Àìṣèdájọ́ òdodo wọ́pọ̀ gan-an láyé òde òní, àwọn èèyàn a sì máa fi àìmọ̀kan sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni. Síbẹ̀, Bíbélì kọ́ wa ní òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tó dùn mọ́ni. Òótọ́ ọ̀rọ̀ náà ni pé “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.” (Sáàmù 37:28) Ní ìsọ̀rí yìí a óò kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, tí ó sì tipa báyìí mú kí ọmọ aráyé nírètí.