Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

 ORÍ 24

Má Ṣe Di Olè!

Má Ṣe Di Olè!

ǸJẸ́ ẹnì kan tíì jí nǹkan rẹ rí?— Báwo ni ọ̀ràn náà ti rí lára rẹ?— Ẹni yòówù kí ó jí i, olè ni, kò sì sí ẹni tó fẹ́ràn olè. Báwo ni o rò pé ẹnì kan ṣe ń di olè? Ṣé wọ́n bí ìwà olè mọ́ ọn ni?—

A ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ọ nínú ẹ̀kọ́ tá a kọ́ tán yìí ni pé a bí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn. Nítorí náà, gbogbo wa jẹ́ aláìpé. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí a bí ní olè. Ó lè jẹ́ inú ìdílé rere ni olè yẹn ti wá. Àwọn òbí rẹ̀, àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ̀ lè jẹ́ olóòótọ́ èèyàn. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan ṣe fẹ́ràn àwọn nǹkan bí owó àti ohun tí owó lè rà lè mú kí ẹni náà di olè.

Ta ni ìwọ rò pé ó jẹ́ olè àkọ́kọ́?— Jẹ́ ká ronú nípa ọ̀rọ̀ náà. Olùkọ́ Ńlá mọ ẹni yẹn nígbà tí ó wà ní ọ̀run. Olè yẹn jẹ́ áńgẹ́lì tẹ́lẹ̀. Àmọ́ níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá àwọn áńgẹ́lì ní pípé, báwo ni áńgẹ́lì yẹn ṣe di olè?— Ó dára, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ́ ọ ní Orí 8 nínú ìwé yìí, ńṣe ni áńgẹ́lì náà ń fẹ́ ohun kan tí kì í ṣe tirẹ̀. Ǹjẹ́ o rántí ohun náà?—

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, áńgẹ́lì yẹn ń fẹ́ kí wọ́n máa sin òun. Kò ní ẹ̀tọ́ kankan sí ìjọsìn wọn o. Ọlọ́run ni ó ni ìjọsìn wọn. Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì yìí jí i! Bí áńgẹ́lì yìí ṣe mú kí Ádámù àti Éfà máa sin òun, ó di olè. Ó sì di Sátánì Èṣù.

Kí ló ń mú kí ẹnì kan di olè?— Tí èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ ni. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí lè lágbára débi pé ẹni tó jẹ́ èèyàn rere lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun búburú. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó di olè kì í ṣíwọ́ olè jíjà mọ́ láti padà máa ṣe ohun tó dára. Ọ̀kan lára  àwọn àpọ́sítélì Jésù jẹ́ irú èèyàn bẹ́ẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Júdásì Ísíkáríótù.

Júdásì mọ̀ pé ó lòdì láti jalè nítorí pé láti ìgbà tó ti jẹ́ ọmọdé ni wọ́n ti ń kọ́ ọ ní Òfin Ọlọ́run. Ó mọ̀ pé Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ọ̀run rí, tí ó sì sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.” (Ẹ́kísódù 20:15) Nígbà tí Júdásì dàgbà, ó pàdé Olùkọ́ Ńlá náà, ó sì di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Jésù tiẹ̀ yan Júdásì láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá pàápàá.

Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ máa ń rin ìrìn àjò pa pọ̀. Wọ́n jọ máa ń jẹun pa pọ̀. Wọ́n máa ń kó owó tí gbogbo wọ́n ní pa pọ̀ sínú àpótí kan. Jésù gbé àpótí yẹn fún Júdásì pé kí ó máa tọ́jú rẹ̀. Àmọ́ ṣá, Júdásì kọ́ ló ni owó náà. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ ohun tí Júdásì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀?—

Kí ló fà á tí Júdásì fi jalè?

Júdásì bẹ̀rẹ̀ sí mú owó nínú àpótí náà nígbà tí kò yẹ kí ó mú un. Ó ń mú un nígbà tí àwọn yòókù kò bá wo ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó tiẹ̀ tún wá ọ̀nà láti rí owó púpọ̀ sí i. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa owó nígbà gbogbo. Jẹ́ kí á wo ohun tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí sún un láti ṣe ní ọjọ́ mélòó kan ṣáájú kí wọ́n tó pa Olùkọ́ Ńlá náà.

Màríà arábìnrin Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù mú òróró iyebíye ó sì dà á sí ẹsẹ̀ Jésù. Ṣùgbọ́n Júdásì bẹ̀rẹ̀ sí ráhùn. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á?— Ó sọ pé ó yẹ kí wọ́n tà á kí wọ́n sì fi owó rẹ̀ fún àwọn tálákà. Ṣùgbọ́n ohun tó ń fẹ́ ni pé kí owó pọ̀ nínú àpótí tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ kí ó lè jí i.—Jòhánù 12:1-6.

Jésù sọ fún Júdásì pé kí ó má ṣe yọ Màríà lẹ́nu, nítorí pé ohun rere ló ń ṣe. Inú Júdásì kò dùn nígbà tí Jésù sọ bẹ́ẹ̀ fún un, nítorí náà ó lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà tí ó jẹ́ ọ̀tá Jésù. Àwọn wọ̀nyí ti fẹ́ wá mú Jésù tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fẹ́ mú un ní òru kí àwọn èèyàn má lè rí wọn.

 Júdásì sọ fún àwọn àlùfáà yìí pé: ‘Èmi yóò kọ́ yín ní ọ̀nà tí ẹ ó fi rí Jésù mú bí ẹ bá fún mi ní owó. Èló ni ẹ óò fún mi?’

Àwọn àlùfáà dáhùn pé: ‘A óò fún ọ ní ọgbọ̀n ẹyọ owó fàdákà.’—Mátíù 26:14-16.

Júdásì gba owó náà. Ṣe ni ó dà bíi pé ó ta Olùkọ́ Ńlá náà fún àwọn ọkùnrin yẹn! Ǹjẹ́ o ronú pé ẹnikẹ́ni máa ṣe irú ohun burúkú bẹ́ẹ̀?— Àmọ́, irú ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà tí ẹnì kan bá ti di olè tó sì ń jí owó. Onítọ̀hún máa ń fẹ́ràn owó ju bí ó ṣe fẹ́ràn àwọn èèyàn yòókù tàbí Ọlọ́run pàápàá lọ.

Bóyá ìwọ yóò sọ pé, ‘Èmi ò ní fẹ́ràn ohunkóhun ju bí mo ṣe fẹ́ràn Jèhófà Ọlọ́run lọ láéláé.’ Ohun tí o sọ yẹn dára. Nígbà tí Jésù yan Júdásì sí ara àwọn àpọ́sítélì, ó ṣeé ṣe kí Júdásì náà rò pé òun ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn èèyàn yòókù tí ó di olè lè rò pé àwọn ò lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára wọn.

Èrò burúkú wo ni Ákáánì àti Dáfídì ń rò?

Ọ̀kan lára wọn ni Ákáánì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà kan rí, tí ó gbé ní ayé tipẹ́tipẹ́ kí wọ́n tó bí Olùkọ́ Ńlá náà. Ákáánì rí ẹ̀wù dáradára kan, ègé góòlù kan, àti ẹyọ owó fàdákà mélòó kan. Òun kọ́ ló ni wọ́n o. Bíbélì sọ pé Jèhófà ló ni wọ́n nítorí pé  ọwọ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run ni wọ́n ti gbà wọ́n. Ṣùgbọ́n ohun wọ̀nyẹn wu Ákáánì gan-an débi pé ó jí wọn.—Jóṣúà 6:19; 7:11, 20-22.

Àpẹẹrẹ mìíràn nìyí. Láyé àtijọ́, Jèhófà fi Dáfídì jẹ ọba lórí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì. Lọ́jọ́ kan, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí wo Bátí-ṣébà tó jẹ́ arẹwà obìnrin. Ó ń wo Bátí-ṣébà títí, ó sì ń ronú nípa bó ṣe máa mú un wá sí ilé rẹ̀ kí ó sọ ọ́ di ìyàwó rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyàwó Ùráyà ni Bátí-ṣébà. Kí ni ó yẹ kí Dáfídì ṣe?—

Ọ̀nà wo ni Ábúsálómù gbà jẹ́ olè?

Ó yẹ kí Dáfídì mú ọkàn kúrò, kí ó má ronú mọ́ nípa bí ó ṣe máa sọ Bátí-ṣébà di tirẹ̀. Ṣùgbọ́n kò mú ọkàn kúrò. Nítorí náà Dáfídì mú un lọ sí ilé. Lẹ́yìn náà Dáfídì mú kí wọ́n pa Ùráyà. Kí ló fà á tí Dáfídì fi ṣe àwọn nǹkan búburú yìí?— Nítorí  pé obìnrin tó jẹ́ ti ẹlòmíràn ń wù ú gan-an.—2 Sámúẹ́lì 11:2-27.

Nítorí pé Dáfídì ronú pìwà dà, Jèhófà fi í sílẹ̀ kí ó wà láàyè. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà ló bá Dáfídì láti ìgbà náà lọ. Ábúsálómù ọmọ Dáfídì fẹ́ gba ipò ọba mọ́ bàbá rẹ̀ lọ́wọ́. Nítorí náà, nígbà tí àwọn èèyàn bá wá láti rí Dáfídì, Ábúsálómù yóò fi ọwọ́ kọ́ wọn lọ́rùn, yóò sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu. Bíbélì sọ pé: “Ábúsálómù sì ń jí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ.” Ó mú kí ó wu àwọn èèyàn wọ̀nyẹn láti fi í jẹ ọba dípò Dáfídì.—2 Sámúẹ́lì 15:1-12.

Ǹjẹ́ ohun kan tíì wù ọ́ gan-an rí, bí ó ṣe wu Ákáánì, Dáfídì, àti Ábúsálómù?— Bí ohun náà bá jẹ́ ti ẹlòmíràn, tí o kò bá gba àṣẹ kí o tó mú un, olè lo jà o. Ǹjẹ́ o rántí ohun tí Sátánì ẹni tó kọ́kọ́ jalè ń fẹ́?— Ó fẹ́ kí àwọn èèyàn máa sin òun dípò kí wọ́n sin Ọlọ́run. Nítorí náà, olè ni Sátánì jà nígbà tó mú kí Ádámù àti Éfà ṣe ohun tí òun ń fẹ́.

Tí ẹnì kan bá ní ohun kan, ẹni náà ní ẹ̀tọ́ láti sọ ẹni tí ó lè lò ó. Bí àpẹẹrẹ, o lè lọ bá àwọn ọmọdé yòókù ṣeré nínú ilé wọn. Ṣé yóò dára tí o bá mú lára àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀ kí o sì mú un wá sí ilé rẹ?— Ó tì o, àyàfi tí bàbá tàbí ìyá àwọn ọmọ wọ̀nyẹn bá sọ fún ọ pé o lè mú un. Bí o bá mú ohunkóhun lọ sí ilé láìgba àṣẹ kí o tó mú un, olè lo jà o.

Kí ni ó lè mú kí o fẹ́ jalè?— O lè fẹ́ jalè tí o bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí kì í ṣe tìrẹ. Kódà bí ẹlòmíràn ò bá tiẹ̀ rí ọ nígbà tí o mú un, ta ló rí ọ?— Jèhófà Ọlọ́run ni. Ó sì yẹ kí á rántí pé Ọlọ́run kórìíra olè jíjà. Nítorí náà, tí o bá fẹ́ràn Ọlọ́run tí o sì fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ, èyí kò ní jẹ́ kó o di olè.

Bíbélì mú un ṣe kedere pé ó lòdì láti jalè. Jọ̀wọ́ ka Máàkù 10:17-19; àti Róòmù 13:9; àti Éfésù 4:28.