Nínú gbogbo ànímọ́ tí Jèhófà ní, ìfẹ́ ló gba iwájú. Òun ló sì fani mọ́ra jù lọ. Bí a ó ṣe máa gbé apá mélòó kan lára ànímọ́ tó dà bí ìṣúra iyebíye yìí yẹ̀ wò, á ó máa rí ìdí tí Bíbélì fi sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”—1 Jòhánù 4:8.