Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Orí 15

Jésù “Gbé Ìdájọ́ Òdodo Kalẹ̀ ní Ilẹ̀ Ayé”

Jésù “Gbé Ìdájọ́ Òdodo Kalẹ̀ ní Ilẹ̀ Ayé”

1, 2. Ìgbà wo ni Jésù bínú, kí sì nìdí rẹ̀?

Ó HÀN pé Jésù bínú gidigidi, ìbínú yẹn sì tọ́. Ó lè ṣòro fún ọ láti gbà pé ó lè ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé ọlọ́kàn tútù bíi tirẹ̀ ṣọ̀wọ́n. (Mátíù 21:5) Àmọ́, kò bínú sódì ṣá o torí pé ìbínú òdodo ni inú tó bí. * Ṣùgbọ́n kí ló tiẹ̀ múnú bí ọkùnrin olùfẹ́ àlàáfíà yìí ná? Ìwà ìrẹ́jẹ tó burú jáì kan ló fà á.

2 Jésù fẹ́ràn tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù gan-an ni. Ní gbogbo ayé ìgbà yẹn, ibẹ̀ nìkan ló jẹ́ ibi ọlọ́wọ̀ tá a yà sí mímọ́ fún ìjọsìn Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Àwọn Júù máa ń ti àwọn ilẹ̀ jíjìn réré wá láti wá jọ́sìn níbẹ̀. Kódà àwọn Kèfèrí tí wọ́n ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn máa ń wá síbẹ̀, wọ́n á dúró níbi àgbàlá tẹ́ńpìlì tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn láti máa lò. Ṣùgbọ́n nígbà ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó wá sínú tẹ́ńpìlì, ó sì rí àwọn nǹkan kan tó kó o nírìíra gan-an. Ibẹ̀ ò dà bí ilé ìjọsìn rárá, àfi bí ẹní wà láàárín ọjà! Ṣe làwọn oníṣòwò àtàwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó kún ibẹ̀ fọ́fọ́. Èwo wá ni ìwà ìrẹ́jẹ nínú ìyẹn? Òun ni pé, àwọn wọ̀nyí kò wá nǹkan méjì wá sí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ju pé kí wọ́n wá kó àwọn èèyàn nífà kí wọ́n sì jà wọ́n lólè bó bá ṣeé ṣe. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?—Jòhánù 2:14.

3, 4. Ìwà ìrẹ́jẹ tó kún fún ìwọra wo ló ń wáyé nínú ilé Jèhófà, kí sì ni Jésù ṣe nípa ọ̀ràn náà?

3 Àwọn aṣáájú ìsìn pàṣẹ pé kìkì oríṣi owó ẹyọ kan pàtó ni káwọn èèyàn máa fi san owó orí ní tẹ́ńpìlì. Nítorí náà, àwọn tó bá wá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ ní láti ṣe pàṣípààrọ̀ owó wọn kí wọ́n tó lè rí irú owó ẹyọ bẹ́ẹ̀. Ìyẹn làwọn tó ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó fi kúkú  gbé tábìlì kalẹ̀ sínú tẹ́ńpìlì gan-an, wọ́n wá fibẹ̀ ṣe ìsọ̀, wọ́n sì ń gbowó lórí pàṣípààrọ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá ṣe fáwọn èèyàn. Èrè rẹpẹtẹ ni wọ́n tún ń jẹ nídìí ẹran ọ̀sìn títà. Kì í ṣe pé àwọn tó bá fẹ́ rúbọ lára àwọn tó wá ṣèbẹ̀wò ò lè rí ẹran rà lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò ní ìgboro, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì lè kọ̀ ọ́ pé kò ṣeé fi rúbọ. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ inú tẹ́ńpìlì níbẹ̀ ni wọ́n ti rà á, ó ti dájú pé wọ́n á tẹ́wọ́ gbà á. Nígbà táwọn oníṣòwò yìí sì ti mọ̀ pé àwọn èèyàn ò lè rí ibòmíràn lọ yàtọ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn, ọ̀wọ́n gógó ni wọ́n ń ta ọjà wọn. * Èyí wá burú ju tàwọn oníṣòwò afánilórí lọ. Olè jíjà ni ká kúkú pè é!

“Ẹ kó nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín!”

4 Jésù ò lè fara mọ́ irú ìrẹ́jẹ bẹ́ẹ̀. Inú ilé Baba rẹ̀ mà rèé! Ká má rí i! Ló bá fi okùn ṣe pàṣán, ó fi lé agbo màlúù àti àgùntàn wọn jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Ó wá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó, ó sì yí tábìlì wọn dà nù. O lè fojú inú wo bí owó ẹyọ wọn ṣe máa fọ́n káàkiri orí ilẹ̀ tí wọ́n fi mábìlì tẹ́ yẹn! Bẹ́ẹ̀ náà ló ń gbójú mọ́ àwọn tó ń ta àdàbà wọ̀nyẹn pé: “Ẹ kó nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín!” (Jòhánù 2:15, 16) Ó dà bíi pé kò sẹ́ni tó jẹ́ ta ko Jésù ọkùnrin onígboyà yìí.

“Ẹní Bíni Làá Jọ”

5-7. (a) Báwo ni ìgbé ayé Jésù ṣáájú kó tó wá sáyé ṣe nípa lórí òye ìdájọ́ òdodo tó ní, kí la sì lè jèrè látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú àpẹẹrẹ tirẹ̀? (b) Báwo ni Kristi ṣe gbógun ti ìwà ìrẹ́jẹ tí Sátánì ti hù sí orúkọ Jèhófà àti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ?

5 Àwọn oníṣòwò yẹn tún padà síbẹ̀ ṣá o. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, Jésù tún gbé ìgbésẹ̀ lórí ìwà ìrẹ́jẹ kan náà yìí, àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ fi bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó sọ ilé Rẹ̀ di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà” ló fà yọ lọ́tẹ̀ yìí. (Mátíù 21:13; Jeremáyà 7:11) Ní ti tòótọ́, nígbà tí Jésù rí bí wọ́n ṣe ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ  àti bí wọ́n ṣe sọ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run di àìmọ́, ó ta á lára gẹ́lẹ́ bó ṣe ń ta Baba rẹ̀ lára. Kò gbọ́dọ̀ yà wá lẹ́nu! Ṣe bí ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún ni Jésù fi gbẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ ọ̀run. Nípa bẹ́ẹ̀, òye ìdájọ́ òdodo Jèhófà kún ọkàn rẹ̀ bámúbámú. A lè rí i pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ pé, “Ẹní bíni làá jọ,” bá Jésù mu gan-an. Nítorí náà, bí a bá fẹ́ kí òye ànímọ́ ìdájọ́ òdodo Jèhófà yé wa kedere, ọ̀nà tó dára jù ni pé ká máa ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ ti Jésù Kristi.—Jòhánù 14:9, 10.

6 Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà wà níbẹ̀ nígbà tí Sátánì ṣàyà gbàǹgbà pe Jèhófà Ọlọ́run ní òpùrọ́, tó tún ṣàríwísí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣàkóso. Áà, ìbanilórúkọjẹ́ yìí pọ̀! Ọmọ yìí tún gbọ́ ìpèníjà Sátánì pé kò sí ẹnikẹ́ni tó kàn lè máa sin Jèhófà nítorí ìfẹ́, bí kò ṣe nítorí ìmọtara-ẹni-nìkan. Dájúdájú ẹ̀sùn èké wọ̀nyí ba Ọmọ tó lẹ́mìí òdodo yìí lọ́kàn jẹ́ gan-an ni. Inú rẹ̀ á mà dùn o nígbà tó mọ̀ pé òun lòun máa ṣe akọgun àwọn tó máa jádìí gbogbo irọ́ yẹn tí wọ́n á sì tún ohun tó ti bà jẹ́ ṣe! (2 Kọ́ríńtì 1:20) Báwo ló ṣe máa ṣe é?

7 Bí a ṣe rí i kọ́ ní Orí 14, Jésù Kristi pèsè paríparì ìdáhùn sí gbogbo ẹ̀sùn tí Sátánì kà sílẹ̀ láti fi tàbùkù ìwà títọ́ gbogbo ìṣẹ̀dá Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ pé Jésù fi ìpìlẹ̀ bí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ yóò ṣe di èyí tá a dá láre, tí orúkọ Rẹ̀ yóò sì di èyí tá a sọ di mímọ́ lélẹ̀. Jésù tó jẹ́ Olórí Aṣojú Jèhófà, ni yóò fìdí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run múlẹ̀ kárí ayé àtọ̀run. (Ìṣe 5:31) Ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú gbé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run yọ. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Jèhófà sọ, pé: “Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sórí rẹ̀, ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ni yóò sì mú ṣe kedere fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 12:18) Báwo ni Jésù ṣe mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣẹ?

Jésù Mú Kí “Ohun Tí Ìdájọ́ Òdodo Jẹ́” Ṣe Kedere

8-10. (a) Báwo ni àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn máa tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí kì í ṣe Júù àtàwọn obìnrin? (b) Ọ̀nà wo ni àwọn òfin àtẹnudẹ́nu gbà sọ òfin Sábáàtì tí Jèhófà fi lélẹ̀ di ẹrù ìnira?

8 Jésù fẹ́ràn Òfin Jèhófà, ó sì tẹ̀ lé e nígbèésí ayé rẹ̀. Ṣùgbọ́n  ńṣe làwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ yí òfin yẹn padà, wọ́n sì túmọ̀ Òfin yẹn sódì. Ni Jésù bá sọ fún wọn pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! . . . Ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.” (Mátíù 23:23) Dájúdájú, àwọn olùkọ́ni ní Òfin Ọlọ́run wọ̀nyẹn kò fi “ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́” hàn kedere. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń bo ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run mọ́lẹ̀. Lọ́nà wo? Wo àpẹẹrẹ mélòó kan.

9 Ìtọ́ni tí Jèhófà kàn fún àwọn èèyàn rẹ̀ ni pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. (1 Àwọn Ọba 11:1, 2) Ṣùgbọ́n, àwọn aṣáájú ìsìn aláṣejù kúkú rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa wo gbogbo àwọn tí kì í ṣe Júù tìkà-tẹ̀gbin. Ìwé Mishnah tiẹ̀ pàṣẹ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ẹran ọ̀sìn yín sílẹ̀ sínú ibùwọ̀ àwọn kèfèrí nítorí ìwà abẹ́rankolòpọ̀ kì í jìnnà sí wọn.” Ìwà ẹ̀tanú tí wọ́n ń hù sí gbogbo ẹni tí kì í ṣe Júù yìí kò bójú mu rárá ni, ó sì lòdì sí ẹ̀mí tí Òfin Mósè fẹ́ gbìn sí wọn lọ́kàn. (Léfítíkù 19:34) Àwọn òfin àtọwọ́dá mìíràn tí wọ́n gbé kalẹ̀ tàbùkù àwọn obìnrin. Òfin àtẹnudẹ́nu sọ pé aya ò gbọ́dọ̀ rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀, ńṣe ni kó máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Wọ́n kìlọ̀ fáwọn ọkùnrin pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá obìnrin sọ̀rọ̀ níta gbangba, àní títí kan aya wọn pàápàá. Wọn ò gba àwọn obìnrin láyè láti jẹ́ ẹlẹ́rìí ọ̀rọ̀ nílé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí wọn ò ṣe gbà ẹrú láyè. Àní àkànṣe àdúrà kan tiẹ̀ wà táwọn ọkùnrin máa fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé àwọn kì í ṣe obìnrin.

10 Àwọn aṣáájú ìsìn rọ́ àwọn òfin àti ìlànà àtọwọ́dá bo Òfin Ọlọ́run mọ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí òfin Sábáàtì kàn wí ni pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ya ọjọ́ yẹn sọ́tọ̀ pé kí wọ́n máa fi ṣe ìjọsìn, kí wọ́n fi gba ìtura tẹ̀mí, kí wọ́n sì fi sinmi. Ṣùgbọ́n àwọn Farisí lọ sọ òfin yẹn di ẹrù ìnira. Wọ́n fúnra wọn ń pinnu ohun tó para pọ̀ jẹ́ “iṣẹ́” tí ibí yìí ń wí. Wọ́n wá pín ìgbòkègbodò tí wọ́n kà sí iṣẹ́ sí ìsọ̀rí mọ́kàndínlógójì, irú bíi ká sọ pé kíkórè àti ṣíṣọdẹ. Pípín tí wọ́n pín in sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí yìí wá ń fa onírúurú ìbéèrè tí kò lópin. Bí àpẹẹrẹ, béèyàn  bá pa iná orí kan ṣoṣo lọ́jọ́ Sábáàtì, ǹjẹ́ ó ṣọdẹ àbí kò ṣọdẹ? Bó bá fọwọ́ já hóró ọkà mélòó kan sẹ́nu tó sì ń jẹ ẹ́ bó ṣe ń rìn lọ ńkọ́, ṣé ó kórè ni, àbí kò kórè? Bó bá rí aláìsàn tó sì wò ó sàn, ǹjẹ́ iṣẹ́ ló ń ṣe yẹn? Gbogbo irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òfin mìíràn tí kò ní àgbéyí kankan ṣàlàyé.

11, 12. Báwo ni Jésù ṣe gbéjà ko àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Farisí tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu?

11 Lábẹ́ irú àwọn ipò báyìí, báwo ni Jésù yóò ṣe mú kí àwọn èèyàn mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́? Ó fìgboyà ta ko àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn nínú àwọn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni àti ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Kọ́kọ́ wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó fi kọ́ni ná. Tààràtà ló bẹnu àtẹ́ lu ẹgbàágbèje òfin àtọwọ́dá tí wọ́n tò kalẹ̀, ó ní: “Ẹ . . . sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín tí ẹ fi léni lọ́wọ́.”—Máàkù 7:13.

12 Jésù kọ́ àwọn èèyàn gbangba gbàǹgbà pé ohun táwọn Farisí lànà sílẹ̀ nípa òfin Sábáàtì kò tọ̀nà rárá, àti pé wọ́n ti gba gbogbo ète òfin yẹn sódì. Ó wá ṣàlàyé pé Mèsáyà gan-an ni “Olúwa sábáàtì,” àti nítorí náà, ó láṣẹ láti woni sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Mátíù 12:8) Láti fi hàn pé òótọ́ ọ̀rọ̀ lòun sọ, ó fi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn níta gbangba lọ́jọ́ Sábáàtì. (Lúùkù 6:7-10) Àwọn ìwòsàn yẹn sì jẹ́ àpẹẹrẹ bí yóò ṣe woni sàn kárí ayé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Rẹ̀. Ẹgbẹ̀rún Ọdún yẹn pàápàá yóò jẹ́ Sábáàtì tó ga jù lọ, nítorí pé ìgbà yẹn gan-an làwọn olóòótọ́ nínú ọmọ aráyé yóò sinmi nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín kúrò nínú làálàá tí wọ́n ti ń ṣe bọ̀ lábẹ́ ẹrù ìnira ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

13. Òfin wo ló wáyé nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Kristi ṣe láyé, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí òfin tó wà ṣáájú rẹ̀?

13 Jésù tún mú kí ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ṣe kedere síni nípa gbígbé tó gbé òfin tuntun kan, ìyẹn “òfin Kristi,” kalẹ̀ lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Gálátíà 6:2) Òfin tuntun yìí kò dà bí Òfin Mósè tó wà ṣáájú rẹ̀, nítorí pé kì í ṣe ètò òfin jàn-ànràn jan-anran, bí kò ṣe àwọn ìlànà téèyàn á máa tẹ̀ lé. Àmọ́ kì í ṣe pé òun náà kò láwọn òfin pàtó o. Ọ̀kan lára òfin rẹ̀ ni Jésù pè ní “àṣẹ tuntun kan.” Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n  fẹ́ràn ara wọn gẹ́lẹ́ bí òun ṣe fẹ́ràn wọn. (Jòhánù 13:34, 35) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ ni ànímọ́ pàtàkì tá a ó fi máa dá gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé “òfin Kristi” nígbèésí ayé wọn mọ̀ yàtọ̀.

Òun Fúnra Rẹ̀ Jẹ́ Àpẹẹrẹ Ìdájọ́ Òdodo

14, 15. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun kì í ré kọjá àṣẹ tóun bá gbà, kí sì nìdí tí èyí fi fọkàn wa balẹ̀?

14 Kì í ṣe pé Jésù kàn fọ̀rọ̀ ìfẹ́ yìí kọ́ni nìkan, ó tún fi “òfin Kristi” ṣèwà hù. Ó lò ó nínú gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Wo ọ̀nà mẹ́ta tí àpẹẹrẹ Jésù ti mú kí ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ yéni kedere.

15 Àkọ́kọ́, Jésù sapá gidigidi láti má hùwà ìrẹ́jẹ kankan bó ti wù ó mọ. Bóyá o ti lè kíyè sí i pé ibi tí ọ̀pọ̀ ìwà ìrẹ́jẹ ti sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ ni ìgbà tí ìgbéraga bá wọ àwọn èèyàn lẹ́wù tán tí wọ́n wá ń kọjá àyè wọn. Jésù kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tirẹ̀. Nígbà kan, ọkùnrin kan tọ Jésù wá, ó ní: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín ogún pẹ̀lú mi.” Kí ni Jésù fi fèsì? Ó fèsì pé: “Ọkùnrin yìí, ta ní yàn mí ṣe onídàájọ́ tàbí olùpín nǹkan fún yín?” (Lúùkù 12:13, 14) Ǹjẹ́ èyí ò wúni lórí? Ọgbọ́n Jésù, làákàyè rẹ̀, kódà ọ̀pá àṣẹ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ ju ti ẹnikẹ́ni lọ láyé ńbí; síbẹ̀, ó ṣì kọ̀ láti tọwọ́ bọ ọ̀ràn yìí, nítorí Ọlọ́run ò pàṣẹ fún un pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Bí Jésù kì í ṣeé kọjá àyè rẹ̀ nìyẹn látẹ̀yìnwá, kódà títí kan gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó ti fi wà kó tó wá sí ilé ayé. (Júúdà 9) Bí Jésù ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ dúró kí Jèhófà fún òun ní ìtọ́ni kó tó ṣe nǹkan kan yìí jẹ́ ká mọ̀ dájú pé ó ní ọba ìwà.

16, 17. (a) Báwo ni Jésù ṣe lo ìdájọ́ òdodo nínú ọ̀nà tó gbà ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé àánú ń bẹ nínú òye ìdájọ́ òdodo òun?

16 Ìkejì, Jésù lo ìdájọ́ òdodo ní ti ọ̀nà tó gbà wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kò sí ẹ̀tanú nínú ọ̀nà tó gbà wàásù rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sapá gidigidi láti wàásù dé ọ̀dọ̀ gbogbo onírúurú èèyàn, yálà olówó ni o tàbí tálákà. Òdì kejì ohun tó ṣe làwọn Farisí ń ṣe ní tiwọn. Orúkọ èébú tí wọ́n fi ń lé àwọn tálákà, aláìní sẹ́yìn ni ʽam-ha·ʼaʹrets, tó túmọ̀ sí “àwọn èèyàn ilẹ̀.” Jésù fi ìgboyà  ta ko ìwà ìrẹ́jẹ yẹn. Nígbà tí Jésù fi ìhìn rere kọ́ àwọn èèyàn, àgàgà nígbà tó bá wọn jẹun, tó tún bọ́ wọn, tó mú wọn lára dá, tàbí nígbà tó jí òkú wọn dìde pàápàá, ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, ẹni tó ń fẹ́ fa “gbogbo onírúurú ènìyàn” mọ́ra, ló ń gbé lárugẹ. *1 Tímótì 2:4.

17 Ìkẹta, àánú pọ̀ gidigidi nínú òye ìdájọ́ òdodo tí Jésù ní. Ó ṣakitiyan gidigidi láti ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. (Mátíù 9:11-13) Kì í jáfara láti ran àwọn ẹni tí kò lè rí ohunkóhun ṣe sí ọ̀ràn ara wọn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kò bá àwọn Farisí lẹ̀dí àpò pọ̀ láti máa kọ́ni pé gbogbo Kèfèrí ni kò ṣeé fọkàn tán. Ó ṣàánú àwọn Kèfèrí ó sì kọ́ òmíràn lára wọn lẹ́kọ̀ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ni a rán an sí ní pàtàkì. Ó gbà láti fi iṣẹ́ ìyanu ṣèwòsàn fún ìránṣẹ́ ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kan, ó ní: “Kò sí ẹnì kan ní Ísírẹ́lì tí èmi tíì rí tí ó ní ìgbàgbọ́ tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀.”—Mátíù 8:5-13.

18, 19. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣètìlẹyìn fún bíbuyì kún àwọn obìnrin? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe mú ká rí ìsopọ̀ tó wà láàárín ìgboyà àti ìdájọ́ òdodo?

18 Bákan náà, Jésù kò fara mọ́ ojú tí àwọn èèyàn ìgbà yẹn fi ń wo àwọn obìnrin. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu ló ń ṣe. Bí àwọn Júù ṣe ka àwọn Kèfèrí sí aláìmọ́ náà ni wọ́n ṣe ka àwọn obìnrin ará Samáríà sí aláìmọ́. Síbẹ̀, Jésù kò fà sẹ́yìn láti wàásù fún obìnrin ará Samáríà kan létí kànga kan ní ìlú Síkárì. Kódà, obìnrin yìí ni Jésù kọ́kọ́ sọ fún ní tààràtà pé òun ni Mèsáyà tá a ṣèlérí. (Jòhánù 4:6, 25, 26) Àwọn Farisí sọ pé kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ fi Òfin Ọlọ́run kọ́ obìnrin, ṣùgbọ́n ńṣe ni Jésù ní tiẹ̀ ń fara balẹ̀ sa gbogbo ipá rẹ̀ láti kọ́ àwọn obìnrin. (Lúùkù 10:38-42) Àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ sọ pé a kò lè gbára lé ẹ̀rí àwọn obìnrin, Jésù buyì kún àwọn obìnrin mélòó kan  nípa fífún wọn láǹfààní láti jẹ́ ẹni tó kọ́kọ́ rí i nígbà tó jíǹde. Ó tiẹ̀ tún sọ pé kí wọ́n lọ ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ọkùnrin!—Mátíù 28:1-10.

19 Dájúdájú, Jésù sọ ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ fáwọn orílẹ̀-èdè ní kedere. Lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ló máa fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó tó lè ṣe é. Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí i pé dídúró lórí ìdájọ́ òdodo gba ìgboyà. Ìyẹn ló fi bá a mu bí wọ́n ṣe pè é ní “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà.” (Ìṣípayá 5:5) Rántí pé kìnnìún jẹ́ àmì ìdájọ́ òdodo tó gba ìgboyà. Àmọ́ ṣá, láìpẹ́ Jésù yóò mú kí ìdájọ́ òdodo tó túbọ̀ gbòòrò jù èyí lọ wáyé. Ìgbà yẹn ni yóò gbé “ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ ní ilẹ̀ ayé” lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.—Aísáyà 42:4.

Mèsáyà Ọba “Gbé Ìdájọ́ Òdodo Kalẹ̀ ní Ilẹ̀ Ayé”

20, 21. Láyé òde òní, báwo ni Mèsáyà Ọba ṣe ti mú kí ìdájọ́ òdodo wà kárí ayé àti láàárín ìjọ Kristẹni?

20 Láti ìgbà tí Jésù ti di Mèsáyà Ọba lọ́dún 1914, ló ti ń mú kí ìdájọ́ òdodo wà kárí ayé. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Òun ni igi lẹ́yìn ọgbà ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tó wà nínú Mátíù 24:14. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó wà lórí ilẹ̀ ayé ń kọ́ àwọn èèyàn láti onírúurú ilẹ̀ ní òtítọ́ nípa Ìjọba Jèhófà. Àwọn náà ṣe bíi tí Jésù ní ti pé wọ́n ń wàásù fúnni bó ṣe tọ́ láìṣojúsàájú. Wọ́n máa ń wá ọ̀nà láti fún gbogbo èèyàn lọ́mọdé lágbà, olówó àti tálákà, tọkùnrin tobìnrin láǹfààní láti dẹni tó mọ Jèhófà, Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo.

21 Jésù tún ń rí sí i pé ìdájọ́ òdodo wà nínú ìjọ Kristẹni tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ Orí fún. Bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe wí, ó ń pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” ìyẹn àwọn Kristẹni alàgbà tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ. (Éfésù 4:8-12) Àpẹẹrẹ Jésù Kristi làwọn ọkùnrin wọ̀nyí sì ń tẹ̀ lè ní ti rírí sí i pé ìdájọ́ òdodo wà bí wọ́n ṣe ń bójú tó agbo iyebíye tí Ọlọ́run ní. Wọ́n ti gbìn ín sọ́kàn pé ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni Jésù máa ń fẹ́ kí wọ́n gbà hùwà sí àgùntàn òun láìka ipò ẹni, béèyàn ṣe gbajúmọ̀ tó tàbí ohun ìní ẹni sí.

22. Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ tó gbòde kan lóde òní ṣe rí lára Jèhófà, kí ló sì ti yan Ọmọ rẹ̀ láti ṣe nípa rẹ̀?

22 Àmọ́ ṣá, láìpẹ́, Jésù yóò gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ ní ayé lọ́nà tó  tayọ gbogbo tàtẹ̀yìnwá. Àìṣèdájọ́ òdodo ló gbòde kan láyé tó kún fún ìwà ìbàjẹ́ yìí. Gbogbo ọmọdé tó bá tipa ebi kú jẹ́ ọmọ tá a rẹ́ jẹ láìsí àwíjàre, àgàgà tí a bá ronú nípa bí ayé ṣe ń náwó nínàákúnàá, tí wọ́n sì ń fi àkókò ṣòfò lórí ìpèsè ohun ìjà ogun àti lórí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí àwọn jayéjayé ń wá. Bí ẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ṣe ń ṣòfò lọ́dọọdún pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára onírúurú ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, èyí sì ń mú kí ìbínú òdodo Jèhófà ru. Ó ti wá yan Ọmọ rẹ̀ pé kó gbé ogun òdodo dìde sí gbogbo ètò búburú ayé láti lè fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ títí láé.—Ìṣípayá 16:14, 16; 19:11-15.

23. Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, báwo ni Kristi yóò ṣe gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ títí ayérayé?

23 Ṣùgbọ́n, kì í ṣe orí pípa àwọn èèyàn burúkú run nìkan ni ìdájọ́ òdodo Jèhófà dé dúró. Ó tún yan Ọmọ rẹ̀ pé kó ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” pẹ̀lú. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, ìjọba Jésù yóò mú kí àlàáfíà wà kárí ayé, yóò sì máa ṣàkóso “nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo.” (Aísáyà 9:6, 7) Ìdùnnú ni yóò sì jẹ́ fún Jésù láti mú gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ tó ti kó ìyọnu àti ìpọ́njú tó ga bá ayé, kúrò. Títí láé ni yóò sì máa fi ìṣòtítọ́ gbé ìdájọ́ òdodo pípé ti Jèhófà lárugẹ. Ìyẹn ló fi ṣe pàtàkì pé ká rí i pé a tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Jèhófà nísinsìnyí. Ẹ jẹ́ ká wá wo bí a ṣe lè tẹ̀ lé e.

^ ìpínrọ̀ 1 Bí Jésù ṣe bínú lọ́nà òdodo yìí, ó fi jọ Jèhófà, ẹni tó jẹ́ pé ó ti “ṣe tán láti fi ìhónú hàn” nítorí ìwà ibi gbogbo. (Náhúmù 1:2) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ oníwàkiwà pé wọ́n ti sọ ilé òun di “kìkì hòrò àwọn ọlọ́ṣà,” ó ní: “Ìbínú mi àti ìhónú mi ni a óò tú jáde sórí ibí yìí.”—Jeremáyà 7:11, 20.

^ ìpínrọ̀ 3 Gẹ́gẹ́ bí ìwé Mishnah ṣe wí, àwọn kan fẹ̀hónú hàn lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, nítorí ọ̀wọ́n gógó tí wọ́n ń ta àdàbà nínú tẹ́ńpìlì. Kíákíá ni wọ́n sọ ọ́ di pọ̀ọ́ǹtọ̀! Àpò ta ni ọ̀pọ̀ jù lọ èrè tí wọ́n ń jẹ nínú òwò tó ń mú èrè rẹpẹtẹ wá yìí ń lọ? Àwọn òpìtàn kan sọ pé agbo ilé Ánásì Àlùfáà Àgbà ló ni àwọn ọjà tí wọ́n ń tà nínú tẹ́ńpìlì wọ̀nyẹ́n, ó sì sọ agbo ilé àlùfáà di ọlọ́rọ̀.—Jòhánù 18:13.

^ ìpínrọ̀ 16 Àwọn Farisí sọ pé àwọn tálákà, tí kò mọ Òfin sórí, jẹ́ “ẹni ègún.” (Jòhánù 7:49) Wọ́n ní ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ kọ́ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, kò gbọ́dọ̀ bá wọn dòwò pọ̀, kò gbọ́dọ̀ bá wọn jẹun tàbí kó bá wọn gbàdúrà. Wọ́n ní bí ẹnikẹ́ni bá gba ọmọbìnrin rẹ̀ láyè láti fẹ́ ọ̀kan lára wọn, onítọ̀hún ṣe ohun tó burú ju pé kó fọmọ rẹ̀ fún ẹranko pa jẹ lọ. Wọ́n ti gbà pé kò sí àjíǹde fún àtìrandíran tálákà láéláé.