Ọ̀RẸ́ wa ni àwọn tó máa ń wù wá láti bá sọ̀rọ̀ àti láti bá ṣeré. Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dára. Ta ni o rò pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa tó dára jù lọ?— Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run ni.

Ǹjẹ́ a lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ní tòótọ́?— Ó dára, Bíbélì sọ pé Ábúráhámù, ọkùnrin kan tó wà láyé àtijọ́, jẹ́ “ọ̀rẹ́ Jèhófà.” (Jákọ́bù 2:23) Ǹjẹ́ o mọ ìdí tó fi jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà?— Bíbélì sọ pé Ábúráhámù ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Kódà nígbà tí ohun tí Ọlọ́run sọ pé kí ó ṣe nira, ó ṣègbọràn. Nítorí náà, kí á tó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó ń fẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù ti ṣe àti gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́ Ńlá náà ti máa ń ṣe nígbà gbogbo.—Jẹ́nẹ́sísì 22:1-14; Jòhánù 8:28, 29; Hébérù 11:8, 17-19.

Kí nìdí tí Ábúráhámù fi jẹ́ “ọ̀rẹ́ Jèhófà”?

 Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.” (Jòhánù 15:14) Níwọ̀n bí gbogbo ohun tí Jésù sọ fún àwọn èèyàn ti wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ohun tí Jésù ń sọ yìí ni pé àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ òun ni àwọn tó bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló fẹ́ràn Ọlọ́run.

Lára àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún Olùkọ́ Ńlá náà ni àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, tí o rí àwòrán wọn lójú ewé 75 nínú ìwé yìí. Wọ́n máa ń bá a rìnrìn àjò kiri, wọ́n sì ń bá a ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni Jésù máa ń wà jù lọ. Wọ́n jọ máa ń jẹun pọ̀. Wọ́n jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Wọ́n sì máa ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn pọ̀. Ṣùgbọ́n Jésù ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mìíràn. Ó máa ń wà pẹ̀lú wọn, wọ́n sì jọ máa ń ṣe fàájì.

Ìdílé kan tí Jésù fẹ́ràn láti máa lọ sọ́dọ̀ wọn ń gbé ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Bẹ́tánì, nítòsí ìlú Jerúsálẹ́mù. Ǹjẹ́ o rántí  wọn?— Àwọn ni Màríà àti Màtá àti Lásárù arákùnrin wọn. Jésù pe Lásárù ní ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jòhánù 11:1, 5, 11) Ìdí tí Jésù fi fẹ́ràn ìdílé yìí tó sì gbádùn wíwà pẹ̀lú wọn ni pé wọ́n fẹ́ràn Jèhófà, wọ́n sì ń sìn ín.

Kí nìdí tí Jésù fi sábà máa ń dúró lọ́dọ̀ ìdílé yìí tí ó bá ń lọ sí Jerúsálẹ́mù? Ǹjẹ́ o mọ orúkọ wọn?

Èyí ò túmọ̀ sí pé Jésù kò fi inú rere hàn sí àwọn tí kò sin Ọlọ́run o. Ó fi inú rere hàn sí wọn. Ó tiẹ̀ lọ sí ilé wọn, ó sì bá wọn jẹun pọ̀. Èyí mú kí àwọn kan sọ pé Jésù jẹ́ “ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Mátíù 11:19) Àmọ́ ṣá, kì í ṣe nítorí pé Jésù fẹ́ràn ìwà tí àwọn èèyàn wọ̀nyí ń hù ló ṣe ń lọ sílé wọn o. Torí kí ó lè bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà ló ṣe máa ń lọ sílé wọn. Ó gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n yí padà kúrò nínú ìwà burúkú wọn, kí wọ́n máa sin Ọlọ́run.

Kí nìdí tí Sákéù fi gun igi yìí?

Èyí ṣẹlẹ̀ ní ìlú Jẹ́ríkò lọ́jọ́ kan. Ńṣe ni Jésù kàn ń gba ibẹ̀ kọjá lọ sí Jerúsálẹ́mù. Àwọn èèyàn wá pọ̀ lẹ́yìn rẹ̀, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sákéù sì wà láàárín ọ̀pọ̀ èrò náà. Òun náà fẹ́ wo Jésù. Ṣùgbọ́n èèyàn kúkúrú ni Sákéù, kò sì lè rí Jésù nítorí pé àwọn èrò dí i lójú. Nítorí náà, ó sáré lọ síwájú, ó lọ gun igi kan tó wà lẹ́bàá ọ̀nà kí ó lè rí Jésù dáadáa nígbà tó bá ń kọjá.

Nígbà tí Jésù dé ìdí igi yẹn, ó wòkè, ó sọ pé: ‘Ṣe  wéré, kí o sọ̀ kalẹ̀, nítorí pé lónìí èmi yóò wá sí ilé rẹ.’ Ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni Sákéù, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan burúkú rí. Kí wá nìdí tí Jésù fi fẹ́ lọ sí ilé irú èèyàn bẹ́ẹ̀?—

Kì í ṣe nítorí pé Jésù fẹ́ràn ìwà ọkùnrin náà ló ṣe lọ. Ó lọ síbẹ̀ láti lọ sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún Sákéù ni. Ó rí gbogbo bí ọkùnrin náà ṣe sapá tó láti rí òun. Nítorí náà ó mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí Sákéù fẹ́ láti feti sílẹ̀. Àkókò tó dára nìyí láti bá Sákéù sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń fẹ́ kí èèyàn máa gbé ìgbésí ayé.

Kí nìdí tí Jésù fi wá sílé Sákéù, kí sì ni Sákéù ṣèlérí pé òun yóò ṣe?

Kí ni a sì wá rí tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí?— Sákéù fẹ́ràn ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ni. Ó kábàámọ̀ ìwà ìrẹ́jẹ tó ti hù sí àwọn èèyàn, ó sì ṣe ìlérí pé òun yóò dá owó tí òun ti gbà lọ́nà àìtọ́ padà. Ó sì wá di ọmọlẹ́yìn Jésù. Ìgbà yìí ni Sákéù àti Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ tó wá di ọ̀rẹ́.—Lúùkù 19:1-10.

Tí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Olùkọ́ Ńlá náà, ǹjẹ́ a óò gbìyànjú láti lọ sí ilé àwọn èèyàn tí kì í ṣe ọ̀rẹ́ wa?— Bẹ́ẹ̀ ni o. Ṣùgbọ́n kì í ṣe torí pé a fẹ́ràn irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé la ó ṣe lọ síbẹ̀ o. A ò sì ní bá wọn ṣe ohun tí kò dára. A óò lọ sílé wọn láti lọ sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn ni.

 Àmọ́ àwọn ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ ni àwọn ẹni tí ó wù wá dénúdénú láti máa bá ṣeré. Kí wọ́n tó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tó tọ́ fún wa láti ní, wọ́n ní láti jẹ́ irú ọ̀rẹ́ tí Ọlọ́run ń fẹ́. Òmíràn lára wọn lè má tiẹ̀ mọ Jèhófà rárá. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá fẹ́ mọ̀ nípa Jèhófà, a lè kọ́ wọn. Tí wọ́n bá ti wá dẹni tó fẹ́ràn Jèhófà bíi tiwa, àwa àti àwọn á wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.

Ọ̀nà mìíràn tún wà tí a fi lè mọ̀ bóyá ẹnì kan lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dára. Kíyè sí àwọn nǹkan tó máa ń ṣe. Ṣé ó máa ń ṣe àwọn nǹkan tí kò dára sí àwọn ẹlòmíràn tí yóò sì máa fi ọ̀rọ̀ náà rẹ́rìn-ín? Èyíinì kò dára, àbí?— Ṣé ó sábà máa ń wọ ìjàngbọ̀n nígbà gbogbo? A ò ní fẹ́ bá a wọ ìjàngbọ̀n, àbí?— Tàbí, ó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dára, kí ó sì máa rò pé òun gbọ́n féfé, nítorí pé wọn ò rí òun mú? Bí wọn ò bá tiẹ̀ rí ẹni náà mú, Ọlọ́run rí ohun tó ń ṣe, àbí kò rí i?— Ṣé o rò pé àwọn tó bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ẹni tó dára láti bá ṣe ọ̀rẹ́?—

O ò ṣe ṣí Bíbélì rẹ? Jẹ́ ká wo ohun tó sọ nípa bí àwọn tí à ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé wa. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ni Kọ́ríńtì kìíní ori kẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], ẹsẹ kẹtàlélọ́gbọ̀n [33]. Ṣé o ti rí i?— Ó kà báyìí pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” Èyí túmọ̀ sí pé bí a bá ń bá àwọn èèyàn búburú rìn, a lè di èèyàn búburú. Ó sì dájú pẹ̀lú pé bí a bá ń bá àwọn èèyàn rere kẹ́gbẹ́, wọn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti di oníwà rere.

Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé láé pé Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wa ni Jèhófà. A ò ní fẹ́ kí ọ̀rẹ́ àwa àti òun bà jẹ́, àbí?— Nítorí náà, a ní láti kíyè sára pé kìkì àwọn tí ó bá fẹ́ràn Ọlọ́run ni à ń bá ṣe ọ̀rẹ́.

A fi bí ó ti ṣe pàtàkì láti máa bá àwọn tó tọ́ kẹ́gbẹ́ hàn nínú Sáàmù 119:115; Òwe 13:20; 2 Tímótì 2:22; àti 1 Jòhánù 2:15.