Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Pa Da Sọ́dọ̀ Jèhófà

 APÁ 5

Pa dà Sọ́dọ̀ ‘Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alábòójútó Rẹ’

Pa dà Sọ́dọ̀ ‘Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alábòójútó Rẹ’

Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà jọ àwọn ohun tá a jíròrò nínú ìwé yìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kó o mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lára àwọn míì náà. Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ àti lóde òní ló ní irú àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu bà, àmọ́ Jèhófà mú kí wọ́n borí àwọn ìṣòro yẹn. Mọ̀ dájú pé á mú kíwọ náà borí tìẹ.

Jèhófà á wà pẹ̀lú rẹ bó o ṣe ń  pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀

 JẸ́ KÓ dá ẹ lójú pé Jèhófà á wà pẹ̀lú rẹ bó o ṣe ń  pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Á mú kó o borí àníyàn, á bá ẹ yanjú ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, á sì jẹ́ kó o ní àlááfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá mọ́. Èyí á mú kó wù ẹ́ láti tún pa dà máa sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn bíi tìẹ. Ọ̀rọ̀ rẹ á wà dà bíi tàwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa wọn pé: “Ẹ dà bí àwọn àgùntàn, tí ń ṣáko lọ; ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ ti padà sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn àti alábòójútó ọkàn yín.”—1 Pétérù 2:25.

Ohun tó dáa jù ni pé kó o pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá múnú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Ìwọ náà sì mọ̀ pé ohun tá a bá ṣe lè múnú Jèhófà dùn tàbí kó o bà á lọ́kàn jẹ́. Ohun kan ni pé, Jèhófà kì í fipá mú wa pé ká sin òun tàbí pé ká nífẹ̀ẹ́ òun. (Diutarónómì 30:19, 20) Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé ńṣe ni ọkàn èèyàn dà bí ilẹ̀kùn kan tó jẹ́ pé inú nìkan ni wọ́n ti lè ṣí i. Béèyàn ò bá fúnra rẹ̀ ṣí i, kò sẹ́lòmíì tó lè ṣí i. Tá a bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, tá a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣe lò dà bíi pé a ṣí ìlẹ̀kùn ọkàn wa sílẹ̀ fún un. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa dà bíi pé a fún Jèhófà ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ẹ̀bùn yẹn la lè fi wé ìṣòtítọ́ wa, èyí á sì múnú rẹ̀ dùn gan-an. Wàá wá rí i pé kò sóhun tá a lè fi wé ayọ̀ téèyàn máa ń ní téèyàn bá fún Jèhófà ní ìjọsìn tó tọ́ sí i.—Ìṣe 20:35; Ìṣípayá 4:11.

Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà pa dà, wàá rí i pé ṣe lo túbọ̀ ń láyọ̀ bó o ṣe ń jọ́sìn rẹ̀. (Mátíù 5:3) Lọ́nà wo? Nǹkan tojú sú àwọn èèyàn níbi gbogbo láyé, wọ́n fẹ́ mọ ìdí tá a fi wà láyé. Wọ́n ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè nípa ìgbésí ayé. Aráyé ń fẹ́ mọ àwọn nǹkan yìí torí Jèhófà dá wa lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ó ti dá a mọ́ wa pé kó máa wù wá láti jọ́sìn òun. Kò sì sóhun tó lè tẹ́ wa lọ́rùn bíi ká jọ́sìn Jèhófà torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 63:1-5.

Ọ̀rẹ́ wa, Jèhófà fẹ́ kó o pa dà wá sọ́dọ̀ òun. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Wò ó báyìí ná: Tàdúràtàdúrà la fi fara balẹ̀ ṣe ìwé yìí. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ alàgbà kan tàbí ẹni tó o ti mọ̀ rí nínú ìjọ ló mú un wá bá ẹ. Ohun tó o kà níbẹ̀ wú ẹ lórí, ó sì ta ọ́ jí tó bẹ́ẹ̀ tó o fi pinnu pé wàá ṣiṣẹ́ lé e lórí. Gbogbo èyí fi hàn pé Jèhófà ò gbàgbé rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè pa dà sọ́dọ̀ òun Ọlọ́run rẹ.—Jòhánù 6:44.

Ó tù wá nínú pé Jèhófà kì í gbàgbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó kúrò nínú ètò rẹ̀. Bó ṣe rí lára arábìnrin kan tó ń jẹ́ Donna nìyẹn, ó ní: “Díẹ̀díẹ̀ ni mo kúrò nínú òtítọ́ láìfura, ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà yẹn, ńṣe ni mo máa ń ronú lórí Sáàmù 139:23, 24, tó ní: ‘Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè. Kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, Kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.’ Ní gbogbo ìgbà yẹn, mo rí i pé ìwà àwọn èèyàn ayé ò bá mi lára mú rárá. Ṣe ni mo máa ń sọ lọ́kàn mi pé, lọ́jọ́ kan màá pa dà sínú ètò Jèhófà torí pé ibẹ̀ ló yẹ kí n wà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé Jèhófà ò pa tì. Èmi ló yẹ kí n wá ọ̀nà láti pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Inú mi sì dùn gan-an pé mo ti pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ báyìí.”

“Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé Jèhófà ò pa tì; èmi ló yẹ kí n wá ọ̀nà láti pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀”

Àdúrà wa ni pé kí ìwọ náà pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, kí ó sì máa rí ìdùnnú rẹ̀. (Nehemáyà 8:10) O ò ní kábàámọ̀ láé pé o pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.