Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

 ORÍ 22

Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́

Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́

KÁ NÍ ọmọdébìnrin kan sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Gbàrà tá a bá ti jáde ní ilé ìwé ni mò ń bọ̀ nílé.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde ilé ìwé, ó wá dúró ó ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣeré. Ìgbà tó wá dé ilé, ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Olùkọ́ mi ló rán mi ní iṣẹ́ lẹ́yìn tí a jáde ní ilé ìwé.” Ṣé ó dára kí ó sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀?—

Kí ni ọmọkùnrin yìí ṣe tí kò dáa?

Tàbí kí ọmọdékùnrin kan sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Rárá, mi ò gbá bọ́ọ̀lù nínú ilé o.” Kó sì wá jẹ́ pé lóòótọ́ ló gbá bọ́ọ̀lù nínú ilé. Ṣé yóò dára kí ó sọ pé òun ò gbá bọ́ọ̀lù níbẹ̀?—

Olùkọ́ Ńlá náà fi ohun tó tọ́ láti ṣe hàn wá. Ó sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ kí Bẹ́ẹ̀ ni yín sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, kí Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́; nítorí ohun tí ó bá ti yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.’ (Mátíù 5:37) Kí ni Jésù ń sọ pé kí á ṣe yìí?— Jésù sọ pé kí á máa ṣe ohun tí a bá sọ.

Ìtàn kan wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì kí á máa sọ òtítọ́. Ó jẹ́ ìtàn àwọn èèyàn méjì tó sọ pé àwọn jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Jẹ́ kí á wo ohun tó ṣẹlẹ̀.

 Ní nǹkan bí oṣù kan ó lé díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù kú, ọ̀pọ̀ èèyàn láti àwọn ibi tó jìnnà réré wá sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe àjọ̀dún pàtàkì kan tí àwọn Júù ń pè ní Pẹ́ńtíkọ́sì. Àpọ́sítélì Pétérù sọ àsọyé dáadáa kan, ó ń sọ̀rọ̀ fún àwọn èèyàn nípa Jésù, ẹni tí Jèhófà jí dìde kúrò nínú òkú. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó wá sí Jerúsálẹ́mù yìí gbọ́ nípa Jésù. Wọ́n wá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Jésù. Nítorí náà, kí ni wọ́n ṣe?

Wọ́n dúró pẹ́ ní Jerúsálẹ́mù ju bí wọ́n ṣe rò tẹ́lẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tó pẹ́ díẹ̀, owó tán lọ́wọ́ àwọn kan nínú wọn, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè rí owó ra oúnjẹ. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù fẹ́ ran àwọn àlejò wọ̀nyí lọ́wọ́. Nítorí náà ọ̀pọ̀ lára wọn ta àwọn ohun tí wọ́n ní wọ́n sì mú owó rẹ̀ wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì Jésù. Àwọn àpọ́sítélì wá mú owó náà fún àwọn tí owó wọn ti tán yìí.

Ananíà àti Sáfírà aya rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ara ọmọ ìjọ Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ta pápá tí wọ́n ní. Kò sẹ́ni tó sọ pé kí wọ́n tà á o. Fúnra wọn ni wọ́n ronú rẹ̀ tí wọ́n sì lọ tà á. Ṣùgbọ́n kì í ṣe torí pé wọ́n fẹ́ràn àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀  di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣe ni Ananíà àti Sáfírà fẹ́ kí àwọn èèyàn máa rò pé àwọn jẹ́ èèyàn dáadáa gan-an. Nítorí náà, wọ́n jọ dì í pé àwọn yóò sọ pé gbogbo owó ilẹ̀ yẹn ni àwọn kó wá láti fi ran àwọn yòókù lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, apá kan lára owó yẹn ni wọ́n fẹ́ kó sílẹ̀ o. Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ pé gbogbo owó yẹn ni àwọn kó wá. Ṣé o rò pé ìyẹn dára?—

Lọ́rọ̀ kan ṣá, Ananíà wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì. Ó kó owó yẹn fún wọn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo owó náà ni ó kó wá. Nítorí náà, Ọlọ́run jẹ́ kí àpọ́sítélì Pétérù mọ̀ pé Ananíà ò sòótọ́.

Irọ́ wo ni Ananíà ń pa fún Pétérù?

Àpọ́sítélì Pétérù wá sọ pé: ‘Ananíà, kí ló dé tí o fi jẹ́ kí Sátánì tì ọ́ láti purọ́? Ìwọ lo sáà ni pápá náà. Kò sẹ́ni tó sọ pé kí o tà á. Lẹ́yìn tí o sì ta pápá náà tán, ohun tó wù ọ́ lo lè fi owó náà ṣe. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí o fi ṣe bí ẹni pé gbogbo owó náà ni o kó wá nígbà tó jẹ́ pé apá kan lára rẹ̀ lo mú wá? Àwa nìkan kọ́ ni o pa irọ́ yìí fún o, o tún parọ́ fún Ọlọ́run pẹ̀lú.’

Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá nìyẹn. Irọ́ ni Ananíà pa! Ohun tó sọ pé òun ṣe kọ́ ló ṣe. Ó kàn ṣe bí ẹni pé òun ṣe é ni. Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fún wa. Ó sọ pé: ‘Bí Ananíà ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù yìí, ó ṣubú  lulẹ̀ ó sì kú.’ Ọlọ́run fi ikú pa Ananíà! Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé òkú rẹ̀ wọ́n lọ sin ín.

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ananíà torí pé ó purọ́?

Ní nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta lẹ́yìn náà, Sáfírà wọlé wá. Kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkọ rẹ̀. Nítorí náà Pétérù bi í pé: ‘Ṣé iye tí ẹ̀yin méjèèjì ta pápá náà ni ẹ kó fún wa?’

Sáfírà dáhùn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, iye yẹn gan-an ni a tà á.’ Ṣùgbọ́n irọ́ ni! Wọ́n ti yọ lára owó tí wọ́n ta pápá náà pa mọ́ fún ara wọn. Nítorí náà, Ọlọ́run fi ikú pa Sáfírà pẹ̀lú.—Ìṣe 5:1-11.

Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ananíà àti Sáfírà?— Ó kọ́ wa pé Ọlọ́run kò fẹ́ràn àwọn òpùrọ́. Ó fẹ́ kí á máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé pípa irọ́ kò burú. Ǹjẹ́ o rò pé ohun tí àwọn ẹni yẹn sọ tọ̀nà?— Ǹjẹ́ o mọ̀ pé irọ́ kan tí ẹnì kan pa ló fa àìsàn, ìrora, àti ikú tó wà nínú ayé lónìí?—

Ta ni Jésù sọ pé ó kọ́kọ́ pa irọ́, kí ló sì yọrí sí?

Rántí pé Èṣù purọ́ fún Éfà obìnrin àkọ́kọ́. Ó sọ fún un pé kò ní kú tó bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tó sì jẹ èso tí Ọlọ́run sọ pé kò gbọ́dọ̀ jẹ. Éfà gba ohun tí Èṣù sọ gbọ́, ó sì jẹ èso yẹn. Éfà mú kí Ádámù jẹ èso náà pẹ̀lú. Bí wọ́n ṣe jẹ èso yẹn wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀, gbogbo ọmọ tí wọ́n yóò bí yóò sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ Ádámù sì ti jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, gbogbo wọn ló ń jìyà tí wọ́n sì ń kú. Kí ló fa gbogbo ìyọnu yẹn?— Irọ́ kan ṣoṣo ló fà á.

Abájọ tí Jésù fi sọ pé Èṣù jẹ́ ‘òpùrọ́ àti baba irọ́’! Òun ni ẹni tó kọ́kọ́ pa irọ́. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá purọ́, ohun tí Èṣù kọ́kọ́ ṣe ni òun náà ń ṣe. A ní láti ronú nípa èyí nígbàkigbà tí ohunkóhun bá fẹ́ mú ká purọ́.—Jòhánù 8:44.

 Ìgbà wo ló lè ṣe ọ́ bíi pé kó o purọ́?— Ǹjẹ́ kì í ṣe ìgbà tí o bá ṣe ohun kan tí kò tọ́?— O lè fọ́ ohun kan láìjẹ́ pé o mọ̀ọ́mọ̀ fọ́ ọ. Bí wọ́n bá bi ọ́ nípa ẹni tí ó fọ́ ọ, ǹjẹ́ ó yẹ kí o sọ pé ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin ló fọ́ ọ? Tàbí ó ha yẹ kí o rọra ṣe bí ẹni pé o kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ bí?—

Ìgbà wo ló lè ṣe ọ́ bíi pé kó o purọ́?

Ká sọ pé ó yẹ kí o ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ tán ṣùgbọ́n apá kan rẹ̀ lo lè ṣe ńkọ́? Ǹjẹ́ ó yẹ kí o sọ pé gbogbo rẹ̀ ni o ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò ṣe gbogbo rẹ̀?— Ó yẹ kí á rántí Ananíà àti Sáfírà. Wọn kò sòótọ́ délẹ̀. Ọlọ́run sì fi ikú pa wọ́n láti fi hàn pé ohun tí wọ́n ṣe burú gan-an.

Nítorí náà, ohunkóhun tó wù kí a ṣe, tí a bá purọ́ nípa rẹ̀, ńṣe la tún mú kí ọ̀ràn yẹn burú sí i. A kò sì gbọ́dọ̀ sọ òótọ́ díẹ̀ kí á wá dákẹ́ ká má sọ èyí tó kù mọ́. Bíbélì sọ pé: “Sọ òtítọ́.” Ó tún sọ pé: “Ẹ má ṣe máa purọ́ fún ara yín.” Jèhófà máa ń sọ òtítọ́ nígbà gbogbo, ó sì retí pé kí àwa náà máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo.—Éfésù 4:25; Kólósè 3:9.

A gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà nínú Ẹ́kísódù 20:16; Òwe 6:16-19; 12:19; 14:5; 16:6; àti Hébérù 4:13.