Olùṣọ́ àgùntàn kan kó agbo ẹran rẹ̀ lọ jẹ̀ nínú pápá, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ọ̀kan lára àwọn àgùntàn náà jẹko lọ láìmọ̀ pé òun ti kúrò láàárín agbo. Ìgbà tó máa gbójú sókè, kò rí àwọn àgùntàn yòókù mọ́, kò sì rí olówó rẹ̀. Ilẹ̀ ti ń ṣú, ibi gbogbo sì dá páropáro. Òun nìkan ló wà nínú igbó táwọn ẹranko ẹhànnà wà. Ṣàdédé ló gbọ́ ohùn olùṣọ́ àgùntàn rẹ̀, ọkùnrin yìí sáré mọ́ àgùntàn náà, ó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó gbé e máyà, ó faṣọ bò ó, ó sì gbé e pa dà sílé.

NÍNÚ Bíbélì, léraléra ni Jèhófà fi ara rẹ̀ wé irú olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Èmi yóò sì wá àwọn àgùntàn mi, èmi yóò sì bójú tó wọn.”—Ìsíkíẹ́lì 34:11, 12.

“Èmi Yóò Bójú Tó Àwọn Àgùntàn Mi”

Àwọn wo ni àgùntàn Jèhófà? Àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó sì ń jọ́sìn rẹ̀ ni àgùntàn Jèhófà. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a jọ́sìn, kí a sì tẹrí ba; ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájú Jèhófà Olùṣẹ̀dá wa. Nítorí òun ni Ọlọ́run wa, àwa sì ni àwọn ènìyàn pápá ìjẹko rẹ̀ àti àwọn àgùntàn ọwọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 95:6, 7) Bí àwọn àgùntàn ṣe máa ń tẹ̀ lé olùṣọ́ àgùntàn wọn bẹ́ẹ̀ làwọn olùjọsìn Jèhófà máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà, Olùṣọ́ àgùntàn wọn. Àmọ́ wọ́n máa ń ṣàṣìṣe, àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Bíbélì sọ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dà bí “àwọn àgùntàn tí a fọ́n ká,” tàbí “àwọn àgùntàn tí ó sọnù,” tàbí “àwọn àgùntàn tí ó ṣáko lọ.” (Ìsíkíẹ́lì 34:12; Mátíù 15:24; 1 Pétérù 2:25) Bí ẹnì kan bá tiẹ̀ fi ètò Jèhófà sílẹ̀,  Jèhófà kì í pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ tì. Ó gbà pé lọ́jọ́ kan, ó máa pa dà wá.

Lọ́kàn rẹ, ǹjẹ́ o gbà pé Jèhófà ṣì ni Olùṣọ́ àgùntàn rẹ? Báwo ni Jèhófà ṣe ń bójú tó wa lónìí? Jẹ́ ká sọ mẹ́ta lára ọ̀nà tó ń gba ṣe bẹ́ẹ̀:

Ó ń fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ bọ́ wa. Jèhófà kò febi òtítọ́ pa wá rí, ìgbà gbogbo ló ń kọ́ wa lóríṣiríṣi ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ń bọ́ sákòókò. Ó sọ pé: “Ní pápá ìjẹko tí ó dára ni èmi yóò ti bọ́ wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò dùbúlẹ̀ sí ní ibi gbígbé tí ó dára, orí pápá ìjẹko ọlọ́ràá ni wọn yóò sì ti máa jẹ.” (Ìsíkíẹ́lì 34:14) Ǹjẹ́ ó rántí ìgbà kan tó o bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó o wá rí ìdáhùn àdúrà rẹ nínú ohun kan tó o kà tàbí àsọyé kan tó o gbọ́ tàbí fídíò kan tó o wò? Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.

Ó ń ṣọ́ wa, ó sì ń tì wá lẹ́yìn. Jèhófà ṣèlérí pé: “Èyí tí ó sọnù ni èmi yóò wá kiri, èyí tí ó fara pa ni èmi yóò sì fi ọ̀já wé, èyí tí ń ṣòjòjò ni èmi yóò sì fún lókun.” (Ìsíkíẹ́lì 34:16) Jèhófà ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí ìdààmú bá. Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń fi ọ̀já wé àgùntàn rẹ̀ tó fara pa bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà máa ń ran àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti pa dà máa fayọ̀ sìn ín, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ló kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Jèhófà ò gbàgbé àwọn tó fi ètò rẹ̀ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń banú jẹ́, ó máa ń wá wọn kó lè mú wọn pa dà sínú agbo.

Ó gbà pé ojúṣe òun ni láti bójú tó wa. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò dá wọn nídè kúrò ní gbogbo ibi tí a tú wọn ká sí, èyí tí ó sọnù ni èmi yóò wá kiri.” (Ìsíkíẹ́lì 34:12, 16) Jèhófà ò wo ẹni tó fi ètò rẹ̀ sílẹ̀ bí ẹni tó ti lọ pátápátá. Ó mọ̀ bí ẹyọ kan bá dín nínú agbo àgùntàn rẹ̀, á wá àgùntàn náà lọ, tó bá sì rí i, inú rẹ̀ máa ń dùn. (Mátíù 18:12-14) Abájọ tó fi pe àwọn tó ń fòótọ́ inú sìn ín ní “ẹ̀yin àgùntàn mi,” tí mò ń bójú tó. (Ìsíkíẹ́lì 34:31) Ọ̀kan lára àwọn àgùntàn yìí ni ìwọ náà.

Jèhófà ò wo ẹni tó fi ètò rẹ̀ sílẹ̀ bí ẹni tó ti lọ pátápátá. Inú rẹ̀ máa ń dùn tó bá rí àgùntàn rẹ̀ tó sọnù

Sọ Ọjọ́ Wa Di Ọ̀tun bíi ti Àtijọ́

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi ń wá ẹ tó sì ń rọ̀ ẹ́ pé kó o pa dà wá sílé? Ó fẹ́ kó o láyọ̀ ni. Ó ṣèlérí pé òun máa rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn àgùntàn òun. (Ìsíkíẹ́lì 34:26) Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán torí pé ìwọ náà ń rọ́wọ́ Jèhófà lára rẹ.

Rántí bí inú rẹ ṣe dùn tó nígbà tó o mọ Jèhófà. Ǹjẹ́ o rántí bó ṣe rí lára rẹ nígbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run àti ohun tó ní lọ́kàn tó fi dá àwa èèyàn. Ǹjẹ́ o rántí bí ara ṣe máa ń tù ẹ́ tí ọkàn rẹ sì máa ń balẹ̀ tó o bá wà láàárín àwọn ará láwọn àpéjọ? Má gbàgbé ìgbà tó o lọ sóde ẹ̀rí tẹ́nì kan sì fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ rẹ, ǹjẹ́ inú rẹ̀ ò dùn lọ́jọ́ náà?

O ṣì lè láyọ̀ bíi ti ìgbà yẹn. Àwọn èèyàn Jèhófà láyé àtijọ́ gbàdúrà pé: “Oluwa yi wa pada sọdọ rẹ, awa o si yipada; sọ ọjọ wa di ọtun gẹgẹ bi ti igbãni.” (Ìdárò 5:21, Yoruba Bible YCE) Jèhófà gbọ́ àdúrà wọn, wọ́n sì pa dà ń fayọ̀ jọ́sìn rẹ̀. (Nehemáyà 8:17) Jèhófà á ran ìwọ náà lọ́wọ́ kó o lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ yìí dùn ún sọ àmọ́ kò dùn ún ṣe. Jẹ́ ká sọ díẹ̀ nínú ohun tó mú kó nira díẹ̀ fáwọn kan láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà àti ohun tí wàá ṣe kó o lè pa dà.