Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè

 ÌBÉÈRÈ 3

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tí àárín ìwọ àti òbí rẹ bá gún, nǹkan á túbọ̀ máa lọ dáadáa fún ẹ.

LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Lálẹ́ ọjọ́ Wednesday kan, Geoff, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ti parí iṣé ilé tó yẹ kó ṣe, ó sì fẹ́ sinmi. Ó tan tẹlifíṣọ̀n, ó sì jókòó pẹ̀sẹ̀ sórí àga tó fẹ́ràn jù.

Bó ṣe ń jókòó báyìí ni Dádì ẹ̀ ń wọlé bọ̀, ó sì hàn lójú wọn pé inú wọn ò dùn.

Dádì ẹ̀ wá sọ pé: “Geoffrey! Ṣé tẹlifíṣọ̀n wíwò ló kàn, nígbà tó yẹ kó o ran àbúrò ẹ lọ́wọ́ kó lè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀! Kò sóhun téèyàn ní kó o ṣe tó o máa ń ṣe láyé tìẹ!”

“Geoffrey wá bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn pé: “Ẹ tún ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn o!”

Dádì ẹ̀ bá sún mọ́ ọn. Ó ní: “Kí lo sọ ná?”

Ó ti sú Geoffrey, ó fèsì pé, “Mi ò sọ nǹkan kan.”

Inú bí Dádì ẹ̀ gan-an. Ó ní: “Ṣé èmi lò ń bá sọ̀rọ̀ bẹ́yẹn?”

Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Geoff, kí lò bá ti ṣe kí àríyànjiyàn yìí má bàa wáyé?

RÒ Ó WÒ NÁ!

Bí ìgbà tó ò ń wa mọ́tò ni ọ̀rọ̀ àárín ìwọ àti òbí rẹ rí. Tó o bá wa mọ́tò débi tí wọ́n ti fi nǹkan dí ojú ọ̀nà, o ò ní torí ìyẹn pa dà sílé, ńṣe ni wàá gba ọ̀nà míì.

 BÍ ÀPẸẸRẸ:

Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Leah sọ pé: “Ó máa ń ṣòro fún mi láti bá dádì mi sọ̀rọ̀. Nígbà míì, mo lè ti máa sọ̀rọ̀ lọ o, wọ́n á kàn dédé sọ pé: ‘Àbí èmi lò ń bá sọ̀rọ̀?’ ”

Ó KÉRÉ TÁN, OHUN MẸ́TA NI LEAH LÈ ṢE.

 1. Kó jágbe mọ́ dádì ẹ̀.

  Leah lè kígbe pé: “Hà! Ṣé pé ẹ ò gbọ́ nǹkan tí mò ń sọ? Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì o!”

 2. Kó má sọ̀rọ̀ mọ́.

  Leah lè rọra dákẹ́, kó má sọ ìṣòro tó ní fún dádì ẹ̀ mọ́.

 3. Kó dúró dìgbà míì tí wọ́n á ráyè, kó wá sọ̀rọ̀ yẹn.

  Leah lè pa dà lọ bá dádì rẹ̀ sọ̀rọ̀ yẹn nígbà míì tàbí kó kọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ sínú lẹ́tà, kó sì fún dádì ẹ̀.

Èwo lo rò pé ó yẹ kí Leah ṣe nínú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?

RÒ Ó WÒ NÁ: Bàbá Leah ò mọ ohun tó ń ṣe ọmọ rẹ̀ torí ọkàn rẹ̀ ò sí níbi ọ̀rọ̀ tọ́mọ rẹ̀ ń bá a sọ. Tí Leah bá ṣe Ohun Kìíní, tó jágbe mọ́ dádì ẹ̀, dádì ẹ̀ lè má mọ ohun tó mú kó jágbe mọ́ òun. Ó ṣeé ṣe kí dádì ẹ̀ máà dá a lóhùn mọ́ tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sì ní fi hàn pé Leah pọ́n dádì ẹ̀ lé, pé ó sì bọ̀wọ̀ fún un. (Éfésù 6:2) Ó dájú pé ibí tọ́rọ̀ náà máa já sí ò ní tẹ́ àwọn méjèèjì lọ́rùn.

Tí wọ́n bá dí ojú ọ̀nà níbì kan, wàá wá ọ̀nà míì gbà, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ ìwọ àti òbí rẹ rí, o yẹ kó o wá bí wàá ṣe máa bá wọn sọ̀rọ̀

Ó lè dà bíi pé Ohun Kejì ló rọrùn jù, àmọ́ kò bọ́gbọ́n mu. Kí nìdí? Kí Leah tó lè yanjú ìṣòro yìí, ó ní láti bá dádì rẹ̀ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá sì máa ràn án lọ́wọ́, àfi kí wọ́n mọ ohun tó ń ṣe é. Béèyàn bá dákẹ́, tara ẹ̀ á bá a dákẹ́.

Àmọ́ tí Leah bá ṣe Ohun Kẹta, tó dúró di ìgbà míì kó tó sọ ohun tó fẹ́ sọ, ó fi hàn pé kò jẹ́ kí ohun tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ dí òun lọ́wọ́ láti bá dádì òun sọ̀rọ̀. Tó bá sì jẹ́ pé lẹ́tà ló pinnu láti kọ sí dádì rẹ̀, ìyẹn lè mú kí ọ̀rọ̀ náà fúyẹ́ lọ́kàn rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Tó bá kọ lẹ́tà, ìyẹn á tún jẹ́ kó lè ṣàlàyé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ dáadáa. Tí bàbá Leah bá ka lẹ́tà náà, á mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ fẹ́ bá a sọ, ó sì lè mú kí ohun tó ń ṣe ọmọ rẹ̀ yé e dáadáa. Nípa báyìí, àwọn méjèèjì ni Ohun Kẹta yìí máa ṣe láǹfààní. Bóyá ojúkojú ni Leah ti bá dádì ẹ̀ sọ̀rọ̀ tàbí ó kọ lẹ́tà, ohun tó ṣe yìí bá ìmọ̀ràn Bíbélì mu, èyí tó sọ pé “máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.”Róòmù 14:19.

Kí làwọn ohun míì tí Leah tún lè ṣe?

Wò ó bóyá wàá lè ronú kan ohun míì tó lè ṣe, kó o wá ro ibi tó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà yọrí sí.

 MÁ SỌ OHUN TÓ LÈ TÚMỌ̀ SÍ NǸKAN MÍÌ

Rántí pé, lọ́pọ̀ ìgbà, o lè sọ ohun kan kó sì jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lohun tó máa túmọ̀ sí létí àwọn òbí rẹ.

BÍ ÀPẸẸRẸ:

Ká sọ pé àwọn òbí rẹ bi ẹ́ pé, “Kí ló ṣe ẹ́ tínú ẹ ò dùn?” Ó wá sọ pé: “Ẹ wò ó, ẹ gbàgbé ẹ̀.”

Ohun tó lè túmọ̀ sí létí àwọn òbí rẹ ni pé: “Mi ò lè máa bá yín sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ torí mi ò fọkàn tán yín. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ni màá sọ fún.”

Ká sọ pé o ní ìṣòro kan tó le gan-an, táwọn òbí ẹ sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá sọ pé: “Ẹ má ṣèyọnu. Màá yanjú ẹ̀ fúnra mi.”

 • Kí ló lè túmọ̀ sí létí àwọn òbí rẹ?

 • Kí ló máa dáa kó o sọ?