Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 10

Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ

Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ

ǸJẸ́ o rántí ohun tó mú kí ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run di Sátánì Èṣù?— Ó jẹ́ nítorí pé ó ṣe ojú kòkòrò, ó fẹ́ kí àwọn èèyàn máa sin òun, ó wá di ọ̀tá Ọlọ́run. Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì kankan di ọmọ ẹ̀yìn Sátánì?— Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì pè wọ́n ní ‘áńgẹ́lì Sátánì,’ tàbí ẹ̀mí èṣù.—Ìṣípayá 12:9.

Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì búburú, tàbí ẹ̀mí èṣù, wọ̀nyí gba Ọlọ́run gbọ́?— Bíbélì sọ pé, ‘Àwọn ẹ̀mí èṣù gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ń bẹ.’ (Jákọ́bù 2:19) Ṣùgbọ́n ní báyìí, ẹ̀rù ń bà wọ́n. Ohun tó fà á ni pé wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run máa fìyà jẹ àwọn nítorí àwọn nǹkan burúkú tí wọ́n ti ṣe. Kí ni àwọn nǹkan búburú yẹn?—

Bíbélì sọ pé àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí fi ibi tí Ọlọ́run dá wọn sí ní ọ̀run sílẹ̀, wọ́n wá sí ayé, wọ́n sì yí padà di ènìyàn wọ́n ń gbé ní ayé. Ohun tó mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ máa bá àwọn obìnrin tó lẹ́wà nínú ayé lò pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2; Júúdà 6) Kí lo mọ̀ tó ń jẹ́ ìbálòpọ̀?—

 Ìbálòpọ̀ ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan bá sùn tira wọn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kan. Lẹ́yìn èyí ni ọmọ á wá máa dàgbà nínú ikùn ìyá rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó lòdì fún àwọn áńgẹ́lì láti máa ní ìbálòpọ̀. Kìkì ọkùnrin àti obìnrin tó bá ti di tọkọtìyàwó nìkan ni Ọlọ́run ń fẹ́ kí wọ́n máa bára wọn lò pọ̀. Lọ́nà bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá bí ọmọ, ọkọ àti ìyàwó á lè pawọ́ pọ̀ tọ́jú ọmọ yẹn.

Kí ni nǹkan burúkú tí àwọn áńgẹ́lì yìí ṣe?

Nígbà tí àwọn áńgẹ́lì para dà di èèyàn tí wọ́n sì ń bá àwọn obìnrin lò pọ̀ ní ayé, àwọn ọmọ tí wọ́n bí dàgbà di òmìrán. Èèyàn burúkú ni wọ́n o, wọ́n sì máa ń ṣèkà gan-an. Nítorí náà, Ọlọ́run mú ìkún omi ńlá kan wá, ó sì fi pa àwọn òmìrán náà àti gbogbo èèyàn burúkú yòókù run. Ṣùgbọ́n ó ní kí Nóà kan áàkì, tàbí ọkọ̀ ojú omi ńlá kan láti fi gba àwọn èèyàn díẹ̀ tó ń hùwà rere là. Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún Omi yẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 6:3, 4, 13, 14; Lúùkù 17:26, 27.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn áńgẹ́lì burúkú yẹn nígbà tí Ìkún Omi náà dé?— Wọ́n bọ́ ara èèyàn tí wọ́n ń lò sílẹ̀, wọ́n sì padà sí ọ̀run. Ṣùgbọ́n wọn kò tún lè di áńgẹ́lì Ọlọ́run mọ́, nítorí náà  wọ́n di áńgẹ́lì Sátánì tàbí ẹ̀mí èṣù. Kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí àwọn òmìrán tó jẹ́ ọmọ wọn?— Ìkún Omi yẹn pa wọ́n. Ìkún Omi yẹn náà ló sì pa àwọn èèyàn yòókù tó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.

Kí ló fà á tí wàhálà fi pọ̀ láyé nísinsìnyí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

Látìgbà Ìkún Omi yìí, Ọlọ́run ò jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù lè para dà di èèyàn mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè fojú rí àwọn ẹ̀mí èṣù yìí, wọ́n ṣì ń dọ́gbọ́n mú kí àwọn èèyàn ṣe àwọn nǹkan tó burú gan-an. Wọ́n túbọ̀ ń dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ láyé ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ohun tó sì fà á ni pé wọ́n ti lé wọn kúrò ní ọ̀run wá sí ayé.

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí a ò fi lè rí àwọn ẹ̀mí èṣù?— Ó jẹ́ torí pé ẹ̀dá ẹ̀mí ni wọ́n, wọn ò ní ara bíi tiwa. Ṣùgbọ́n a mọ̀ dájú pé wọ́n wà. Bíbélì sọ pé Sátánì ‘ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ní gbogbo ayé.’ Àwọn ẹ̀mí èṣù ló sì ń ràn án lọ́wọ́ láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà.—Ìṣípayá 12:9, 12.

Ǹjẹ́ Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù lè ṣi àwa náà lọ́nà tàbí kí wọ́n tàn wá jẹ pẹ̀lú?— Bẹ́ẹ̀ ni o, wọ́n lè tàn wá jẹ tá ò bá ṣọ́ra. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ẹ̀rù wọn máa bà wá o. Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé: ‘Èṣù ò lágbára lórí mi.’ Bí a bá sún mọ́ Ọlọ́run, yóò dáàbò bò wá lọ́wọ́ Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù.—Jòhánù 14:30.

Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ àwọn ohun burúkú tí àwọn ẹ̀mí èṣù yóò máa sapá láti mú ká ṣe. Nítorí náà ronú nípa rẹ̀. Kí làwọn ohun burúkú tí àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe nígbà tí wọ́n wá sí ilẹ̀ ayé?— Ṣáájú Ìkún Omi, ńṣe ni wọ́n ń bá àwọn obìnrin lò pọ̀, ìyẹn sì jẹ́ ohun tó lòdì fún àwọn áńgẹ́lì láti ṣe. Láyé òde òní, inú àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń dùn tí àwọn èèyàn bá ń ṣàìgbọràn sí òfin Ọlọ́run nípa ìbálòpọ̀. Jẹ́ kí n bi ọ́, àwọn ta ló yẹ kò máa bára wọn lò pọ̀?— O gbà á, kìkì àwọn tó ti ṣègbéyàwó ni o.

Lóde òní, àwọn ọmọdé ọkùnrin àti obìnrin máa ń bára wọn lò pọ̀, ó sì lòdì pé kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ló dá ẹ̀ya ìbímọ ọkùnrin àti ti obìnrin. Jèhófà dá ẹ̀ya ara méjèèjì yìí nítorí nǹkan pàtàkì kan, tó jẹ́ pé kìkì àwọn tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló  gbọ́dọ̀ ṣe é. Inú àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń dùn tí àwọn èèyàn bá ń ṣe ohun tí Jèhófà sọ pé a kò gbọ́dọ̀ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń dùn mọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù tí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin bá ń fi ẹ̀yà ìbímọ ara wọn ṣeré. Kò sì yẹ kí á mú inú àwọn ẹ̀mí èṣù dùn, àbí ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?—

Nǹkan mìíràn tún wà tí àwọn ẹ̀mí èṣù fẹ́ràn ṣùgbọ́n tí Jèhófà kórìíra. Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n?— Ìwà ipá ni o. (Sáàmù 11:5) Ìwà ipá ni pé kéèyàn máa ṣìkà, kí ó pa ọmọnìkejì rẹ̀ lára. Rántí pé ohun tí àwọn òmìrán tó jẹ́ ọmọ àwọn ẹ̀mí èṣù ṣe nìyẹn.

Àwọn ẹ̀mí èṣù tún fẹ́ràn kí wọ́n máa dẹ́rù ba àwọn èèyàn. Nígbà mìíràn wọ́n máa ń ṣe bíi pé wọ́n jẹ́ ẹni tó ti kú. Wọ́n tiẹ̀ lè ṣe ohùn wọn bí ohùn ẹnì kan tó ti kú. Ọ̀nà yìí làwọn ẹ̀mí èṣù fi ń tan ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ tí wọ́n fi máa ń rò pé àwọn òkú ń rìn káàkiri, àti pé wọ́n lè bá ẹni tó wà láàyè sọ̀rọ̀. Àwọn ẹ̀mí èṣù ló ń mú kí àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àkúdàáyà (òkú tó ń fara hàn káàkiri) wà.

Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí Sátánì àti  àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ má tàn wá jẹ. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: ‘Sátánì máa ń ṣe bíi áńgẹ́lì rere lójú àwọn èèyàn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì máa ń ṣe bákan náà.’ (2 Kọ́ríńtì 11:14, 15) Ṣùgbọ́n ká sòótọ́, àwọn ẹ̀mí èṣù burú o. Jẹ́ ká wo bí wọ́n ṣe lè dọ́gbọ́n sọ wá dà bí wọ́n ṣe dà.

Ibo làwọn èèyàn ti ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń hùwà ipá, àti ìbálòpọ̀ tó lòdì, àti lílo ẹ̀mí èṣù, tí wọ́n sì ti ń gbọ́ nípa òkú tó ń sọ̀rọ̀?— Ǹjẹ́ kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bá ń wo àwọn eré kan lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí fídíò, tàbí látinú kíkó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ ní ilé ìwé tàbí láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ burúkú ni? Ṣé nǹkan wọ̀nyí ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ni tàbí ó ń múni túbọ̀ sún mọ́ Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù? Kí lèrò rẹ?—

Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí a bá ń wo ìwà ipá?

Ta lo rò pé ó ń fẹ́ ká máa fetí sí àwọn nǹkan tó burú wọ̀nyẹn ká sì máa wò wọ́n?— Dájúdájú, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù ni. Nítorí náà, kí ló yẹ kí ìwọ àti èmi máa ṣe?— Nǹkan dáadáa tó lè ṣe wá láǹfààní tí yóò sì mú ká lè máa sin Jèhófà ló yẹ ká máa kà, ká máa fetí sí, ká sì máa wò. Ǹjẹ́ o lè sọ díẹ̀ nínú àwọn nǹkan dáadáa wọ̀nyí tí a lè máa ṣe?—

Kí ló dára ká máa ṣe?

Bí a bá ti ń ṣe nǹkan rere, kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Jésù lágbára jù wọ́n lọ, wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, àwọn ẹ̀mí èṣù kígbe lóhùn rara bí wọ́n ṣe rí Jésù, wọ́n ní: “Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni?” (Máàkù 1:24) Ǹjẹ́ inú wa kò ní dùn tí àkókò bá tó tí Jésù yóò pa Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù run?— Kó tó di ìgbà náà, kí ó dá wa lójú pé Jésù yóò dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù bí a bá fà sún mọ́ òun àti Baba rẹ̀ tí ń bẹ ní ọ̀run.

Jẹ́ kí a kà nípa ohun tó yẹ ká ṣe nínú 1 Pétérù 5:8, 9 àti Jákọ́bù 4:7, 8.