TÁ A bá bá ẹnì kan pàdé, a sábà máa ń fẹ́ mọ orúkọ rẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Gbogbo wa pátá la ní orúkọ. Ọlọ́run fún ọkùnrin tó kọ́kọ́ dá sí ayé ní orúkọ. Ádámù ni orúkọ rẹ̀. Éfà sì ni orúkọ ìyàwó Ádámù.

Àmọ́, àwa èèyàn nìkan kọ́ la ní orúkọ o. Jẹ́ ká ronú nípa àwọn nǹkan mìíràn tó ní orúkọ. Àwọn ẹran ọ̀sìn bí ajá máa ń ní orúkọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Ìyẹn fi hàn pé orúkọ ṣe pàtàkì gan-an ni.

Wo àwọn ìràwọ̀ tín-tìn-tín tó máa ń wà lójú ọ̀run lálẹ́. Ǹjẹ́ o rò pé wọ́n ní orúkọ?— Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run fún ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan tó wà lójú ọ̀run ní orúkọ. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ó ka iye àwọn ìràwọ̀; gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ wọn pè.”—Sáàmù 147:4.

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan ló ní orúkọ?

Ta ni ẹni tí o rò pé ó ṣe pàtàkì jù lọ ní ayé àti ní ọ̀run?— Ọlọ́run ni. Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run ní orúkọ?— Jésù sọ pé Ọlọ́run ní orúkọ. Nígbà kan tí Jésù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: ‘Mo ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ẹyìn mi.’ (Jòhánù 17:26) Ǹjẹ́ o mọ orúkọ Ọlọ́run?— Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ orúkọ yẹn fún wa. Ó sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” Nítorí náà, JÈHÓFÀ ni orúkọ Ọlọ́run.—Aísáyà 42:8.

Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tí àwọn èèyàn bá rántí orúkọ rẹ?— Inú rẹ máa ń dùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Jèhófà náà fẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ òun. Nítorí náà, ó yẹ ká máa lo orúkọ náà Jèhófà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Olùkọ́ Ńlá náà máa ń lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, nígbà tó bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Jésù tiẹ̀ sọ nígbà kan pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ.”—Máàkù 12:30.

 Jésù mọ̀ pé orúkọ tó ṣe pàtàkì púpọ̀ ni orúkọ náà “Jèhófà.” Nítorí náà, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa lo orúkọ Ọlọ́run. Ó tún kọ́ wọn pé kí wọ́n máa dárúkọ Ọlọ́run tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Jésù mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Òun.

Láyé àtijọ́, Ọlọ́run fi bí orúkọ rẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó han Mósè tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ kan tó ń jẹ́ Íjíbítì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé nígbà yẹn. Àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìlú Íjíbítì tí à ń sọ yìí là ń pè ní ará Íjíbítì tàbí ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì. Àwọn ará Íjíbítì yìí sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú, wọ́n sì ń hùwà ìkà sí wọn. Nígbà tí Mósè dàgbà, ó gbìyànjú láti ran ọ̀kan lára àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́. Èyí bí Fáráò tí i ṣe ọba ilẹ̀ Íjíbítì nínú. Ó sì ń wá bó ṣe máa pa Mósè! Nítorí náà, Mósè sá kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.

Mósè sá lọ sí ilẹ̀ ibòmíràn. Ilẹ̀ Mídíánì  ló sá lọ. Ibẹ̀ ni Mósè ti fẹ́ ìyàwó tó sì bí àwọn ọmọ. Ó tún ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn níbẹ̀. Lọ́jọ́ kan, bí Mósè ṣe ń da àwọn àgùntàn rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè kan, ó rí ohun abàmì kan. Ó rí i tí iná ń yọ làù lára igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún kan, ṣùgbọ́n igi náà fúnra rẹ̀ kò jóná! Mósè sún mọ́ ibẹ̀ kó lè rí igi tó ń jó yẹn dáadáa.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀?— Mósè gbọ́ ohùn kan látinú iná tó ń jó lára igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà. Ohùn náà ké sí i pé: “Mósè! Mósè!” Ta ni ẹni tó ń pe Mósè?— Ọlọ́run ni! Ọlọ́run ní iṣẹ́ tó pọ̀ fún Mósè láti ṣe. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: ‘Wá, jẹ́ kí n rán ọ lọ sọ́dọ̀ Fáráò, ọba Íjíbítì. Kí o sì kó àwọn èèyàn mi, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.’ Ọlọ́run mú kó dá Mósè lójú pé òun á ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí.

Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Mósè kọ́ níbi iná tó ń jó lára igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà?

Àmọ́ Mósè sọ fún Ọlọ́run pé: ‘Ká ní mo dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Íjíbítì tí mo sì sọ fún wọn pé Ọlọ́run ló rán mi, tí wọ́n wá béèrè pé, “Kí lorúkọ Ọlọ́run náà?” Kí ni kí n sọ?’ Ọlọ́run ní kí Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Jèhófà ló rán mi sí i yín, ó sì sọ pé Jèhófà  ni orúkọ òun títí láé.’ (Ẹ́kísódù 3:1-15) Èyí fi hàn pé títí láé ni Ọlọ́run yóò máa jẹ́ orúkọ náà Jèhófà. Kò ní yí i padà láéláé. Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa pe òun ní orúkọ náà Jèhófà títí láé.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú káwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ̀ ní Òkun Pupa?

Nígbà tí Mósè padà lọ sí Íjíbítì, àwọn ará Íjíbítì rò pé òrìṣà kékeré kan lásán ni Jèhófà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sìn. Wọn ò mọ̀ pé Ọlọ́run gbogbo àgbáyé ni Jèhófà. Nítorí náà, Jèhófà sọ fún ọba Íjíbítì pé: ‘Èmi yóò mú kí àwọn èèyàn ibi gbogbo ní ayé mọ orúkọ mi.’ (Ẹ́kísódù 9:16) Jèhófà sì mú kí àwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ̀ lóòótọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Ọlọ́run ṣe láti mú kí àwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ̀?—

Ọlọ́run sọ pé kí Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Nígbà tí wọ́n dé etí Òkun Pupa, Jèhófà mú kí omi òkun yẹn pínyà sí méjì, kí ilẹ̀ gbígbẹ lè wà láàárín omi òkun tí ó pínyà náà. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá gba orí ilẹ̀ gbígbẹ náà kọjá láìsí ìṣòro. Ṣùgbọ́n bí Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ ṣe ń rìn lọ lórí ilẹ̀ gbígbẹ náà, omi tó pínyà sí méjì náà kàn ya bò wọ́n ni. Gbogbo wọ́n sì kú.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí gbogbo aráyé fi bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohun tí Jèhófà ṣe ní Òkun Pupa. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn èèyàn gbọ́ nípa rẹ̀?— Bí a ṣe mọ̀ ni pé ní nǹkan bí ogójì ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn ọmọ  Ísírẹ́lì dé ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ tí Jèhófà ti ṣèlérí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun máa fún wọn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ráhábù sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘A ti gbọ́ bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí omi Òkun Pupa gbẹ kúrò níwájú yín nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Íjíbítì.’—Jóṣúà 2:10.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe bíi tàwọn ará Íjíbítì wọ̀nyẹn. Wọn ò gbà gbọ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run gbogbo àgbáyé. Nítorí náà, Jèhófà ń fẹ́ kí àwọn tó jẹ́ èèyàn òun máa sọ̀rọ̀ nípa òun fún àwọn ẹlòmíràn. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn.  Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn.”—Jòhánù 17:26.

Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o lè sọ ibi tí orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì?

Ṣé o fẹ́ dà bíi Jésù? Bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, nígbà náà, máa sọ fún àwọn ẹlòmíràn pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. O lè rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò tiẹ̀ mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Kódà, o lè fi hàn wọ́n pé ó wà nínú Sáàmù 83:18. Gbé Bíbélì rẹ nísinsìnyí kó o sì jẹ́ ká jọ wo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn. Ó kà pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Kí ni ibi tí a kà yìí jẹ́ ká mọ̀?— Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ tó ṣe pàtàkì jù lọ. Orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè ni. Ọlọ́run yìí ni Bàbá Jésù. Òun sì ni Ẹni tó dá ohun gbogbo. Má sì ṣe gbàgbé pé Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ fi gbogbo ọkàn wa fẹ́ràn Jèhófà Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o fẹ́ràn Jèhófà?—

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ràn Jèhófà?— Ohun àkọ́kọ́ ni pé kí á mọ Jèhófà dáadáa pé ó jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa. Lẹ́yìn náà, a ó máa sọ orúkọ rẹ̀ fún àwọn èèyàn. A lè ṣí Bíbélì ká fi ibi tó wà níbẹ̀ hàn wọ́n pé Jèhófà ni orúkọ rẹ̀. A tún lè sọ fún wọn nípa àwọn ohun ìyanu tí Jèhófà ti dá àti àwọn ohun rere tó ti ṣe. Èyí máa ń mú inú Jèhófà dùn gan-an nítorí pé ó fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa òun. Àwa náà lè sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—

Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni yóò fẹ́ láti tẹ́tí sí wa tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fetí sílẹ̀ nígbà tí Jésù tó tiẹ̀ jẹ́ Olùkọ́ Ńlá náà ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Àmọ́ ìyẹn ò mú kí Jésù dákẹ́ kó má sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà mọ́.

Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká dà bíi Jésù. Ká máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà nígbà gbogbo. Tí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà Ọlọ́run á dùn sí wa nítorí pé a fẹ́ràn orúkọ rẹ̀.

Ní báyìí, jẹ́ ká jọ ka ẹsẹ Bíbélì bíi mélòó kan sí i tó fi hàn bí orúkọ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó: Aísáyà 12:4, 5; Mátíù 6:9; Jòhánù 17:6; àti Róòmù 10:13.