Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà Ọlọ́run

 Orí 6

Agbára Ìpanirun—Jèhófà, “Akin Lójú Ogun”

Agbára Ìpanirun—Jèhófà, “Akin Lójú Ogun”

1-3. (a) Kí ni àwọn ará Íjíbítì gbìdánwò láti ṣe sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe jà fún àwọn èèyàn rẹ̀?

ÀWỌN ọmọ Ísírẹ́lì há sáàárín gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè eléwu àti òkun tí kò ṣeé rọ́ lù. Àwọn ọmọ ogun Íjíbítì apààyàn rèé tó ń lépa wọn bọ̀ kíkankíkan yìí. Erìkìnà òǹrorò ni wọ́n, kò sì sí ìdí mìíràn tí wọn ń bá bọ̀ ju pé kí wọ́n wá run gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì pátá. * Síbẹ̀ Mósè rọ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé kí wọ́n má sọ̀rètí nù. Ó fún wọn ní ìdánilójú, ó ní: “Jèhófà yóò fúnra rẹ̀ jà fún yín.”—Ẹ́kísódù 14:14.

2 Síbẹ̀síbẹ̀, ó jọ pé Mósè ṣì ké pe Jèhófà, ìyẹn ni Ọlọ́run fi dá a lóhùn pé: “Èé ṣe tí o fi ń ké jáde ṣáá sí mi? . . . Ní tìrẹ, gbé ọ̀pá rẹ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí o sì pín in níyà.” (Ẹ́kísódù 14:15, 16) Ìwọ fojú inú wo ohun tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fún áńgẹ́lì rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ̀n àwọsánmà kúrò níwájú Ísírẹ́lì, ó sì bọ́ sẹ́yìn wọn, bóyá ńṣe ló tiẹ̀ nà gbọọrọ lọ bí ògiri tó sì dínà mọ́ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì kí wọ́n má lè bẹ̀rẹ̀ ìjà. (Ẹ́kísódù 14:19, 20; Sáàmù 105:39) Bẹ́ẹ̀ ni Mósè na ọwọ́ rẹ̀. Ẹ̀fúùfù líle wá fẹ́, ó sì pín òkun náà níyà. Ni omi rẹ̀ bá dì gbagidi, ó dúró bí ògiri lọ́tùn-ún lósì, tí ọ̀nà tó fẹ̀ tó èyí tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà lè gbà kọjá sì là!—Ẹ́kísódù 14:21; 15:8.

3 Bí Fáráò ṣe rí ọ̀nà àrà tí Ọlọ́run gbà fi agbára rẹ̀ hàn yìí, ṣebí ńṣe ni ì bá kàn pàṣẹ fún agbo ọmọ ogun rẹ̀ láti padà sílé. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ o, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Fáráò agbéraga pàṣẹ  pé káwọn ọmọ ogun rẹ̀ mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lé. (Ẹ́kísódù 14:23) Bí àwọn ará Íjíbítì ṣe gbá tọ̀ wọ́n wọnú ọ̀nà tó là gba inú òkun kọjá nìyẹn, ṣùgbọ́n wọn ò tíì bá eré wọn débì kankan tí nǹkan fi yíwọ́. Àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn bẹ̀rẹ̀ sí fò yọ dà nù. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gòkè odò tán pátá báyìí ni Jèhófà pàṣẹ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí omi náà lè padà wá sórí àwọn ará Íjíbítì, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun wọn àti àwọn agẹṣinjagun wọn.” Bí omi tó dúró bí ògiri nì ṣe wó nìyẹn o, tó bo Fáráò àti agbo ọmọ ogun rẹ̀ mọ́lẹ̀!—Ẹ́kísódù 14:24-28; Sáàmù 136:15.

Ní Òkun Pupa, Jèhófà fi hàn pé òun jẹ́ “akin lójú ogun”

4. (a) Irú ẹni wo ni Jèhófà fi hàn pé òun jẹ́ ní Òkun Pupa? (b) Kí ló lè jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn kan sí ohun tí ibí fi hàn pé Jèhófà ṣe yìí?

4 Ohun mánigbàgbé ni gbígbà tí Jèhófà gba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì là nínú Òkun Pupa yìí jẹ́ nínú ìtàn àjọṣe Ọlọ́run pẹ̀lú ọmọ aráyé. Jèhófà fi hàn níbẹ̀ pé òun jẹ́ “akin lójú ogun.” (Ẹ́kísódù 15:3) Àmọ́, kí ni ìṣarasíhùwà tìrẹ nípa ohun tí ibí fi hàn pé Jèhófà ṣe yìí? Ní tòdodo, ogun ti kó ìrora àti ìjìyà púpọ̀ bá ọmọ aráyé. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣé bí Ọlọ́run ṣe lo agbára rẹ̀ láti ṣèparun yìí ò lé ọ sá dípò kó mú ọ fà mọ́ ọn?

Ogun Ọlọ́run Ní Ìfiwéra Pẹ̀lú Tọmọ Aráyé

5, 6. (a) Kí nìdí tó fi tọ́ láti pe Ọlọ́run ní “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun”? (b) Báwo ni ogun Ọlọ́run ṣe yàtọ̀ sí ogun ọmọ aráyé?

5 Ó tó ọ̀ọ́dúnrún ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti ẹ̀ẹ̀mejì nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tá a pe Ọlọ́run ní orúkọ oyè yìí, “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” (1 Sámúẹ́lì 1:11) Nítorí pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, ọ̀kẹ́ àìmọye agbo ogun àwọn áńgẹ́lì ló wà níkàáwọ́ rẹ̀. (Jóṣúà 5:13-15; 1 Àwọn Ọba 22:19) Ìparun tí agbo ọmọ ogun yìí lágbára láti ṣe pọ̀ jọjọ. (Aísáyà 37:36) Ìparun ọmọ ènìyàn kì í ṣe ohun tó dùn mọ́ni láti máa ronú lé rárá. Àmọ́, ká rántí pé ogun Ọlọ́run kò dà bí  ìforígbárí tó ń wáyé láàárín ọmọ aráyé. Àwọn olórí ogun àtàwọn aṣáájú òṣèlú lè fẹ́ máa sọ pé nítorí kí nǹkan lè dáa làwọn fi ń gbógun dìde. Ṣùgbọ́n bá a bá wádìí ohun tí ń bẹ lẹ́yìn ogun ọmọ aráyé, ìwọra àti ìmọtara-ẹni nìkan la óò bá níbẹ̀.

6 Ṣùgbọ́n ti Jèhófà yàtọ̀, ìwàǹwára kọ́ ló ń sún un jagun ní tirẹ̀. Diutarónómì 32:4 sọ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàápàá tiẹ̀ sọ pé ìbínú àìníjàánu, ìwà ìkà àti ìwà ipá kò dára. (Jẹ́nẹ́sísì 49:7; Sáàmù 11:5) Nítorí náà, Jèhófà kì í dìde ogun láìnídìí. Kì í sì í fi gbogbo agbára rẹ̀ jà tó bá fẹ́ pa àwọn olubi run, ìgbà tọ́ràn bá dójú ẹ̀ tán ló máa ń lò ó. Bí ó ṣe gbẹnu Ìsíkíẹ́lì wòlíì rẹ̀ sọ̀rọ̀ ló ṣe jẹ́, ó ní: “‘Èmi ha ní inú dídùn rárá sí ikú ẹni burúkú,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘bí kò ṣe pé kí ó yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè ní ti tòótọ́?’”—Ìsíkíẹ́lì 18:23.

7, 8. (a) Èrò òdì wo ni Jóòbù ní nípa ìyà tó ń jẹ ẹ́? (b) Báwo ni Élíhù ṣe tún èrò Jóòbù ṣe lórí ọ̀ràn yìí? (d) Ẹ̀kọ́ wo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù kọ́ wa?

7 Kí wá nìdí tí Jèhófà fi ń lo agbára rẹ̀ láti fi ṣèparun? Ká tó dáhùn, ẹ lè jẹ́ ká kọ́kọ́ rántí ọ̀ràn Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ nì. Sátánì lóun ò gbà pé Jóòbù, àtọmọ aráyé èyíkéyìí pàápàá, lè pa ìwà títọ́ mọ́ lójú àdánwò. Ohun tí Jèhófà fi dáhùn ọ̀rọ̀ yìí ni pé ó gbà kí Sátánì dán ìwà títọ́ Jóòbù wò. Nípa bẹ́ẹ̀, àìsàn gbé Jóòbù dè, ọrọ̀ rẹ̀ pòórá, àwọn ọmọ rẹ̀ sì tún kú mọ́ ọn lójú. (Jóòbù 1:1-2:8) Nítorí pé Jóòbù kò mọ ohun tí ń bẹ nídìí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó kàn ti gbà pé Ọlọ́run ló ń fìyà tí kò tọ́ sóun jẹ òun. Ìyẹn ló fi ń bi Ọlọ́run léèrè ìdí tó fi fòun “ṣe àfojúsùn” rẹ̀ tó sì ka òun sí “ọ̀tá.”—Jóòbù 7:20; 13:24.

8 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Élíhù tọ́ka ohun tó lòdì nínú èrò Jóòbù, ó ní: “Ìwọ wí pé, ‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ.’” (Jóòbù 35:2) Òótọ́ ni o, kò bọ́gbọ́n mu rárá láti rò pé a mọ̀  ju Ọlọ́run lọ tàbí ká kàn máa ronú pé kò ṣẹ̀tọ́. Élíhù sọ pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú, àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!” Ó sì tún wá sọ pé: “Ní ti Olódùmarè, àwa kò lè rídìí rẹ̀; ó ga ní agbára, òun kì yóò sì fi ojú kékeré wo ìdájọ́ òdodo àti ọ̀pọ̀ yanturu òdodo.” (Jóòbù 34:10; 36:22, 23; 37:23) Kí ó dá wa lójú pé ajà-má-jẹ̀bi ni Ọlọ́run, kí ó tó jà ó máa ń nídìí. Nígbà tá a ti wá mọ ìyẹn wàyí, ẹ jẹ́ ká wá wo àwọn ìdí díẹ̀ tí Ọlọ́run àlàáfíà fi máa ń di jagunjagun nígbà mìíràn.—1 Kọ́ríńtì 14:33.

Ìdí Tó Fi Máa Ń Di Dandan Kí Ọlọ́run Àlàáfíà Jà

9. Kí nìdí tí Ọlọ́run àlàáfíà fi máa ń jà?

9 Lẹ́yìn tí Mósè yin Ọlọ́run pé ó jẹ́ “akin lójú ogun,” ó wá polongo pé: “Jèhófà, ta ní dà bí rẹ láàárín àwọn ọlọ́run? Ta ní dà bí rẹ, tí o ń fi ara rẹ hàn ní alágbára ńlá ní ìjẹ́mímọ́?” (Ẹ́kísódù 15:11) Wòlíì Hábákúkù pẹ̀lú kọ̀wé pé: “Ojú rẹ ti mọ́ gaara jù láti rí ohun tí ó burú; ìwọ kò sì lè wo ìdààmú.” (Hábákúkù 1:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó tún jẹ́ Ọlọ́run ìjẹ́mímọ́, òdodo àti ìdájọ́ òdodo. Àwọn ànímọ́ báwọ̀nyí ló máa ń mú kó di dandan fún un láti lo agbára rẹ̀ láti pani run nígbà mìíràn. (Aísáyà 59:15-19; Lúùkù 18:7) Nítorí náà, kì í ṣe pé Ọlọ́run ń kó àbààwọ́n bá ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ nígbà tó bá jà. Kàkà bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ ló ṣe máa ń jà.—Ẹ́kísódù 39:30.

10. (a) Ìgbà wo ló kọ́kọ́ hàn pé ó di dandan kí Ọlọ́run jà, báwo ló sì ṣe ṣẹlẹ̀? (b) Ọ̀nà kan ṣoṣo wo ni ìṣọ̀tá tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ tẹ́lẹ̀ yóò gbà yanjú, àǹfààní wo nìyẹn yóò sì mú wá fún aráyé?

10 Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà, tọkọtaya àkọ́kọ́, ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ká ní pé Jèhófà ti gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ìwà àìṣòdodo tí wọ́n hù ni, ì bá ti jin ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run lẹ́sẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo, ó di dandan fún un láti dájọ́ ikú fún wọn. (Róòmù 6:23) Ó sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì pé ìṣọ̀tá yóò wà láàárín àwọn ìránṣẹ́ òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn Sátánì, “ejò” nì. (Ìṣípayá 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ohun tó sì máa yanjú ọ̀rọ̀ ìṣọ̀tá yìí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín  ni pé ká tẹ Sátánì rẹ́. (Róòmù 16:20) Ṣùgbọ́n ìdájọ́ yẹn á yọrí sí ìbùkún ńláǹlà fún àwọn olódodo nínú ọmọ aráyé, yóò palẹ̀ gbogbo yánpọnyánrin tí Sátánì dá sílẹ̀ mọ́ kúrò ní ayé, yóò sì wá mú kí Párádísè kárí ayé ṣeé ṣe. (Mátíù 19:28) Àmọ́ kí ìyẹn tó ṣẹlẹ̀, àwọn tó bá Sátánì lẹ̀dí àpò pọ̀ kò ní yéé yọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́nu nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Yóò di dandan pé kí Jèhófà máa dá sí ọ̀ràn ọ̀hún lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Ọlọ́run Gbé Ìgbésẹ̀ Láti Mú Ìwà Ibi Kúrò

11. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi rí i pé ó di dandan pé kóun mú ìkún omi wá sórí gbogbo ayé?

11 Ìkún Omi ọjọ́ Nóà jẹ́ ọ̀kan lára ìgbà tí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn ọ̀hún. Jẹ́nẹ́sísì 6:11, 12 sọ pé: “Ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́, ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá. Nítorí náà, Ọlọ́run rí ilẹ̀ ayé, sì wò ó! ó bàjẹ́, nítorí pé gbogbo ẹlẹ́ran ara ti ba ọ̀nà ara rẹ̀ jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” Ṣé Ọlọ́run á wá gbà kí àwọn olubi kúkú wá paná ìwọ̀nba ìwà rere tó ṣẹ́ kù láyé bámúbámú ni? Ó tì o. Jèhófà rí i pé ó di dandan kí òun mú ìkún omi wá sórí gbogbo ayé láti pa àwọn tó ti sọ ìwà ipá àti ìṣekúṣe di bára kú run.

12. (a) Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa “irú-ọmọ” Ábúráhámù? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run yóò fi pa àwọn Ámórì rẹ́?

12 Irú ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Kénáánì lẹ́jọ́. Jèhófà fi hàn pé látọ̀dọ̀ Ábúráhámù ni “irú-ọmọ” tí gbogbo ìdílé ayé yóò tipasẹ̀ rẹ̀ máa bù kún ara wọn yóò ti wá. Níbàámu pẹ̀lú ète yẹn, Ọlọ́run pàṣẹ pé kí ilẹ̀ Kénáánì, níbi táwọn èèyàn tá à ń pè ní àwọn Ámórì ń gbé nígbà yẹn, di ti àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Kí ni Ọlọ́run fi lè jàre fífi tí yóò fi ipá lé àwọn èèyàn yẹn jáde kúrò ní ilẹ̀ wọn? Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé òun ò ní lé wọn jáde títí di nǹkan bí irínwó ọdún sí ìgbà yẹn, ìyẹn títí di ìgbà tí “ìṣìnà àwọn Ámórì” yóò fi “parí.” * (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3; 13:14, 15; 15:13, 16; 22:18)  Láàárín ìgbà yìí, kàkà kéwé àgbọn àwọn Ámórì ó rọ̀, líle ló ń le sí i, ńṣe ni ìwà ìbàjẹ́ wọn ń pọ̀ sí i. Ilẹ̀ Kénáánì wá di ilẹ̀ ìbọ̀rìṣà, ìpànìyàn àti ìṣekúṣe tó burú jáì. (Ẹ́kísódù 23:24; 34:12, 13; Númérì 33:52) Àní àwọn olùgbé ibẹ̀ tilẹ̀ ń ju àwọn ọmọ wọn sínú iná láti fi rúbọ. Ṣé Ọlọ́run mímọ́ á wá gbà kí àwọn èèyàn rẹ̀ máa wá fojú winá irú ìwà ibi bẹ́ẹ̀? Rárá o! Ọlọ́run kéde pé: “Ilẹ̀ náà jẹ́ aláìmọ́, èmi yóò sì mú ìyà wá sórí rẹ̀ nítorí ìṣìnà rẹ̀, ilẹ̀ náà yóò sì pọ àwọn olùgbé rẹ̀ jáde.” (Léfítíkù 18:21-25) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé Jèhófà kàn pa gbogbo wọn run láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Ó dá àwọn tó ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ lára àwọn ọmọ Kénáánì sí, irú bíi Ráhábù àtàwọn ará Gíbéónì.—Jóṣúà 6:25; 9:3-27.

Ó Ń Jà Nítorí Orúkọ Rẹ̀

13, 14. (a) Èé ṣe tó fi di dandan pé kí Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe wẹ ẹ̀gàn nù kúrò lára orúkọ rẹ̀?

13 Nítorí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú. (Léfítíkù 22:32) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Ìṣọ̀tẹ̀ inú ọgbà Édẹ́nì tàbàwọ́n sí orúkọ Ọlọ́run, ní ti pé ó dá iyèméjì sílẹ̀ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe àkóso. Jèhófà ò jẹ́ gba irú ìbànilórúkọjẹ́ àti ìṣọ̀tẹ̀ bẹ́ẹ̀ láyè rárá. Ó di dandan fún un pé kó wẹ ẹ̀gàn nù kúrò lára orúkọ rẹ̀.—Aísáyà 48:11.

14 Tún wo ọ̀ràn tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú. Tí wọ́n bá fi lè máa wà lóko ẹrú ní Íjíbítì nìṣó, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù pé ipasẹ̀ Irú-Ọmọ rẹ̀ ni gbogbo ìdílé ayé yóò máa bù kún ara wọn kò ní lè ṣẹ. Ṣùgbọ́n bí Jèhófà ṣe dá wọn nídè tó sì fìdí wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, ńṣe ló wẹ ẹ̀gàn nù kúrò lára orúkọ rẹ̀. Ìyẹn ni wòlíì Dáníẹ́lì fi gbà á mọ́ àdúrà rẹ̀ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, ìwọ . . . mú àwọn ènìyàn rẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì nípa ọwọ́ líle, tí o sì tẹ̀ síwájú láti ṣe orúkọ fún ara rẹ.”—Dáníẹ́lì 9:15.

15. Kí nìdí tí Jèhófà fi gba àwọn Júù kúrò nígbèkùn Bábílónì?

 15 Ó yẹ fún àfiyèsí pé ìgbà kan tí àwọn Júù ń fẹ́ kí Jèhófà tún ṣe nǹkan kan nítorí orúkọ Rẹ̀ ni Dáníẹ́lì gba àdúrà tí a wí yìí. Lásìkò yẹn, àwọn Júù aláìgbọràn wà nígbèkùn ní Bábílónì. Jerúsálẹ́mù olú ìlú wọn sì wà láhoro. Dáníẹ́lì mọ̀ pé mímú àwọn Júù padà bọ̀ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn yóò gbé orúkọ Jèhófà ga. Nípa bẹ́ẹ̀, Dáníẹ́lì gbàdúrà pé: “Sáà dárí jì, Jèhófà. Sáà fetí sílẹ̀ kí o sì gbé ìgbésẹ̀, Jèhófà. Má ṣe jáfara, nítorí tìrẹ, Ọlọ́run mi, nítorí orúkọ rẹ ni a fi pe ìlú ńlá rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ.”—Dáníẹ́lì 9:18, 19.

Ó Ń Jà Nítorí Àwọn Èèyàn Rẹ̀

16. Ṣàlàyé ìdí tí fífẹ́ tí Jèhófà fẹ́ràn àtimáa gbèjà orúkọ rẹ̀ kò fi mú kó jẹ́ aláìláàánú àti onímọtara-ẹni-nìkan.

16 Ǹjẹ́ bí Jèhófà ṣe fẹ́ràn àtimáa gbèjà orúkọ rẹ̀ mú kó jẹ́ aláìláàánú àti onímọtara-ẹni-nìkan? Rárá o, nítorí bí ó ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ mímọ́ àti bó ṣe fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo ń mú kó dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Ìwọ wo ohun tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì orí kẹrìnlá ná. Níbẹ̀ la ti kà nípa àwọn ọba mẹ́rin tó ṣígun wá tí wọ́n sì kó Lọ́ọ̀tì àbúrò Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ lẹ́rú. Ọlọ́run wá ran Ábúráhámù lọ́wọ́ tó fi lè ṣẹ́gun agbo ọmọ ogun tó ju tirẹ̀ lọ ní ìlọ́po-ìlọ́po yìí! Ìtàn ìṣẹ́gun yìí ló máa fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ èyí tó kọ́kọ́ wọnú “ìwé Àwọn Ogun Jèhófà,” ìyẹn ìwé kan tó jọ pé ó tún pìtàn àwọn ogun kan tí Bíbélì kò mẹ́nu kàn. (Númérì 21:14) Ọ̀pọ̀ ìṣẹ́gun mìíràn ló tún wáyé lẹ́yìn èyí.

17. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ń jà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n wọ ilẹ̀ Kénáánì? Mú àwọn àpẹẹrẹ wá.

17 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì ni Mósè rán wọn létí pé: “Jèhófà Ọlọ́run yín ni ẹni tí ń lọ níwájú yín. Òun yóò jà fún yín, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ṣe fún yín ní Íjíbítì.” (Diutarónómì 1:30; 20:1) Jèhófà sì jà fún àwọn èèyàn rẹ̀ lóòótọ́, bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Jóṣúà tó rọ́pò Mósè títí kan ìgbà ayé àwọn Onídàájọ́ àti ìgbà ìṣàkóso àwọn olóòótọ́ nínú àwọn ọba Júdà, ó ń mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn lọ́nà  ìyanu.—Jóṣúà 10:1-14; Àwọn Onídàájọ́ 4:12-17; 2 Sámúẹ́lì 5:17-21.

18. (a) Kí nìdí tá a fi lè dúpẹ́ pé Jèhófà kò yí padà títí di báyìí? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìṣọ̀tá tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ̀rọ̀ rẹ̀ bá fi máa dé ògógóró rẹ̀?

18 Jèhófà kò yí padà títí di báyìí; bẹ́ẹ̀ ni kò yí ète rẹ̀ láti sọ ilé ayé yìí di Párádísè padà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ọlọ́run ṣì kórìíra ìwà ibi títí di ìsinsìnyí. Ẹ̀wẹ̀, ó fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀ gidigidi yóò sì jà nítorí tiwọn láìpẹ́. (Sáàmù 11:7) Kódà, a retí pé kí ìṣọ̀tá tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ̀rọ̀ rẹ̀ gbóná janjan dé ògógóró rẹ̀ láìpẹ́. Kí Jèhófà lè wá sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ kí ó sì dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, yóò tún di “akin lójú ogun” lẹ́ẹ̀kan sí i!—Sekaráyà 14:3; Ìṣípayá 16:14, 16.

19. (a) Ṣàpèjúwe ìdí tí lílò tí Ọlọ́run ń lo agbára rẹ̀ láti fi pa àwọn ẹni búburú run fi lè mú wa sún mọ́ ọn. (b) Ipa wo ló yẹ kí fífẹ́ tí Ọlọ́run ń fẹ́ láti jà nítorí tiwa ní lórí wa?

19 Wo àpèjúwe kan: Jẹ́ ká sọ pé ẹranko ẹhànnà kan kọjú ìjà sí ìdílé ọkùnrin kan, kí ọkùnrin yìí sì pa kuru mọ́ ẹranko ẹhànnà yìí, kó bá a jà kó sì pa á. Ǹjẹ́ wàá retí pé kí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ wá máa bínú sí ohun tó ṣe yìí? Ó tì o, ńṣe ni wàá retí pé kí ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ tó ní sí wọn yìí wú wọn lórí gidigidi. Lọ́nà kan náà, kò yẹ kí lílò tí Ọlọ́run ń lo agbára rẹ̀  láti fi pa àwọn ẹni búburú run bí wa nínú. Ó yẹ kí ìfẹ́ tó ní tó fi ń jà láti lè dáàbò bò wá mú ká túbọ̀ máa fẹ́ràn rẹ̀ ni. Ó sì yẹ kí ọ̀wọ̀ tí a ní fún agbára rẹ̀ tí kò lópin túbọ̀ jinlẹ̀ sí i ni pẹ̀lú. Ìyẹn la ó fi lè máa “ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run . . . pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.”—Hébérù 12:28.

Sún Mọ́ “Akin Lójú Ogun”

20. Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí a bá ka ìtàn kan nípa ogun Ọlọ́run nínú Bíbélì tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ yé wa, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

20 Lóòótọ́, Bíbélì kò ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìpinnu Jèhófà tó mú kó ja ọ̀kọ̀ọ̀kan ogun tó jà. Ṣùgbọ́n ìgbà gbogbo ni kí ó máa dá wa lójú pé: Kì í ṣe agbára ló ń gun Jèhófà tó fi ń lo agbára rẹ̀ láti ṣèparun, pé kì í lò ó láti fojú ẹni gbolẹ̀, kì í sì í lò ó láti fi ṣìkà. Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá ṣàyẹ̀wò ìtàn tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì tàbí àwọn ìsọfúnni tó jẹ mọ́ ọn, á jẹ́ kí òye ọ̀ràn yẹn túbọ̀ yé wa sí i. (Òwe 18:13) Kódà bí a ò tiẹ̀ mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn kan, bí a bá lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tí a sì ṣe àṣàrò nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó ṣeyebíye, gbogbo iyèméjì tó bá sọ sí wa lọ́kàn ni a óò mú kúrò. Bí a bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, a óò wá rí i pé a ní ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run wa Jèhófà.—Jóòbù 34:12.

21. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà mìíràn Jèhófà máa ń di “akin lójú ogun,” irú ẹni wo ni Jèhófà jẹ́?

21 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ọ̀ràn bá dójú ẹ̀, Jèhófà máa ń di “akin lójú ogun,” èyí ò túmọ̀ sí pé ó jẹ́ arógunyọ̀. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa kẹ̀kẹ́ ọ̀run, a fi Jèhófà hàn bí ẹni tó ń múra láti bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà. Síbẹ̀, Ìsíkíẹ́lì ṣì rí i pé òṣùmàrè wà yí po Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀, àmì àlàáfíà ni òṣùmàrè jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 9:13; Ìsíkíẹ́lì 1:28; Ìṣípayá 4:3) Èyí fi hàn dájú pé ọlọ́kàn tútù àti ẹni àlàáfíà ni Jèhófà jẹ́. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Gbogbo ànímọ́ Jèhófà kì í sì í ya ara wọn sílẹ̀ rárá. Àǹfààní ńláǹlà ló mà jẹ́ o, pé a lè sún mọ́ Ọlọ́run tó ní irú agbára yìí síbẹ̀ tó ṣì jẹ́ onífẹ̀ẹ́!

^ ìpínrọ̀ 1 Gẹ́gẹ́ bí Josephus, òpìtàn Júù náà ṣe wí, “ẹgbẹ̀ta [600] kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] agẹṣinjagun àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó tó ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000], tó dìhámọ́ra gbágbáágbá,” ló ń lépa àwọn Hébérù bọ̀ kíkankíkan.—Jewish Antiquities, Apá Kejì, ojú ewé 324 [xv, 3].

^ ìpínrọ̀ 12 Ẹ̀rí fi hàn pé gbólóhùn náà “Ámórì” tá a lò níhìn-ín kó gbogbo àwọn èèyàn Kénáánì pa pọ̀.—Diutarónómì 1:6-8, 19-21, 27; Jóṣúà 24:15, 18.

Mọ Púpọ̀ Sí I

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọjọ́ Ìdájọ́ á ṣe jẹ́ ìbùkún fún àwọn olóòótọ́ èèyàn.