Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà Ọlọ́run

 Orí 13

“Òfin Jèhófà Pé”

“Òfin Jèhófà Pé”

1, 2. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi ka òfin sí, síbẹ̀ irú ìṣarasíhùwà wo ni àwa lè ní nípa àwọn òfin Ọlọ́run?

“ÒFIN jẹ́ òjìngbùn-jingbùn ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ tó . . . máa ń gbé ohun gbogbo mì gbùn-ún.” Inú ìwé kan tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 1712 lọ́hùn-ún lọ̀rọ̀ yìí ti wá. Ńṣe ni òǹkọ̀wé náà ń bẹnu àtẹ́ lu ètò òfin kan tó jẹ́ pé nígbà mìíràn ó máa ń sọ ẹjọ́ di ọ̀ràn wá-lónìí wá-lọ́la nílé ẹjọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, títí tí olùpẹ̀jọ́ á fi wọko gbèsè. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ètò òfin àti ètò ilé ẹjọ́ díjú gan-an, ó sì kún fún àìsí ìdájọ́ òdodo, ẹ̀tanú àti àìdúró lórí ìlànà kan pàtó tó bẹ́ẹ̀ tí àìbọ̀wọ̀ fún òfin fi kúkú wá gbòde kan.

2 Ní ìyàtọ̀ sí èyí, wo ọ̀rọ̀ kan tá a kọ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá [2,700] ọdún sẹ́yìn, ìyẹn: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” (Sáàmù 119:97) Kí nìdí tí òfin yẹn fi wu ẹni tó kọ sáàmù yìí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé òfin tó gbóríyìn fún yìí kò ti ọ̀dọ̀ ìjọba èèyàn kankan wá rárá, ọ̀dọ́ Jèhófà Ọlọ́run ló ti wá. Bí o bá ṣe ń kọ́ nípa àwọn òfin Jèhófà sí i, ìwọ pẹ̀lú lè dẹni tó túbọ̀ ń ní irú ẹ̀mí kan náà tí onísáàmù yìí ní. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kó o túbọ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ẹni tó mọ̀ nípa ètò ìdájọ́ jù lọ láyé àtọ̀run.

Afúnnilófin Gíga Jù Lọ

3, 4. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà fi hàn pé òun jẹ́ Afúnnilófin?

3 Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹnì kan ni ó wà tí ó jẹ́ afúnnilófin àti onídàájọ́.” (Jákọ́bù 4:12) Ká sòótọ́, Jèhófà nìkan ṣoṣo ló jẹ́ Afúnnilófin tòótọ́. Kódà “òfin ojú ọ̀run” tí ó gbé kalẹ̀ ló ń darí ìyípo àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run. (Jóòbù 38:33, The New Jerusalem Bible) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì mímọ́ tí Jèhófà ní lòfin Ọlọ́run ń darí bákan náà, nítorí gbogbo wọn la ṣètò sí ipò wọn lọ́wọ̀ọ̀wọ́, wọ́n sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ fún Jèhófà tó ń darí wọn.—Sáàmù 104:4; Hébérù 1:7, 14.

4 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà fún aráyé láwọn òfin pẹ̀lú. Olúkúlùkù wa  ló ní ẹ̀rí ọkàn, èyí tí í ṣe àwòṣe ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo tí Jèhófà ní. Níwọ̀n bí ẹ̀rí ọkàn ti ń ṣiṣẹ́ bí òfin tí ń bẹ nínú ẹni, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fìyàtọ̀ sí ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. (Róòmù 2:14) Ẹ̀rí ọkàn pípé ni Ọlọ́run dá mọ́ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ̀nba òfin díẹ̀ ni wọ́n nílò. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Àmọ́ èèyàn aláìpé nílò àwọn òfin tó pọ̀ ní tirẹ̀ kí wọ́n lè máa ṣamọ̀nà rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn baba ńlá ìgbàanì bíi Nóà, Ábúráhámù àti Jékọ́bù gba àwọn òfin látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n sì ṣàlàyé òfin wọ̀nyẹn fún ìdílé wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:22; 9:3-6; 18:19; 26:4, 5) Jèhófà sọ ara rẹ̀ di Afúnnilófin lọ́nà tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí nígbà tó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àkọsílẹ̀ Òfin kan nípasẹ̀ Mósè. Àkọsílẹ̀ òfin yìí sì jẹ́ ká túbọ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye gan-an nípa ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo tí Jèhófà ní.

Àkópọ̀ Òfin Mósè

5. Ṣé yaágbó-yaájù ẹrù, tí kò lójútùú, ni Òfin Mósè jẹ́, kí sì nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?

5 Ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń rò pé yaágbó-yaájù ẹrù ni Òfin Mósè jẹ́ àti pé òfin wọ̀nyẹn kò lójútùú. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò tọ̀nà rárá. Lóòótọ́, àpapọ̀ òfin tó wà nínú ìwé òfin yẹn ju ẹgbẹ̀ta lọ. Ìyẹn sì lè dà bíi pé ó pọ̀ lóòótọ́, ṣùgbọ́n ìwọ rò ó wò ná: Nígbà tó fi máa di January 1990, òfin tí ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìkan ní kún inú àwọn ìwé òfin tó jẹ́ ìdìpọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, tí ojú èwé rẹ̀ lápapọ̀ ju ọ̀kẹ́ mẹ́jọ [160,000] lọ. Bẹ́ẹ̀ láàárín 1990 sí September 1999 wọ́n tún gbé ọ̀tàdínlẹ́gbẹ́tà òfin mìíràn kalẹ̀ láfikún sí i! Nítorí náà, tá a bá ní ká sọ ti pípọ̀ òfin, òbítíbitì ẹrù ni òfin èèyàn jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òfin Mósè. Síbẹ̀, àní Òfin Ọlọ́run tún ń darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn ẹ̀ka ìgbésí ayé tó jẹ́ pé àwọn òfin òde òní ò tiẹ̀ tíì gbé yẹ̀ wò rárá. Jẹ́ ká wo àkópọ̀ Òfin Mósè ná.

6, 7. (a) Kí ló mú kí Òfin Mósè yàtọ̀ sí àkọsílẹ̀ òfin èyíkéyìí, èwo ló sì tóbi jù lọ nínú Òfin yẹn? (b) Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò ṣe fi hàn pé àwọn tẹ́wọ́ gba ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ?

6 Òfin Mósè gbé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ga. Nítorí náà, Òfin Mósè kì í ṣe ẹgbẹ́ àkọsílẹ̀ òfin èyíkéyìí rárá. Èyí tó tóbi  jù lọ nínú àwọn òfin rẹ̀ ni: “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni. Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run yóò ṣe fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Ó jẹ́ nípa sísìn ín, kí wọ́n sì máa tẹrí ba fún ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ.—Diutarónómì 6:4, 5; 11:13.

7 Olúkúlùkù ọmọ Ísírẹ́lì yóò fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ nígbà tó bá ti ń tẹrí ba fún àwọn tó wà nípò àṣẹ lórí rẹ̀. Lápapọ̀, àwọn òbí, ìjòyè, àlùfáà àti lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn ọba, ló jẹ́ aṣojú àṣẹ Ọlọ́run nígbà yẹn. Jèhófà sì ka ṣíṣàtakò sáwọn tó wà nípò àṣẹ gẹ́gẹ́ bí àtakò sóun fúnra rẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, àwọn tó wà nípò àṣẹ pẹ̀lú yóò rí ìbínú Jèhófà bí wọ́n bá hùwà àdàkàdekè sí àwọn èèyàn rẹ̀ tàbí pé wọ́n fọwọ́ ọlá gbá wọn lójú. (Ẹ́kísódù 20:12; 22:28; Diutarónómì 1:16, 17; 17:8-20; 19:16, 17) Nípa bẹ́ẹ̀ tọ̀tún tòsì wọn ló ní láti gbé ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lárugẹ.

8. Báwo ni Òfin Mósè ṣe gbé ìlànà ìjẹ́mímọ́ Jèhófà lárugẹ?

8 Òfin Mósè gbé ìlànà ìjẹ́mímọ́ Jèhófà lárugẹ. Ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” àti “ìjẹ́mímọ́” fara hàn níye ìgbà tó ju ọ̀rìnlérúgba [280] lọ nínú Òfin Mósè. Òfin Mósè mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun mímọ́ àti àìmọ́, ó tọ́ka sí àádọ́rin onírúurú nǹkan tó lè sọ ọmọ Ísírẹ́lì kan di aláìmọ́ lójú ìlànà ìsìn. Àwọn òfin wọ̀nyí mẹ́nu kan ìmọ́tótó tara ẹni, ti oúnjẹ àti bíbo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀ pàápàá. Irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní fún ìlera gan-an ni. * Ṣùgbọ́n ète tó ga jù bẹ́ẹ̀ lọ ló wà fún, ìyẹn ni láti mú kí àwọn èèyàn náà máa ṣe ohun tí yóò mú wọn máa rójú rere Jèhófà, kí wọ́n sì ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú ìṣe àwọn orílẹ̀-èdè oníwà ìbàjẹ́ tó yí wọn ká. Wo àpẹẹrẹ kan.

9, 10. Àwọn ìlànà wo nípa ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí ló wà nínú májẹ̀mú Òfin, àǹfààní wo sì ni irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀ ń ṣe?

 9 Àwọn ìlànà inú májẹ̀mú Òfin sọ pé ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí, àní láàárín tọkọtaya pàápàá, ń sọni di aláìmọ́ fún àkókò kan. (Léfítíkù 12:2-4; 15:16-18) Àwọn ìlànà yìí kò bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ẹ̀bùn mímọ́ yìí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:18-25) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni òfin wọ̀nyẹn ń gbé ìjẹ́mímọ́ Jèhófà lárugẹ nípa mímú kí àwọn olùjọsìn wọ̀nyẹn má ṣe di ẹni tá a sọ deléèérí. Ó yẹ fún àfiyèsí pé ńṣe làwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká sábà máa ń fi ìbálòpọ̀ àti ìbímọlémọ kún ara ààtò ìjọsìn wọn. Kí ọkùnrin àti obìnrin máa ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó wà lára ìjọsìn àwọn ará Kénáánì. Èyí fa ìwà ìbàjẹ́ tó burú jù lọ, ìwà yìí sì gbilẹ̀. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, ńṣe ni Òfin Mósè ya ìjọsìn Jèhófà sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀. * Àǹfààní mìíràn tún wà nínú Òfin yìí pẹ̀lú.

10 Àwọn òfin yẹn tún jẹ́ ọ̀nà kan láti kọ́ wọn ní kókó pàtàkì kan. * Àbí, ọ̀nà wo ni ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù gbà ń ti ara ìran kan dé òmíràn? Nípasẹ̀ ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí ha kọ́? (Róòmù 5:12) Ó dájú pé ńṣe ni Òfin Ọlọ́run ń rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé inú ayé ẹ̀ṣẹ̀ là ń gbé. Òótọ́ sì ni, gbogbo wa ni a bí nínú ẹ̀ṣẹ̀. (Sáàmù 51:5) A nílò ìdáríjì àti ìràpadà kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Ọlọ́run wa mímọ́.

11, 12. (a) Ìlànà ìdájọ́ pàtàkì wo ni Òfin Mósè tẹnu mọ́? (b) Àwọn nǹkan wo ni Òfin Mósè sọ pé ó yẹ ní ṣíṣe kí ìṣègbè nínú ìdájọ́ má bàa wáyé?

11 Òfin Mósè gbé ìdájọ́ òdodo pípé ti Jèhófà lárugẹ. Òfin Mósè tẹnu mọ́ ìlànà ìṣedéédéé tàbí ìbáradọ́gba nínú ọ̀ràn ìdájọ́. Ìyẹn ni Òfin fi sọ pé: “Ọkàn fún ọkàn, ojú fún ojú, eyín fún eyín,  ọwọ́ fún ọwọ́, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀.” (Diutarónómì 19:21) Nípa bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá máa dá ọ̀daràn lẹ́jọ́, ìyà tó ṣe déédéé ẹ̀ṣẹ̀ onítọ̀hún ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi jẹ ẹ́. Ìlànà ìdájọ́ tí Ọlọ́run là sílẹ̀ yìí kó ipa pàtàkì jálẹ̀ Òfin Mósè. Títí dòní, ó jẹ́ nǹkan pàtàkì tó lè múni lóye ìdí tá a fi nílò ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù, gẹ́gẹ́ bí Orí 14 yóò ṣe fi hàn.—1 Tímótì 2:5, 6.

12 Òfin Mósè tún sọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe kí ìṣègbè nínú ìdájọ́ má bàa wáyé. Bí àpẹẹrẹ, ó kéré tán ẹlẹ́rìí méjì ní láti wà kí á tó lè gbà pé ẹ̀sùn kan jóòótọ́. Ìyà ńlá ní ń bẹ fún ẹlẹ́rìí èké àti ìbúra èké. (Diutarónómì 19:15, 18, 19) Òfin sì ka ìwà ìbàjẹ́ àti àbẹ̀tẹ́lẹ̀ léèwọ̀ pátápátá. (Ẹ́kísódù 23:8; Diutarónómì 27:25) Kódà nínú òwò ṣíṣe pàápàá, àwọn èèyàn Ọlọ́run ní láti tẹ̀ lé ìlànà ìdájọ́ òdodo gíga tí Jèhófà ní. (Léfítíkù 19:35, 36; Diutarónómì 23:19, 20) Áà, ìbùkún ńláǹlà ni àkọsílẹ̀ òfin dáadáa, tó bá ìdájọ́ òdodo mu yìí jẹ́ fún Ísírẹ́lì!

Òfin Tó Tẹnu Mọ́ Lílo Àánú àti Àìṣojúsàájú Nínú Ìdájọ́

13, 14. Báwo ni Òfin Mósè ṣe mú kí olè àti ẹni tá a jà lólè rí ìdájọ́ tó tọ́ gbà láìsí ìṣègbè?

13 Ṣé àkójọ òfin tó le koko, tí kò fàyè sílẹ̀ fún àánú rárá ni Òfin Mósè jẹ́ ni? Rárá o! Ọlọ́run mí sí Dáfídì Ọba láti kọ̀wé pé: “Òfin Jèhófà pé.” (Sáàmù 19:7) Ohun tóun náà mọ̀ dájú ni, pé Òfin Mósè tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ àánú ṣíṣe àti àìṣègbè. Ọ̀nà wo ni Òfin yẹn gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

14 Ní àwọn ilẹ̀ kan lóde òní, ó jọ pé àwọn ọ̀daràn ń rí àánú àti ojú rere gbà lábẹ́ òfin ju ẹni tí wọ́n ṣe ní jàǹbá lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ju olè sẹ́wọ̀n fúngbà pípẹ́. Àmọ́ láàárín àkókò yẹn, ẹni tí wọ́n jà lólè lè máà tíì rí ẹrù rẹ̀ tí wọ́n jí gbà, síbẹ̀ ó tún gbọ́dọ̀ máa san owó orí tí wọn yóò tún máa lò láti fi bójú tó ọgbà ẹ̀wọ̀n tí olè yẹn wà àti oúnjẹ tí ó ń jẹ. Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, kò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní bá a ṣe mọ̀ ọ́n lónìí. Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ kò gbọ́dọ̀ ré kọjá ohun tí òfin ti là sílẹ̀. (Diutarónómì 25:1-3) Olè gbọ́dọ̀ san àsanfidípò fún ẹni tó jà lólè. Láfikún sí i, olè yìí yóò ní láti tún san ìtanràn  mìíràn pẹ̀lú. Èló ni yóò san? Iye rẹ̀ máa ń yàtọ̀ síra. Ó jọ pé a fún àwọn onídàájọ́ láyè láti gbé onírúurú nǹkan yẹ̀ wò ná, irú bíi bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ ọ̀hún ronú pìwà dà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìyẹn ni yóò jẹ́ ìdí tí ìtanràn tí Léfítíkù 6:1-7 sọ pé olè yóò san fi kéré gan-an sí èyí tí Ẹ́kísódù 22:7 mẹ́nu kàn.

15. Báwo ni Òfin Mósè ṣe mú kí àánú àti ìdájọ́ òdodo lè wáyé nínú ọ̀ràn ẹni tó bá ṣèèṣì pànìyàn?

15 Òfin Mósè fi àánú hàn, ó gbà pé kì í ṣe gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ló jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀dá. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá ṣèèṣì pànìyàn, kì í ṣe dandan ni pé yóò fi ọkàn dípò ọkàn tó bá ti gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́ nípa sísá lọ sí ọkàn nínú àwọn ìlú ńlá ìsádi tó wà káàkiri ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Bí àwọn onídàájọ́ tó tóótun bá sì gbé ẹjọ́ rẹ̀ yẹ̀ wò tán, ó ní láti máa gbé nínú ìlú ńlá ìsádi títí àlùfáà àgbà á fi kú. Lẹ́yìn ikú àlùfáà yìí, ó lè lọ gbé níbikíbi tó bá wù ú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó jàǹfààní àánú Ọlọ́run. Lẹ́sẹ̀ kan náà, òfin yìí fi hàn gbangba pé ẹ̀mí èèyàn ṣe pàtàkì gan-an ni.—Númérì 15:30, 31; 35:12-25.

16. Báwo ni Òfin Mósè ṣe dáàbò bo àwọn ẹ̀tọ́ ẹni kan?

16 Òfin Mósè dáàbò bo ẹ̀tọ́ ẹni. Wo àwọn ọ̀nà tó gbà dáàbò bo ẹni tó bá jẹ gbèsè ná. Òfin yìí sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wọnú ilé ẹni tó jẹ gbèsè lọ láti fi túláàsì gbé ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìdógò fún gbèsè tó jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìta ni oní-ǹkan yóò dúró sí, yóò jẹ́ kí ẹni tó jẹ gbèsè fúnra rẹ̀ mú ohun tí yóò fi dógò jáde wá fún un. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ já wọlé ọmọnìkejì rẹ̀. Bí oní-ǹkan bá gba àwọ̀lékè ajigbèsè lọ́rùn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò, ó ní láti dá a padà lálẹ́, nítorí ó ṣeé ṣe kí ajigbèsè náà fẹ́ fi bora sùn lóru.—Diutarónómì 24:10-14.

17, 18. Ní ti ọ̀ràn ogun jíjà, báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí sì nìdí tí wọ́n fi yàtọ̀?

17 Kódà ogun jíjà ní ìlànà lábẹ́ Òfin Mósè. Ogun tí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa jà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ nítorí pé agbára ń gùn wọ́n tàbí láti kàn máa jagun-ṣẹ́gun káàkiri. Ìgbà tí Ọlọ́run bá fẹ́ lò wọ́n láti ja “Àwọn Ogun Jèhófà” nìkan ni wọ́n lè jagun. (Númérì 21:14) Lọ́pọ̀ ìgbà pàápàá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti kọ́kọ́ fún àwọn wọ̀nyẹn láyè láti juwọ́ sílẹ̀, wọ́n á sì sọ ohun tí wọ́n  máa ṣe fún wọn. Ìgbà tí ìlú náà bá kọ̀ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lè dó tì í, wọ́n sì ní láti ṣe é níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run. A ò gba àwọn ọkùnrin inú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì láyè láti máa fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀ tàbí kí wọ́n kàn bẹ̀rẹ̀ sí pani nípakúpa, èyí tó yàtọ̀ sí ìwà àwọn ọmọ ogun yòókù láyé. Kódà wọ́n ní láti ṣe ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn jẹ́jẹ́ nípa ṣíṣàì gé àwọn igi eléso wọn dà nù. * Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ yòókù ò ní irú ìkálọ́wọ́kò wọ̀nyí rárá.—Diutarónómì 20:10-15, 19, 20; 21:10-13.

18 Ǹjẹ́ kì í bà ọ́ nínú jẹ́ láti gbọ́ pé wọ́n ń kọ́ àwọn màjèṣín lásán làsàn ní iṣẹ́ ogun jíjà láwọn orílẹ̀-èdè kan? Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, bí ọkùnrin kò bá tí ì pé ọmọ ogún ọdún a kì í gbà á sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun. (Númérì 1:2, 3) Kódà bí ẹ̀rù bá ń ba géńdé ọkùnrin jù pàápàá, a ó yọ ọ́ kúrò. Ẹni tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó kò ní lọ sógun fún ọdún kan gbáko. Onítọ̀hún yóò lè fi ìyẹn ní àrólé kó tó lọ tọrùn bọ irú iṣẹ́ eléwu bẹ́ẹ̀. Òfin Mósè sọ pé lọ́nà bẹ́ẹ̀, ọkọ ìyàwó ọ̀ṣìngín yìí á lè mú kí aya rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ “máa yọ̀.”—Diutarónómì 20:5, 6, 8; 24:5.

19. Kí làwọn nǹkan tó wà nínú Òfin Mósè fún ààbò àwọn obìnrin, ọmọdé, ìdílé, opó àtàwọn ọmọ òrukàn?

19 Òfin Mósè tún dáàbò bo àwọn obìnrin, ọmọdé àtàwọn ìdílé nípa pé ó bójú tó ọ̀ràn wọn. Ó pa á láṣẹ pé káwọn òbí máa fún àwọn ọmọ wọn láfiyèsí lemọ́lemọ́, kí wọ́n sì máa fún wọn nítọ̀ọ́ni nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Diutarónómì 6:6, 7) Ó ka gbogbo ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ìbátan léèwọ̀, ó ní kí wọ́n pa àwọn tó bá lọ́wọ́ nínú rẹ̀. (Léfítíkù, orí 18) Bákan náà ló tún ka panṣágà, tó jẹ́ pé ó sábà máa ń fọ́ ìdílé, tó sì ń ba ìbàlẹ̀-ọkàn àti iyì ìdílé jẹ́, léèwọ̀. Òfin Mósè bójú tó ọ̀ràn àwọn opó àti ọmọ òrukàn, ó sì sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ wọ́n.—Ẹ́kísódù 20:14; 22:22-24.

20, 21. (a) Kí nìdí tí Òfin Mósè fi fàyè gba ìkóbìnrinjọ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (b) Ní ti ọ̀ràn ìkọ̀sílẹ̀, kí nìdí tí Òfin Mósè fi yàtọ̀ sí ìlànà tí Jésù dá padà nígbà tó yá?

 20 Níwọ̀n bí àwọn ìpèsè yìí ti wà, àwọn kan lè máa rò ó lọ́kàn pé, ‘Kí wá nìdí tí Òfin Mósè fi fàyè gba ìkóbìnrinjọ?’ (Diutarónómì 21:15-17) Ó yẹ ká kọ́kọ́ wo ohun tó ń lọ láyé ìgbà yẹn kó tó di pé irú àwọn òfin yẹn wáyé. Àwọn tó bá ń fojú ohun tó ń lọ láyé ìsinsìnyí àti àṣà òde òní díwọ̀n Òfin Mósè yóò ṣi Òfin yẹn lóye dájúdájú. (Òwe 18:13) Ìlànà tí Jèhófà ti là sílẹ̀ láti Édẹ́nì lọ́hùn-ún wá ni pé kí ìgbéyàwó jẹ́ ìsopọ̀ títí ayé láàárín ọkùnrin kan ṣoṣo àti obìnrin kan ṣoṣo. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 20-24) Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà fi máa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Mósè, àwọn ìwà bí ìkóbìnrinjọ ti fìdí múlẹ̀ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú. Jèhófà sì mọ̀ dájú pé àwọn “ọlọ́rùn-líle ènìyàn” yẹn yóò tiẹ̀ máa rú àwọn òfin tó ṣe pàtàkì jù lọ, irú bí àwọn tó ka ìbọ̀rìṣà léèwọ̀ pàápàá. (Ẹ́kísódù 32:9) Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, Jèhófà ò fi ìgbà yẹn ṣe àkókò tí yóò ṣàtúnṣe sí gbogbo àṣàkaṣà tó wọnú ọ̀ràn ìgbéyàwó. Àmọ́ ṣá o, mọ̀ dájú pé Jèhófà kọ́ ló dá ìkóbìnrinjọ sílẹ̀ o. Ṣùgbọ́n, ó lo Òfin Mósè láti fi bójú tó àṣà ìkóbìnrinjọ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, àti láti fi dènà àṣìlò rẹ̀.

21 Bákan náà, Òfin Mósè gbà kí ọkùnrin kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí onírúurú ẹ̀sùn tó rinlẹ̀. (Diutarónómì 24:1-4) Jésù sọ pé ńṣe ni Ọlọ́run kàn yọ̀ǹda èyí fún àwọn Júù “ní tìtorí líle-ọkàn” wọn. Àmọ́ ìyọ̀ǹda yìí kàn wà fúngbà díẹ̀ ni. Jésù dá ìlànà tí Jèhófà fi lélẹ̀ fún ìgbéyàwó ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ padà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Mátíù 19:8.

Òfin Mósè Gbé Ìfẹ́ Lárugẹ

22. Àwọn ọ̀nà wo ni Òfin Mósè gbà fúnni níṣìírí láti máa lo ìfẹ́, ta ni wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa lò ó sí?

22 Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ìgbésí ayé ṣe máa rí lábẹ́ ètò òfin òde òní kan tó ń fúnni níṣìírí láti lo ìfẹ́? Òfin Mósè gbé ìfẹ́ lárugẹ ju ohunkóhun mìíràn lọ. Àní, nínú ìwé Diutarónómì nìkan, ó ju ogún ìgbà lọ tí ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” ti fara hàn lónírúurú  ọ̀nà. “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ” ni òfin kejì tó ga jù lọ nínú Òfin Mósè. (Léfítíkù 19:18; Mátíù 22:37-40) Kì í ṣe àwọn èèyàn wọn nìkan làwọn èèyàn Ọlọ́run ní láti ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sí o, ó tún kan àwọn àtìpó tí ń bẹ láàárín wọn pẹ̀lú, nítorí wọ́n ní láti rántí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú jẹ́ àtìpó nígbà kan rí. Wọ́n ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìní àtàwọn ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, kí wọ́n fi ohun ìní ṣèrànwọ́ fún wọn, kí wọ́n má sì tìtorí pé wọ́n wà nínú ìpọ́njú rẹ́ wọn jẹ. Òfin tiẹ̀ ní kí wọ́n ṣe inúure sí àwọn ẹranko arẹrù wọn, kí wọ́n sì gba tiwọn rò.—Ẹ́kísódù 23:6; Léfítíkù 19:14, 33, 34; Diutarónómì 22:4, 10; 24:17, 18.

23. Kí ni a sún ẹni tó kọ Sáàmù 119 láti ṣe, kí ni àwa náà lè pinnu láti ṣe?

23 Ó ṣòro ká tó tún rí orílẹ̀-èdè tá a pèsè irú àkọsílẹ̀ òfin bẹ́ẹ̀ fún, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Abájọ tí onísáàmù fi kọ̀wé pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” Fífẹ́ tó fẹ́ràn òfin yìí kì í ṣe ti ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Nítorí èyí sún un láti ṣe nǹkan kan, ó mú kó sapá láti pa á mọ́, láti máa tẹ̀ lé e nígbèésí ayé rẹ̀. Ó sọ síwájú sí i pé: “Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 119:11, 97) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òfin Jèhófà déédéé. Kò sí àní-àní pé bó ṣe ń kọ́ ọ tó ló ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìfẹ́ tó ní sí Afúnnilófin náà, Jèhófà Ọlọ́run, túbọ̀ ń ga sí i pẹ̀lú. Bó o ṣe ń bá a lọ láti kọ́ òfin Ọlọ́run, ǹjẹ́ kí ìwọ náà dẹni tó túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, Afúnnilófin Ńlá àti Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo.

^ ìpínrọ̀ 8 Bí àpẹẹrẹ, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jàǹfààní òfin tó sọ nípa bíbo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀, sísé alárùn mọ́ àti pé kí ẹni tó bá fọwọ́ kan òkú rí i pé òun wẹ̀, làwọn orílẹ̀-èdè yòókù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé ó dára kí àwọn náà fi sínú òfin tiwọn.—Léfítíkù 13:4-8; Númérì 19:11-13, 17-19; Diutarónómì 23:13, 14.

^ ìpínrọ̀ 9 Nígbà tó jẹ́ pé àwọn ará Kénáánì máa ń ya àwọn yàrá kan sọ́tọ̀ fún ìbálòpọ̀ nínú tẹ́ńpìlì wọn, Òfin Mósè sọ pé àwọn tó bá wà nípò àìmọ́ ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ wọnú tẹ́ńpìlì rárá. Níwọ̀n bí ìbálòpọ̀ sì tí máa ń sọni di aláìmọ́ fún àkókò kan, ohun àìbófinmu ló máa jẹ́ fún ẹnikẹ́ni láti fi ìbálòpọ̀ kún ààtò ìjọsìn nínú ilé Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 10 Ohun pàtàkì kan tí Òfin wà fún ni láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ní ti gidi, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé ọ̀rọ̀ náà toh·rah tí wọ́n ń pe “òfin” lédè Hébérù túmọ̀ sí “ìtọ́ni.”

^ ìpínrọ̀ 17 Òfin Mósè tiẹ̀ béèrè pé: “Ṣé ènìyàn ni igi pápá jẹ́ tí ìwọ yóò fi sàga tì í?” (Diutarónómì 20:19) Philo ọmọ Júù tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní tọ́ka sí òfin yìí, ó wá ṣàlàyé pé Ọlọ́run kà á sí pé ó jẹ́ “ìwà àìtọ́ láti torí pé à ń bínú èèyàn lọ máa ba àwọn ohun tí kò lè hùwà ibi jẹ́.”