Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 13

Iṣẹ́ Òkùnkùn àti Ìbẹ́mìílò Kò Dára

Iṣẹ́ Òkùnkùn àti Ìbẹ́mìílò Kò Dára

Sátánì ń fẹ́ kóo máa ṣe iṣẹ́ òkùnkùn. Àìmọye èèyàn ló máa ń rúbọ sí àwọn baba ńlá tàbí àwọn ẹ̀mí àìrí láti dáàbò bo ara wọn kúrò lọ́wọ́ ewu. Wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n bẹ̀rù agbára tí àwọn ẹ̀mí àìrí ní. Wọ́n máa ń lo òrùka oògùn tàbí ońdè. Wọ́n máa ń mu “oògùn” tí wọ́n gbà pé ó ní agbára abàmì, tàbí kí wọ́n máa fi í para. Àwọn èèyàn kan máa ń fi àwọn nǹkan kan tí wọ́n gbà pé ó lágbára láti dáàbò bo àwọn pa mọ́ sínú ilé wọn tàbí kí wọ́n rì í mọ́lẹ̀. Àwọn mìíràn máa ń lo “oògùn” tó ní agbára abàmì nítorí pé wọ́n gbà pé yóò mú kí àwọn ṣòwò jèrè, tàbí kí àwọn páàsì nínú ìdánwò ní ilé ẹ̀kọ́, tàbí kí ẹni táwọn ń fẹ́ sọ́nà lè jẹ́ tàwọn.

Fífi Jèhófà ṣọ̀rẹ́ ló lè dáàbò tó nípọn bò ọ́ kúrò lọ́wọ́ Sátánì. Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ lágbára gidigidi ju Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lọ. (Jákọ́bù 2:19; Ìṣípayá 12:9) Jèhófà múra tán láti lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀—àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí i délẹ̀délẹ̀.—2 Kíróníkà 16:9.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ pidán [ṣe iṣẹ́ òkùnkùn].” Jèhófà ka ṣíṣe iṣẹ́ òkùnkùn àti bíbá ẹ̀mí lò léèwọ̀ nítorí pé wọ́n lè fi èèyàn sábẹ́ agbára Sátánì Èṣù.—Léfítíkù 19:26.