Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè

 ÌBÉÈRÈ 7

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìbálòpọ̀ Lọ̀ Mí?

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìbálòpọ̀ Lọ̀ Mí?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ipa kékeré kọ́ ni ìpinnu tó o bá ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ máa ní lórí ìgbésí ayé rẹ.

LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Kò tíì ju oṣù méjì lọ tí Heather àti Mike ti ń fẹ́ra, àmọ́ lójú Heather, àfi bíi pé wọ́n ti mọra tipẹ́. Wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wọn ní gbogbo ìgbà, ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n fi máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ lórí fóònù, kódà, níbi tọ́rọ̀ wọn wọ̀ dé, bí ọ̀kan nínú wọn bá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀, èkejì lè bá a parí ẹ̀ torí ó ti mọ ohun tó fẹ́ sọ! Àmọ́ ohun tí Mike ń wá jùyẹn lọ.

Láàárín oṣù méjì tó kọjá, Mike àti Heather ò ṣe kọjá kí wọ́n kàn dira wọn lọ́wọ́ mú kí wọ́n sì fẹnu konu fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Heather ò sì fẹ́ kó jùyẹn lọ. Síbẹ̀, kò fẹ́ kí Mike fi òun sílẹ̀. Kò sẹ́ni tó gba tiẹ̀ bíi Mike, ṣe ni Mike máa ń kẹ́ ẹ lójú kẹ́ ẹ nímú. Ó tún ń rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Èmi àti Mike kúkú fẹ́ràn ara wa gan-an . . . ’

Tó bá jẹ́ ìwọ ni Heather, tó o sì ti dàgbà tẹ́ni tó ń ní àfẹ́sọ́nà, kí lo máa ṣe?

RÒ Ó WÀ NÁ!

Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìbálòpọ̀, àwọn tó sì ti ṣègbéyàwó nìkan ló wà fún. Tó o bá ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó, ṣe lò ń ṣe ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún ẹ báṣubàṣu. Ṣe nìyẹn sì dà bí ìgbà tó o sọ aṣọ olówó iyebíye tẹ́nì kan fún ẹ di aṣọ ìnulẹ̀

Ẹni bá finá ṣeré, iná á jó o. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí tó o bá rú òfin tó jẹ mọ́ irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, bí èyí tó sọ pé: “Ẹ ta kété sí àgbèrè.”1 Tẹsalóníkà 4:3.

Kí làwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó o bá rú òfin yìí? Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ṣé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí?

 Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé ọ̀kan tàbí jú bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn nǹkan tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò yìí ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó ti ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó.

  • ÌDÀÀMÚ ỌKÀN. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó ló sọ pé àwọn pa dà kábàámọ̀ rẹ̀.

  • WỌN KÌ Í FỌKÀN TÁN ARA WỌN. Lẹ́yìn táwọn méjì tí kò tíì ṣègbéyàwó bá ti ní ìbálòpọ̀, wọ́n á máa sọ lọ́kàn ara wọn pé, ‘Ta ló mọ ẹlòmíì tó ti tún bá sùn?’

  • ÌJÁKULẸ̀. Nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún, àwọn ọmọbìnrin sábà máa ń fẹ́ ẹni tó máa tọ́jú wọn, kì í ṣẹni tó kàn máa bá wọn sùn tán, táá sì já wọn jù sílẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin sì máa ń sọ pé àwọn ò lè fẹ́ ọmọbìnrin táwọn ti bá sùn.

  • Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá lọ ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó, ṣe lo ta ara rẹ lọ́pọ̀, ohun iyebíye lo sì gbé sọ nù yẹn. (Róòmù 1:24) O ṣeyebíye gan-an, kò sì ní dáa kó o tara ẹ lọ́pọ̀!

Séra ró, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ “ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Tó o bá sì wá pa dà ṣègbéyàwó, wàá lómìnira láti ní ìbálòpọ̀. Wàá sì lè gbádùn rẹ̀ dáadáa, láìsí ìdààmú tàbí àbámọ̀, o ò sì ní kó sínú ìṣòro àìbalẹ̀ ọkàn tí àwọn tó ní ìbálòpọ̀ láìtíì ṣègbéyàwó máa ń ní.Òwe 7:22, 23; 1 Kọ́ríńtì 7:3.

 KÍ LÈRÒ Ẹ?

  • Ṣẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ lóòótọ́ á ṣe ohun tó máa pa ẹ́ lára táá sì tún kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ?

  • Ṣẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ dénú á tàn ẹ́ láti ṣe ohun tó máa mú kí àjọṣe ìwọ àti Ọlọ́run bà jẹ́?Hébérù 13:4.