Kí ni ìṣòro tí ọkùnrin yìí ní?

NÍ ỌJỌ́ kan, ọkùnrin kan lọ bá Jésù. Ó mọ̀ pé Jésù gbọ́n púpọ̀, nítorí náà, ó sọ fún un pé: ‘Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi pé kí ó fún mi lára àwọn nǹkan tí ó ní.’ Ọkùnrin náà rò pé ó yẹ kí díẹ̀ lára àwọn nǹkan yẹn jẹ́ ti òun.

Ká sọ pé ìwọ ni Jésù, kí ni ìwọ ì bá sọ?— Jésù rí i pé ọkùnrin náà ní ìṣòro kan. Ṣùgbọ́n ìṣòro rẹ̀ kì í ṣe pé ó nílò ohun tí arákùnrin rẹ̀ ní. Ìṣòro ọkùnrin náà ni pé kò mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé.

Jẹ́ ká ronú nípa èyí. Kí ló yẹ kí ó ṣe pàtàkì jù lọ lójú wa? Ṣé bí a ó ṣe ní àwọn ohun ìṣeré tuntun, aṣọ tuntun, tàbí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni?— Ó tì o, ohun kan wà tí ó ṣe pàtàkì púpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìyẹn sì ni ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ kọ́ni. Nítorí náà, ó sọ ìtàn kan nípa ọkùnrin kan tó gbàgbé Ọlọ́run. Ṣé wàá fẹ́ gbọ́ ọ?—

Ọlọ́rọ̀ ni ọkùnrin ọ̀hún. Ó ní oko tí ó pọ̀, ó sì ní ọ̀pọ̀ àká tàbí ibi tí wọ́n ń kó irè oko sí. Àwọn ohun tó gbìn sí oko rẹ̀ dàgbà dáadáa. Àwọn àká rẹ̀ kò lè gba gbogbo nǹkan oko rẹ̀ tí ó kórè. Kí ló máa wá ṣe? Ó sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Èmi yóò wó àwọn àká mi, èmi yóò sì kọ́ àwọn tí ó tóbi gan-an. Èmi yóò wá kó gbogbo èso oko mi àti gbogbo àwọn ohun rere mi jọ sínú àwọn àká tuntun yìí.’

Ọlọ́rọ̀ yìí rò pé ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe nìyẹn. Ó rò pé òun gbọ́n  dáadáa bí òun ṣe to àwọn nǹkan púpọ̀ pa mọ́. Ó sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Mo ti to ọ̀pọ̀ nǹkan rere pa mọ́. Èmi yóò lo ọ̀pọ̀ ọdún kí n tó jẹ ẹ́ tán. Nítorí náà, mi ò wulẹ̀ ní ṣe wàhálà mọ́. Ohun tó kù ni pé kí n máa jẹ, kí n máa mu, kí n sì máa gbádùn ara mi.’ Ṣùgbọ́n ohun kan wà tí kò tọ́ nínú èrò ọkùnrin yìí. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan náà?— Kìkì ti ara rẹ̀ àti ìgbádùn ara rẹ̀ ló ń rò. Ó gbàgbé Ọlọ́run.

Kí ni ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yìí ń rò lọ́kàn?

Nítorí náà, Ọlọ́run bá ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí. Alẹ́ òní yìí ni ìwọ yóò kú. Ta ni yóò wá ni gbogbo nǹkan tí o ti tò pa mọ́?’ Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yìí á tún lè lo àwọn nǹkan yẹn lẹ́yìn tó bá kú tán?— Ó tì o, yóò di ti ẹlòmíràn. Jésù sọ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ohun ìní jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.’—Lúùkù 12:13-21.

Ìwọ ò fẹ́ dà bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn, àbí?— Olórí ohun tó fi ayé rẹ̀ ṣe ni pé ó ń kó àwọn ohun ìní jọ. Àṣìṣe ló ṣe yẹn. Ó máa ń fẹ́ ní  nǹkan púpọ̀ sí i nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n kò ní “ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló dà bíi ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn. Wọ́n máa ń fẹ́ ní nǹkan púpọ̀ sí i nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n èyí máa ń fa àwọn ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, o ní àwọn ohun ìṣeré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Kí ni àwọn ohun ìṣeré tí o ní? Sọ fún mi.— Tí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ní bọ́ọ̀lù kan tàbí bèbí kan tàbí oríṣi ohun ìṣeré mìíràn tí ìwọ kò ní ńkọ́? Ṣé yóò dára kí o sọ pé dandan ni kí àwọn òbí rẹ ra tìrẹ fún ẹ?—

Àwọn ìgbà kan lè wà tí ohun ìṣeré lè dà bí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an. Ṣùgbọ́n kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn ìgbà díẹ̀?— Yóò bà jẹ́, o kò sì ní fẹ́ ẹ mọ́. Ní tòótọ́, o ní ohun kan tó ṣe pàtàkì ju àwọn ohun ìṣeré lọ. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan náà?—

Kí lo ní tó ṣe pàtàkì ju àwọn ohun ìṣeré lọ?

Ẹ̀mí rẹ ni. Ẹ̀mí rẹ ṣe pàtàkì gan-an, nítorí láìsí ìwàláàyè, kò sí ohun tí o lè ṣe. Ṣùgbọ́n ìwàláàyè rẹ sinmi lórí ṣíṣe ohun tó wu Ọlọ́run, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí á dà bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tí kò gbọ́n yẹn, tó gbàgbé Ọlọ́run.

Kì í ṣe àwọn ọmọdé nìkan ló lè ṣe àwọn nǹkan òmùgọ̀ bíi ti  ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn o. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbàlagbà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn mìíràn lára wọn máa ń fẹ́ ní nǹkan púpọ̀ sí i nígbà gbogbo ju èyí tí wọ́n ní. Wọ́n lè ní oúnjẹ púpọ̀ tó láti jẹ lóòjọ́, aṣọ láti wọ̀, àti ibi tí wọ́n máa gbé. Ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ ní púpọ̀ sí i. Wọ́n ń fẹ́ ní aṣọ púpọ̀. Wọ́n sì ń fẹ́ ní ilé tí ó tóbi sí i. Nǹkan wọ̀nyí sì ń náni lówó. Nítorí náà, wọ́n yóò ṣiṣẹ́-ṣiṣẹ́ láti lè ní owó púpọ̀. Bí wọ́n sì ṣe ń ní owó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń fẹ́ ní owó púpọ̀ sí i.

Àwọn àgbàlagbà mìíràn ń lo àkókò tó pọ̀ gan-an níbi iṣẹ́ kí wọ́n lè ní owó. Fún ìdí yìí, wọn kò rí àyè láti máa wà pẹ̀lú ìdílé wọn. Wọn kò sì rí àyè gbọ́ ti Ọlọ́run. Ǹjẹ́ owó wọn lè mú kí wọ́n wà láàyè?— Rárá o, kò lè mú kí wọ́n wà láàyè. Ṣé wọ́n lè lo owó wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá kú?— Rárá o. Ìdí ni pé òkú kò lè ṣe ohunkóhun rárá.—Oníwàásù 9:5, 10.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ó lòdì láti ní owó?— Ó tì o. Owó la fi ń ra oúnjẹ àti aṣọ. Bíbélì sọ pé owó wà fún ìdáàbòbò. (Oníwàásù 7:12) Ṣùgbọ́n tí a bá fẹ́ràn owó, a máa ní ìṣòro gan-an. A ó dà bí òmùgọ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn, tí ó to ìṣúra pa mọ́ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Tí a bá sọ pé èèyàn ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí ló túmọ̀ sí?— Ó túmọ̀ sí pé kí á fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo tí a bá ń ṣe láyé wa. Àwọn èèyàn kan sọ pé àwọn gbà pé Ọlọ́run wà. Wọ́n rò pé tí àwọn bá kàn ti gbà pé ó wà, ìyẹn nìkan ti tó. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ wọ́n ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run ní ti gidi?— Rárá o, bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó gbàgbé Ọlọ́run yẹn ni wọ́n rí.

Jésù kò gbàgbé Baba rẹ̀ ní ọ̀run rárá. Kò gbìyànjú láti ní owó rẹpẹtẹ. Kò sì ní àwọn ohun ìní púpọ̀. Jésù mọ ohun tó ṣe pàtàkì gidi ní ìgbésí ayé. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà?— Òun ni jíjẹ́ ọlọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Kí ni ọmọdé yìí ń ṣe tó ṣe pàtàkì gan-an?

Sọ fún mi kí n gbọ́, báwo ni a ṣe lè jẹ́ ọlọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?— A lè jẹ́ ọlọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run tí a bá ń ṣe ohun tí ó wù ú. Jésù sọ pé: “Nígbà  gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:29) Inú Ọlọ́run máa ń dùn tí a bá ṣe àwọn nǹkan tí ó ń fẹ́ kí á ṣe. Wàyí o, sọ fún mi, kí ni àwọn nǹkan tí o lè ṣe láti mú inú Ọlọ́run dùn?— Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ka Bíbélì, o lè lọ sí ìpàdé Kristẹni, o lè gbàdúrà sí Ọlọ́run, o sì lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ló ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé.

Nítorí pé Jésù ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, Jèhófà tọ́jú rẹ̀. Ó san èrè fún Jésù pé kí ó máa wà láàyè títí láé. Bí a bá dà bíi Jésù, Jèhófà yóò fẹ́ràn wa yóò sì tọ́jú àwa náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á dà bíi Jésù, kí á má ṣe dà bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó gbàgbé Ọlọ́run yẹn.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan nìyí, tó fi hàn bí a ṣe lè máa fi ojú tí ó tọ́ wo nǹkan ìní ti ara: Òwe 23:4; 28:20; 1 Tímótì 6:6-10; àti Hébérù 13:5.