Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?

 ÌSỌ̀RÍ 3

Àwọn Wo Ló Ń Gbé ní Ibùgbé Àwọn Ẹni Ẹ̀mí?

Àwọn Wo Ló Ń Gbé ní Ibùgbé Àwọn Ẹni Ẹ̀mí?

1. Lọ́nà wo ni àwọn kan gbà fi ẹ̀sìn àbáláyé wé òkè aboríṣóńṣó-bìdí-rẹ̀kẹ̀tẹ̀?

ÀWỌN kan ti fi ohun tí àwọn ẹ̀sìn àbáláyé, tó wà ní Áfíríkà, gbà gbọ́ wé òkè aboríṣóńṣó-bìdí-rẹ̀kẹ̀tẹ̀. Pé, Ọlọ́run ló wà lókè, òun ló ní agbára ẹ̀mí gíga jù lọ. Àwọn irúnmọlẹ̀ tàbí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n jẹ́ ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òkè náà. Àwọn baba ńlá tí wọ́n ń rántí àwọn ìdílé wọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n sì ń bójú tó ire wọn dáadáa wà pẹ̀lú wọn. Àwọn agbára ẹ̀mí tó rẹlẹ̀: àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn, woṣẹ́woṣẹ́ àti àwọn àjẹ́, ló wà nísàlẹ̀.

2. Báwo ni ọ̀rọ̀ kan táwọn ará Áfíríkà máa ń sọ ṣe fi hàn pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn àbáláyé ń nípa lórí ẹ̀sìn yòókù?

2 Àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn àbáláyé yìí ti ní ipa tó lágbára lórí àwọn ẹ̀sìn yòókù ní ilẹ̀ Áfíríkà. Ohun tí àwọn ará Áfíríkà kan máa ń sọ nípa rẹ̀ ni pé: “Ẹ̀sìn (ì báà jẹ́ ti Kristẹni tàbí ti Ìsìláàmù) kò ní ká má ṣorò ilé baba ẹni.”

3. Ibo la ti lè rí ohun tó jóòótọ́ nípa àwọn tó ń gbé ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí?

3 Báwo ni àwọn ohun tí ẹ̀sìn àbáláyé ní Áfíríkà gbà gbọ́ ṣe jóòótọ́ tó? Bíbélì sọ ohun tó jóòótọ́ fún wa nípa àwọn tó ń gbé ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí.

Jèhófà, Ọlọ́run Tòótọ́

4. Kí ni àwọn lájorí ẹ̀sìn tó wà nílẹ̀ Áfíríkà jọ gbà gbọ́?

4 Àwọn lájorí ẹ̀sìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà nílẹ̀ Áfíríkà gbà pé Ọlọ́run wà àti pé òun ni ẹni gíga jù lọ. Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ “Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run títóbi, alágbára ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù.” (Diutarónómì 10:17) Àwọn Mùsùlùmí pẹ̀lú gbà gbọ́ pé Ọlọ́run gíga jù lọ kan ṣoṣo ló wà. Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Geoffrey Parrinder ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn àbáláyé nílẹ̀ Áfíríkà, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Áfíríkà ló gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run gíga jù lọ kan tó jẹ́ bàbá àwọn irúnmọlẹ̀ àti ènìyàn, ẹni tó dá ayé àti ọ̀run.”

5. Kí ni díẹ̀ lára orúkọ tí wọ́n fi ń pe Ọlọ́run?

5 Ṣùgbọ́n, bí ọ̀pọ̀ ṣe gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run tó, ọ̀pọ̀ jù lọ ni òye wọn kò ṣe kedere nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Ohun tá a kọ́kọ́ máa ń mọ̀ nípa ẹnì kan ni orúkọ rẹ̀. Àmọ́ ìdàrúdàpọ̀ wà nínú ìsìn wọ̀nyí nípa orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́. Láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, Ọlọ́run ni wọ́n sábà máa ń pè é, orúkọ oyè lásán sì ni, ó túmọ̀ sí pé òun ni “Olú Ọ̀run,” Alágbára Ńlá. Allah làwọn Mùsùlùmí ń pè é. Láàárín àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn àbáláyé, orúkọ tí wọ́n fi ń pe Ẹni Gíga Jù Lọ náà yàtọ̀ láti èdè kan sí òmíràn. Nínú ìwé tí John S. Mbiti kọ, tó pè  Concepts of God in Africa [Òye Àwọn Ará Áfíríkà Nípa Ọlọ́run], ó kọ onírúurú orúkọ àti orúkọ àpèjúwe tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ tí àwọn ará Áfíríkà fi ń pe Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ní èdè Yorùbá, wọ́n ń pe Ọlọ́run ní Olódùmarè; àwọn Kikuyu (ní Kẹ́ńyà) ń pè é ní Ngai, àwọn Zulu (ní Gúúsù Áfíríkà) sì ń pè é ní Unkulunkulu.

6, 7. Kí ni orúkọ Ọlọ́run, báwo la sì ṣe mọ̀?

6 Kí ni Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ nípa orúkọ rẹ̀? Nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Mósè pé kí ó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì, Mósè béèrè pé: “Ká ní mo wá dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ni ó rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì sọ fún mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn?”—Ẹ́kísódù 3:13.

7 Ọlọ́run fèsì pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ni ó rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” (Ẹ́kísódù 3:15) Orúkọ Ọlọ́run yìí fara hàn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì ní ìgbà tó ju ẹgbẹ̀rún méje lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan ti fi àwọn orúkọ oyè bí “Ọlọ́run” tàbí “Olúwa” dípò rẹ̀.

8. Báwo ni Jèhófà ṣe rí, bí a bá sì fẹ́ rí ojú rere rẹ̀, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?

8 Báwo ni Jèhófà ṣe rí gan-an? Ẹ̀mí ni, alágbára ńlá ni, ológo sì ni. Òun ni ẹni gíga jù lọ, kò láfiwé, kò sì sí ẹni tó bá a dọ́gba. (Diutarónómì 6:4; Aísáyà 44:6) Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” Ká sọ ọ́ lọ́nà mìíràn, bí a óò bá rí ojú rere Jèhófà, òun nìkan la gbọ́dọ̀ jọ́sìn. Kò fẹ́ ká jọ́sìn ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn.—Ẹ́kísódù 20:3-5.

Jésù Kristi, Ọba Ìjọba Ọlọ́run

9. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù kò bá Jèhófà dọ́gba?

9 Lónìí, ìdàrúdàpọ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ nípa ẹni tí Jésù jẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gbà pé Jésù jẹ́ apá kan Mẹ́talọ́kan “Mímọ́.” Ṣùgbọ́n Bíbélì kò fi kọ́ni pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni mẹ́ta nínú ọ̀kan. Kò sì fi kọ́ni pé Jésù bá Jèhófà dọ́gba. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.”—Jòhánù 14:28.

10. Ibo ni Jésù wà kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé?

10 Bíbélì kọ́ wa pé kí Jésù tó yí padà di ènìyàn tó wá gbé lórí ilẹ̀ ayé, ó ti wà lókè ọ̀run tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára. Bí Jèhófà ṣe dá Ádámù àti Éfà sórí ilẹ̀ ayé gẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe dá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí sí òkè ọ̀run. Jésù ni ẹ̀dá ẹ̀mí tí Jèhófà kọ́kọ́ dá.—Jòhánù 17:5; Kólósè 1:15.

11. Báwo ni Jésù ṣe di ẹni tí a bí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn?

11 Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, Jèhófà ta àtaré ìwàláàyè ẹ̀dá ẹ̀mí yìí sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún un pé: “Ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba . . . kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.”—Lúùkù 1:31, 33. *

12. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ìdí tí Jésù fi wá sáyé?

12 Bó ṣe di pé wọ́n bí Jésù nìyẹn, tó dàgbà di géńdé ọkùnrin, tó sì kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí Jèhófà fẹ́ àti ète Rẹ̀. Ó sọ fún gómìnà kan tó jẹ́ ará Róòmù pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Nípa ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù fi kọ́ni, a lè mọ òtítọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti ète Rẹ̀. A lè mọ bí a ó ṣe jèrè ojú rere Ọlọ́run.

13. Kí nìdí kejì tí Jésù fi wá sáyé?

13 Ìdí kejì tí Jésù fi wá sáyé ni pé kí ó lè fi  ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn lélẹ̀ láti ra aráyé padà. (Mátíù 20:28) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kí a lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún látọ̀dọ̀ baba ńlá wa Ádámù. Èyí ni yóò wá mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

14. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù lẹ́yìn tó kú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn? (b) Ipò wo ni Jésù wà lọ́run báyìí?

14 Lẹ́yìn tí Jésù kú gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, Ọlọ́run jí i dìde sí ọ̀run níbi tó ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára padà, tó sì ń bá ìwàláàyè rẹ̀ nìṣó. (Ìṣe 2:32, 33) Nígbà tó yá, Jèhófà fún un ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Ọlọ́run ti fi Jésù jẹ Ọba alágbára; òun ni Ọba Ìjọba Jèhófà tó wà ní ọ̀run. Láìpẹ́, òun yóò fi agbára rẹ̀ hàn ní gbogbo ayé.

Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ Òjíṣẹ́ Ọlọ́run

15. Ìgbà wo ni Ọlọ́run dá àwọn áńgẹ́lì, ibo ló sì dá wọn sí?

15 Kì í ṣe Jèhófà àti Jésù nìkan ló ń gbé ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí. Jèhófà dá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn tí à ń pè ní áńgẹ́lì. Gébúrẹ́lì tó bá Màríà sọ̀rọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Àwọn áńgẹ́lì kò fìgbà kan rí jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Tipẹ́tipẹ́ kí Ọlọ́run tó dá ilẹ̀ ayé ló ti dá wọn sókè ọ̀run. (Jóòbù 38:4-7) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ áńgẹ́lì ló wà.—Dáníẹ́lì 7:10.

Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ kì í gbà kéèyàn jọ́sìn àwọn

16. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí àwọn èèyàn jọ́sìn àwọn áńgẹ́lì?

16 Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ kò fẹ́ ká jọ́sìn àwọn. Ìgbà méjèèjì tí àpọ́sítélì Jòhánù gbìyànjú láti jọ́sìn àwọn áńgẹ́lì ni wọ́n bá a wí, pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! . . . Jọ́sìn Ọlọ́run.”—Ìṣípayá 19:10; 22:8, 9.

17. Kí ló fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì lè dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kí sì nìdí tí èyí fi ń tuni nínú?

17 Àwọn áńgẹ́lì kì í fara han àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe nígbà tí wọ́n dá àwọn àpọ́sítélì Jésù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. (Ìṣe 5:18, 19) Síbẹ̀síbẹ̀, bí a bá ń jọ́sìn Jèhófà ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a lè ní ìdánilójú pé agbo àwọn áńgẹ́lì alágbára tí a kò lè fojú rí, tí wọ́n jẹ́ ti Ọlọ́run yóò dáàbò bò wá. Bíbélì sọ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.” (Sáàmù 34:7; 91:11) Kí nìdí tó fi yẹ kí èyí tù wá nínú? Ìdí ni pé àwọn ọ̀tá burúkú wà ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí tí wọ́n fẹ́ pa wá run!

Sátánì Jẹ́ Ọ̀tá Ọlọ́run

18. (a) Kí nìdí tí áńgẹ́lì kan fi ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run? (b) Àwọn orúkọ wo ni áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí ń jẹ́?

18 Kì í ṣe gbogbo àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ló jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Àwọn kan ṣọ̀tẹ̀ sí i. Wọ́n sọ ara wọn di ọ̀tá Ọlọ́run àti ọ̀tá àwọn èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Báwo lèyí ṣe ṣẹlẹ̀? Gbogbo áńgẹ́lì tí Ọlọ́run dá ló jẹ́ olóòótọ́ àti  ẹni rere. Ṣùgbọ́n, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀mí pípé yìí fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun, ó sì ṣe nǹkan kan láti rí i pé òun mú ìfẹ́ ọkàn búburú yìí ṣẹ. Orúkọ ẹ̀dá ẹ̀mí yẹn ni Sátánì, tó túmọ̀ sí “Alátakò [Ọlọ́run].” Ó tún ń jẹ́ Èṣù, tó túmọ̀ sí “Abanijẹ́,” níwọ̀n bí ó ti pa irọ́ burúkú mọ́ Jèhófà.

19. Kí nìdí tí Sátánì fi pọ́n Jóòbù lójú, báwo ló sì ṣe ṣe é?

19 Sátánì máa ń fínná mọ́ àwọn èèyàn láti mú wọn mọ́ra nínú ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Ìwọ ronú nípa ohun tó ṣe sí Jóòbù tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Jóòbù jẹ́ ẹni tó lọ́rọ̀ gidigidi. Ó ní ẹgbẹ̀rún méje àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ràkúnmí, ẹgbẹ̀rún kan abo àti akọ màlúù pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó tún ní àwọn ọmọ mẹ́wàá àti ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Sátánì pa àwọn ẹran ọ̀sìn àtàwọn ìránṣẹ́ Jóòbù. Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú kí “ẹ̀fúùfù ńláǹlà” bi ilé tí àwọn ọmọ Jóòbù wà wó, ó sì pa gbogbo wọn. Lẹ́yìn náà, Sátánì fi “oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀” láti pọ́n ọn lójú.—Jóòbù 1:3-19; 2:7.

20. (a) Báwo ni Ọlọ́run ṣe san èrè fún Jóòbù nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ti Jóòbù, òún jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kí ni Sátánì ti ṣe sí ọ̀pọ̀ èèyàn?

20 Bí àdánwò ńláǹlà yìí ṣe bá Jóòbù tó, ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Nítorí náà, Jèhófà wò ó sàn, ó sì “fún Jóòbù ní àfikún ohun gbogbo tí ó jẹ́ tirẹ̀ rí, ní ìlọ́po méjì.” (Jóòbù 42:10) Sátánì kò rí ìwà títọ́ Jóòbù bà jẹ́, ṣùgbọ́n ó ti ṣeé ṣe fún un láti yí ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì wí pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.

21. (a) Báwo ni Sátánì ṣe fi hàn pé òun fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun? (b) Kí nìdí tí Jésù fi kọ̀ láti jọ́sìn Sátánì?

21 Sátánì ń fẹ́ ká jọ́sìn òun. Èyí ṣe kedere nínú bó ṣe dán Jésù wò ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá ọdún sẹ́yìn. Bíbélì ròyìn pé: “Èṣù . . . mú [Jésù] lọ sí òkè ńlá kan tí ó ga lọ́nà kíkàmàmà, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.’” Jésù kọ̀, ó sì sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” (Mátíù 4:8-10) Jésù mọ òfin Jèhófà dunjú, kò sì ṣe ohun tí Sátánì fẹ́.

Ẹ̀dá Ẹ̀mí Búburú Làwọn Ẹ̀mí Èṣù

22. Kí làwọn ẹ̀mí èṣù ti ṣe sí àwọn ẹ̀dá èèyàn?

22 Àwọn áńgẹ́lì mìíràn dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀mí èṣù yìí jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Òǹrorò ni wọ́n, oníwà ipá sì ni wọ́n pẹ̀lú. Nígbà àtijọ́, wọ́n sọ àwọn kan di odi àti afọ́jú. (Mátíù 9:32, 33; 12:22) Wọ́n sọ àwọn kan di aláìsàn, wọ́n sì sọ àwọn mìíràn di ayírí. (Mátíù 17:15, 18; Máàkù 5:2-5) Kódà, wọ́n dá àwọn ọmọdé lóró pẹ̀lú.—Lúùkù 9:42.

23. (a) Kí làwọn ẹ̀mí búburú ń fẹ́ kí àwọn èèyàn máa ṣe fáwọn? (b) Kí ni Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti tan àwọn èèyàn láti máa ṣe?

23 Bíi ti Sátánì, ńṣe làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú yìí ń fẹ́ kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn àwọn. Dípò tí wọn ì bá fi kọ̀ kí àwọn ènìyàn máa jọ́sìn àwọn, wọ́n sáà mọ̀ pé Jèhófà nìkan ni ìjọsìn tọ́ sí, ńṣe ni wọ́n ń wá ìjọsìn ọ̀hún lójú méjèèjì, tí wọ́n sì ń tan àwọn ènìyàn láti máa jọ́sìn wọn. Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ti lo ìtànjẹ, irọ́ àti ìdáyàjáni láti mú kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn wọn. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ làwọn ń jọ́sìn. Yóò ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu láti mọ̀ pé Sátánì ni ìsìn wọn ń bọlá fún. Síbẹ̀, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ, wọ́n fi ń rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù, kì í sì í ṣe sí Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:20.

24. Kí ni ọ̀kan lára ètekéte tí Sátánì ń lò láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà?

24 Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń lò láti fi ṣi àwọn èèyàn lọ́nà kí wọ́n lè máa jọ́sìn wọn ni títan èrò tí kò tọ̀nà kálẹ̀ nípa àwọn tó ti kú. Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa èyí.

^ ìpínrọ̀ 11 Kùránì sọ̀rọ̀ nípa ìbí Jésù lọ́nà iṣẹ́ ìyanu nínú Surah 19 (Mariyama), Al-Kuránì Ti A Tumọ si Ède Yoruba. Ó sọ pé: “Awa si ran ẹmi wa si (Mariyama), o si fi ara hãn gẹgẹbi ọkunrin ti o mọ kan. On (Mariyama) wipe: Emi sadi Ọba Ajọkẹ aiye kuro lọdọ rẹ bi irẹ ba jẹ olubẹru (Ọlọhun). On (Malaika) wipe: Dajudaju iranṣẹ Oluwa rẹ ni emi jẹ pe: Emi yio fun ọ ni (iro) ọmọkunrin ti o mọ kan. (Mariyama) wipe: Bawo ni ọdọmọkunrin yio ṣe wa fun mi nigbati abara kan kò fọwọkan mi bẹni emi kò si jẹ àgbèrè (panṣaga). O wipe: Bẹni yio jẹ. Oluwa rẹ wipe: Ọ rọrun fun Mi (lati ṣe); atipe ki A le ṣe e ni arisami fun awọn enia ati anu lati ọdọ Wa. O si jẹ ọ̀rọ ti a ti pari.”