Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó gba ẹ̀mí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ là. Ọ̀dọ́kùnrin yìí ni mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù. A kò mọ orúkọ ọ̀dọ́kùnrin náà, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé ó ní ìgboyà. Ṣé o fẹ́ mọ ohun tó ṣe?—

Inú ẹ̀wọ̀n ni Pọ́ọ̀lù wà ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn aláṣẹ ti mú un torí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù. Àwọn ọkùnrin burúkú kan kórìíra Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì ti sọ bí wọ́n ṣe fẹ́ hùwà burúkú yìí. Wọ́n sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká sọ fún ọ̀gágun pé kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mú Pọ́ọ̀lù wá sí kóòtù. Àá wá lọ fara pa mọ́ sójú ọ̀nà, tí Pọ́ọ̀lù bá ń kọjá lọ, àá kàn yọ sí i lójijì, àá sì pa á!

Mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù sọ fún Pọ́ọ̀lù àti ọ̀gágun náà nípa ohun burúkú táwọn ọkùnrin yẹn fẹ́ ṣe

Mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù tá a sọ yẹn gbọ́ nípa ohun tí àwọn ọkùnrin burúkú yìí fẹ́ ṣe. Kí ni ọ̀dọ́kùnrin yìí máa wá ṣe o? Ńṣe ló lọ bá Pọ́ọ̀lù lẹ́wọ̀n, ó sì sọ fún un. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé kó lọ sọ fún ọ̀gágun nípa ohun burúkú táwọn ọkùnrin yìí fẹ́ ṣe. Ǹjẹ́ o rò pé ó rọrùn fún mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù láti lọ bá ọ̀gágun yẹn sọ̀rọ̀?— Rára o, torí pé èèyàn pàtàkì ni ọ̀gágun yẹn. Àmọ́ mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù nígboyà, ó lọ bá ọ̀gágun náà sọ̀rọ̀.

Ọ̀gágun náà mọ ohun tó yẹ kó ṣe. Àwọn ọmọ ogun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn ún márùn ún [500] ló kó tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù, kí wọ́n lè dáàbò bò ó! Ó ní kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lọ sí Kesaréà ní alẹ́ ọjọ́ yẹn. Ṣé Pọ́ọ̀lù dé ibẹ̀ láìsí ewu?— Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọkùnrin burúkú yẹn kò rí i pa! Ohun burúkú tí wọ́n fẹ́ ṣe kò yọrí sí rere.

Kí lo rí kọ́ nínú ìtàn yìí?— Ìwọ náà lè nígboyà bíi ti mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù. Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fún àwọn èèyàn, a gbọ́dọ̀ nígboyà. Ṣé wàá jẹ́ onígboyà, kí o sì máa báa lọ láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà?— Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o lè gba ẹ̀mí èèyàn là.