Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà Ọlọ́run

Ọlọ́run ní kó o wá sún mọ́ òun. Ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bó o ṣe lè ṣe é

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

O lè sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, kó o sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ títí láé

ORÍ 1

“Wò Ó! Ọlọ́run Wa Nìyí”

Kí lò dé tí Mósè fi béèrè orúkọ Ọlọ́run nígbà tó jẹ́ pé ó ti mọ orúkọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀?

ORÍ 2

Ǹjẹ́ O Lè “Sún Mọ́ Ọlọ́run” Ní Tòótọ́?

Jèhófà Ọlọ́run tó dá ọ̀run àti ayé ní ká wá di ọ̀rẹ́ òun, ó sì ṣèlérí kan fún wa.

ORÍ 3

“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”

Kí ló dé tí Bíbélì fi so ìjẹ́mímọ́ mọ́ ẹwà?

ORÍ 4

“Jèhófà . . . Tóbi ní Agbára”

Ṣé ó yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run nítorí agbára rẹ̀? A lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ní, ká sì tún sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́.

ORÍ 5

Agbára Ìṣẹ̀dá—“Olùṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ilẹ̀ Ayé”

Gbogbo nǹkan tí Jèhófà dá, látorí òórùn tó tóbi dé orí ẹyẹ akùnyùnmù tó kéré gan-an, ló ń kọ́ wa ní nǹkan pàtàkì nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́.

ORÍ 6

Agbára Ìpanirun—Jèhófà, “Akin Lójú Ogun”

Kí ló dé tí “Ọlọ́run àlááfíà” ṣe máa ń jagun?

ORÍ 7

Agbára Ìdáàbòboni—‘Ọlọ́run Jẹ́ Ibi Ìsádi fún Wa’

Ọ̀nà méjì ni Ọlọ́run ń gbà dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ ọ̀kan ṣe pàtàkì jù.

ORÍ 8

Agbára Ìmúbọ̀sípò—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”

Jèhófà ti mú ìjọsìn tòótọ́ bọ̀ sípò. Kí làwọn ohun tó máa mú bọ̀ sípò lọ́jọ́ iwájú?

ORÍ 9

“Kristi Agbára Ọlọ́run”

Kí ni àwọn iṣẹ́ ìyanu àti ẹ̀kọ́ Jésù kọ́ wa nípa Jèhófà?

ORÍ 10

“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run” Nípa Bí Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára

O lè lágbára ju bó o ṣe rò lọ​—báwo lo ṣe lè lò ó lọ́nà tó dáa?

ORÍ 11

“Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀ Jẹ́ Ìdájọ́ Òdodo”

Báwo ni ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣe ń mú ká sún mọ́ ọn?

ORÍ 12

“Àìṣèdájọ́ Òdodo Ha Wà Pẹ̀lú Ọlọ́run Bí?”

Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Jèhófà kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ, kí ló dé tí ìwà ìrẹ́jẹ fi kúnnú ayé?

ORÍ 13

“Òfin Jèhófà Pé”

Báwo ni òfin ṣe lè mú kéèyàn máa nífẹ̀ẹ́?

ORÍ 14

Jèhófà Pèsè “Ìràpadà ní Pàṣípààrọ̀ fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”

Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí kò ṣòroó lóye tó máa mú wa sún mọ́ Ọlọ́run

ORÍ 15

Jésù “Gbé Ìdájọ́ Òdodo Kalẹ̀ ní Ilẹ̀ Ayé”

Báwo ni Jésù ṣe gbé ìdájọ́ òdodo lárugẹ láyé àtijọ́? Báwo lo ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní báyìí? Báwo ló sì ṣe máa fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

ORÍ 16

Máa “Ṣe Ìdájọ́ Òdodo” Bó O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Rìn

Kí ló dé tí Jésù fi kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́”?

ORÍ 17

‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’

Kí nìdí tí ọgbọ́n Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì ju ìmọ̀ àti òye rẹ̀ lọ?

ORÍ 18

Ọgbọ́n Wà Nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì dípò kó lo àwọn áńgẹ́lì tàbí kóun fúnra rẹ̀ ṣe é?

ORÍ 19

“Ọgbọ́n Ọlọ́run Nínú Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Kan”

Kí ni àṣírí ọlọ́wọ̀ tí Ọlọ́run fi pa mọ́ nígbà kan àmọ́ tó ti ṣí payá báyìí?

ORÍ 20

Ó Jẹ́ “Ọlọ́gbọ́n ní Ọkàn-Àyà”—Síbẹ̀ Onírẹ̀lẹ̀ Ni

Báwo ni Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé àti ọ̀run ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

ORÍ 21

Jésù Fi “Ọgbọ́n Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” Hàn

Báwo ni ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ àwọn èèyàn ṣe mú kí àwọn ọmọ ogun tó wá mú un pa dà lọ́wọ́ òfo?

ORÍ 22

Ǹjẹ́ Ò Ń Lo “Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè” Nígbèésí Ayé Rẹ?

Bíbélì jẹ́ ká mọ nǹkan mẹ́rin tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

ORÍ 23

“Òun Ni Ó Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”

Kí ni ọ̀rọ̀ náà, “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” túmọ̀ sí?

ORÍ 24

Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”

Irọ́ gbuu ni pé Ọlọ́run kò lè nífẹ̀ẹ́ rẹ láé tàbí pé o ò wúlò. Wo ìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀.

ORÍ 25

“Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run Wa”

Ọ̀nà wo ni ọwọ́ tí Ọlọ́run fi ń mú ẹ fi dà bí ọwọ́ tí ìyá fi ń mú ọmọ rẹ̀?

ORÍ 26

Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

Tó bá jẹ́ Ọlọ́run máa ń rántí gbogbo nǹkan, báwo ló ṣe lè dárí jini kò si gbàgbé ẹ̀?

ORÍ 27

“Wo Bí Oore Rẹ̀ Ti Pọ̀ Tó!”

Kí ló túmọ̀ sí pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni rere?

ORÍ 28

“Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”

Kí ló dé tí ìdúróṣinṣin Ọlọ́run fi lágbára jú ìṣòtítọ́ rẹ̀ lọ?

ORÍ 29

“Láti Mọ Ìfẹ́ Kristi”

Apá mẹ́ta tí ìfẹ́ Jésù pín sí jẹ́ ká mọ irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní dáadáa.

ORÍ 30

“Máa Bá A Lọ ní Rírìn Nínú Ìfẹ́”

Ìwé Kọ́ríńtì kìíní jẹ́ ká mọ ọ̀nà mẹ́rìnlá tá a lè gbà fi ìfẹ́ hàn.

ORÍ 31

“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò sì Sún Mọ́ Yín”

Ìbéèrè wo ló ṣe pàtàkì jù tó o lè bi ara ẹ? Báwo lo ṣe máa dáhùn?