Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè

Tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn àti àbá tó lè mú kí ìgbésí ayé ẹ dáa.

ÌBÉÈRÈ 1

Irú Èèyàn Wo Gan-an Ni Mo Jẹ́?

Tó o bá mọ àwọn ìwà tó dáa tó yẹ kó o máa hù, tó o mọ ibi tó o dáa sí, ibi tó o kù sí, tó o sì ní àfojúsùn, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe ohun tó tọ́ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ fẹ́ kó o ṣe ohun tí ò dáa.

ÌBÉÈRÈ 2

Ṣó Yẹ Kí N Máa Da Ara Mi Láàmú Torí Bí Mo Ṣe Rí?

Tó o bá ń wo ara ẹ nínú dígí, ṣé inú ẹ máa ń dùn sí bó o ṣe rí? Àwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu wo lo lè ṣe kí ìrísí ẹ lè dáa sí i?

ÌBÉÈRÈ 3

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?

Àwọn àbá yìí lè túbọ̀ mú kó rọrùn fún ẹ láti bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀.

ÌBÉÈRÈ 4

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe tí Mo Bá Ṣàṣìṣe?

Bópẹ́ bóyá, wàá ṣàṣìṣe lọ́jọ́ kan, torí gbogbo èèyàn ló máa ń ṣàṣìṣe. Kí ló wá yẹ kó o ṣe tó o bá ṣàṣìṣe?

ÌBÉÈRÈ 5

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Níléèwé?

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè borí ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ láìbá a jà.

ÌBÉÈRÈ 6

Kí Ni Mo Lè Ṣe Káwọn Ojúgbà Mi Má Bàa Ba Ìwà Mi Jẹ́?

Kì í sábà rọrùn láti kọ̀ jálẹ̀ pé ohun tó tọ́ lo fẹ́ ṣe.

ÌBÉÈRÈ 7

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìbálòpọ̀ Lọ̀ Mí?

Wo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ kan tó ti ṣe ohun tí ò yẹ kí wọ́n ṣe.

ÌBÉÈRÈ 8

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá-Báni-Lòpọ̀?

Àwọn ọ̀dọ́ ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ fipá bá lò pọ̀. Kí lo lè ṣe láti dáàbò bo ara ẹ?

ÌBÉÈRÈ 9

Ṣó Yẹ Kí N Gba Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Gbọ́?

Èwo ló bọ́gbọ́n mu, pé gbogbo nǹkan ṣàdédé wà àbí ẹnì kan ló dá wọn?

ÌBÉÈRÈ 10

Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé ìtàn àròsọ ló kún inú Bíbélì, pé ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ò bóde mu àti pé ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣòroó lóye. Irọ́ lásán làsàn ni.