Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 18

Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Títí Láé!

Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Títí Láé!

Ọ̀rẹ́ gidi ṣòroó rí; ṣíṣàìjẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ náà já sì tún gba aápọn. Ìsapá tí o bá ṣe láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kí o sì máa bá irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ nìṣó ni Ọlọ́run yóò bù kún gidigidi. Jésù sọ fáwọn tó gbà á gbọ́ pé: “Òtítọ́ yóò . . . dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Kí nìyẹn túmọ̀ sí?

O lè dòmìnira nísinsìnyí. O lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké àti irọ́ tí Sátánì ti tàn kálẹ̀. O lè bọ́ lọ́wọ́ àìnírètí tí ń dààmú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí kò mọ Jèhófà. (Róòmù 8:22) Kódà, àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run bọ́ lọ́wọ́ “ìbẹ̀rù ikú” pàápàá.—Hébérù 2:14, 15.

Òmìnira lè di tìrẹ nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run. Wo bí òmìnira tí o lè ní lọ́jọ́ ọ̀la ti jẹ́ àgbàyanu tó! Nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, àá bọ́ lọ́wọ́ ogun, àìsàn, àti ìwà ọ̀daràn. Ọwọ́ ipò òṣì àti ebi kò tún ní tẹ̀ wá mọ́. Ọjọ́ ogbó àti ikú kò ní rí wa gbé ṣe mọ́. A óò bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù, ìnilára, àti àìṣèdájọ́ òdodo. Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Sáàmù 145:16.

 Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run yóò wà láàyè títí láé. Ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye tí Ọlọ́run yóò fún gbogbo àwọn tó bá bá a dọ́rẹ̀ẹ́. (Róòmù 6:23) Rò ó wò ná, ohun tí ìyè àìlópin yóò túmọ̀ sí fún ọ!

Àkókò yóò wà fún ọ láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan. Bóyá wàá fẹ́ láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò orin kan. Tàbí bóyá o fẹ́ kọ́ bí wọ́n ṣe ń yàwòrán tàbí o fẹ́ di káfíńtà. Bóyá wàá fẹ́ láti ní ìmọ̀ nípa àwọn ẹranko tàbí ewéko. Tàbí, ó ṣeé ṣe kí o fẹ́ láti máa rìnrìn àjò kí o sì mọ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn èèyàn. Níní ìyè àìnípẹ̀kun yóò mú kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣeé ṣe!

Àkókò yóò wà fún ọ láti ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́. Wíwà láàyè títí láé yóò mú kó ṣeé ṣe láti mọ ọ̀pọ̀ èèyàn tí àwọn náà jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Wàá mọ̀ nípa ẹ̀bùn àti ànímọ́ àtàtà tí wọ́n ní, àwọn pẹ̀lú yóò sì jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ. Wàá fẹ́ràn wọn, àwọn náà á sì fẹ́ràn rẹ. (1 Kọ́ríńtì 13:8) Gbígbé títí láé láìkú yóò jẹ́ kí o ní àkókò tí ó tó láti di ọ̀rẹ́ gbogbo èèyàn orí ilẹ̀ ayé! Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọ̀rẹ́ ìwọ pẹ̀lú Jèhófà yóò túbọ̀ máa ṣe tímọ́tímọ́ sí i láti ọ̀rúndún dé ọ̀rúndún. Àdúrà wa ni pé kí o jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run títí láé!