Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

 ORÍ 21

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Fọ́nnu?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Fọ́nnu?

TÍ A bá sọ pé èèyàn ń fọ́nnu, kí ló túmọ̀ sí? Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n?— Àpẹẹrẹ kan nìyí. Ǹjẹ́ ó tíì ṣẹlẹ̀ sí ọ rí pé o fẹ́ ṣe ohun kan tí o kò mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa? Bóyá o fẹ́ láti gbá bọ́ọ̀lù. Tàbí bóyá ò ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń gun kẹ̀kẹ́. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tíì fi ọ́ rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà kó sì sọ pé, “Kúrò jọ̀ọ́. Mo mọ̀ ọ́n ṣe jù ẹ́ lọ”?— Onítọ̀hún ń fọ́nnu nìyẹn.

Nígbà tí àwọn èèyàn bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ? Ǹjẹ́ o máa ń fẹ́ bẹ́ẹ̀?— Nígbà náà, tí ìwọ náà bá ń fọ́nnu báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn ẹlòmíràn?— Ṣé ó dára láti sọ fún ẹlòmíràn pé, “Mò ń ṣe dáadáa jù ọ́ lọ”?— Ǹjẹ́ inú Jèhófà máa ń dùn sí àwọn tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀?—

Olùkọ́ Ńlá náà mọ àwọn èèyàn tí wọ́n rò pé àwọn ń ṣe dáadáa ju àwọn ẹlòmíràn lọ. Wọ́n máa ń fọ́nnu, wọ́n máa ń ṣògo, tàbí kí wọ́n máa gbéra ga, wọ́n sì máa ń fojú yẹpẹrẹ wo gbogbo èèyàn yòókù. Nítorí náà, lọ́jọ́ kan Jésù sọ ìtàn kan fún wọn láti fi hàn wọ́n pé ó lòdì gan-an pé kí èèyàn máa fọ́nnu nípa ara rẹ̀. Jẹ́ ká gbọ́ ìtàn yẹn.

Ó jẹ́ ìtàn nípa Farisí kan àti agbowó orí kan. Wàyí o, àwọn Farisí jẹ́ olùkọ́ni ní ìsìn, wọ́n sì sábà máa ń ṣe bí ẹni pé wọ́n jẹ́ olódodo tàbí ẹni tó mọ́ ju àwọn èèyàn yòókù lọ. Farisí tí Jésù ń sọ ìtàn rẹ̀ yìí wọ inú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù láti lọ gbàdúrà.

Kí nìdí tí inú Ọlọ́run fi dùn sí agbowó orí, àmọ́ tí inú rẹ̀ kò dùn sí Farisí náà?

Jésù sọ pé agbowó orí kan lọ sínú tẹ́ńpìlì láti lọ gbàdúrà bákan náà. Àwọn èèyàn tó pọ̀ jú lọ kò fẹ́ràn àwọn agbowó orí. Wọ́n rò pé àwọn agbowó orí máa ń fẹ́ láti rẹ́ wọn jẹ. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó orí sábà máa ń rẹ́ni jẹ.

 Nínú tẹ́ńpìlì, Farisí náà gbàdúrà sí Ọlọ́run báyìí pé: ‘Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé èmi kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ bí àwọn ènìyàn yòókù. Èmi kì í rẹ́ni jẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kì í ṣe àwọn ohun burúkú. Èmi kò dà bí agbowó orí tó wà lọ́hùn-ún yẹn. Olódodo ni mí. Ìgbà méjì ní ọ̀sẹ̀ ni èmi kì í jẹun kí n lè rí àyè ronú nípa rẹ. Mo ń mú ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí mo ní wá sínú tẹ́ńpìlì.’ Farisí yìí rò pé òun ń ṣe dáadáa ju àwọn èèyàn yòókù lọ lóòótọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Ó tiẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run pẹ̀lú.

Ṣùgbọ́n agbowó orí yẹn kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tirẹ̀. Kò gbé ojú sókè wo ọ̀run nígbà tó ń gbàdúrà. Ó dúró sí òkèèrè, ó sì tẹrí ba. Inú agbowó orí náà bà jẹ́ gidigidi nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì ń fọwọ́ lu àyà rẹ̀ nítorí tí inú rẹ̀ bà jẹ́. Kò gbìyànjú láti sọ fún Ọlọ́run pé ẹni rere lòun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbàdúrà pé: ‘Ọlọ́run, ṣàánú mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’

Èwo nínú àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí lo rò pé inú Ọlọ́run dùn sí? Ṣé Farisí yẹn ni, tí ó rò pé èèyàn rere gan-an lòun? Tàbí, ṣé agbowó orí, tí inú rẹ̀ bà jẹ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yẹn ni?—

Jésù sọ pé agbowó orí yẹn ni inú Ọlọ́run dùn sí. Èé ṣe? Jésù ṣàlàyé pé: ‘Nítorí pé gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ máa ṣe bí ẹni pé òun dára ju àwọn èèyàn yòókù lọ ni a óò rẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ara rẹ̀ sí ẹni tó rẹlẹ̀ ni a óò gbé ga.’—Lúùkù 18:9-14.

Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù ń kọ́ wa nínú ìtàn rẹ̀ yìí?— Ó kọ́  wa pé ó lòdì láti máa rò pé a dára ju àwọn ẹlòmíràn lọ. A lè máà sọ ọ́ lẹ́nu pé a dára jù wọ́n lọ o, ṣùgbọ́n ohun tí à ń ṣe lè fi hàn pé à ń rò bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o ti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?— Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù.

Nígbà tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé gbogbo wọn máa sá nígbà tí àwọn aláṣẹ bá wá mú òun, Pétérù fọ́nnu pé: ‘Bí gbogbo èèyàn bá tilẹ̀ sá, èmi ò ní sá láéláé!’ Ṣùgbọ́n Pétérù kò tọ̀nà. Ó dá ara rẹ̀ lójú jù. Níkẹyìn ó fi Jésù sílẹ̀ ó sì sá lọ. Àmọ́ ṣá, ó tún padà wá bá Jésù, gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa rí i ní Orí 30 nínú ìwé yìí.—Mátíù 26:31-33.

Ẹ jẹ́ ká mú àpẹẹrẹ òde òní kan wá. Ká sọ pé wọ́n béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ ìwọ àti ọmọ kíláàsì rẹ kan nílé ìwé. Kí lo máa ṣe tó bá jẹ́ pé ìwọ tètè mọ ìdáhùn náà, ṣùgbọ́n tí ẹnì kejì rẹ kò tètè mọ̀ ọ́n? Lóòótọ́, inú rẹ máa dùn pé o mọ àwọn ìdáhùn náà. Ṣùgbọ́n ṣé ó dára kí o máa gbéra ga pé o mọ̀ ìwé ju ẹni tí kò lè tètè dáhùn yẹn?— Ǹjẹ́ ó tọ́ pé kí o máa ṣakọ kí o sì máa pe ẹnì kejì rẹ ní olódo?—

Ohun tí Farisí yẹn ṣe nìyẹn. Ó fọ́nnu pé òun ń ṣe dáadáa ju agbowó orí yẹn lọ. Ṣùgbọ́n Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé ohun tí Farisí yìí ṣe kò dára. Lóòótọ́, ó lè ṣeé ṣe kí ẹnì kan mọ ohun kan ṣe dáadáa ju ẹlòmíràn lọ. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò fi hàn pé ó jẹ́ ẹni tó dára jù.

Tí o bá mọ ohun kan ju ẹnì kan lọ, ṣé ìyẹn wá mú ọ dára ju onítọ̀hún lọ?

Nítorí náà, tí a bá mọ ohun kan ju ẹlòmíràn lọ, ǹjẹ́ ó yẹ kí á máa wá torí ìyẹn fọ́nnu bí?— Ronú nípa rẹ̀ ná. Ṣé àwa fúnra wa ló dá ọpọlọ wa ni?— Rárá o, Ọlọ́run ló fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ọpọlọ. Púpọ̀ jù lọ nínú ohun tí a mọ̀, ẹlòmíràn ló kọ́ wa. Bóyá a ka àwọn ohun kan nínú ìwé, tàbí bóyá ẹnì kan ló sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyẹn fún wa, tàbí ká tiẹ̀ sọ pé fúnra wa ni a ronú tí a sì ṣe ohun náà, kí ni a lò láti fi ṣe é?— Bẹ́ẹ̀ ni o, ọpọlọ tí Ọlọ́run fún wa ni a lò.

 Bí ẹnì kan bá ti sapá gan-an, ohun tó dára ni pé kí o sọ ohun tó máa mú inú rẹ̀ dùn. Sọ fún un pé inú rẹ dùn fún ohun tó ṣe. Bóyá o tiẹ̀ lè ràn án lọ́wọ́ kí ó lè ṣe dáadáa jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ohun tí ìwọ náà máa fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe fún ọ nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fọ́nnu tá a bá lágbára ju ẹlòmíì lọ?

Àwọn èèyàn kan lágbára ju àwọn mìíràn lọ. Ká sọ pé o lágbára ju ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin lọ ńkọ́? Ṣé ó yẹ kí o wá torí ìyẹn máa fọ́nnu?— Rárá o. Oúnjẹ tí à ń jẹ ló ń jẹ́ ká lágbára. Ọlọ́run ló sì ń fún wa ní oòrùn, òjò àti gbogbo ohun tí ewéko nílò láti lè mú oúnjẹ jáde, àbí òun kọ́?— Nítorí náà, ọwọ́ Ọlọ́run ló ti yẹ kí á dúpẹ́ pé a dàgbà tí a sì lágbára.—Ìṣe 14:16, 17.

Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó fẹ́ máa gbọ́ kí ẹnì kan máa fọ́nnu nípa ara rẹ̀, àbí?— Jẹ́ kí á rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní dà bíi Farisí tó fọ́nnu nínú ìtàn tí Olùkọ́ Ńlá náà sọ.—Lúùkù 6:31.

 Ní ìgbà kan, ẹnì kan pe Jésù ní ẹni rere. Ǹjẹ́ Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹni rere ni mí’?— Rárá o, kò sọ bẹ́ẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Kò sí ẹni rere, àyàfi ẹnì kan, Ọlọ́run.” (Máàkù 10:18) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Olùkọ́ Ńlá náà, kò fọ́nnu nípa ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi gbogbo ìyìn fún Jèhófà Bàbá rẹ̀.

Nítorí náà, ǹjẹ́ ẹnì kan wà tí a lè fi fọ́nnu tàbí kí á fi ṣògo?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà. A lè fi Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run ṣògo. Tí a bá rí bí oòrùn ṣe lẹ́wà nígbà tí oòrùn fẹ́ wọ̀, tàbí tí a rí àwọn ohun ìyanu mìíràn tí Ọlọ́run dá, a lè sọ fún ẹnì kan pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa tó ń ṣe ohun ìyanu ló dá èyí o!’ Ẹ jẹ́ kí ó máa wù wá nígbà gbogbo láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ńlá tí Jèhófà ti ṣe fún wa, àti èyí tí yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú.

Kí ni ọmọdé yìí fi ń ṣògo?

Kà nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ wí nípa fífọ́nnu, ṣíṣògo tàbí gbígbéraga, kí o sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe lè yẹra fún fífọ́nnu nípa ara wa: Òwe 16:5, 18; Jeremáyà 9:23, 24; 1 Kọ́ríńtì 4:7; àti 1Kọ 13:4.