Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!

 Ẹ̀kọ́ 8

Àwọn Wo Ni Ọ̀tá Ọlọ́run?

Àwọn Wo Ni Ọ̀tá Ọlọ́run?

Sátánì Èṣù ni olórí ọ̀tá Ọlọ́run. Ó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Sátánì ń bá a nìṣó láti bá Ọlọ́run jà, ó sì ń fa ìṣòro ńlá fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn. Sátánì jẹ́ ẹni ibi. Òpùrọ́ ni, ó sì jẹ́ apààyàn.—Jòhánù 8:44.

Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run. Bíbélì pè wọ́n ní ẹ̀mí èṣù. Bíi ti Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn. Wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa pa àwọn èèyàn lára. (Mátíù 9:32, 33; 12:22) Jèhófà máa pa Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ run títí láé. Àkókò tí wọ́n ní láti fi dààmú àwọn èèyàn kò tó nǹkan mọ́.—Ìṣípayá 12:12.

Bí o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o kò gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Sátánì ń fẹ́ kí o ṣe. Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù kórìíra Jèhófà. Ọ̀tá Ọlọ́run ni wọ́n, wọ́n sì ń fẹ́ kí ìwọ náà di ọ̀tá Ọlọ́run. O gbọ́dọ̀ yan ẹni tí o fẹ́ tẹ́ lọ́rùn, yálà Sátánì ni tàbí Jèhófà. Bí o bá ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun, o gbọ́dọ̀ yàn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Sátánì ní ọ̀pọ̀ àrékérekè àti ọ̀pọ̀ ọ̀nà tó ń gbà tan àwọn èèyàn jẹ. Ó ti tan ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ.—Ìṣípayá 12:9.