Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà Ọlọ́run

 ORÍ 10

“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run” Nípa Bí Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára

“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run” Nípa Bí Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára

1. Ọ̀fìn wo ni ọmọ aráyé sábà máa ń jìn sí ní wẹ́rẹ́?

“Ọ̀FÌN kan ń bẹ fún gbogbo alágbára.” Ohun tí obìnrin akéwì ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún sọ yìí ń pàfiyèsí sí ewu ìkọ̀kọ̀ kan, ìyẹn ni: àṣìlò agbára. Ohun tó ń dunni ni pé, wẹ́rẹ́ báyìí ni ẹ̀dá èèyàn aláìpé sì máa ń jìn sí ọ̀fìn yìí. Ó wà nínú ìtàn ìran èèyàn látẹ̀yìnwá pé ńṣe ni àwọn ènìyàn ń “jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Àìfi ìfẹ́ lo agbára yìí ti kó ìpọ́njú bá ọmọ aráyé gan-an ni.

2, 3. (a) Kí ló wúni lórí nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà lo agbára? (b) Kí làwọn nǹkan tó lè jẹ́ agbára wa, báwo ló sì ṣe yẹ kí á máa lo gbogbo irú agbára bẹ́ẹ̀?

2 Ǹjẹ́ kò wúni lórí nígbà náà, pé Jèhófà Ọlọ́run tí agbára rẹ̀ kò lópin, ṣi agbára lò nígbàkigbà rí? Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé nínú àwọn orí tí a ti kà sẹ́yìn, gbogbo ìgbà ló máa ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó bá àwọn ète rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ mu, ì báà jẹ́ agbára ìṣẹ̀dá, agbára ìpanirun, agbára ìdáàbòboni tàbí agbára ìmúbọ̀sípò. Nígbà tí a bá ronú nípa ọ̀nà tó ń gbà lo agbára rẹ̀, ó máa ń wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn. Èyí sì lè mú ká “di aláfarawé Ọlọ́run” nínú ọ̀nà tí àwa náà ń gbà lo agbára. (Éfésù 5:1) Ṣùgbọ́n agbára wo làwa ọmọ èèyàn tiẹ̀ ní ná?

3 Rántí pé ìrí àti “àwòrán Ọlọ́run” ni a dá èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Nípa bẹ́ẹ̀, àwa pẹ̀lú ní agbára díẹ̀ ó kéré tán. Agbára wa lè jẹ mọ́ ti ṣíṣe nǹkan láṣeyọrí, ìyẹn ti iṣẹ́ ṣíṣe; tàbí pé kí á lágbára tàbí kí á láṣẹ lórí àwọn ẹlòmíràn; tàbí kí á nípa lórí àwọn èèyàn, pàápàá àwọn tó fẹ́ràn wa; tàbí kí á jẹ́ ẹni tó taagun; tàbí kí á jẹ́ ọlọ́rọ̀. Onísáàmù sọ nípa Jèhófà pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Nítorí náà, yálà ní tààràtà ni o tàbí láìṣe tààràtà, Ọlọ́run ni orísun gbogbo  agbára tó bófin mu. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa lò ó lọ́nà tí yóò mú inú rẹ̀ dùn. Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí?

Ìfẹ́ Loògùn Rẹ̀

4, 5. (a) Kí ni ohun pàtàkì tó máa jẹ́ kí á lo agbára lọ́nà tó tọ́, báwo sì ni àpẹẹrẹ Ọlọ́run ṣe fọ̀nà tí a lè gbà lò ó hàn wá? (b) Báwo ni ìfẹ́ yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lo agbára wa bó ṣe tọ́?

4 Ohun pàtàkì tó ń múni lo agbára lọ́nà tó tọ́ ni ìfẹ́. Àpẹẹrẹ ti Ọlọ́run sì ti jẹ́ ká mọ ọ̀nà tí a lè gbà ṣe èyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Rántí ohun tí a sọ ní Orí Kìíní nípa ànímọ́ pàtàkì mẹ́rin tí Ọlọ́run ń lò, ìyẹn agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Nínú ànímọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin èwo ló gba iwájú? Ìfẹ́ ni. Ìwé 1 Jòhánù 4:8 sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ ni Jèhófà jẹ́ tinú tòde; ó sì ń nípa lórí gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, nígbàkigbà tó bá lo agbára, ìfẹ́ ló sún un lò ó. Ó sì máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ fún ire àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀.

5 Ìfẹ́ ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lo agbára tiwa náà lọ́nà ẹ̀tọ́. Bíbélì sáà sọ fún wa pé ìfẹ́ a máa ní “inú rere” àti pé “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Torí ìdí yìí ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká máa kanra mọ́ àwọn tí a láṣẹ lé lórí dé ìwọ̀n àyè kan tàbí kí á máa hùwà ìkà sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó máa fi ọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n, a ó sì máa gba tiwọn rò ṣáájú tiwa.—Fílípì 2:3, 4.

6, 7. (a) Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run, báwo sì ni ànímọ́ yìí yóò ṣe mú ká yẹra fún àṣìlò agbára? (b) Ṣàpèjúwe bí ìbẹ̀rù pé ká má ṣe ohun tí yóò bí Ọlọ́run nínú àti fífẹ́ràn Ọlọ́run ṣe wé mọ́ra.

6 Ìfẹ́ tún jẹ mọ́ ànímọ́ mìíràn tí yóò mú ká yẹra fún àṣìlò agbára. Òun ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Báwo ni ànímọ́ yìí ṣe wúlò tó? Òwe 16:6 sọ pé: “Nípa ìbẹ̀rù Jèhófà, ènìyàn a yí padà kúrò nínú ohun búburú.” Ó dájú pé àṣìlò agbára jẹ́ ara ohun búburú tó yẹ ká yí padà kúrò nínú rẹ̀. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká máa da àwọn tí a bá lágbára lé lórí ríborìbo. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé, a mọ̀ pé a ó jíhìn fún Ọlọ́run nípa ọ̀nà tí a gbà hùwà sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. (Nehemáyà 5:1-7, 15)  Àmọ́ ṣá o, ohun tó wé mọ́ ìbẹ̀rù Ọlọ́run ju ìyẹn lọ. Ọ̀rọ̀ tí èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ ń lò fún “ìbẹ̀rù” sábà máa ń tọ́ka sí ìbẹ̀rù tó ń múni bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an fún Ọlọ́run. Òun ló fi jẹ́ pé Bíbélì so ìbẹ̀rù pọ̀ mọ́ nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Diutarónómì 10:12, 13) Ìbẹ̀rù tó ń múni bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an fún Ọlọ́run yìí kì í ṣe ìbẹ̀rù nítorí ìyà tó lè jẹ wá, kàkà bẹ́ẹ̀ ó wé mọ́ ìbẹ̀rù ti pé a ò tiẹ̀ fẹ́ ṣe ohun tó lè bí Ọlọ́run nínú rárá nítorí pé a fẹ́ràn rẹ̀ gan-an.

7 Bí àpẹẹrẹ: Wo bí àárín bàbá àti ọmọkùnrin rẹ̀ kékeré ṣe máa ń dùn tó. Ọmọ náà mọ̀ pé bàbá òun fẹ́ràn òun gan-an. Ṣùgbọ́n ọmọ yìí á tún mọ̀ pé bàbá òun ń retí pé kóun máa ṣe àwọn nǹkan kan, ó sì mọ̀ pé bóun bá ṣìwà hù bàbá yìí á bá òun wí. Àmọ́ kì í ṣe pé jìnnìjìnnì á máa bò ọmọ yìí lójoojúmọ́ nítorí ìbẹ̀rù bàbá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò fẹ́ràn bàbá rẹ̀ yìí gan-an. Yóò wu ọmọ yìí láti máa ṣe ohun tí inú bàbá rẹ̀ yóò dùn sí. Bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Nítorí pé a fẹ́ràn Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run, a máa ń bẹ̀rù láti ṣe ohunkóhun tó bá máa “dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:6) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń wù wá ká máa mú ọkàn àyà rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Ìyẹn sì nìdí tó fi yẹ ká máa lo agbára wa lọ́nà tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ ṣàkíyèsí ọ̀nà tí a lè gbà máa lo agbára wa lọ́nà tó tọ́.

Nínú Ìdílé

8. (a) Àṣẹ wo ni ọkọ ní nínú ìdílé, báwo ló sì ṣe yẹ kó lò ó? (b) Báwo ni ọkọ ṣe lè fi hàn pé òun bọlá fún aya òun?

8 Kọ́kọ́ wo bí a ṣe lè lo agbára lọ́nà tó tọ́ nínú ìdílé ná. Éfésù 5:23 sọ pé: “Ọkọ ni orí aya rẹ̀.” Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ lo àṣẹ tí Ọlọ́run fún un yìí? Bíbélì sọ fún ọkọ pé kí ó máa bá aya rẹ̀ ‘gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ó máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera.’ (1 Pétérù 3:7) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a túmọ̀ sí “ọlá” níhìn-ín lá tún lè túmọ̀ sí, “kà sí pàtàkì, kà sí iyebíye, . . . bọ̀wọ̀ fún.” A sì túmọ̀ àwọn  ọ̀rọ̀ tó fara pẹ́ ọ̀rọ̀ yìí sí “ẹ̀bùn” àti “iyebíye.” (Ìṣe 28:10; 1 Pétérù 2:7) Ọkọ tó bá bọlá fún aya rẹ̀ kò jẹ́ nà án rárá o; bẹ́ẹ̀ ni kò ní tẹ́ ẹ tàbí kó dójú tì í láti mú kó rí ara rẹ̀ bí ẹni tí ò wúlò. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò mọyì aya rẹ̀, yóò sì máa fọ̀wọ̀ wọ̀ ọ́. Yóò máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe, ì báà jẹ́ ní ìkọ̀kọ̀ tàbí ní gbangba, pé òun kà á sí ẹni iyebíye. (Òwe 31:28) Yàtọ̀ sí pé aya náà á fẹ́ràn irú ọkọ bẹ́ẹ̀ tí yóò sì bọ̀wọ̀ fún un, ọkọ yìí á tún rí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ gbà, ìyẹn ojú rere Ọlọ́run.

Bí ọkọ àti aya bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn, a jẹ́ pé wọ́n ń lo agbára wọn lọ́nà tó tọ́ nìyẹn

9. (a) Irú agbára wo ni aya ní nínú ìdílé? (b) Kí ló lè ran aya kan lọ́wọ́ láti máa lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún ọkọ rẹ̀, kí ni yóò sì yọrí sí?

9 Aya pẹ̀lú ní agbára dé ìwọ̀n àyè kan nínú ìdílé. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin tó jẹ́ olùfọkànsìn, tó jẹ́ pé wọ́n ń sún ọkọ wọn láti ṣe ohun rere tàbí tó jẹ́ pé, láìní rú ìlànà ọ̀wọ̀ fún ipò orí, wọ́n ń ran ọkọ wọn lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣi ẹsẹ̀ gbé. (Jẹ́nẹ́sísì 21:9-12; 27:46-28:2) Aya lè jẹ́ ẹni tí nǹkan máa ń tètè yé ju ọkọ rẹ̀ lọ tàbí kó tiẹ̀ ní àwọn ànímọ́ mìíràn tí ọkọ rẹ̀ ò ní. Síbẹ̀ ó ṣì ní láti ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún ọkọ rẹ̀ kí ó sì “ní ìtẹríba” fún un “gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa.” (Éfésù 5:22, 33) Bí aya bá ń ronú nípa ṣíṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí, yóò lè máa fi ẹ̀bùn tó bá ní ṣètìlẹ́yìn ọkọ rẹ̀ dípò tá a fi máa tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ tàbí kí ó jọ̀gá lé ọkọ lórí. Ńṣe ni irú “obìnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́” bẹ́ẹ̀ máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ láti gbé ìdílé wọn ró. Yóò sì tipa báyìí wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.—Òwe 14:1.

10. (a) Àṣẹ wo ni Ọlọ́run fún àwọn òbí? (b) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìbáwí,” báwo ló sì ṣe yẹ kí òbí fún ọmọ ní ìbáwí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

10 Àwọn òbí ní àṣẹ tí Ọlọ́run fún àwọn náà pẹ̀lú. Bíbélì gba baba níyànjú pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí” lè túmọ̀ sí “ìtọ́dàgbà, ìdálẹ́kọ̀ọ́, ìtọ́ni.” Àwọn ọmọ nílò ìbáwí; wọ́n máa ń ṣe dáadáa tí a bá fún wọn ní ìtọ́ni tó ṣe kedere, tí a sì sọ ààlà ibi tí wọ́n lè dé fún wọn. Bíbélì máa  ń so irú ìbáwí, tàbí ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ pọ̀ mọ́ ìfẹ́. (Òwe 13:24) Nípa bẹ́ẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ lo “ọ̀pá ìbáwí” lọ́nà tó lè ṣeni léṣe, yálà ní ti ìmí-ẹ̀dùn ni o tàbí nípa ti ara. * (Òwe 22:15; 29:15) Ìbáwí tó le koko tàbí tá a fi ìkanra fúnni láìsí ẹ̀rí ìfẹ́ jẹ́ àṣìlò àṣẹ òbí, ó sì lè dá ọmọ lágara. (Kólósè 3:21) Àmọ́ bí àwọn òbí bá ń fún àwọn ọmọ ní ìbáwí lọ́nà tó tọ́, ó máa ń jẹ́ kó hàn sí àwọn ọmọ náà pé òbí wọn nífẹ̀ẹ́ wọn, pé wọ́n sì bìkítà nípa irú ẹni tí àwọn fẹ́ dà nígbèésí ayé.

11. Báwo ni àwọn ọmọ ṣe lè lo agbára wọn lọ́nà títọ́?

11 Àwọn ọmọ ńkọ́? Báwo ni wọ́n ṣe lè lo agbára wọn lọ́nà tó tọ́? Òwe 20:29 sọ pé: “Ẹwà àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.” Ó dájú pé ọ̀nà tó dára jù lọ tí àwọn ọ̀dọ̀ lè gbà lo okun àti agbára wọn ni pé kí wọ́n fi sin ‘Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá.’ (Oníwàásù 12:1) Ó dára kí àwọn èwe rántí pé ìṣe wọn lè mú inú àwọn òbí wọn dùn, ó sì lè bà wọ́n nínú jẹ́. (Òwe 23:24, 25) Tí àwọn ọmọ bá ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń rin ọ̀nà títọ́, wọ́n máa ń mú inú àwọn òbí wọn dùn. (Éfésù 6:1) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń “dára gidigidi nínú Olúwa.”—Kólósè 3:20.

Nínú Ìjọ

12, 13. (a) Ojú wo ló yẹ kí àwọn alàgbà máa fi wo àṣẹ wọn nínú ìjọ? (b) Ṣàpèjúwe ìdí tó fi yẹ kí àwọn alàgbà fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú agbo Ọlọ́run.

12 Jèhófà pèsè àwọn alábòójútó tí yóò máa mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni. (Hébérù 13:17) Ńṣe ló yẹ kí àwọn ọkùnrin tó tóótun wọ̀nyí máa lo àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn láti fi pèsè ìrànlọ́wọ́ tó yẹ àti láti fi máa wá ire agbo. Ṣé ipò àwọn alàgbà wá mú kí wọ́n dẹni tó lè máa jẹ olúwa lé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lórí ni? Rárá o! Kò yẹ kí àwọn alàgbà máa  fẹlá nítorí ipa tí wọ́n ń kò nínú ìjọ, ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ló yẹ kí wọ́n jẹ́. (1 Pétérù 5:2, 3) Bíbélì sọ fún àwọn alábòójútó pé kí wọ́n “ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Gbólóhùn yìí mú ká rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ kí á fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú olúkúlùkù ẹni tó wà nínú agbo Ọlọ́run.

13 A lè ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ kan ní kó o bá òun tọ́jú ohun ìní kan tó fẹ́ràn gidigidi. O mọ̀ pé ohun ńláǹlà ni ọ̀rẹ́ rẹ san láti fi ra ohun ìní ọ̀hún. Ǹjẹ́ o ò ní rọra máa gbé e gẹ̀gẹ̀, bí ohun ẹlẹgẹ́? Bákan náà ló ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run fa ohun ìní rẹ̀ iyebíye kan lé àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti bójú tó, ìyẹn ni ìjọ, tó jẹ́ pé ó fi àwọn èèyàn inú rẹ̀ wé àgùntàn. (Jòhánù 21:16, 17) Jèhófà fẹ́ràn àwọn àgùntàn rẹ̀ gan-an, àní ó fẹ́ràn wọn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi fi ẹ̀jẹ̀ iyebíye ti Jésù Kristi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo rà wọ́n. Ohun tó ga jù lọ ni Jèhófà san láti fi ra àwọn àgùntàn rẹ̀. Àwọn alàgbà onírẹ̀lẹ̀ máa ń fi èyí sọ́kàn, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n máa fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn àgùntàn Jèhófà.

“Agbára Ahọ́n”

14. Kí ni ahọ́n lágbára láti ṣe?

14 Bíbélì sọ pé: “Ikú àti ìyè ń bẹ ní agbára ahọ́n.” (Òwe 18:21) Ní tòótọ́, ìpalára kékeré kọ́ ni ahọ́n lè ṣe o. Àbí nínú wa, ta ni kò tíì gbọ́ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tó ń dunni wọnú egungun rí, ì báà jẹ́ lọ́nà àwàdà tàbí lọ́nà ẹ̀gàn? Àmọ́, ahọ́n tún lágbára láti tún nǹkan ṣe pẹ̀lú. Òwe 12:18 sọ pé: “Ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” Ní tòótọ́, bí oògùn ìwọ́ra ni ọ̀rọ̀ ìwúrí ṣe máa ń rí lọ́kàn ẹni. Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.

15, 16. Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà lo ahọ́n wa láti fi fún ọmọnìkejì wa níṣìírí?

15 Ìwé 1 Tẹsalóníkà 5:14 sọ pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àní nígbà mìíràn ìsoríkọ́ lè máa bá àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà pàápàá fínra. Ọ̀nà wo la lè  gbà ran irú àwọn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? Yìn wọ́n látọkànwá lórí ohun kan pàtó láti jẹ́ kí wọ́n rí i pé àwọn wúlò lójú Jèhófà. Lo àwọn ọ̀rọ̀ alágbára tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó fi hàn pé ire “àwọn oníròbìnújẹ́” àti “àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀” jẹ Jèhófà lógún àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. (Sáàmù 34:18) Bí a bá ń lo ahọ́n wa láti fi sọ̀rọ̀ ìtùnú fún ọmọnìkejì wa, ńṣe là ń fi hàn pé à ń fara wé Ọlọ́run wa oníyọ̀ọ́nú, ẹni “tí ó ń tu àwọn ọkàn tí wọn bá rẹ̀wẹ̀sì nínú.”—2 Kọ́ríńtì 7:6, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀.

16 A tún lè lo agbára ahọ́n wa láti fún ọmọnìkejì wa ní ìṣírí tó wúlò gidigidi. Ṣé èèyàn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kan kú ni? Tí a bá sọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn tí a sì ṣaájò wọn, ìtùnú ńlá nìyẹn lè mú wá fún ẹni tó ń kẹ́dùn. Ṣé ará kan tó ti darúgbó ń rò pé òun ò wúlò mọ́ ni? Bí a bá sọ̀rọ̀ ìṣírí fáwọn àgbàlagbà, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n gbà pé àwọn ṣì wúlò àti pé a mọrírì àwọn. Ṣé ẹnì kan ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn látìgbà pípẹ́ ni? Tí a bá kàn sí aláìsàn lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tàbí kí á lọ kí i láti ṣaájò rẹ̀, iṣẹ́ kékeré kọ́ nìyẹn lè ṣe láti túbọ̀ mú ara rẹ̀ yá sí i. Inú Ẹlẹ́dàá wa mà ń dùn gan-an o, tí a bá  lo agbára ọ̀rọ̀ sísọ wa láti fi sọ ohun tó “dára fún gbígbéniró”!—Éfésù 4:29.

Sísọ ìhìn rere fúnni jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà lo agbára wa

17. Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà lo ahọ́n wa láti fi ṣe ọmọnìkejì wa láǹfààní, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

17 Kò sí ọ̀nà tó tún ṣe pàtàkì bí i pé kí á lo agbára ahọ́n wa láti fi sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún ọmọnìkejì wa. Òwe 3:27 sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” Ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ló jẹ́ fún wa láti sọ ìhìn rere tí ń gbẹ̀mí là fáwọn èèyàn. Kò ní jẹ́ ohun tó tọ́ fún wa láti bo ìhìn tó jẹ́ kánjúkánjú yìí mọ́ra, nítorí inúure ni Jèhófà fi jẹ́ ká mọ̀ ọ́n. (1 Kọ́ríńtì 9:16, 22) Ṣùgbọ́n báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí ipa tí a máa kó nínú iṣẹ́ yìí pọ̀ tó?

 Fífi “Gbogbo Okun” Wa Sin Jèhófà

18. Kí ni Jèhófà ń fẹ́ ká máa ṣe?

18 Ìfẹ́ wa fún Jèhófà máa ń sún wa láti kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Kí ni Jèhófà ń fẹ́ ká máa ṣe nínú iṣẹ́ yìí? Ohun tí gbogbo wa lè ṣe láìka ipòkípò tí a lè wà nígbèésí ayé sí ni. Kó ṣáà ti jẹ́ pé ‘ohun yòówù tí a bá ń ṣe, à ń fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.’ (Kólósè 3:23) Nígbà tí Jésù ń sọ òfin tó tóbi jù lọ, ó ní: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ń fẹ́ kí olúkúlùkù wa nífẹ̀ẹ́ òun kí á sì máa fi gbogbo ọkàn wa sin òun.

19, 20. (a) Níwọ̀n bí ọkàn ti jẹ́ àpapọ̀ ọkàn àyà, èrò inú àti okun ẹni, kí wá nìdí tí Máàkù 12:30 tún fi mẹ́nu kan àwọn ẹ̀ya ara yìí lọ́tọ̀? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà?

19 Kí ló túmọ̀ sí láti máa fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run? Èèyàn lódindi, tòun ti gbogbo agbára rẹ̀ àti làákàyè rẹ̀ ni ọkàn ń tọ́ka sí. Níwọ̀n bí ọkàn ti jẹ́ àpapọ̀ ọkàn àyà, èrò inú àti okun ẹni, kí wá nìdí tí Máàkù 12:30 tún fi mẹ́nu kan àwọn ẹ̀ya ara yìí lọ́tọ̀? Wo àpèjúwe kan. Láyé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì, ẹnì kan lè ta ara rẹ̀ sóko ẹrú. Síbẹ̀, ẹrú ọ̀hún lè má fi tọkàntọkàn sin ọ̀gá rẹ̀; ó lè má lo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára rẹ̀ tàbí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ làákàyè rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún ìtẹ̀síwájú ọ̀gá rẹ̀. (Kólósè 3:22) Ìyẹn ni Jésù fi mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ yòókù yìí lọ́tọ̀ láti fi tẹnu mọ́ ọn pé a kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ohunkóhun kù láìlò nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. Fífi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run túmọ̀ sí pé ká fi ara wa jin iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, nípa lílo okun àti agbára wa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn yẹn.

20 Ṣé fífi gbogbo ọkàn wa sìn wá túmọ̀ sí pé gbogbo wa ní láti máa lo iye wákàtí àti ìwọ̀n agbára kan náà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa ni? Bóyá nìyẹn á fi lè ṣeé ṣe, nítorí ipò tó yí kálukú ká àti agbára olúkúlùkù yàtọ̀ síra látorí ẹnì kan sí ẹnì kejì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ kan tí ara rẹ̀ le koko lè máa lo àkókò púpọ̀ sí i lóde  ẹ̀rí ju ẹnì kan tó ti ń darúgbó tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́. Ó sì ṣeé ṣe kí ohun tí ẹni tí ò lọ́kọ tàbí ẹni tí ò láya, tí kò sí pé ó ń gbọ́ bùkátà ìdílé, máa ṣe pọ̀ ju tẹni tó ń gbé ẹrù ìdílé lọ. Bí a bá ní okun, tí a sì wà ní ipò tí a fi lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ńṣe ni ká máa dúpẹ́ o! Àmọ́ ṣá, ká má ṣe ṣàríwísí ẹnikẹ́ni, débi pé ká máa wá fi ara wa wé ẹlòmíràn lórí ọ̀ràn yìí o. (Róòmù 14:10-12) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa lo agbára wa láti fi fún ọmọnìkejì wa níṣìírí.

21. Ọ̀nà wo ló dára tó sì ṣe pàtàkì jù lọ tí a lè gbà lo agbára wa?

21 Jèhófà a máa lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó tọ́, nípa bẹ́ẹ̀ ó ti fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa. Gbogbo ipá wa ló yẹ ká máa sà láti fara wé e débi tó bá ti ṣeé ṣe fún èèyàn aláìpé láti ṣe é dé. Kí á máa lo agbára wa lọ́nà tó tọ́ nípa bíbuyì kún àwọn tí a láṣẹ lé lórí dé ìwọ̀n àyè kan. Láfikún sí i, ó yẹ ká máa fi gbogbo ọkàn wa ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó ń gbẹ̀mí là tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ láti ṣe. (Róòmù 10:13, 14) Rántí pé inú Jèhófà máa ń dùn nígbà tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe, tó túmọ̀ sí pé ò ń fí gbogbo ọkàn rẹ sìn ín. Ǹjẹ́ kò sì wù ọ́ látọkànwá láti máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti fi sin irú Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti olóye yìí? Ọ̀nà yìí lọ̀nà tó dára jù lọ tàbí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o tún lè gbà lo agbára rẹ.

^ ìpínrọ̀ 10 Láyé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “ọ̀pá” ni wọ́n ń lò fún sàǹda, ìyẹn ọ̀pá táwọn olùṣọ́ àgùntàn máa fi ń da àgùntàn. (Sáàmù 23:4) Bákan náà, ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ ni “ọ̀pá” àṣẹ òbí ń tọ́ka sí, kì í ṣe fífi ìkanra tàbí ìwà ìkà jẹni níyà.