Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ń ṣe fún Jèhófà?

Kò rọrùn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà rárá, àmọ́ ó ṣe ohun tí bàbá rẹ̀ ṣèlérí fún Jèhófà

Ṣé o rí ọmọbìnrin tó wà nínú àwòrán yìí?— Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jẹ́fútà ni bàbá rẹ̀. Bíbélì kò sọ orúkọ ọmọbìnrin yìí fún wa, àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé ó mú inú bàbá rẹ̀ àti inú Jèhófà dùn. Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun àti Jẹ́fútà bàbá rẹ̀.

Ẹni rere ni Jẹ́fútà, ó máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti kọ́ ọmọ rẹ̀ nípa Jèhófà. Ó lágbára gan-an, aṣáájú rere sì ni. Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé kó ṣáájú àwọn, kí wọ́n lè lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà.

Jẹ́fútà gbàdúrà sí Ọlọ́run, pé kó jẹ́ kí òun ṣẹ́gun. Ó wá ṣèlérí pé tí òun bá ṣẹ́gun, ẹni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pàdé òun ni òun máa fún Jèhófà. Gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ni ẹni yẹn á fi máa gbé  nínú àgọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, tí á sì máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Inú ibi tí àwọn èèyàn ti máa ń lọ jọ́sìn Ọlọ́run nígbà yẹn ló ń jẹ́ àgọ́ ìjọsìn. Lọ́rọ̀ kan, Jẹ́fútà ṣẹ́gun nínú ìjà náà! Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó kọ́kọ́ jáde nínú ilé rẹ̀ nígbà tó pa dà dé ilé?—

Bẹ́ẹ̀ ni, ọmọbìnrin Jẹ́fútà ni! Ọmọ kan ṣoṣo tó ní nìyẹn, àmọ́ ní báyìí ó gbọ́dọ̀ rán ọmọ náà lọ. Inú Jẹ́fútà kò dùn rárá. Ṣùgbọ́n o, rántí pé ó ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sọ pé, ‘Bàbá mi, ẹ ti ṣèlérí fún Jèhófà, ẹ ní láti mú ìlérí yín ṣẹ.’

Lọ́dọọdún, àwọn ọ̀rẹ́ ọmọbìnrin Jẹ́fútà máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀

Inú ọmọbìnrin Jẹ́fútà náà kò dùn. Tó bá lọ sí àgọ́ ìjọsìn, kò ní lọ́kọ, kò sì ní bímọ. Àmọ́ ó gbà láti ṣe ohun tí bàbá rẹ̀ sọ, kí ó lè mú inú Jèhófà dùn. Ó gbà pé ìyẹn ṣe pàtàkì sí òun ju ọkọ tàbí ọmọ lọ. Torí náà, ó kúrò nílé, gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ló sì fi gbé nínú àgọ́ ìjọsìn.

Ǹjẹ́ o rò pé ohun tó ṣe yẹn mú inú bàbá rẹ̀ àti inú Jèhófà dùn?— Bẹ́ẹ̀ ni o, inú wọn dùn! Tí ìwọ náà bá jẹ́ onígbọràn tí o sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi ti ọmọbìnrin Jẹ́fútà, wàá mú inú àwọn òbí rẹ àti inú Jèhófà dùn.