Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Orí 12

“Àìṣèdájọ́ Òdodo Ha Wà Pẹ̀lú Ọlọ́run Bí?”

“Àìṣèdájọ́ Òdodo Ha Wà Pẹ̀lú Ọlọ́run Bí?”

1. Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ ṣe sábà máa ń rí lára ẹni?

ÀWỌN gbájúẹ̀ fẹ̀tàn gba gbogbo owó tí arúgbó opó kan fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ tù jọ láti máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Abiyamọ aláìláàánú kan gbọ́mọ ẹ̀ jòjòló jù síbì kan ó sì sá lọ. Wọ́n gbé ọkùnrin kan jù sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀. Báwo ni gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣe rí lára rẹ ná? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ta ọ́ lára, bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn. Àwa èèyàn ní òye tó mú hánhán nípa ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Bí ẹnì kan bá hùwà ìrẹ́jẹ inú máa ń bí wa. A máa ń fẹ́ kí wọ́n dá ẹ̀tọ́ ẹni tí wọ́n rẹ́ jẹ padà, kí ẹni tó rẹ́ni jẹ ọ̀hún sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bọ́ràn ò bá wá rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa ń mú ká máa rò ó lọ́kàn pé: ‘Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé? Kí nìdí tí kò fi ṣe nǹkan kan sí i?’

2. Kí ni ìṣarasíhùwà Hábákúkù sí ìwà ìrẹ́jẹ, kí sì nìdí tí Jèhófà kò fi bá a wí nítorí rẹ̀?

2 Àtayébáyé làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Hábákúkù gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Èé ṣe tí o fi mú kí ń máa rí ìwà ìrẹ́jẹ tó gadabú bẹ́ẹ̀? Èé ṣe tó o fi gbà kí ìwà ipá, ìwà ta-ni-yóò-mú-mi, ìwà ọ̀daràn àti ìwà ìkà gbòde kan?” (Hábákúkù 1:3, Contemporary English Version) Jèhófà kò bá Hábákúkù wí, pé ó ṣe béèrè àwọn ìbéèrè tó ká a lára yẹn, nítorí Òun ló dá ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo mọ́ èèyàn. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà bùn wa ní díẹ̀ lára ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ tó kọyọyọ.

Jèhófà Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ

3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà mọ ìwà ìrẹ́jẹ tó ń lọ láyé jù wá lọ?

3 Jèhófà kì í dijú sí ìwà ìrẹ́jẹ. Ó kúkú ń rí ohun tó ń lọ. Bíbélì sọ fún wa nípa ìgbà ayé Nóà pé: “Jèhófà rí i pé  ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5) Ẹ wo ohun tí gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí ná. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwọ̀nba ìròyìn díẹ̀ tá a bá gbọ́ tàbí ọ̀ràn tó bá kan àwa fúnra wa la fi ń mọ̀ pé ìwà ìrẹ́jẹ wáyé. Àmọ́ ní ti Jèhófà, gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé ló mọ̀. Kedere ló ń rí gbogbo rẹ̀! Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó mọ ohun téèyàn ń gbèrò láti ṣe, ìyẹn gbogbo ètekéte tí ń bẹ lẹ́yìn ìwà ìrẹ́jẹ pátá.—Jeremáyà 17:10.

4, 5. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé Jèhófà ń kọbi ara sí ọ̀ràn àwọn ẹni tá a rẹ́ jẹ? (b) Báwo ni wọ́n ṣe hùwà ìrẹ́jẹ sí Jèhófà fúnra rẹ̀?

4 Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé Jèhófà kàn fọwọ́ lẹ́rán tó ń wo gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ o. Ó máa ń bìkítà nípa ọ̀ràn àwọn tí wọ́n bá rẹ́ jẹ. Nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá ń fojú àwọn èèyàn Jèhófà gbolẹ̀, ó kẹ́dùn “nítorí ìkérora wọn nítorí àwọn tí ń ni wọ́n lára àti àwọn tí ń tì wọ́n gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n kiri.” (Àwọn Onídàájọ́ 2:18) Bóyá o ti kíyè sí i pé tí àwọn èèyàn bá ń rí ìwà ìrẹ́jẹ lemọ́lemọ́, ó máa ń mọ́ wọn lára, kò sì ní fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkan kan lójú wọn mọ́. Ti Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀ o! Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà ló ti ń rí gbogbo onírúurú àìṣèdájọ́ òdodo, síbẹ̀ ọ̀nà tó gbà kórìíra rẹ̀ kò dín kù rárá. Dípò ìyẹn, Bíbélì mú un dá wa lójú pé irú àwọn nǹkan bí “ahọ́n èké,” “ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀,” àti “ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ” jẹ́ ìríra lójú rẹ̀.—Òwe 6:16-19.

5 Tún wo ìbáwí líle koko tí Jèhófà fún àwọn olórí tó ń ṣègbè ní Ísírẹ́lì. Ó mí sí wòlíì rẹ̀ láti bi wọ́n pé: “Kì í ha ṣe iṣẹ́ yín ni láti mọ ìdájọ́ òdodo?” Lẹ́yìn tí Jèhófà ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àpèjúwe bí wọ́n ṣe ń ṣi agbára lò, ó wá sọ ohun tí yóò gbẹ̀yìn àwọn ọkùnrin oníwà ìbàjẹ́ wọ̀nyẹn, ó ní: “Wọn yóò ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kì yóò dá wọn lóhùn. Yóò sì fi ojú rẹ̀ pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní àkókò yẹn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe búburú nínú ìbánilò wọn.” (Míkà 3:1-4) Jèhófà mà kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ o! Àní, wọ́n tiẹ̀ ti rẹ́ òun alára jẹ  pàápàá! Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Sátánì ti ń ṣáátá rẹ̀. (Òwe 27:11) Síwájú sí i, wọ́n hùwà ìrẹ́jẹ tó ga jù lọ láyé lọ́run sí Jèhófà fúnra rẹ̀ nígbà tí wọ́n pa Ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn, bẹ́ẹ̀ “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan” o. (1 Pétérù 2:22; Aísáyà 53:9) Dájúdájú, Jèhófà ò dijú sí ìnira àwọn tá a rẹ́ jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò ṣàì kọbi ara sí ọ̀ràn wọn.

6. Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa sí ìwà ìrẹ́jẹ, kí sì nìdí rẹ̀?

6 Síbẹ̀síbẹ̀, bí a bá rí i pé wọ́n rẹ́ àwọn kan jẹ, tàbí pé wọ́n rẹ́ àwa fúnra wa gan-an jẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, ó sábà máa ń ta wa lára. Ìdí ni pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, ìwà ìrẹ́jẹ sì lòdì pátápátá sí irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi gba ìwà ìrẹ́jẹ láyè?

Ọ̀ràn Ipò Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Ọba Aláṣẹ

7. Ṣàpèjúwe bí ó ṣe di pé ìpèníjà wáyé lórí ọ̀ràn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ.

7 Ìdáhùn ìbéèrè yìí wé mọ́ ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, Ẹlẹ́dàá ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso ayé yìí àti gbogbo àwọn tó ń gbé inú rẹ̀. (Sáàmù 24:1; Ìṣípayá 4:11) Àmọ́, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn, ìpèníjà wáyé lórí ọ̀ràn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀? Jèhófà pàṣẹ fún Ádámù, ọkùnrin kìíní, pé kò gbọ́dọ̀ jẹ lára èso igi kan tó wà nínú Párádísè tó ń gbé. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bó bá jẹ ẹ́? Ọlọ́run sọ fún un pé: “Dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Òfin tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ yìí kò fa ìnira kankan fún Ádámù àti Éfà aya rẹ̀. Àmọ́, Sátánì fi yé Éfà pé ńṣe ni Ọlọ́run kàn ká wọn lọ́wọ́ kò láìnídìí. Tí Éfà bá sì wá jẹ lára èso igi yẹn ńkọ́? Sátánì sọ ọ́ ní ṣàkó fún Éfà pé: “Dájúdájú ẹ̀yin yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.

8. (a) Kí ni Sátánì fẹ́ fà yọ nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fún Éfà? (b) Kí ni Sátánì pè níjà nípa ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ?

8 Yàtọ̀ sí pé Sátánì sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí pé Jèhófà ń fi ìsọfúnni  pàtàkì kan pa mọ́ fún Éfà, ó tún sọ pé Ọlọ́run ń purọ́ fún un. Sátánì ò ta ko òtítọ́ náà pé Ọlọ́run ni ọba aláṣẹ, ṣe ló pẹ́ ìhà yẹn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ó pe lílò tí Ọlọ́run ń lo ipò yẹn níjà. Ó ní kò tọ́ bó ṣe ń lò ó; pé kò yẹ kó máa lò ó, àti pé kò bá ọ̀nà òdodo mu. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ó ní Jèhófà kò lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lọ́nà òdodo àti pé kò lò ó fún ire àwọn tó wà lábẹ́ rẹ̀.

9. (a) Ní ti Ádámù àti Éfà, kí ni àbájáde àìgbọràn wọn, àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ló sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ yọ? (b) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn run?

9 Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n jẹ lára èso igi tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ fún wọn. Àìgbọràn wọn mú kí ikú tọ́ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀. Irọ́ Sátánì yìí mú kí àwọn ìbéèrè pàtàkì kan jẹ yọ. Ìyẹn ni, ṣé Jèhófà ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso aráyé lóòótọ́, tàbí èèyàn ló yẹ kó máa ṣàkóso ara rẹ̀? Ǹjẹ́ Jèhófà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lọ́nà tó dára jù lọ? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ níbẹ̀ ni Jèhófà ì bá ti lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olódùmarè láti pa gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn run. Àmọ́ ìbéèrè tó wà nílẹ̀ kò dá lórí bí Ọlọ́run ṣe lágbára sí, bí kò ṣe lórí bí ìṣàkóso rẹ̀ ṣe jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, pípa Ádámù, Éfà àti Sátánì run kì bá má fi ẹ̀rí hàn pé ìṣàkóso òdodo ni ìṣàkóso Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ì bá túbọ̀ mú kí ìbéèrè púpọ̀ sí i máa yọjú nípa ìṣàkóso rẹ̀. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti gbà mọ̀ bóyá aráyé lè fúnra wọn ṣàkóso ara wọn yanjú, láìsí ọwọ́ Ọlọ́run níbẹ̀, ni pé kí Ọlọ́run fàyè sílẹ̀ fún wọn láti ṣe é wò fúngbà kan ná.

10. Kí ni ìtàn jẹ́ ká mọ̀ nípa ìṣàkóso èèyàn?

10 Kí ni ìtàn àtìgbà yẹn wá sì ti fi hàn? Onírúurú ìjọba làwọn èèyàn ti dán wò, títí kan ìjọba apàṣẹwàá, ìjọba tiwa-n-tiwa, ìjọba àjùmọ̀ní àti ìjọba Kọ́múníìsì. Pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí, orí òdodo ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ náà ló ń já sí, pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ìyẹn lohun tí wòlíì Jeremáyà sọ fi tọ́, ó ní: “Mo mọ̀ dáadáa,  Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.

11. Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà kí ìran ènìyàn jìyà?

11 Jèhófà mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pé béèyàn bá dá dúró lómìnira kúrò lọ́dọ̀ òun tàbí béèyàn bá ń dá ṣàkóso ara rẹ̀, àjẹkún ìyà ni wọn máa jẹ. Ṣé a lè wá sọ pé Ọlọ́run ò ṣẹ̀tọ́ ní ti bó ṣe gbà kí nǹkan tó mọ̀ pé ó máa forí ṣánpọ́n bẹ̀rẹ̀? Rárá o! Àpèjúwe kan rèé: Jẹ́ ká sọ pé o lọ́mọ kan tó yẹ kí dókítà ṣe iṣẹ́ abẹ fún láti lè wo àìsàn kan tó lè ṣekú pa á sàn. O mọ̀ pé iṣẹ́ abẹ yìí máa fa ìrora fún ọmọ rẹ, ìyẹn sì lè bà ọ́ nínú jẹ́ gidigidi. Síbẹ̀, o mọ̀ pé ṣíṣe iṣẹ́ abẹ yẹn á túbọ̀ mú kí ọmọ rẹ ní ìlera tó dáa lọ́jọ́ ọ̀la. Bákan náà ni Ọlọ́run ṣe mọ̀ tẹ́lẹ̀, ó tiẹ̀ sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, pé fífi tí òun fàyè gba àwọn èèyàn láti máa ṣàkóso ara wọn yóò fa ìrora àti ìjìyà dé ìwọ̀n àyè kan. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19) Ṣùgbọ́n ó tún mọ̀ bákan náà pé àfi bí òun bá jẹ́ kí ọmọ aráyé fojú ara wọn rí ohun tí ìṣọ̀tẹ̀ máa ń dá sílẹ̀ ni ìtura gidi tó máa ṣeé ṣe. Àti pé ọ̀nà yìí ni ìpèníjà náà kò fi ní gbérí mọ́ títí láé.

Ọ̀ràn Ìwà Títọ́ Ọmọ Aráyé

12. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn Jóòbù ṣe fi hàn, ẹ̀sùn wo ni Sátánì kà sí ọmọ aráyé lọ́rùn?

12 Ìhà mìíràn tún wà nínú ọ̀ràn yìí. Bí Sátánì ṣe pe ẹ̀tọ́ àti òdodo ìṣàkóso Ọlọ́run níjà, kì í ṣe pé ó ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ ní ti ohun tó sọ nípa ipò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ nìkan ni; ó tún ba àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ní ti ọ̀ràn ìwà títọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí ohun tí Sátánì sọ fún Jèhófà nípa Jóòbù, ọkùnrin olódodo nì, ó sọ pé: “Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká, àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká? Ìwọ ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, àní ohun ọ̀sìn rẹ̀ ti tàn káàkiri ilẹ̀. Ṣùgbọ́n, fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan  ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.”—Jóòbù 1:10, 11.

13. Kí ni Sátánì dọ́gbọ́n fi àwọn ẹ̀sùn tó fi kan Jóòbù sọ, báwo lèyí sì ṣe kan gbogbo ọmọ aráyé?

13 Sátánì ṣàròyé pé ńṣe ni Jèhófà ń fi agbára ìdáàbòboni Rẹ̀ rọ̀gbà yí Jóòbù ká tìtorí kó lè máa fóun ní ìfọkànsìn. Ẹ̀wẹ̀, èyí á túmọ̀ sí pé ẹ̀tàn ni gbogbo ìwà títọ́ tí Jóòbù sọ pé òun ní, àti pé torí ohun tó máa rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan ló ṣe ń sìn ín. Sátánì wá sọ pé bí Jóòbù ò bá rí ìbùkún Ọlọ́run gbà mọ́, jagunlabí á gbé Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ṣépè. Sátánì mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Jóòbù kò láfiwé ní ti jíjẹ́ “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán,” àti ẹni “tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.” * Nípa bẹ́ẹ̀, bí Sátánì bá lè ba ìwà títọ́ Jóòbù jẹ́, kí ni tàwọn ọmọ aráyé yòókù á ti wá jẹ́? Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìwà títọ́ gbogbo àwọn tó fẹ́ máa sin Ọlọ́run ni Sátánì ń pè níjà ní ti gidi. Ní tòótọ́, Sátánì fẹ ọ̀ràn náà síwájú sí i, ó sọ fún Jèhófà pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn [kì í ṣe Jóòbù nìkan] bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.”—Jóòbù 1:8; 2:4.

14. Kí ni ìtàn ti fi hàn nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan ọmọ èèyàn?

14 Ìtàn fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, bíi ti Jóòbù, ló ti dúró ṣinṣin sí Jèhófà lójú àdánwò, ní ìyàtọ̀ sí ohun tí Sátánì sọ. Ìgbé ayé ìṣòtítọ́ tí wọ́n gbé mú ọkàn Jèhófà yọ̀, ó sì ti jẹ́ kí Jèhófà rí nǹkan dáhùn ìṣáátá Sátánì pé tọ́wọ́ ìyà bá ba ọmọ èèyàn kò ní sin Ọlọ́run mọ́. (Hébérù 11:4-38) Dájúdájú àwọn olódodo ò dẹ̀yìn kọ Ọlọ́run o. Àní nígbà tí ìpọ́njú tó ga jù lọ bá fẹ́rẹ̀ẹ́ pin wọ́n lẹ́mìí pàápàá, ńṣe ni wọ́n tún ń túbọ̀ gbára lé Jèhófà pé kí ó fún àwọn lókun láti lè fara dà á.—2 Kọ́ríńtì 4:7-10.

15. Ìbéèrè wo la lè béèrè nípa àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ti ṣe sẹ́yìn àti èyí tó ń bọ̀ wá ṣe lọ́jọ́ iwájú?

 15 Àmọ́ ohun tó wé mọ́ ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣèdájọ́ òdodo ju ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ àti ọ̀ràn ìwà títọ́ ọmọ aráyé lọ. Àkọsílẹ̀ àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà ti ṣe lórí àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan àtàwọn orílẹ̀-èdè lódindi pàápàá ń bẹ nínú Bíbélì. Àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìdájọ́ tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú tún wà nínú rẹ̀ pẹ̀lú. Kí nìdí tá a fi lè ní ìdánilójú pé ọ̀nà òdodo ni Jèhófà ti ń gbà ṣèdájọ́ látẹ̀yìnwá àti pé yóò fi òdodo ṣèdájọ́ lọ́jọ́ iwájú?

Ìdí Tí Ìdájọ́ Ọlọ́run Fi Ga Jù Lọ

Láéláé, Jèhófà kì yóò “gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú”

16, 17. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé òye èèyàn mọ níwọ̀nba tó bá di pé ká ṣèdájọ́ òdodo?

16 Ní ti Jèhófà, a lè sọ ní ti tòótọ́ pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Diutarónómì 32:4) Kò sí ẹnì kankan nínú wa tó lè sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa ara rẹ̀, nítorí àìmọye ìgbà ni òye wa tó mọ níwọ̀nba kì í jẹ́ ká mọ ohun tó tọ́. Fi ti Ábúráhámù ṣe àpẹẹrẹ. Àní ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jèhófà kó má pa Sódómù run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ibi gbòde kan níbẹ̀. Ó bi Jèhófà pé: “Ìwọ, ní ti tòótọ́, yóò ha gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú bí?” (Jẹ́nẹ́sísì 18:23-33) Kò sí àní-àní pé bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn ìbéèrè rẹ̀. Ìgbà tí Lọ́ọ̀tì olódodo àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ dé ìlú Sóárì láìséwu ni Jèhófà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ “mú kí òjò imí ọjọ́ àti iná rọ̀” sórí Sódómù. (Jẹ́nẹ́sísì 19:22-24) Ní ti Jónà, ńṣe ni ‘inú rẹ̀ ru fún ìbínú’ nígbà tí Ọlọ́run ṣàánú àwọn èèyàn Nínéfè. Nígbà tí Jónà ti lè kéde ìparun sórí wọn, ṣe ni inú rẹ̀ ì bá dùn tí wọ́n bá pa rẹ́ lóòótọ́, àní pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ronú pìwà dà tọkàntọkàn yẹn.—Jónà 3:10-4:1.

17 Jèhófà fi ọkàn Ábúráhámù balẹ̀ pé ìdájọ́ òdodo òun kò mọ sí kìkì pípa àwọn ẹni burúkú run, ó tún kan ti gbígba àwọn olódodo là pẹ̀lú. Àmọ́ ní ti Jónà, ọ̀ràn tirẹ̀ yìí ló ṣẹ̀ṣẹ̀ fi mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà. Pé bí àwọn ẹni burúkú bá yí ọ̀nà wọn padà, Ọlọ́run ‘ṣe tán láti dárí jì wọ́n.’ (Sáàmù  86:5) Jèhófà kò dà bí ọmọ èèyàn tó máa ń bẹ̀rù kí ipò òun máà bọ́ lọ́wọ́ òun, nípa bẹ́ẹ̀ kì í dáni lẹ́jọ́ láti fi yéni pé òun lágbára, bẹ́ẹ̀ ni kì í torí ìbẹ̀rù pé wọ́n á rò pé ojo lòun kó má ṣàánú ẹni. Ìṣe rẹ̀ ni pé ó máa ń ṣàánú nígbà tí àánú bá yẹ.—Aísáyà 55:7; Ìsíkíẹ́lì 18:23.

18. Fi hàn látinú Bíbélì pé ìṣe èèyàn ni Jèhófà fi ń dá a lẹ́jọ́.

18 Àmọ́ ṣá, ìṣe èèyàn ni Jèhófà fi ń dá a lẹ́jọ́, kì í wojú èèyàn gbé ìgbésẹ̀. Nígbà tí àwọn èèyàn Jèhófà tara bọ ìbọ̀rìṣà, Jèhófà sọ fún wọn ṣàkó pé: “Èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ, èmi yóò sì mú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí rẹ wá sórí rẹ. Ojú mi kì yóò sì káàánú fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ní ìyọ́nú, nítorí èmi yóò mú àwọn ọ̀nà rẹ wá sórí rẹ.” (Ìsíkíẹ́lì 7:3, 4) Nítorí náà, tó bá di pé àwọn èèyàn kọ̀ láti jáwọ́ nínú ìṣe wọn, Jèhófà á fi ìṣe wọn yẹn dá wọn lẹ́jọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ ni Jèhófà máa ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kà. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí “igbe ìráhùn” nípa Sódómù àti Gòmórà ń dé etígbọ̀ọ́ Jèhófà, ó ní: “Mo ti pinnu tán láti sọ̀ kalẹ̀ lọ kí n lè rí bóyá wọ́n hùwà látòkè délẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú igbe ẹkún tí wọ́n ń ké lé e lórí tí ó ti wá sọ́dọ̀ mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà kò dà bí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n á ti fi ìkánjú dáni lẹ́jọ́ kí wọ́n tiẹ̀ tó gbọ́ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an! Irú ẹni tí Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ náà ló jẹ́ lóòótọ́, ìyẹn ni, “Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀.”—Diutarónómì 32:4.

Gbẹ́kẹ̀ Lé Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà

19. Kí la lè ṣe bí àwọn nǹkan kan bá wà tó rú wa lójú nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ṣèdájọ́?

19 Kì í ṣe gbogbo ìbéèrè tá a lè ní nípa ìgbésẹ̀ Jèhófà látẹ̀yìnwá ni Bíbélì sọ̀rọ̀ lé lórí tán; bẹ́ẹ̀ ni kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ bí Jèhófà yóò ṣe ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwùjọ kọ̀ọ̀kan lọ́jọ́ iwájú. Tó bá di pé ìtàn tàbí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan tí kò ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé rú wa lójú, a lè fara wé irú ẹ̀mí ìdúróṣinṣin  kan náà tí wòlíì Míkà ní, ẹni tó kọ̀wé pé: “Èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—Míkà 7:7.

20, 21. Kí nìdí tá a fi lè ní ìdánilójú pé kò sígbà kan tí Jèhófà kò ní ṣe ohun tó tọ́?

20 Kí ó dá wa lójú pé, nínú ipòkípò, Jèhófà á ṣe ohun tó tọ́. Kódà nígbà tó bá dà bíi pé àwọn èèyàn ò ka ìwà ìrẹ́jẹ sí, ìlérí Jèhófà ni pé: “Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san.” (Róòmù 12:19) Tí a bá fìjà fún Ọlọ́run jà, àwa náà á lè fi ìdánilójú sọ irú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Àìṣèdájọ́ òdodo ha wà pẹ̀lú Ọlọ́run bí? Kí èyíinì má ṣe rí bẹ́ẹ̀ láé!”—Róòmù 9:14.

21 Ní báyìí ná, à ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Ìwà ìrẹ́jẹ àti “ìwà ìninilára” mú káwọn èèyàn máa fojú ọmọnìkejì wọn gbolẹ̀ lónírúurú ọ̀nà. (Oníwàásù 4:1) Ṣùgbọ́n, Jèhófà kò yí padà o. Ó ṣì kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ, ó sì bìkítà gidigidi nípa ọ̀ràn àwọn tá à ń rẹ́ jẹ. Bá a bá dúró ṣinṣin sí Jèhófà àti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, yóò fún wa lókun láti máa forí tì í títí dìgbà tí àkókó tó yàn fi máa tó tí yóò sì ṣe àtúnṣe gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ lábẹ́ Ìjọba rẹ̀.—1 Pétérù 5:6, 7.

^ ìpínrọ̀ 13 Jèhófà sọ nípa ti Jóòbù pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé.” (Jóòbù 1:8) Nígbà náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àárín ìgbà tí Jósẹ́fù kú àti kí Ọlọ́run tó yan Mósè ṣe aṣáájú Ísírẹ́lì ni Jóòbù gbé láyé. Nípa bẹ́ẹ̀, lásìkò yẹn ó ṣeé ṣe láti sọ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó ní irú ìwà títọ́ tí Jóòbù ní.