Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà Ọlọ́run

 Orí 7

Agbára Ìdáàbòboni—‘Ọlọ́run Jẹ́ Ibi Ìsádi fún Wa’

Agbára Ìdáàbòboni—‘Ọlọ́run Jẹ́ Ibi Ìsádi fún Wa’

1, 2. Ewu wo ló wà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí wọ́n ṣe wọ ẹkùn ilẹ̀ Sínáì lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, báwo sì ni Jèhófà ṣe fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?

INÚ ewu làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà bí wọ́n ṣe wọ ẹkùn ilẹ̀ Sínáì lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìrìn ńlá tó gba ìgboyà ní ń bẹ níwájú wọn, ìrìn tó máa gbé wọn gba inú “aginjù ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù, tí ó ní àwọn ejò olóró àti àwọn àkekèé” ni. (Diutarónómì 8:15) Àwọn orílẹ̀ èdè ọ̀tá sì tún ń bẹ lọ́nà tí yóò yọ wọ́n lẹ́nu. Jèhófà ló kó àwọn èèyàn rẹ̀ wá sínú ipò yẹn. Ǹjẹ́ òun gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn á sì lè dáàbò bò wọ́n?

2 Ọ̀rọ̀ Jèhófà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni, ó ní: “Ẹ̀yin fúnra yín ti rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Íjíbítì, kí èmi lè gbé yín lórí ìyẹ́ apá àwọn idì, kí n sì mú yín wá sọ́dọ̀ ara mi.” (Ẹ́kísódù 19:4) Jèhófà rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé òun lòun gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, tí òun sì gbé wọn débi ààbò lọ́nà kan tó dà bíi pé idì lòun lò láti fi gbé wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ìdí mìíràn tún wà tó fi bá a mu láti lo “ìyẹ́ apá àwọn idì” láti fi ṣàpèjúwe ààbò Ọlọ́run.

3. Kí nìdí tó fi bá a mu láti fi “ìyẹ́ apá àwọn idì” ṣàpèjúwe ààbò Ọlọ́run?

3 Kì í ṣe rírà bàbà lójú ọ̀run nìkan ni idì ń lo ìyẹ́ apá rẹ̀ fún. Nígbà tí oòrùn bá mú ganrínganrín, abo idì yóò ga ìyẹ́ apá rẹ̀, tó máa ń gùn tó mítà méjì, bí agboòrùn láti fi ṣíji bo àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké kúrò lọ́wọ́ oòrùn tó gbóná janjan. Nígbà mìíràn yóò fi ìyẹ́ apá rẹ̀ yìí bo àwọn ọmọ rẹ̀ láti gbà wọ́n lọ́wọ́ atẹ́gùn tútù. Gẹ́lẹ́ bí idì ṣe máa ń pa àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe ṣíji bo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde bọ̀ tó sì dáàbò bò wọ́n. Bí àwọn èèyàn Jèhófà sì ṣe dénú aginjù,  yóò máa fi òjìji ìyẹ́ apá ńlá rẹ̀ dáàbò bò wọ́n nìṣó bí wọ́n bá ti lè máa bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́. (Diutarónómì 32:9-11; Sáàmù 36:7) Ṣùgbọ́n ṣé ó tọ́ pé kí àwa náà lónìí máa retí pé kí Ọlọ́run dáàbò bò wá?

Ìlérí Ààbò Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

4, 5. Kí nìdí tá a fi lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun yóò dáàbò bò wá?

4 Ó dájú pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Òun ni “Ọlọ́run Olódùmarè,” tí í ṣe orúkọ òye tó ń fi hàn pé agbára rẹ̀ borí ohun gbogbo. (Jẹ́nẹ́sísì 17:1) Bí ìgbì òkun tí ohunkóhun ò lè dá dúró ni agbára Jèhófà ṣe rí, bó bá ti lò ó kò sóhun tó lè dènà rẹ̀. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé kò sí ohunkóhun tó bá sáà ti fẹ́ tí kò lè ṣe, a lè béèrè pé, ‘Ṣé Jèhófà máa ń fẹ́ láti lo agbára rẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?’

5 Ní ṣókí, bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà ń mú un dá wa lójú pé òun yóò máa dáàbò bo àwọn èèyàn òun. Sáàmù 46:1 sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run “kò lè purọ́,” a lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé nínú ìlérí rẹ̀ pé òun yóò máa dáàbò bò wá. (Títù 1:2) Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú àwọn àkàwé ṣíṣe kedere tí Jèhófà lò láti fi ṣàpèjúwe bí òun ṣe máa ń fìṣọ́ ṣọ́ni.

6, 7. (a) Irú ààbò wo ni olùṣọ́ àgùntàn máa ń pèsè fún àgùntàn rẹ̀ láyé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe fífi tí Jèhófà ń fi tọkàntọkàn fẹ́ láti dáàbò bo àgùntàn rẹ̀ kí ó sì tọ́jú wọn?

6 Olùṣọ́ Àgùntàn ni Jèhófà jẹ́, àwa sì ni “àgùntàn pápá ìjẹko rẹ̀.” (Sáàmù 23:1; 100:3) Nínú àwọn ẹranko tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo ara wọn rárá, ti àgùntàn ló yọyẹ́. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ayé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì ní láti jẹ́ onígboyà láti lè dáàbò bo àgùntàn wọn kúrò lọ́wọ́ kìnnìún, ìkookò, béárì àti àwọn olè pẹ̀lú. (1 Sámúẹ́lì 17:34, 35; Jòhánù 10: 12, 13) Ṣùgbọ́n àwọn ìgbà mìíràn wà tí dídáàbò bo àgùntàn máa ń gba ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé àgùntàn bímọ síbi tó jìnnà sí gàá, olùṣọ́ àgùntàn yóò ní láti ṣọ́ àgùntàn yìí lásìkò tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára yẹn, kí ó sì tún gbé ọ̀dọ́ àgùntàn lẹ̀jẹ́-lẹ̀jẹ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà wá sí gàá.

“Oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí”

7 Nígbà tí Jèhófà sì fi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn, ńṣe ló ń mú un dá wa lójú pé tọkàntọkàn lòun ń fẹ́ láti máa dáàbò bò wá. (Ìsíkíẹ́lì 34:11-16) Rántí àpèjúwe Jèhófà tó wà nínú Aísáyà 40:11 tá a ṣàlàyé ní Orí 2 nínú ìwé yìí, tó sọ pé: “Bí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí.” Báwo ni ọ̀dọ́ àgùntàn ṣe dé “oókan àyà” olùṣọ́ àgùntàn yìí, ìyẹn ibi ìṣẹ́po aṣọ rẹ̀ lápá òkè? Ó ṣeé ṣe kí àgùntàn náà tọ olùṣọ́ àgùntàn wá, bóyá kó tiẹ̀ máa forí nù ún lẹ́sẹ̀. Àmọ́, olùṣọ́ àgùntàn náà ni yóò fúnra rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ gbé ọ̀dọ́ àgùntàn náà lé oókan àyà rẹ̀ láti dáàbò bò ó. Àpèjúwe bí Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá yìí ṣe ń fẹ́ láti fi ìṣọ́ ṣọ́ wa kí ó sì dáàbò bò wá mà tuni lára o!

8. (a) Àwọn wo ni ìlérí ààbò tí Ọlọ́run ṣe wà fún, báwo sì ni Òwe 18:10 ṣe fi èyí hàn? (b) Kí ló rọ̀ mọ́ fífi orúkọ Ọlọ́run ṣe ààbò?

8 Àmọ́ ṣá o, ìlérí ìdáàbòbò tí Ọlọ́run ṣe sinmi lórí àwọn ipò kan, ìyẹn ni pé, kìkì àwọn tó bá sún mọ́ ọn ló wà fún. Òwe 18:10 sọ pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” Láyé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì, wọ́n sábà máa ń kọ́ ilé gogoro sínú aginjù láti fi ṣe ibi ìsádi. Ó wá kù sọ́wọ́ ẹni tó wà nínú ewu láti sá lọ sínú ilé gogoro yẹn fún ààbò. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ pẹ̀lú fífi orúkọ Ọlọ́run ṣe ààbò nìyẹn. Ó ju pé kéèyàn sáà ti máa pe orúkọ Ọlọ́run léraléra; nítorí orúkọ Ọlọ́run kì í ṣe ohun tí à ń sà bí ẹní sa oògùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò ní láti mọ Ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn kí á sì máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Inúure Jèhófà mà pọ̀ o tó fi lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé bí a bá fi ìgbàgbọ́ yíjú sí òun, òun yóò jẹ́ ilé gogoro ààbò fún wa!

 “Ọlọ́run Wa . . . Lè Gbà Wá Sílẹ̀”

9. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣe ju pé kó kàn fẹnu ṣèlérí ààbò lásán?

9 Jèhófà ò kàn fẹnu ṣèlérí ààbò lásán, ó ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Láyé ìgbà tá à ń kọ Bíbélì, onírúurú ọ̀nà ló gbà fi hàn pé òun lè dáàbò bo àwọn èèyàn òun. Ó hàn nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé “ọwọ́” agbára ńlá Jèhófà sábà máa ń dá àwọn ọ̀tá wọn lẹ́kun. (Ẹ́kísódù 7:4) Àmọ́ ṣá, Jèhófà tún máa ń lo agbára rẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

10, 11. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló fi bí Jèhófà ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti dáàbò bo ẹnì kọ̀ọ̀kan hàn?

10 Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Hébérù mẹ́ta náà, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kọ̀ láti tẹrí ba fún ère wúrà tí Nebukadinésárì Ọba gbé kalẹ̀, ọba yìí fara ya, ó ní òun yóò gbé wọn jù sínú iná ìléru gbígbóná janjan. Nebukadinésárì, ọba tó lágbára jù lọ láyé ìgbà yẹn wá dá ṣíọ̀ wọn, ó ní: “Ta sì ni ọlọ́run yẹn tí ó lè gbà yín sílẹ̀ ní ọwọ́ mi?” (Dáníẹ́lì 3:15) Ó dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí lójú dáadáa pé Ọlọ́run àwọn lè dáàbò bo àwọn, ṣùgbọ́n wọn ò fi tìyẹn ṣe. Òun ni wọ́n fi dáhùn pé: “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run wa, ẹni tí àwa ń sìn lè gbà wá sílẹ̀.” (Dáníẹ́lì 3:17) Ní tòótọ́, ìléru oníná tí wọ́n tiẹ̀ mú kó gbóná ní ìlọ́po méje ju ti tẹ́lẹ̀ lọ yìí kò jẹ́ nǹkan kan rárá lọ́dọ̀ Ọlọ́run wọn alágbára gbogbo. Ó sì dáàbò bò wọ́n lóòótọ́, débi tí ọba yìí fi sọ tipátipá pé: “Kò . . . sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè dáni nídè bí èyí.”—Dáníẹ́lì 3:29.

11 Bákan náà, Jèhófà tún fi agbára rẹ̀ láti dáàbò boni hàn lọ́nà àgbàyanu nígbà tó ta àtaré ẹ̀mí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sínú ilé ọlẹ̀ Màríà wúńdíá ọmọ Júù náà. Áńgẹ́lì kan sọ fún Màríà pé: “Ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Áńgẹ́lì yìí ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́.” (Lúùkù 1:31, 35) Ó jọ pé kò tíì sígbà kankan tí Ọmọ Ọlọ́run wà nínú irú ipò ẹlẹgẹ́ bẹ́ẹ̀ rí. Ṣé jíjẹ́ tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé kò ní ran ọlẹ̀ yẹn báyìí? Ṣé Sátánì á ráyè ṣèpalára fún Ọmọ yẹn tàbí kó tiẹ̀  pa á ká tó bí i? Àgbẹdọ̀! Nítorí èyí, Jèhófà ṣe odi ààbò yí ká Màríà kí ohunkóhun, ì báà jẹ́ àìpé ẹ̀dá, ohun ìpalára èyíkéyìí, apànìyàn yòówù tàbí ẹ̀mí èṣù kankan, má lè ba oyún yẹn jẹ́ ní gbàrà tí oyún yẹn ti dúró lára rẹ̀. Jèhófà sì ń bá a lọ láti dáàbò bo Jésù nígbà èwe rẹ̀. (Mátíù 2:1-15) Mìmì kan ò ní lè mi ààyò Ọmọ Ọlọ́run yìí títí di àkókò tí Ọlọ́run yàn kalẹ̀.

12. Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo àwọn kan lọ́nà àrà láyé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì?

12 Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo àwọn kọ̀ọ̀kan ní àwọn ọ̀nà àrà bẹ́ẹ̀? Ìgbà púpọ̀ ló jẹ́ pé Jèhófà dáàbò bo àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan láti lè pa ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì gidi mọ́, ìyẹn: ìmúṣẹ ète rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù ṣì jẹ́ ọmọ kékeré, ó ṣe pàtàkì pé kó wà láàyè kí ète Ọlọ́run lè ṣẹ, tí yóò sì wá já sí àǹfààní fún gbogbo ọmọ aráyé. Àkọsílẹ̀ onírúurú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fi agbára rẹ̀ dáàbò boni jẹ́ ara Ìwé Mímọ́ tó ní ìmísí tí “a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, àpẹẹrẹ wọ̀nyí túbọ̀ máa ń fún ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Ọlọ́run wa Olódùmarè lókun. Ṣùgbọ́n irú ààbò wo ni a lè retí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lóde òní?

Ohun Tí Ààbò Ọlọ́run Kò Túmọ̀ Sí

13. Ṣé ó di dandan kí Jèhófà máa torí tiwa ṣe iṣẹ́ ìyanu? Ṣàlàyé.

13 Ìlérí ààbò tí Ọlọ́run ṣe kò túmọ̀ sí pé ó di dandan kí Jèhófà máa torí tiwa ṣe iṣẹ́ ìyanu. Ó tì o, Ọlọ́run wa kò ṣèlérí pé ayé gbẹdẹmukẹ la óò máa gbé ṣáá nínú ètò ògbólógbòó yìí. Ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti fojú winá ìpọ́njú, àìlówólọ́wọ́, ogun, àìsàn àti ikú. Jésù tiẹ̀ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbangba gbàǹgbà pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Ìyẹn ni Jésù fi wá tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n fara dà á dé òpin. (Mátíù 24:9, 13) Bí Jèhófà bá lọ ń fi agbára rẹ̀ gbà wá sílẹ̀ lọ́nà ìyanu ní gbogbo ìgbà, ìyẹn  lè fún Sátánì lẹ́nu ọ̀rọ̀ èyí tí yóò fi máa ṣáátá Jèhófà tí yóò sì máa ṣàríwísí nípa bóyá ìfọkànsìn wa sí Ọlọ́run jẹ́ ojúlówó tàbí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀.—Jóòbù 1:9, 10.

14. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà kì í fìgbà gbogbo dáàbò bo gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ pátá lọ́nà kan náà?

14 Kódà láyé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì, Jèhófà kò lo agbára rẹ̀ láti fi gba olúkúlùkù ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ikú òjijì. Bí àpẹẹrẹ, Hẹ́rọ́dù pa àpọ́sítélì Jákọ́bù lọ́dún 44 Sànmánì Tiwa; síbẹ̀, àìpẹ́ lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run dá Pétérù nídè “kúrò lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù.” (Ìṣe 12:1-11) Ẹ̀mí Jòhánù arákùnrin Jákọ́bù sì tún gùn ju ti Pétérù àti Jákọ́bù lọ. Ó dájú pé a ò lè retí pé kí Ọlọ́run máa dáàbò bo gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ pátá lọ́nà kan náà. Ẹ̀wẹ̀, gbogbo wa pátá ni ‘ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí.’ (Oníwàásù 9:11) Báwo wá ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá lónìí?

Jèhófà Pèsè Ààbò Nípa Ti Ara

15, 16. (a) Ẹ̀rí wo ló wà tó fi hàn pé Jèhófà ti pèsè ààbò nípa ti ara fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan? (b) Kí nìdí tí a fi lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nísinsìnyí àti nígbà “ìpọ́njú ńlá”?

15 Kọ́kọ́ wo ọ̀ràn ààbò nípa ti ara ná. Lápapọ̀, àwa olùjọsìn Jèhófà lè retí ààbò nípa ti ara gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Sátánì yóò máa he wa bí ẹní he ìgbín. Òótọ́ ọ̀rọ̀ kan nìyí: Kó sóhun tí ì bá dùn mọ́ Sátánì “olùṣàkóso ayé yìí” bíi pé kó rí i kí ìsìn tòótọ́ pa rẹ́. (Jòhánù 12:31; Ìṣípayá 12:17) Ọ̀pọ̀ àwọn ìjọba tó lágbára jù lọ láyé ló ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa tí wọ́n sì ti gbìyànjú láti pa wá rẹ́ pátápátá. Síbẹ̀síbẹ̀, mìmì kan ò mi àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n ṣì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ láìfọ̀tápè! Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ò fi lè fòpin sí ìgbòkègbodò àwùjọ àwọn Kristẹni tí ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, tí wọ́n sì tún dà bí èyí tí kò láàbò kankan yìí? Ìdí ni pé Jèhófà ti fi ìyẹ́ apá rẹ̀ alágbára dáàbò bò wá!—Sáàmù 17:7, 8.

16 Báwo ni ti ìpèsè ààbò nípa ti ara nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀? Kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù ọ̀nà tí Ọlọ́run yóò gbà  ṣe ìdájọ́ rẹ̀. Ó ṣe tán, “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.” (Ìṣípayá 7:14; 2 Pétérù 2:9) Ní báyìí ná, kí nǹkan méjì yìí máa dá wa lójú nígbà gbogbo. Àkọ́kọ́, Jèhófà ò jẹ́ gbà láéláé pé kí ẹnikẹ́ni pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ rẹ́ kúrò láyé. Ìkejì, yóò san èrè ìyè ayérayé nínú ayé tuntun òdodo fún àwọn olùpa ìwà títọ́ mọ́, tàbí kí ó jí wọn dìde sí ibẹ̀ tó bá jẹ́ pé ìyẹn ló gbà. Ní ti àwọn tó bá kú, kò tún sí abẹ́ ààbò téèyàn lè wà tó ju pé kí Ọlọ́run fini sí ìrántí rẹ̀.—Jòhánù 5:28, 29.

17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáàbò bò wá?

17 Nísinsìnyí pàápàá, Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ wa nípasẹ̀ “ọ̀rọ̀” rẹ̀ tí ó yè, tó lágbára láti wo ọkàn wa sàn, tó sì lè tún ayé wa ṣe. (Hébérù 4:12) Bí a bá ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò, yóò dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìpalára nípa ti ara dé ìwọ̀n àyè kan. Aísáyà 48:17 sọ pé: “Èmi, Jèhófà, . . . ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” Láìsí àní-àní, bí a bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàkóso ìgbésí ayé wa, ó lè mú kí á túbọ̀ ní ìlera tó dáa, kí ẹ̀mí wa sì gùn sí i. Bí àpẹẹrẹ, nítorí pé à ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kí á ta kété sí àgbèrè àti pé kí á wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin sílò, à ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìwà àìmọ́ àti ìwà apanilára tó ń bayé ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́. (Ìṣe 15:29; 2 Kọ́ríńtì 7:1) A mà dúpẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń dáàbò bò wá o!

Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Nípa Tẹ̀mí

18. Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè ààbò nípa tẹ̀mí fún wa?

18 Èyí tó tún wá pabanbarì nínú rẹ̀ ni pé Jèhófà ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí. Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ máa ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ewu tẹ̀mí nípa pípèsè gbogbo ohun tí a nílò láti lè forí ti àdánwò àti pé kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ má ṣe bà jẹ́. Nípa ṣíṣe èyí, ńṣe ni Jèhófà ń bá wa pa ìwàláàyè wa mọ́, ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ kọ́ ni yóò fi pa á mọ́ o, títí láé ni. Wo díẹ̀ lára àwọn ìpèsè Ọlọ́run tó lè dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí ná.

19. Báwo ni ẹ̀mí Jèhófà ṣe lè mú kó ṣeé ṣe fún wa láti kojú àdánwò yòówù kó dé bá wa?

 19 Jèhófà ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Tó bá dà bí i pé pákáǹleke ayé yìí fẹ́ pin wá lẹ́mìí, tí a bá sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wa fún un pátá, a óò rí ìtura tí ó tó gbà. (Fílípì 4:6, 7) Ó lè má ṣe iṣẹ́ ìyanu láti mú àdánwò wa yẹn kúrò o, ṣùgbọ́n láti dáhùn àdúrà àtọkànwá tí a gbà, ó lè fún wa ní ọgbọ́n tí a óò fi bójú tó o. (Jákọ́bù 1:5, 6) Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tó bá béèrè fún un. (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí alágbára yẹn lè mú kí á lè kojú àdánwò tàbí ìṣòro yòówù kí ó dé bá wa. Ó lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” tí a fi lè máa forí tì í nìṣó títí Jèhófà yóò fi mú gbogbo ìṣòro ríronilára kúrò nínú ayé tuntun tó kù sí dẹ̀dẹ̀ yìí.—2 Kọ́ríńtì 4:7.

20. Báwo ni Jèhófà ṣe lè tipasẹ̀ àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa lo agbára rẹ̀ láti dáàbò bò wá?

20 Nígbà mìíràn, ó lè jẹ́ pé ipasẹ̀ àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa ni Jèhófà yóò ti lo agbára rẹ̀ láti dáàbò bò wá. Jèhófà pe àwọn èèyàn rẹ̀ wá sínú “ẹgbẹ́ àwọn ará” tó kárí ayé. (1 Pétérù 2:17; Jòhánù 6:44) À ń rí ẹ̀rí tó hàn gbangba látinú ìwà àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ ará tó dùn mọ́ni yìí pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń súnni ṣe rere. Ẹ̀mí yẹn máa ń jẹ́ ká méso jáde,  ìyẹn àwọn àtàtà ànímọ́ tó wuni, títí kan ìfẹ́, inú rere àti ìwà rere. (Gálátíà 5:22, 23) Nítorí náà, bí a bá wà nínú wàhálà, tí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kan sì rí i pé á dáa kí òun fún wa ní ìmọ̀ràn dáadáa kan, tàbí pé kóun sọ̀rọ̀ ìṣírí tí a nílò gan-an fún wa, kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó tipa bẹ́ẹ̀ ń ṣètọ́jú wa.

21. (a) Irú oúnjẹ nípa tẹ̀mí tó ń bọ́ sákòókò wo ni Jèhófà ń pèsè fún wa nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”? (b) Ọ̀nà wo ni ìwọ alára ti gbà jàǹfààní látinú àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè láti fi dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí?

21 Jèhófà tún ń pèsè nǹkan mìíràn láti fi dáàbò bò wá. Oúnjẹ nípa tẹ̀mí tó ń bọ́ sákòókò ni. Jèhófà yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa pèsè oúnjẹ nípa tẹ̀mí láti mú kí á lè máa rí okun gbà látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹrú olóòótọ́ yìí máa ń lo àwọn ìtẹ̀jáde, títí kan ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ àkànṣe, àyíká àti ti àgbègbè láti fi pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ fún wa, ìyẹn ni pé wọ́n ń pèsè àwọn ohun tá a nílò lásìkò. (Mátíù 24:45) Ǹjẹ́ ó tíì ṣẹlẹ̀ sí ọ rí pé o gbọ́ nǹkan kan ní ìpàdé Kristẹni, bóyá nínú ìdáhùn ẹnì kan, ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ lórí pèpéle tàbí nínú àdúrà pàápàá, tó fún ọ ní okun àti ìṣírí tó o nílò gẹ́lẹ́? Ǹjẹ́ o tíì rí àpilẹ̀kọ pàtó kan tí a tẹ̀ jáde nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn wa tó nípa lórí ìgbésí ayé rẹ? Má ṣe gbàgbé pé Jèhófà ló ń pèsè irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ láti fi dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí.

22. Ọ̀nà wo ni Jèhófà máa ń gbà lo agbára rẹ̀ nígbà gbogbo, kí sì nìdí tí lílò tó ń lò ó lọ́nà bẹ́ẹ̀ fi máa ń jẹ́ fún ire wa?

22 Dájúdájú, apata ni Jèhófà jẹ́ “fún gbogbo àwọn tí ń sá di í.” (Sáàmù 18:30) Ó yé wa pé kì í lo agbára rẹ̀ láti yọ wá nínú gbogbo àjálù pátá nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé ó máa ń lo agbára tó fi ń dáàbò boni yìí láti fi rí i pé ète òun nímùúṣẹ. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ire àwọn èèyàn rẹ̀ sì ni ohun tó bá ṣe máa ń já sí. Bí a bá sún mọ́ Jèhófà tí a kò sì yà kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀, yóò fún wa ní ìwàláàyè pípé títí ayérayé. Bí ìyẹn bá sì ti wà lọ́kàn wa, ìyà yòówù kó máa jẹ wá nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí, ńṣe la ó kà á sí ohun tó kàn wà fún “ìgbà díẹ̀, tí ó sì fúyẹ́.”—2 Kọ́ríńtì 4:17.