni Jèhófà sọ tó fi bí inú rẹ̀ ṣe dùn sí Ọmọ rẹ̀ tó hàn?

7 Síbẹ̀síbẹ̀, Bàbá rán Ọmọ rẹ̀ wá sílé ayé, kí a lè bí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọwọ́ tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ní ọ̀run du ara rẹ̀. Tọkàntara ni Ó ń wo Jésù látọ̀run, bó ṣe ń dàgbà di ọkùnrin pípé. Jésù ṣèrìbọmi nígbà tó pé ẹni nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní sísọ pé inú Jèhófà dùn sí Ọmọ rẹ̀ yìí gan-an. Bàbá fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Ẹ sáà wo bí inú Bàbá Jésù á ti dùn tó nígbà tó rí i pé Jésù fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo ohun tá a sọ tẹ́lẹ̀ àti gbogbo ohun tá a ní kó ṣe!—Jòhánù 5:36; 17:4.

8, 9. (a) Kí ni nǹkan tójú Jésù rí lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, báwo ló sì ṣe rí lára Baba rẹ̀ ọ̀run? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ jìyà, kí ó sì kú?

8 Àmọ́ o, báwo lọ̀ràn ṣe wá rí lára Jèhófà lọ́jọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Tiwa? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n da Jésù, táwọn èèyànkéèyàn sì mú un nímùú ọ̀daràn lóru ọjọ́ yẹn? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà táwọn ọ̀rẹ́ Jésù sá fi í sílẹ̀, táwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ awúrúju ìgbẹ́jọ́? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń fi Ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń tutọ́ sí i lára, tí wọ́n ń gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń nà án lọ́rẹ́, tí ọrẹ́ náà sì dá egbò sí i lẹ́yìn yánnayànna? Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń fi ìṣó kan ọwọ́ àtẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́ òpó igi, táwọn èèyàn sì ń kẹ́gàn rẹ̀ bó ṣe wà lórí igi oró? Báwo ló ṣe rí lára Bàbá nígbà tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ké lóhùn rara sí i nínú ìrora gógó? Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Jésù mí èémí àmíkẹ́yìn, tó wá di pé fún ìgbà àkọ́kọ́ láti àtètèkọ́ṣe, Ọmọ Rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣaláìsí?—Mátíù 26:14-16, 46, 47, 56, 59, 67; 27:38-44, 46; Jòhánù 19:1.

“Ọlọ́run . . . fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni”

 9 Áà, ọ̀rọ̀ ọ̀hún kọjá sísọ. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ ẹni tí ń mọ nǹkan lára, ìrora tó máa ní nítorí ikú Ọmọ rẹ̀ kọjá àfẹnusọ. Ohun tí a sọ ni ohun tó sún Jèhófà tó fi mú kó ṣẹlẹ̀. Kí nìdí tí Bàbá fi fara da gbogbo ìyẹn? A rí ìdí náà nínú Jòhánù 3:16, èyí tó jẹ́ ẹsẹ Bíbélì tó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi ń pè é ní àkópọ̀ ìwé Ìhìn Rere. Jòhánù 3:16 sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Nítorí náà, ohun tó sún Jèhófà ṣe é ni ìfẹ́. Ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa, ìyẹn rírán Ọmọ rẹ̀ láti wá jìyà, kí ó sì kú fún wa, ni ìfẹ́ gíga jù lọ láyé lọ́run.

Irú Ìfẹ́ Tí Ọlọ́run Ní

10. Kí lohun tí ẹ̀dá ènìyàn nílò, kí ló sì ti ṣẹlẹ̀ sí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́”?

10 Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́”? Wọ́n ní ìfẹ́ lohun tí ènìyàn nílò jù lọ. Láti ọjọ́ ìbí títí dọjọ́ ikú làwọn èèyàn ń lépa ìfẹ́ lójú méjèèjì, tí wọ́n ń gbádùn ìtura tó ń mú wá. Bẹ́ẹ̀ náà layé ń súni, táwọn èèyàn sì ń kú níbi tí ìfẹ́ kò bá sí. Síbẹ̀síbẹ̀, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ìfẹ́ ṣòroó túmọ̀. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ ìfẹ́ kì í wọ́n lẹ́nu àwọn èèyàn. Àìmọye ìwé, orin àti ewì ni wọ́n ti kọ nípa rẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo rẹ̀ náà ńkọ́, àwọn èèyàn ò tíì lè sọ ohun tí ìfẹ́ jẹ́ gan-an. Kódà, àlòjù tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ ń jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ fara sin ni.

11, 12. (a) Níbo la ti lè rí ẹ̀kọ́ ńlá kọ́ nípa ìfẹ́, èé sì ti ṣe? (b) Oríṣi ìfẹ́ mélòó làwọn tí ń sọ èdè Gíríìkì ìgbàanì mẹ́nu kàn, ọ̀rọ̀ wo la sì lò jù lọ fún “ìfẹ́” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (d) Kí ni a·gaʹpe?

11 Àmọ́ ṣá o, Bíbélì ṣàlàyé yékéyéké nípa ìfẹ́. Ìwé Expository Dictionary of New Testament Words, tí ọ̀gbẹ́ni Vine ṣe, sọ pé: “Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà mọ ìfẹ́ ni nípa ṣíṣàkíyèsí àwọn ìgbésẹ̀ tí ìfẹ́ ń súnni gbé.” Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìgbésẹ̀ Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun púpọ̀ nípa ìfẹ́ rẹ̀, ìyẹn àwọn oore tó ti ṣe nínú àánú rẹ̀ fún àwa ẹ̀dá rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ó yẹ kí ọ̀ràn nípa ànímọ́ yìí tún máa rú wa lójú bá a bá ronú lórí ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́  tí Jèhófà fi hàn, bá a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ ní ìṣáájú? Nínú àwọn àkòrí tí ń bẹ níwájú, a óò rí àpẹẹrẹ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìgbésẹ̀ tí Jèhófà fìfẹ́ gbé. Láfikún sí i, òye wa á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i bá a bá wo àwọn ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n lò fún “ìfẹ́” nínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń lò nínú èdè Gíríìkì ìgbàanì fún “ìfẹ́.” * Lára ọ̀rọ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà, èyí tó wọ́pọ̀ jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni a·gaʹpe. Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì pe ọ̀rọ̀ yìí ní “ọ̀rọ̀ tó lágbára jù lọ tó ṣeé lò fún ìfẹ́.” Èé ṣe?

12 A·gaʹpe jẹ́ ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà. Fún ìdí yìí, kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe ànímọ́ tí à ń fi hàn nítorí ohun tí ẹlòmíràn sọ tàbí tó ṣe. Ó gbòòrò ju àwọn ìfẹ́ yòókù lọ, ó sì gba ìrònújinlẹ̀ àti ìpinnu àtọkànwá ju àwọn yòókù. Lékè gbogbo rẹ̀, a·gaʹpe kì í ṣe ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan rárá. Bí àpẹẹrẹ, tún padà lọ wo Jòhánù 3:16. “Ayé” wo ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fún? Ayé àwọn ọmọ aráyé tó ṣeé rà padà ni. Lára wọn ni ọ̀pọ̀ èèyàn tí ń gbé ìgbé-ayé ẹ̀ṣẹ̀. Ṣé ohun tí à ń sọ ni pé Jèhófà fẹ́ràn kálukú wọn bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, bó ṣe fẹ́ràn Ábúráhámù olóòótọ́? (Jákọ́bù 2:23) Rárá o, ṣùgbọ́n Jèhófà ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣoore fún gbogbo èèyàn, láìka ohun ńláǹlà tó máa ná an sí. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí ọ̀nà wọn padà. (2 Pétérù 3:9) Ọ̀pọ̀ ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì ń fi tayọ̀tayọ̀ sọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ ara rẹ̀.

13, 14. Kí ló fi hàn pé a·gaʹpe jẹ́ ìfẹ́ ọlọ́yàyà àtọkànwá?

13 Àmọ́ o, ojú òdì làwọn kan fi ń wo a·gaʹpe. Lójú tiwọn, ìfẹ́ tó tutù ni, tó jẹ́ pé làákàyè nìkan ló bá lọ. Kò sì rí bẹ́ẹ̀ o,  nítorí pé ìfẹ́ ọlọ́yàyà àtọkànwá ni a·gaʹpe jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jòhánù kọ̀wé pé, “Baba nífẹ̀ẹ́ Ọmọ,” ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ a·gaʹpe ló lò. (Jòhánù 3:35) Ṣé irú ìfẹ́ tí kì í yá mọ́ni ni? Ṣàkíyèsí pé Jésù sọ nínú Jòhánù 5:20, pé, “Baba ní ìfẹ́ni fún Ọmọ,” ọ̀rọ̀ tó sì lò tan mọ́ phi·leʹo (ìyẹn ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́). Ìfẹ́ Jèhófà jẹ́ ìfẹ́ ọlọ́yàyà àtọkànwá. Àmọ́, ìfẹ́ rẹ̀ kì í ṣe èyí tá a gbé karí ìgbónára lásán. Ìlànà òdodo rẹ̀ tó bọ́gbọ́n mu ló máa ń gbé e kà.

14 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, gbogbo ànímọ́ Jèhófà ló pegedé, tó jẹ́ pípé, tó sì fani mọ́ra. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ ló fani mọ́ra jù lọ nínú gbogbo wọn. Kò sí ànímọ́ mìíràn tó tún lè fà wá sún mọ́ Jèhófà bí ìfẹ́. Inú wa sì dùn pé ìfẹ́ ló gbawájú lára àwọn ànímọ́ rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”

15. Gbólóhùn wo ni Bíbélì sọ nípa ànímọ́ Jèhófà náà ìfẹ́, ọ̀nà wo sì ni gbólóhùn náà gbà jẹ́ àrà ọ̀tọ̀? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

15 Bíbélì sọ nǹkan kan nípa ìfẹ́, èyí tí kò sọ rárá nípa àwọn lájorí ànímọ́ Jèhófà yòókù. Ìwé Mímọ́ kò sọ pé Ọlọ́run jẹ́ agbára tàbí pé Ọlọ́run jẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ọgbọ́n pàápàá. Ó ànímọ́ wọ̀nyẹn ni, òun ni orísun ànímọ́ wọ̀nyẹn, ó sì ní ànímọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ́nà àìláfiwé. Àmọ́ o, a sọ ohun kan tó jẹ́ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ kẹrin, èyíinì ni pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” * (1 Jòhánù 4:8) Kí lọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?

16-18. (a) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́”? (b) Lára gbogbo ẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé, ó ṣe jẹ́ pé èèyàn ni àpẹẹrẹ tó bá ànímọ́ ìfẹ́ tí Jèhófà ní mu wẹ́kú?

16 Gbólóhùn náà “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” kì í wulẹ̀ẹ́ ṣọ̀ràn fífi nǹkan méjì wéra, bíi sísọ pé “Ọlọ́run àti ìfẹ́ dọ́gba.” Gbólóhùn náà  kò ṣeé gbé ní àtoríkòdì, pé “ìfẹ́ jẹ́ Ọlọ́run.” Jèhófà kọjá ẹni tá a lè fi wé ànímọ́ kan lásán. Ó jẹ́ ẹnì kan tó ní ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìmọ̀lára àti àwọn ànímọ́ mìíràn láfikún sí ìfẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ìfẹ́ ni àkójá gbogbo ọ̀nà Jèhófà. Fún ìdí yìí, ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ nípa ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ yìí pé: “Afi-gbogbo-ara jẹ́ ìfẹ́ ni Ọlọ́run.” Lédè mìíràn, a lè sọ pé: Agbára Jèhófà ń jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún un láti gbé ìgbésẹ̀. Ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ máa ń darí ìgbésẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ Jèhófà ló máa ń sún un gbé ìgbésẹ̀. Ìfẹ́ rẹ̀ sì máa ń hàn nínú bó ṣe ń lo àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù.

17 A sábà máa ń sọ pé Jèhófà gan-an ni àpẹẹrẹ ìfẹ́. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Dájúdájú, a lè rí ànímọ́ àtàtà yìí nínú ẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n kí nìdí téèyàn fi ní in? Nígbà ìṣẹ̀dá, ó hàn gbangba pé Ọmọ rẹ̀ ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa, ní ìrí wa.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Lára gbogbo ẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé, àwọn ọkùnrin àti obìnrin nìkan ló lè yàn láti nífẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fìwà jọ Baba wọn ọ̀run. Rántí pé Jèhófà fi onírúurú ẹ̀dá ṣàpẹẹrẹ àwọn lájorí ànímọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ènìyàn, tó wà ní ipò gíga jù lọ lára àwọn ẹ̀dá rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ni Jèhófà fi ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́, tó gbawájú lára àwọn ànímọ́ Rẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 1:10.

18 Bá a bá fìfẹ́ hàn lọ́nà àìmọtara-ẹni-nìkan, níbàámu pẹ̀lú ìlànà, a jẹ́ pé èyí tó gbawájú lára àwọn ànímọ́ Jèhófà là ń gbé yọ. Bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ó ní: “Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Àmọ́ àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa?

Jèhófà Ló Kọ́kọ́ Gbé Ìgbésẹ̀

19. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ kó ipa pàtàkì nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Jèhófà?

19 Ìfẹ́ kì í ṣe ohun tuntun. Àbí, kí ló sún Jèhófà tó fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá? Kì í ṣe torí pé ó dá wà, tó wá ń wá ẹni kúnra. Jèhófà pé pérépéré, láìkù síbì kan, kò sì nílò ohunkóhun  látọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ rẹ̀, tó jẹ́ ànímọ́ tí ń súnni ṣiṣẹ́, ló sún un látọkànwá tó fi ṣàjọpín ayọ̀ wíwàláàyè pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá onílàákàyè tó lè gbádùn ẹ̀bùn ìwàláàyè. Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá” rẹ̀. (Ìṣípayá 3:14) Lẹ́yìn ìyẹn ni Jèhófà lo Àgbà Òṣìṣẹ́ rẹ̀ yìí láti ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan yòókù, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 38:4, 7; Kólósè 1:16) Níwọ̀n bí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára wọ̀nyí ti ní òmìnira, làákàyè àti ìmọ̀lára, wọ́n láǹfààní láti ní àjọṣe onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ara wọn lẹ́nì kìíní kejì, àti lékè gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 3:17) Nípa báyìí, wọ́n nífẹ̀ẹ́ nítorí pé a ti kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wọn.

20, 21. Ẹ̀rí wo ló ṣe kedere sí Ádámù àti Éfà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe hùwà padà?

20 Bẹ́ẹ̀ náà ló rí nínú ọ̀ràn ti ọmọ aráyé. Látìbẹ̀rẹ̀ pàá ni a ti fi ìfẹ́ tẹ́ Ádámù àti Éfà lọ́rùn. Ẹ̀rí pé Bàbá nífẹ̀ẹ́ wọn hàn ní gbogbo ibi tí wọ́n bá yíjú sí nínú Párádísè tí wọ́n ń gbé ní Édẹ́nì. Ohun tí Bíbélì sọ rèé: “Jèhófà Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì, síhà ìlà-oòrùn, ibẹ̀ ni ó sì fi ọkùnrin tí ó ti ṣẹ̀dá sí.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8) Ǹjẹ́ o ti wọnú ọgbà tó lẹ́wà gan-an rí? Kí ló wù ọ́ jù lọ? Ṣé ìmọ́lẹ̀ tó ń yọ láàárín ewé lábẹ́ àwọn ibòji ní kọ̀rọ̀ ibẹ̀ ni? Tàbí ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn òdòdó aláwọ̀ mèremère ni? Ṣé ìró omi tó ń dún bó ṣe ń ṣàn lọ àti orin àwọn ẹyẹ àtàwọn kòkòrò tí ń kùn yunmuyunmu ni? Òórùn dídùn tó ń wá láti ara igi àti èso àtàwọn òdòdó tó yọ yẹtuyẹtu ńkọ́? Bó ti wù kó rí, kò sí ọgbà kankan lónìí tó ṣeé fi wé ọgbà Édẹ́nì. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

21 Ìdí ni pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ló gbin ọgbà náà! Kódà, ó ti lọ wà jù. Gbogbo igi ẹlẹ́wà tàbí eléso adùnyùngbà ló wà níbẹ̀. Kò sí ọ̀dá omi nínú ọgbà náà, ọgbà tó sì fẹ̀ ni, ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn ẹranko tó fani mọ́ra sì wà níbẹ̀. Ádámù àti Éfà ní gbogbo nǹkan tó lè mú kí ayé wọ́n dùn, kí ayọ̀ wọ́n sì kún, títí kan iṣẹ́ tó dùn mọ́ni àti àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán. Jèhófà ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wọn, láìsí àní-àní ó sì yẹ káwọn náà fìfẹ́ hàn padà.  Àmọ́ wọn ò fìfẹ́ hàn padà. Dípò kí wọ́n fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣègbọràn sí Baba wọn ọ̀run, ṣe ni wọ́n fi ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ṣọ̀tẹ̀ sí i.—Jẹ́nẹ́sísì, orí 2.

22. Báwo ni ìṣarasíhùwà Jèhófà sí ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì ṣe fi hàn pé ìfẹ́ ìdúróṣinṣin ló ní?

22 Á mà dun Jèhófà o! Ṣùgbọ́n ṣé ìwà ọ̀tẹ̀ yìí wá lé ọkàn rẹ̀ tó kún fún ìfẹ́ lóró ni? Rárá o! “Inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ [tàbí, “ìfẹ́ ìdúróṣinṣin,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW] wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 136:1) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ ló ṣe ètò onífẹ̀ẹ́ fún ìràpadà ẹnikẹ́ni tó bá ní ọkàn títọ́ lára àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé, lára ètò yẹn ni ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, tó ná Baba ní ohun ńláǹlà.—1 Jòhánù 4:10.

23. Kí ni ọ̀kan lára ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ìbéèrè pàtàkì wo sì ni a ó sọ̀rọ̀ lé lórí ní àkòrí tó kàn?

23 Bẹ́ẹ̀ ni o, láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Jèhófà ti fúnra rẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti fìfẹ́ hàn sí ọmọ aráyé. Àìmọye ọ̀nà ló fi jẹ́ pé “òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” Ìfẹ́ ń fi kún ìṣọ̀kan àti ayọ̀. Abájọ tá a fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Àmọ́, ìbéèrè pàtàkì kan jẹ yọ wàyí. Ǹjẹ́ Jèhófà tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Àkòrí tó kàn yóò sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí.

^ ìpínrọ̀ 11 Ọ̀rọ̀ ìṣe náà phi·leʹo, tó túmọ̀ sí “láti ní ìfẹ́ni fún, tàbí láti fẹ́ràn (béèyàn ṣe ń fẹ́ràn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn tàbí béèyàn ṣe ń fẹ́ràn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni),” wọ́pọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ọ̀rọ̀ kan tó jẹ mọ́ stor·geʹ, ìyẹn ìfẹ́ láàárín ìdílé, la lò ní 2 Tímótì 3:3 láti fi hàn pé irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ á ṣọ̀wọ́n ní ọjọ́ ìkẹyìn. Eʹros, ìyẹn ìfẹ́ láàárín takọtabo, kò sí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, àmọ́ a sọ̀rọ̀ irú ìfẹ́ yẹn nínú Bíbélì.—Òwe 5:15-20.

^ ìpínrọ̀ 15 Àwọn gbólóhùn mìíràn nínú Ìwé Mímọ́ fara jọ èyí. Bí àpẹẹrẹ, “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀” àti “Ọlọ́run . . . jẹ́ iná tí ń jóni run.” (1 Jòhánù 1:5; Hébérù 12:29) Ṣùgbọ́n àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ni gbólóhùn wọ̀nyí, torí pé ṣe ni wọ́n fi Jèhófà wé àwọn ohun tó ṣeé fojú rí. Jèhófà dà bí ìmọ́lẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ àti adúróṣinṣin. Kò sí “òkùnkùn,” ìyẹn àìmọ́, nínú rẹ̀ rárá. A sì lè fi í wé iná nítorí bó ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti fi pa nǹkan run.