Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!

Ohun tó wà níbí á jẹ́ kó o mọ bí o ṣe lè ṣe é.

Ẹ̀KỌ́ 1

Ọlọ́run Ń Pè Ọ́ Pé Kí O Wá Di Ọ̀rẹ́ Òun

Àwọn èèyàn láti apá ibi gbogbo láyé ti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ìwọ náà lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

Ẹ̀KỌ́ 2

Ọlọ́run Lọ̀rẹ́ Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Ní

Ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè láyọ̀, kí ayé rẹ sì tòrò.

Ẹ̀KỌ́ 3

Ó Yẹ Kí O Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run

Ó máa jẹ́ kó o mọ ohun tó fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́.

Ẹ̀KỌ́ 4

Bó O Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run

Ó jẹ́ ká lè mọ àwọn ohun tó ṣe nígbà àtijọ́, ohun tó ń ṣe báyìí àti ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ ọ̀la.

Ẹ̀KỌ́ 5

Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Yóò Gbé Inú Párádísè

Párádísè ò ní dà bí irú ayé tí à ń gbé lónìí. Báwo ló ṣe máa rí?

Ẹ̀KỌ́ 6

Párádísè Sún Mọ́lé!

Báwo la ṣe mọ̀?

Ẹ̀KỌ́ 7

Ìkìlọ̀ Láti Inú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Nígbà Àtijọ́

Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn Nóà kọ́ wa?

Ẹ̀KỌ́ 8

Àwọn Wo Ni Ọ̀tá Ọlọ́run?

O lè dá àwọn ọ̀tá yìí mọ̀ kí wọ́n má bàa tàn ọ́ jẹ.

Ẹ̀KỌ́ 9

Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Kí sì ni wọ́n fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa Jèhófà?

Ẹ̀KỌ́ 10

Bí O Ṣe Lè Rí Ẹ̀sìn Tòótọ́

Àwọn nǹkan kan wà tó lè jẹ́ kó o dá a mọ̀.

Ẹ̀KỌ́ 11

Kọ Ẹ̀sìn Èké Sílẹ̀!

Báwo lo ṣe lè dá ẹ̀sìn èké mọ̀? Kí ló dé tó fi burú tó bẹ́ẹ̀?

Ẹ̀KỌ́ 12

Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Ikú?

Bíbélì jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa rẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ 13

Iṣẹ́ Òkùnkùn àti Ìbẹ́mìílò Kò Dára

Kí ló dé tí Ọlọ́run fi dẹ́bi fún wọn?

Ẹ̀KỌ́ 14

Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Sá fún Ohun Búburú

Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí Ọlọ́run kórìíra?

Ẹ̀KỌ́ 15

Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run A Máa Ṣe Rere

Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rere tó máa mú ká di ọ̀rẹ́ rẹ̀?

Ẹ̀KỌ́ 16

Fi Ìfẹ́ Tó O Ní sí Ọlọ́run Hàn

Kí ìwọ àti ẹnì kan tó lè jọ máa jẹ́ ọ̀rẹ́ lọ, o gbọ́dọ̀ máa bá a sọ̀rọ, kó o máa gbọ́ tirẹ̀, kó o sì máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa fún àwọn èèyàn. Bó ṣe rí téèyàn bá máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run náà nìyẹn.

Ẹ̀KỌ́ 17

Bó O Bá Fẹ́ Kẹ́nì Kan Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Rẹ, Ìwọ Náà Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Rẹ̀

Bó o ba ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run ni ìfẹ́ tó o ní sí i á máa pọ̀ sí i.

Ẹ̀KỌ́ 18

Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Títí Láé!

Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye tí Ọlọ́run máa fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni ìyè àìnípẹ̀kun.