Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kọ́ Ọmọ Rẹ

 Ẹ̀kọ́ 13

Tímótì Fẹ́ Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́

Tímótì Fẹ́ Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́

Tímótì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin tí inú rẹ̀ máa ń dùn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ó rin ìrìn àjò lọ sí ìlú tó pọ̀ kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ níbẹ̀. Ohun tó ṣe yìí mú kí ó gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀. Ṣé o fẹ́ mọ̀ nípa ohun tó ṣe?—

Ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà kọ́ ọ nípa Jèhófà

Ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Lísírà ni Tímótì gbé dàgbà. Láti kékeré ni ìyá rẹ̀ àgbà tó ń jẹ́ Lọ́ìsì àti ìyá rẹ̀ tó ń jẹ́ Yùníìsì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ nípa Jèhófà. Bí Tímótì ṣe ń dàgbà, ó wù ú kí ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí ó sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

Nígbà tí Tímótì ṣì wà ní ọ̀dọ́kùnrin, Pọ́ọ̀lù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó máa fẹ́ tẹ̀ lé òun kí àwọn jọ lọ wàásù ní àwọn ìlú mìíràn. Tímótì sọ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni!’ Torí pé, ó wù ú láti lọ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

 Tímótì àti Pọ́ọ̀lù rin ìrìn àjò lọ sí ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Tẹsalóníkà ní àgbègbè Makedóníà. Ibẹ̀ jìnnà gan-an, torí náà wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àmọ́ inú ń bí àwọn kan, wọ́n sì gbìyànjú láti ṣe wọ́n léṣe. Bí Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ṣe kúrò níbẹ̀ nìyẹn, wọ́n sì lọ wàásù ní àwọn ìlú mìíràn.

Tímótì láyọ̀, ó sì gbádùn ìgbésí ayé

Oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó pa dà lọ sí ìlú Tẹsalóníkà kó lọ wo bí àwọn ará tó wà níbẹ̀ ṣe ń ṣe sí. Tímótì gbọ́dọ̀ nígboyà torí pé ewu wà nílùú yẹn! Síbẹ̀, Tímótì lọ sí ìlú náà torí pé ó fẹ́ràn àwọn ará tó wà níbẹ̀. Ìròyìn ayọ̀ ló mú bọ̀ láti ibẹ̀, torí pé àwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà ń ṣe dáadáa!

Ọ̀pọ̀ ọdún ni Tímótì fi bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́. Nígbà kan, Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà pé Tímótì ni ẹni tó dára jù tí òun lè rán pé kó lọ ran àwọn ará tó wà ní ìjọ lọ́wọ́. Ìdí ni pé Tímótì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.

Ṣé ìwọ náà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn? Ṣé ó sì wù ẹ́ kí o ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?— Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á máa láyọ̀, wàá sì gbádùn ìgbésí ayé rẹ bíi ti Tímótì!