OBÌNRIN ẹni ọdún 25 kan kọ̀wé pé: “Ní 1981 ìyá tí ó gbà mí fi ṣọmọ kú nítorí àrùn jẹjẹrẹ. Ikú rẹ̀ nira gan-⁠an fún èmi àti fún arákùnrin mi tí a gbà fi ṣọmọ. Mo jẹ́ ẹni ọdún 17, arákùnrin mi sì jẹ́ ọmọ ọdún 11. Mo ṣàárò rẹ̀ gan an ni. Níwọ̀n bí a ti fi kọ mi pé ọ̀run ni ó wà, mo fẹ́ láti gba ẹ̀mí araàmi láti lè wà pẹ̀lú rẹ̀.”

Ó jọ pé kò dára rárá pé kí ikú ní agbára láti mú ẹni tí ìwọ fẹ́ràn lọ. Nígbà tí ó bá sì ṣẹlẹ̀, èrò ti ṣíṣàì lè jọ sọ̀rọ̀, rẹ́rìn-⁠ín, tàbí di olólùfẹ́ rẹ mú lè jẹ èyí tí ó nira jùlọ láti faradà. Ìrora yẹn ni a kò fi dandan mú kúrò nípa sísọ fún ọ pé ẹni tí o fẹ́ràn wà lókè ọ̀run.

Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli nawọ́ ìrètí tí ó yàtọ̀ pátápátá síni. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí ṣáájú, Ìwé Mímọ́ fihàn pé ó ṣeéṣe láti tún wàpapọ̀ pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ tí ó ti kú ní ọjọ́-ọ̀la tí ó súnmọ́lé, kìí ṣe ní ọ̀run kan tí a kò mọ̀ ṣùgbọ́n níhìn-⁠ín gan-⁠an lórí ilẹ̀-ayé lábẹ́ àwọn ipò òdodo, alálàáfíà. Àti pé ní àkókò yẹn àwọn ẹ̀dá ènìyàn yóò ní ìfojúsọ́nà ìrètí gbígbádùn ìlera pípé, tí wọn kì yóò sì tún níláti kú mọ́ láé. ‘Ṣùgbọ́n ó dájú pé ìdára-ẹni nínú dùn nìyẹn!’ ni àwọn kan lè sọ.

Kí ni yóò gbà láti mu dá ọ lójú pé ìrètí tí ó dájú ni èyí? Láti gba ìlérí kan gbọ́, ìwọ yóò níláti ní ìdánilójú pé ẹni tí ń ṣèlérí náà múratán ó sì ní agbára láti mú un ṣẹ. Ta ni, nígbà náà, ni ó ṣèlérí pé àwọn òkú yóò tún padà wàláàyè?

Ní ìgbà ìrúwé 31 C.E., Jesu Kristi fi tìgboyà tìgboyà ṣèlérí pé: “Nítorí gẹ́gẹ́ bí Baba ti ń jí òkú dìde, tí ó sì ń sọ wọ́n di ààyè; bẹ́ẹ̀ni Ọmọ sì ń sọ àwọn tí ó fẹ́ di ààyè. Kí èyí kí ó máṣe yà yín ní ẹnu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní isà òkú yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ [Jesu]. Wọn óò sì jáde wá.” (Johannu 5:21, 28, 29) Bẹ́ẹ̀ni, Jesu Kristi ṣèlérí pé àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n ti kú nísinsìnyí yóò tún padà wàláàyè lórí ilẹ̀-ayé yìí wọ́n yóò sì ní ìfojúsọ́nà ìrètí ti wíwà nínú rẹ̀ títíláé nínú àwọn ipò paradise, alálàáfíà. (Luku 23:43; Johannu 3:16; 17:3; fiwé Orin Dafidi 37:29 àti Matteu 5:5.) Níwọ̀n bí Jesu ti ṣe ìlérí náà, ó dárajù láti gbà pé ó múratán láti mú un ṣẹ. Ṣùgbọ́n òun ha ní agbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí?

Ní èyí tí ó dín sí ọdún méjì lẹ́yìn ṣíṣe ìlérí yẹn, Jesu fihàn lọ́nà lílágbára pé òun múratán òun sì ní agbára láti jínidìde.

“Lasaru, Jáde Wá”

Ó jẹ́ ìran kan tí ń rùmọ̀lára sókè. Lasaru ń ṣàìsàn gidigidi. Àwọn arábìnrin rẹ̀ méjèèjì, Maria àti Marta, ránṣẹ́ sí Jesu, tí ó wà ní òdìkejì Odò Jordani pé: “Oluwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.” (Johannu 11:3) Wọ́n mọ̀ pé Jesu fẹ́ràn Lasaru. Jesu kò ha ní fẹ́ láti rí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń ṣàìsàn bí? Sí ìyàlẹ́nu, dípò lílọ sí Betani lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jesu dúró sí ibi tí ó wà fún ọjọ́ méjì síi.​—⁠Johannu 11:5, 6.

Lasaru kú ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ìhìn-iṣẹ́ àìsàn rẹ̀ ránṣẹ́. Jesu mọ ìgbà tí Lasaru kú, ó sì ní ohun kan lọ́kàn láti ṣe nípa rẹ̀. Nígbà tí Jesu fi máa dé sí Betani nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin. (Johannu 11:17, 39) Jesu ha lè mu ẹni tí ó ti kú fún àkókò pípẹ́ bẹ́ẹ̀ padà wá sí ìyè bí?

Ní gbígbọ́ pé Jesu ń bọ̀, Marta, obìnrin tí kìí jáfira, sáré jáde lọ pàdé rẹ̀. (Fiwé Luku 10:38-42.) Bí ìbànújẹ́ rẹ̀ ti dùn ún wọra, Jesu mu dá a lójú pé: “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.” Nígbà tí ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn nínú àjíǹde ọjọ́-ọ̀la, Jesu sọ fún un ní kedere pé: “Èmi ni àjíǹde, àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.”​—⁠Johannu 11:20-25.

Ní dídé ibi isà òkú náà, Jesu pàṣẹ pé kí a gbé òkúta tí ó dí ẹnu ọ̀nà àbáwọnú rẹ̀ kúrò. Nígbà náà, lẹ́yìn gbígbàdúrà sókè, ó pàṣẹ pé: “Lasaru, jáde wá.”​—⁠Johannu 11:38-43.

Gbogbo ènìyàn tí ó wà níbẹ̀ tẹjúmọ́ isà òkú  náà. Lẹ́yìn náà, láti inú òkùnkùn, ènìyàn kan farahàn. Àwọn ẹsẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ ni a dì pẹ̀lú aṣọ ìdìkú, a sì fi aṣọ dì í ní ojú. “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ,” ni Jesu pàṣẹ. Èyí tí ó kẹ́yìn nínú aṣọ tí a fi dì í tú sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, Lasaru gan-⁠an ni, ọkùnrin náà tí ó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin!​—Johannu 11:44.

Ó Ha Ṣẹlẹ̀ Níti Gidi Bí?

Ìròyìn nípa jíjí Lasaru dìde ní a fihàn nínú ìwé Ìhìnrere ti Johannu gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ọ̀rọ̀ ìtàn. Àwọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé rẹ̀ ti jẹ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ju ohun tí ó lè jẹ́ ìtàn ìṣàpẹẹrẹ lásán. Láti ṣiyèméjì ìjójúlówó rẹ̀ jẹ́ láti ṣiyèméjì gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu inú Bibeli, títí kan àjíǹde Jesu Kristi fúnraarẹ̀. Láti sẹ́ àjíǹde Jesu sì jẹ́ láti sẹ́ gbogbo ìgbàgbọ́ Kristian.​—1 Korinti 15:13-15.

Níti gidi, bí ìwọ bá gba wíwà Ọlọrun gbọ́, kò yẹ kí o ní ìṣòro pẹ̀lú gbígba àjíǹde gbọ́. Láti ṣàkàwé: Ẹnìkan lè gba àlàyé àti ìbúra ìhágún rẹ̀ sórí fídíò, lẹ́yìn tí ó bá sì ti kú, àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lè rí i kí wọn sì gbọ́ ọ, níti gidi, bí ó ti ń ṣàlàyé nípa bí ó ṣe fẹ́ kí a bójútó àwọn ohun-⁠ìní òun. Ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún sẹ́yìn, kò sí ẹni tí ó ronú irú ohun bẹ́ẹ̀. Sí àwọn kan tí wọ́n ń gbé lónìí ní apá ibi jíjìnnà réré nínú ayé, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ fídíò rékọjá ohun tí wọ́n lè mòye rẹ̀ débi tí ó fi dàbí iṣẹ́ ìyanu. Bí àwọn ènìyàn bá lè lo àwọn ètò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí Ẹlẹ́dàá ṣe láti fi gbé ìran tí ó ṣeé rí tí ó sì ṣeé gbọ́ bẹ́ẹ̀ jáde, Ẹlẹ́dàá kò ha níláti ní agbára láti ṣe jú bẹ́ẹ̀ lọ bí? Kò ha lọ́gbọ́nnínú, nígbà náà, pé Ẹni náà tí ó dá ìwàláàyè ní agbára títún un dá bí?

Iṣẹ́ ìyanu ti mímú Lasaru padà wá si ìyè ṣiṣẹ́ láti fikún ìgbàgbọ́ nínú Jesu àti àjíǹde. (Johannu 11:41, 42; 12:9-11, 17-19) Ní ọ̀nà tí ń ru ìmọ̀lára sókè, ó tún ṣípayá ìmúratán àti ìfẹ́-ọkàn Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀ láti jínidìde.

‘Ọlọrun Yóò Ṣàfẹ́rí’

Ìdáhùnpadà Jesu sí ikú Lasaru fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́nkẹ́ hàn ní ìhà ọ̀dọ̀ Ọmọkùnrin Ọlọrun. Àwọn ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tí ó ní ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi ìfẹ́-ọkàn mímúná rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde hàn ní kedere. A kà pé: “Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu gbé wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, Oluwa, ìbáṣepé ìwọ ti wà níhìn-⁠ín, arákùnrin mi kì bá kú. Ǹjẹ́ nígbà tí Jesu rí i, tí ó sọkún, àti àwọn Ju tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora ní ọkàn rẹ̀, inú rẹ̀ sì bàjẹ́, Ó sì wí pé, Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí? Wọ́n sì wi fún un pé, Oluwa, wá wò ó. Jesu sọkún. Nítorí náà àwọn Ju wí pé, sáà wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”​—Johannu 11:32-36.

Ìyọ́nú àtọkànwá tí Jesu ní ni a fihàn níhìn-⁠ín nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta: “kérora,” “inú rẹ̀ sì bàjẹ́,” àti “sọkún.” Àwọn ọ̀rọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a lò ní ṣíṣàkọsílẹ̀ ìran arùmọ̀lára sókè yìí fihàn pé ikú Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n àti rírí arábìnrin Lasaru tí ń sọkún ba Jesu nínú jẹ́ púpọ̀ tí omije fi ń dà ni ojú Rẹ̀. *

Ohun tí ó jọni lójú ni pé ṣáájú àkókò yìí Jesu ti mú àwọn ẹni méjì mìíràn wá sí ìyè. Òun ni lọ́kàn dáadáa láti ṣe ohun kan náà fún Lasaru. (Johannu 11:11, 23, 25) Síbẹ̀, ó “sọkún.” Nígbà  náà mímú ènìyàn padà wá sí ìyè kìí wulẹ̀ ṣe ọ̀nà ìgbàṣe kan lásán fún Jesu. Ìyọ́nú àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti fihàn ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní kedere fi ìfẹ́-ọkàn mímúná rẹ̀ hàn láti mú òfò ikú kúrò.

Ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́nkẹ́ Jesu nígbà tí ó ń jí Lasaru dìde fi ìfẹ́-ọkàn mímúná rẹ̀ hàn láti mú àwọn òfò ikú kúrò

Níwọ̀n bí Jesu ti jẹ́ ‘àwòrán Jehofa Ọlọrun fúnraarẹ̀’ gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́, a kò retí ohun tí ó dínkù ní ìhà ọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run. (Heberu 1:3, NW) Níti ìmúratán Jehofa fúnraarẹ̀ láti jínidìde, ọkùnrin adúróṣinṣin náà Jobu sọ pé: “Bí ọkùnrin abarapá kan bá kú òun ha lè tún padà wàláàyè bí? . . . Ìwọ yóò pè, èmi fúnraàmi yóò sì dá ọ lóhùn, ìwọ yóò ṣàfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jobu 14:14, 15, NW) Níhìn-⁠ín ọ̀rọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a túmọ̀sí “ìwọ yóò ṣàfẹ́rí” dúró fún ìyánhànhàn àti ìfẹ́-ọkàn mímúná tí Ọlọrun ní. (Genesisi 31:30; Orin Dafidi 84:2) Ní kedere, Jehofa gbọ́dọ̀ ti máa fi pẹ̀lú ìfojúsọ́nà mímúhánhán wọ̀nà fún àjíǹde.

A ha lè gba ìlérí àjíǹde gbọ́ níti gidi bí? Bẹ́ẹ̀ni, kò sí iyèméjì pé Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀ múratán tí wọ́n sì ní agbára láti mú un ṣẹ. Kí ni èyí túmọ̀sí fún ọ? Ìwọ ni ìfojúsọ́nà ìrètí ti wíwàpapọ̀ pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ rẹ tí wọ́n ti kú níhìn-⁠ín gan-⁠an lórí ilẹ̀-ayé ṣùgbọ́n lábẹ́ àwọn ipò tí ó yàtọ̀ pátápátá!

Jehofa Ọlọrun, ẹni tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ aráyé nínú ọgbà ẹlẹ́wà kan, ti ṣèlérí láti dá Paradise padà sórí ilẹ̀-ayé yìí lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba ọ̀run Rẹ̀ ní ọwọ́ Jesu Kristi tí a ti ṣe lógo nísinsìnyí. (Genesisi 2:7-9; Matteu 6:10; Luku 23:​42, 43) Nínú Paradise tí a dá padà náà, ìdílé ènìyàn yóò ní ìfojúsọ́nà ìrètí ti gbígbádùn ìwàláàyè tí kò lópin, tí ó bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àìsàn àti àrùn. (Ìfihàn 21:1-4; fiwé Jobu 33:25; Isaiah 35:5-7.) Gbogbo ìkórìíra, ẹ̀tanú ẹ̀yà ìran, rúkèrúdò ẹ̀yà, àti ìfọrọ̀-ajé ninilára yóò dópin. Sínú ilẹ̀-ayé tí a ti fọ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni Jehofa Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi yóò jí àwọn òkú dìde sí.

Àjíǹde, tí a gbékarí ẹbọ ìràpadà Kristi Jesu, yóò mú ayọ̀ wá fún gbogbo orílẹ̀-èdè

Ìyẹn ni ìrètí Kristian obìnrin tí a mẹ́nukan ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ka yìí. Àwọn ọdún mélòókan lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ kú, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ràn án lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli dáradára. Òun rántí pé: “Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí àjíǹde, mo sọkún. Ohun àgbàyanu ni ó jẹ́ láti mọ̀ pé èmi yóò tún padà rí ìyá mi.”

Bí ọkàn-àyà rẹ lọ́nà kan náà bá ṣàfẹ́rí láti tún rí olólùfẹ́ rẹ padà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò fi tayọ̀tayọ̀ ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ bí o ṣe lè sọ ìrètí dídájú yìí di tìrẹ. Èéṣe tí o kò fi kàn sí wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó súnmọ́ ọ, tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó súnmọ́ ọ jùlọ tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú-ìwé 32.

^ ìpínrọ̀ 20 Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀sí “kérora” wá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe náà (em·bri·maʹo·mai) tí o dúró fún láti nírora, tàbí banújẹ́ gidigidi. Ọ̀mọ̀wé kan nípa Bibeli ṣàkíyèsí pé: “Ohun tí ó lè túmọ̀sí níhìn-⁠ín ni pé irú èrò-ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ mú Jesu tí ó fi jẹ́ pé ìkérora wá fúnraarẹ̀ láti ọkàn-àyà Rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ náà tí a túmọ̀sí “inú rẹ̀ sì bàjẹ́” wá láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà (ta·rasʹso) tí ó tọ́kasí ìrugùdù. Gẹ́gẹ́ bí olùṣe ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ kan ṣe sọ, ó túmọ̀sí “láti fa ìdàrúdàpọ̀ inú lọ́hùn-⁠ún fún ẹnìkan, . . . kí ìroragógó tàbí ìbànújẹ́ nípalórí ẹni.” Ọ̀rọ̀ náà “sọkún” wá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe Griki náà (da·kryʹo) tí ó túmọ̀sí “láti da omije, láti sọkún sínú.”