Jèhófà kì yóò jẹ́ kí àwọn èèyàn búburú ba Párádísè jẹ́. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nìkan ni yóò máa gbé ibẹ̀. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn búburú? Láti mọ ìdáhùn rẹ̀, ṣàyẹ̀wò ìtàn tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, ìtàn Nóà. Nóà gbé ayé ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Èèyàn rere ni, ó sì gbìyànjú gidigidi nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n, ohun búburú ni àwọn èèyàn yòókù lórí ilẹ̀ ayé ń ṣe. Nítorí náà, Jèhófà sọ fún Nóà pé Òun yóò mú ìkún omi wá láti pa gbogbo àwọn ẹni ibi wọ̀nyẹn run. Ó sọ fún Nóà pé kí ó kan áàkì kan kí òun àti ìdílé rẹ̀ má bàa kú nígbà tí Ìkún Omi náà bá dé.—Jẹ́nẹ́sísì 6:9-18.

Nóà àti ìdílé rẹ̀ kan áàkì. Nóà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé Ìkún Omi ń bọ̀, ṣùgbọ́n wọn ò gbọ́ tirẹ̀. Wọ́n ń ṣe búburú lọ ràì. Nígbà tí Nóà parí áàkì náà, ó kó àwọn ẹranko sínú rẹ̀, òun àti ìdílé rẹ̀ sì wọnú áàkì náà pẹ̀lú. Jèhófà wá mú kí ìjì líle jà. Òjò rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru. Omi kún bo gbogbo ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 7:7-12.

 Àwọn èèyàn búburú pàdánù ẹ̀mí wọn, ṣùgbọ́n a gba Nóà àti ìdílé rẹ̀ là. Jèhófà mú wọn la Ìkún Omi náà já, wọ́n bọ́ sínú ayé táa ti mú ìwà ibi rẹ̀ kúrò. (Jẹ́nẹ́sísì 7:22, 23) Bíbélì sọ pé àkókò ń bọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, nígbà tí Jèhófà yóò pa àwọn tó bá kọ̀ láti ṣe ohun tó tọ́ run. Kò ní pa àwọn èèyàn rere run. Wọn yóò wà láàyè títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé.—2 Pétérù 2:5, 6, 9.

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe àwọn ohun búburú. Ayé kún fún ìjàngbọ̀n. Jèhófà ń rán àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ léraléra láti kìlọ̀ fún àwọn èèyàn, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ni kì í fẹ́ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà. Wọn ò fẹ́ yí ọ̀nà wọn padà. Wọn ò fẹ́ gba ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn wọ̀nyí? Ṣé wọ́n ń bọ̀ wá yí padà lọ́jọ́ kan? Ọ̀pọ̀ ò ní yí padà láé. Àkókò ń bọ̀ tí Ọlọ́run yóò pa àwọn ẹni ibi run, tí wọn ò sì ní wà láàyè mọ́.—Sáàmù 92:7.

A kì yóò pa ilẹ̀ ayé run; a óò sọ ọ́ di párádísè. Àwọn tó bá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run yóò wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 37:29.