Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 3

Ó Yẹ Kí O Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run

Ó Yẹ Kí O Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run

Láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mọ orúkọ rẹ, ǹjẹ́ wọ́n sì máa ń fi pè ọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run ń fẹ́ kí o mọ orúkọ òun pẹ̀lú, kí o sì máa fi pe òun. Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18; Mátíù 6:9) O tún gbọ́dọ̀ mọ ohun tó fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́. O gbọ́dọ̀ mọ àwọn ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run àti àwọn tó jẹ́ ọ̀tá rẹ̀. Ó máa ń gba àkókò, ká tó lè mọ ẹnì kan dáadáa. Bíbélì sọ pé, ó bọ́gbọ́n mu láti ya àkókò sọ́tọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.—Éfésù 5:15, 16.

Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó ń tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Ronú nípa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Bí o bá ń hùwà tí ò dáa sí wọn, tí o sì ń ṣe ohun tí wọn ò fẹ́, ṣé wọ́n á tún máa bá ẹ ṣọ̀rẹ́? Rárá o! Lọ́nà kan náà, bí o ba fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó ń dùn mọ́ Ọlọ́run nínú.—Jòhánù 4:24.

Kì í ṣe gbogbo ẹ̀sìn ní ń sọni di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Jésù, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jù lọ fún Ọlọ́run, sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà méjì. Ọ̀nà kan fẹ̀, tìrítìrí sì làwọn èèyàn ń wọ́ lójú ọ̀nà náà. Ìparun lọ̀nà ọ̀hún sì lọ. Ọ̀nà kejì tóóró, ṣùgbọ́n kéréje làwọn èèyàn tí ń rìn ín. Ìyè àìnípẹ̀kun lọ̀nà yìí lọ. Èyí túmọ̀ sí pé bí o bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà jọ́sìn rẹ̀.—Mátíù 7:13, 14.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ?

Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, lára rẹ̀ ni Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá, àti Olúwa. Fídíò yìí sọ orúkọ Ọlọ́run gangan èyí tó fara hàn ní ibi tó lé ni ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú Bíbélì.

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ẹ̀sìn Tòótọ́ ?

Ǹjẹ́ ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà? Wo àwọn kókó márùn-ún téèyàn lè fi dá ẹ̀sìn tòótọ́ mọ̀.