Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?

Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?

ÒTÍTỌ́ nípa kí ni? Òtítọ́ nípa ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn èèyàn tíì béèrè rí. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ alára ti máa wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi:

  • Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà nípa wa?

  • Ṣé ogun àti ìjìyà máa dópin?

  • Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú?

  • Ṣé ìrètí kankan tiẹ̀ wà fáwọn tó ti kú?

  • Báwo ni mo ṣe lè gbàdúrà tí Ọlọ́run á sì gbọ́ àdúrà mi?

  • Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ aláyọ̀?

Ibo gan-an lo ti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí? Bó o bá lọ sáwọn ilé ìkówèésí tàbí ilé ìtàwé, ó ṣeé ṣe kó o rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé tí wọ́n sọ pó dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà ńṣe làwọn ìwé ọ̀hún máa ń ta kora wọn. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí ìdáhùn táwọn kan pèsè wúlò fúngbà díẹ̀, àmọ́ bópẹ́ bóyá, wọ́n á dohun àtijọ́, á sì wá di dandan kí wọ́n tún ìwé ọ̀hún tẹ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fi òmíràn rọ́pò rẹ̀.

Àmọ́, ìwé kan wà táwọn ìdáhùn ẹ̀ sáwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Ìwé tó ń fòótọ́ kọ́ni ni. Nínú àdúrà tí Jésù Kristi gbà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Ọ̀rọ̀ yẹn la wá mọ̀ sí Bíbélì Mímọ́ lónìí. Wàá rí díẹ̀ lára àwọn àlàyé tó ṣe kedere àti ìdáhùn tó jóòótọ́ látinú Bíbélì sáwọn ìbéèrè tá a mẹ́nu kàn lókè yìí, bẹ̀rẹ̀ láti ojú ìwé tó tẹ̀lé e.

 Ṣé Lóòótọ́ Ni Ọlọ́run Bìkítà Nípa Wa?

ÌDÍ TÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ FI JẸ YỌ: Inú ayé táwọn èèyàn ti rorò bí ataare, tí ìwà ìrẹ́jẹ sì ti wọ́pọ̀ là ń gbé. Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé àkọọ́lẹ̀ Ọlọ́run ni ìyà téèyàn ń jẹ.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI: Ọlọ́run kì í ṣebi. Jóòbù 34:10 sọ pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú, àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!” Ọlọ́run ti pinnu ọjọ́ ọ̀la tó dáa fún ìran èèyàn. Ìyẹn ló mú kí Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí . . . ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Ọlọ́run ní ire wa lọ́kàn débi pé, gbogbo ohun tó gbà ló fún un kí ohun tó fẹ́ ṣe fún ìran èèyàn lè ṣẹ.—Jòhánù 3:16.

Tún wo Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; Jákọ́bù 1:13; àti 1 Pétérù 5:6, 7.

Ṣé Ogun àti Ìjìyà Máa Dópin?

ÌDÍ TÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ FI JẸ YỌ: Àwọn tí ogun ń pa ò lóǹkà, kò sì sẹ́ni tó máa sọ pé òun ò jìyà rí.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI: Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí òún máa mú kí àlàáfíà jọba kárí ayé. Àwọn èèyàn ò ní “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́” lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó máa ṣàkóso látọ̀run wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n á “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀.” (Aísáyà 2:4) Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo onírúurú ìwà ìrẹ́jẹ àti ìjìyà. Bíbélì ṣèlérí pé: “[Ọlọ́run] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ [títí kan ìwà ìrẹ́jẹ àti ìjìyà tó gbòde kan lónìí] ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Tún wo Sáàmù 37:10, 11; 46:9; àti Míkà 4:1-4.

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tá A Bá Kú?

ÌDÍ TÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ FI JẸ YỌ: Ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀sìn tó wà lágbàáyé ló ń kọ́ni pé ohun kan wà nínú èèyàn tó máa ń wà láàyè lẹ́yìn téèyàn bá kú. Àwọn kan gbà pé àwọn òkú lè han àwa alàyè léèmọ̀, àwọn míì sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa dá àwọn aṣebi lóró títí láé nínú ọ̀run àpáàdì.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI: Béèyàn bá ti kú, kò sí níbì kankan mọ́. Ìwé Oníwàásù 9:5 sọ pé: “Àwọn òkú . . . kò mọ nǹkan kan rárá.” Níwọ̀n bí àwọn òkú ò ti mọ ohunkóhun, tí wọn ò sì nímọ̀lára, wọn ò lè fi nǹkan kan ṣe àwọn tó wà láàyè wọn ò sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 146:3, 4.

Tún wo Jẹ́nẹ́sísì 3:19 àti Oníwàásù 9:6, 10.

 Ṣé Ìrètí Kankan Tiẹ̀ Wà Fáwọn Tó Ti Kú?

ÌDÍ TÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ FI JẸ YỌ: Kò sẹ́ni tó fẹ́ kú, ó sì máa ń wù wá ká jẹ̀gbádùn ayé pẹ̀lú àwọn tá a fẹ́ràn. Nítorí náà, ìwà ẹ̀dá ló jẹ́ pé kó máa wù wá láti padà rí àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI: Púpọ̀ lára àwọn tó ti kú ni Ọlọ́run máa jí dìde. Jésù ṣèlérí pé “àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí . . . [máa] jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde máa láǹfààní láti gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, torí ète Ọlọ́run fáwa èèyàn gan-an nìyẹn. (Lúùkù 23:43) Ara tó jí pépé wà lára ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn èèyàn, àwọn onígbọràn sì tún máa wà láàyè títí láé. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

Tún wo Jóòbù 14:14, 15; Lúùkù 7:11-17 àti Ìṣe 24:15.

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbàdúrà Tí Ọlọ́run Á sì Gbọ́ Àdúrà Mi?

ÌDÍ TÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ FI JẸ YỌ: Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹlẹ́sìn ló ń gbàdúrà. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ló ń rò pé Ọlọ́run ò dáhùn àdúrà àwọn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI: Jésù kọ́ wa pé ká yé máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà ṣáá tá a bá ń gbàdúrà. Ó sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mátíù 6:7) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ gbà á lọ́nà tó fẹ́. Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ká sì máa fi wọ́n sádùúrà. Jòhánù kìíní orí karùn-ún ẹsẹ kẹrìnlá ṣàlàyé pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ [Ọlọ́run], ó ń gbọ́ tiwa.”

Tún wo Sáàmù 65:2; Jòhánù 14:6, 14 àti 1 Jòhánù 3:22.

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?

ÌDÍ TÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ FI JẸ YỌ: Ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé owó, iyì tàbí ẹwà lè jẹ́ káwọn láyọ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n ṣe ń fi gbogbo ìgbésí ayé wọn lè àwọn nǹkan wọ̀nyí, àmọ́ sí ìyàlẹ́nu wọn, ńṣe láyọ̀ ń fò wọ́n ru.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI: Jésù fi àṣírí ayọ̀ hàn wá nígbà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ká sòótọ́, ó dìgbà tá a bá ṣe ohun tó yẹ ká ṣe láti kájú àìní wa tó ṣe pàtàkì jù lọ ká tó lè láyọ̀ tòótọ́, ìyẹn fífẹ́ láti mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ìdí tó fi dá wa sáyé. Òótọ́ yẹn wà nínú Bíbélì. Lẹ́yìn tá a bá mọ òtítọ́ yẹn la tó lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó ṣe pàtàkì àtèyí tí kò ṣe pàtàkì. Tá a bá ń jẹ́ kí òótọ́ tó wà nínú Bíbélì darí ìgbésí ayé wa, tá a sì ń gbé àwọn ìpinnu ka àwọn ìlànà rẹ̀, ìgbésí ayé wa á túbọ̀ nítumọ̀.—Lúùkù 11:28.

Tún wo Òwe 3:5, 6, 13-18 àti 1 Tímótì 6:9, 10.

 Díẹ̀ lára ìdáhùn Bíbélì sáwọn ìbéèrè mẹ́fà tó wà nínú ìwé yìí lo ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí. Ṣó o fẹ́ àlàyé síwájú sí i? Tó o bá wà lára àwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn,” ó dájú pé wàá fẹ́ àlàyé síwájú sí i. Ó ṣeé ṣe kó o ti máa wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè míì, irú bí i: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa lóòótọ́, kí nìdí tó fi fàyè gba ìwà ibi àti ìjìyà látayébáyé? Báwo ni mo ṣe lè mú ìgbésí ayé ìdílé mi sunwọ̀n sí i?’ Ìdáhùn Bíbélì sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ ìbéèrè míì kún, ó sì tẹ́nilọ́rùn.

Àmọ́, àwọn kan kì í fẹ́ ka Bíbélì rárá. Lójú wọn, Bíbélì dà bí ìwé ńlá kan tó máa ń ṣòro láti lóye. Ṣé wàá fẹ́ kẹ́nì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú Bíbélì? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà méjì kan.

Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni ti ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tá a ṣe láti ran àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí bí Bíbélì ṣe pèsè ìdáhùn tó ṣe kedere sáwọn ìbéèrè pàtàkì. Èkejì ni ti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a ṣe láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn lọ́fẹ̀ẹ́. Ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé ládùúgbò rẹ, tó sì tóótun láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè wá máa lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ bóyá nínú ilé rẹ tàbí níbòmíì tó o bá yàn láàyò. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn yíká ayé ló ti jàǹfààní látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí. Púpọ̀ nínú wọn ló láyọ̀ láti sọ pé: “Mo ti rí òtítọ́!”

Kò sí ìṣura téèyàn lè rí tó ju èyí lọ. Òótọ́ tó wà nínú Bíbélì ló ń gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, ìdàrúdàpọ̀ àti ìbẹ̀rù lórí asán. Ó ń jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa, ó ń jẹ́ kí ayé wa nítumọ̀, ó sì ń fún wa láyọ̀. Jésù sọ pé: “Ẹ ó . . . mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:32.