Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

 ORÍ 30

Ìrànlọ́wọ́ Láti Borí Ìbẹ̀rù

Ìrànlọ́wọ́ Láti Borí Ìbẹ̀rù

ǸJẸ́ ó rọrùn fún ọ láti sin Jèhófà?— Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé kò ní rọrùn láti sin Jèhófà. Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa Jésù, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kí ó tó kórìíra yín.”—Jòhánù 15:18.

Pétérù fọ́nnu pé òun ò ní fi Jésù sílẹ̀ láé, àmọ́ Jésù sọ pé Pétérù yóò sẹ́ òun ní ẹ̀ẹ̀mẹta ní alẹ́ ọjọ́ yẹn. Pétérù sì sẹ́ ẹ lóòótọ́! (Mátíù 26:31-35, 69-75) Kí ló jẹ́ kí Pétérù sẹ́ bẹ́ẹ̀?— Ó jẹ́ nítorí pé Pétérù bẹ̀rù, àwọn àpọ́sítélì yòókù sì bẹ̀rù pẹ̀lú.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á tí àwọn àpọ́sítélì fi bẹ̀rù?— Ohun pàtàkì kan wà tí wọ́n kùnà láti ṣe. Tí a bá mọ ohun náà, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti sin Jèhófà láìka ohun tí ẹnikẹ́ni lè sọ tàbí kí ó ṣe sí wa sí. Ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kí á ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ ní alẹ́ tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ wà pa pọ̀ kẹ́yìn.

Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ṣe ayẹyẹ àjọ Ìrékọjá pa pọ̀. Ìrékọjá jẹ́ oúnjẹ pàtàkì kan tí wọ́n máa ń jẹ lọ́dọọdún láti fi rán àwọn èèyàn Ọlọ́run létí nípa bí wọ́n ṣe bọ́ kúrò ní oko ẹrú ní Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, Jésù dá oúnjẹ àrà ọ̀tọ̀ kan sílẹ̀ fún wọn láti máa jẹ. A ó sọ̀rọ̀ nípa èyí nínú àkòrí kan níwájú, a ó sì ṣàlàyé nípa bí oúnjẹ yìí yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti máa rántí Jésù. Lẹ́yìn oúnjẹ yẹn àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Jésù mú wọn jáde lọ sínú ọgbà Gẹtisémánì. Ọgbà yìí jẹ́ ibi tí wọ́n sábà máa ń lọ dáadáa.

Níbẹ̀, Jésù kúrò láàárín wọn ó nìkan lọ gbàdúrà ní ibì kan  nínú ọgbà náà. Ó sọ fún Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù pé kí àwọn pẹ̀lú máa gbàdúrà. Ṣùgbọ́n wọ́n sùn lọ. Ẹ̀ẹ̀mẹta ni Jésù fi wọ́n sílẹ̀ tó lọ gbàdúrà, ní ẹ̀ẹ̀mẹtẹ̀ẹ̀ta yìí ló sì padà wá tí ó bá Pétérù àti àwọn yòókù tí wọ́n ń sùn! (Mátíù 26:36-47) Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n sùn ṣùgbọ́n kí wọ́n máa gbàdúrà?— Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa èyí.

Kí nìdí tí kò fi yẹ kí Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù sùn?

Júdásì Ísíkáríótù wà ní ibi Ìrékọjá tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jẹ pa pọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ yẹn. Ṣé o rántí pé Júdásì ti di olè. Nísinsìnyí, ó di afinihàn. Júdásì mọ ibi tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti sábà máa ń pàdé nínú ọgbà Gẹtisémánì. Nítorí náà, Júdásì kó àwọn ọmọ ogun wá síbẹ̀ kí wọ́n wá mú Jésù. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jésù bi wọ́n pé: “Ta ni ẹ̀ ń wá?”

Àwọn ọmọ ogun dáhùn pé: ‘Jésù ni.’ Jésù kò bẹ̀rù, nítorí náà, ó dáhùn pé: ‘Èmi nìyí.’ Ìgboyà tí Jésù ní yìí ya àwọn ọmọ ogun lẹ́nu débi pé wọ́n rìn sẹ́yìn wọ́n sì ṣubú lulẹ̀. Lẹ́yìn náà Jésù sọ pé: ‘Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn àpọ́sítélì mi máa lọ.’—Jòhánù 18:1-9.

Nígbà tí àwọn ọmọ ogun gbá Jésù mú, tí wọ́n dè é, ẹ̀rù ba àwọn àpọ́sítélì, wọ́n sì sá lọ. Ṣùgbọ́n Pétérù àti Jòhánù fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, nítorí náà wọ́n rọra ń tẹ̀ lé wọn lẹ́yìn láìsún mọ́ wọn. Níkẹyìn wọ́n mú Jésù wá sí ilé Káyáfà àlùfáà àgbà. Nítorí pé àlùfáà àgbà mọ Jòhánù, ẹni tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà jẹ́ kí òun àti Pétérù wọ inú àgbàlá náà.

Àwọn àlùfáà ti kóra jọ sí ilé Káyáfà dè wọ́n láti gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Wọ́n ṣáà fẹ́ kí wọ́n pa Jésù. Nítorí náà, wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wá, kí wọ́n lè purọ́ mọ́ ọn. Wọ́n gbá Jésù ní ẹ̀ṣẹ́, wọ́n sì gbá a létí. Pétérù wà nítòsí ibẹ̀ nígbà tí gbogbo èyí ń ṣẹlẹ̀.

Ìránṣẹ́bìnrin tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, tó jẹ́ kí Pétérù àti Jòhánù wọlé,  kíyè sí Pétérù dáadáa. Ó sì sọ pé: “Ìwọ, náà, wà pẹ̀lú Jésù!” Ṣùgbọ́n Pétérù sẹ́ pé òun ò tiẹ̀ mọ Jésù rárá. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ìránṣẹ́bìnrin mìíràn dá Pétérù mọ̀, ó sì sọ fún àwọn tó dúró nítòsí rẹ̀ pé: “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù.” Pétérù tún sẹ́ pé òun kò mọ̀ ọ́n. Nígbà tó tún yá, àwọn èèyàn kan rí Pétérù wọ́n sì sọ fún un pé: “Dájúdájú, ìwọ pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára wọn.” Pétérù tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kẹta, ó ní: “Èmi kò mọ ọkùnrin náà!” Pétérù tiẹ̀ búra pé òun ò purọ́. Nígbà náà ni Jésù yí ojú padà, ó wo Pétérù.—Mátíù 26:57-75; Lúùkù 22:54-62; Jòhánù 18:15-27.

Kí ló jẹ́ kí Pétérù bẹ̀rù gan-an tó fi purọ́ pé òun kò mọ Jésù?

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó jẹ́ kí Pétérù purọ́?— Torí pé ó bẹ̀rù ni. Ṣùgbọ́n kí ló jẹ́ kí ó bẹ̀rù? Kí ni ohun tí kò ṣe ṣáájú tí kò fi ní ìgboyà? Rò ó ná. Kí ni Jésù ṣe tó fi ní ìgboyà?— Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ láti ní ìgboyà. Sì rántí o pé, Jésù sọ fún Pétérù nígbà mẹ́ta pé kí ó gbàdúrà, kí ó wà lójúfò kí ó sì máa ṣọ́nà. Ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀?—

Nígbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta Pétérù ń sùn ni. Kò gbàdúrà, kò ṣọ́nà. Nítorí náà, ó bá a lójijì pé wọ́n mú Jésù. Nígbà tí wọ́n tún ń na Jésù bí  wọ́n ṣe ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣètò láti pa á, ẹ̀rù ba Pétérù. Síbẹ̀, ní wákàtí mélòó kan ṣáájú ìgbà náà, kí ni Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n máa retí?— Jésù sọ fún wọn pé gẹ́gẹ́ bí ayé ṣe kórìíra òun, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa kórìíra wọn pẹ̀lú.

Báwo ni irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù ṣe lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà?

Wàyí o, jẹ́ ká ronú nípa ohun kan tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa tí yóò dà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù. Jẹ́ ká sọ pé o wà nínú kíláàsì nígbà tí àwọn kan ń sọ̀rọ̀ tí kò dára nípa àwọn tí kì í kí àsíá tàbí àwọn tí kì í ṣe Kérésìmesì. Lẹ́yìn náà kí ẹnì kan wá yíjú sí ọ kí ó béèrè pé: “Ṣé pé ìwọ kì í kí àsíá lóòótọ́?” Tàbí kí àwọn mìíràn sọ pé: “A gbọ́ pé ìwọ kì í ṣe Kérésìmesì pàápàá!” Ṣé  ẹ̀rù máa bà ọ́ láti sọ òtítọ́?— Ṣé kò ní dà bíi pé kí o purọ́, gẹ́gẹ́ bíi ti Pétérù?—

Nígbà tí Pétérù ti sẹ́ tán pé òun kò mọ Jésù, ó wá dun Pétérù gan-an. Nígbà tí ó rí i pé òun ti ṣe ohun tí kò dára, ó bọ́ síta ó ń sunkún. Nípa báyìí, ó padà sọ́dọ̀ Jésù. (Lúùkù 22:32) Wàyí o, ronú nípa rẹ̀. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe bẹ̀rù débi tí a óò fi wá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Pétérù?— Rántí pé Pétérù kò gbàdúrà, kò sì ṣọ́nà. Nítorí náà, kí ni o máa sọ pé ó yẹ kí á máa ṣe láti lè máa jẹ́ ọmọlẹ́yìn Olùkọ́ Ńlá náà?—

A ní láti máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí Jésù gbàdúrà ǹjẹ́ o mọ ohun tí Ọlọ́run ṣe fún un?— Ó rán áńgẹ́lì kí ó wá sọ̀rọ̀ tí yóò fún un lókun. (Lúùkù 22:43) Ǹjẹ́ áńgẹ́lì Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́?— Bíbélì sọ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.” (Sáàmù 34:7) Ṣùgbọ́n kí á tó lè rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà, a ó ṣe ohun mìíràn ní àfikún sí gbígbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun mìíràn tí ó yẹ kí á ṣe?— Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wà lójúfò kí wọ́n sì máa ṣọ́nà. Báwo ni o rò pé a ṣe lè ṣe é?—

A ó máa fetí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí wọ́n ń sọ ní àwọn ìpàdé Kristẹni, a ó sì máa fiyè sí ohun tí a bá kà nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n a tún ní láti máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé kí á sì máa bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ kí á lè máa sìn ín. Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti lè borí ìbẹ̀rù. Nígbà náà, inú wa á máa dùn nígbà tí a bá ní àǹfààní láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Olùkọ́ Ńlá náà àti Bàbá rẹ̀.

Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí lè ràn wá lọ́wọ́ kí á má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù àwọn èèyàn mú kí á fà sẹ́yìn láti ṣe ohun tó tọ́: Òwe 29:25; Jeremáyà 26:12-15, 20-24; àti Jòhánù 12:42, 43.