OHUN tí ìwọ náà lè ti mọ̀ dáadáa ni pé, lóde òní, àwọn èèyàn ń di arúgbó, wọ́n ń ṣàìsàn, wọ́n sì ń kú. Kódà àwọn ọmọdé máa ń kú. Ṣé ó yẹ kí o máa bẹ̀rù ikú tàbí kí o máa bẹ̀rù ẹni tó ti kú?— Ǹjẹ́ o mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá kú?—

Ó dára, kò sí ẹnikẹ́ni tó wà láàyè ní ayé lónìí, tó tíì kú tó tún jí padà tó sì wá sọ bí ikú ṣe jẹ́ fún wa. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù Olùkọ́ Ńlá náà wà ní ayé, ọkùnrin kan wà tí ó kú tó sì padà jí. A lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ó kú, tí a bá ka ìtàn nípa ọkùnrin yìí. Ọ̀rẹ́ Jésù ni ọkùnrin náà, ó sì gbé ní ìlú Bẹ́tánì, ìlú kékeré kan tí kò jìnnà sí Jerúsálẹ́mù. Lásárù ni orúkọ rẹ̀, ó sì ní arábìnrin méjì. Orúkọ wọn ń jẹ́ Màtá àti Màríà. Jẹ́ kí á wo ohun tí Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, Lásárù ṣàìsàn gan-an. Lásìkò náà, Jésù wà níbi tó jìnnà réré sí wọn. Nítorí náà Màtá àti Màríà rán ẹnì kan láti lọ sọ fún Jésù pé Lásárù arákùnrin àwọn ń ṣàìsàn. Wọ́n ṣe èyí nítorí wọ́n mọ̀ pé Jésù lè wá láti mú arákùnrin wọn lára dá. Jésù kì í ṣe dókítà o, ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún un ní agbára tí ó fi lè wo oríṣiríṣi àrùn sàn.—Mátíù 15:30, 31.

Àmọ́ kí Jésù tó lọ wo Lásárù, àìsàn náà ti wọ Lásárù lára jù, ó sì kú. Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé Lásárù ń sùn pé òun yóò lọ jí i. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí. Nítorí náà, Jésù sọ kedere pé: “Lásárù ti kú.” Kí ni èyí fi hàn  nípa ikú?— Ìyẹn ni pé ikú dà bí ìgbà tí èèyàn bá sun oorun àsùnwọra. Ó jẹ́ oorun téèyàn máa ń sùn lọ bámúbámú tí kò tiẹ̀ ní lá àlá rárá.

Jésù ń bọ̀ wá láti kí Màtá àti Màríà nísinsìnyí. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn ti wá síbẹ̀. Wọ́n wá láti tu Màtá àti Màríà nínú nítorí pé arákùnrin wọn kú. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Màríà pẹ̀lú jáde lọ láti rí Jésù. Inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an, ó ń sunkún, ó sì wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ yòókù tó tẹ̀ lé Màríà ń sunkún pẹ̀lú.

Olùkọ́ Ńlá béèrè ibi tí wọ́n gbé Lásárù sí. Àwọn èèyàn wá mú Jésù lọ síbi ibojì tí wọ́n sin Lásárù sí. Nígbà tí Jésù rí i tí gbogbo àwọn èèyàn ń sunkún òun pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí sunkún. Ó mọ bí ó ṣe máa ń dunni tó tí ikú bá pa ènìyàn wa kan.

Òkúta kan wà níwájú ihò àpáta náà, nítorí náà Jésù sọ pé: “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Ṣé ó yẹ kí wọ́n gbé e kúrò?— Màtá ò rò pé ó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: ‘Olúwa, ní báyìí yóò ti máa rùn, nítorí ó ti di ọjọ́ mẹ́rin tó ti kú.’

Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún un pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ pé bí ìwọ bá gbà gbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?” Ohun tí Jésù ń sọ ni pé Màtá yóò rí ohun tí yóò mú kí wọ́n yin Ọlọ́run lógo. Kí ni ohun tí Jésù fẹ́ ṣe? Nígbà tí wọ́n gbé òkúta náà kúrò, Jésù gbàdúrà sókè sí Jèhófà. Lẹ́yìn náà Jésù kígbe lóhùn rara pé: “Lásárù, jáde wá!” Ṣé yóò jáde? Ǹjẹ́ ó lè jáde wá?—

Ó dára, ǹjẹ́ o lè jí ẹni tó ń sùn?— Bẹ́ẹ̀ ni, tí o bá kígbe pè é yóò jí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o lè jí ẹnì kan tí ó sùn nínú ikú dìde?— Rárá. Bó ti wù kí o kígbe tó, ẹni tó ti kú kò lè gbọ́. Kò sí ohun tí ìwọ tàbí èmi tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn ní ayé lónìí lè ṣe tí a fi lè jí òkú dìde.

Kí ni Jésù ṣe fún Lásárù?

 Ṣùgbọ́n ti Jésù yàtọ̀. Ọlọ́run fún un ní agbára àrà ọ̀tọ̀. Nítorí náà, nígbà tí Jésù pe Lásárù, ohun ìyanu kan ṣẹlẹ̀. Ọkùnrin tí ó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin náà jáde wá látinú ihò àpáta! Jésù sọ ọ́ di alààyè padà! Ó ń mí, ó ń rìn, ó sì tún ń sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i! Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù jí Lásárù dìde kúrò nínú ikú.—Jòhánù 11:1-44.

Wàyí o, ronú nípa rẹ̀: Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Lásárù nígbà tí ó kú? Ṣé ohun kan nínú ara rẹ̀, ìyẹn ọkàn tàbí ẹ̀mí, jáde kúrò ní ara rẹ̀ tó sì lọ́ gbé níbòmíràn? Ǹjẹ́ ọkàn Lásárù lọ sí ọ̀run? Ṣé ó wà láàyè fún ọjọ́ mẹ́rin yẹn ní ọ̀run pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn áńgẹ́lì mímọ́?—

Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Rántí, Jésù sọ pé Lásárù ń sùn. Tí o bá sùn báwo ló ṣe máa ń rí? Nígbà tí o bá sùn wọra gan-an, o kì í mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká rẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Nígbà tí o bá sì jí o kì í mọ bí o ti sùn pẹ́ tó àfi tí o bá wo aago.

Bí ó ṣe rí fún àwọn òkú nìyẹn. Wọn kò mọ nǹkan kan. Wọn  kì í mọ ohunkóhun lára. Wọn kò sì lè ṣe nǹkan kan. Bí ọ̀ràn Lásárù ṣe rí nìyẹn nígbà tí ó kú. Ikú dà bí ìgbà tí èèyàn bá sun oorun àsùnwọra, tí èèyàn kì í lè rántí ohunkóhun. Bíbélì sọ pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5, 10.

Ipò wo ni Lásárù wà nígbà tí ó kú?

Tún ronú nípa èyí: Bí Lásárù bá wà ní ọ̀run fún ọjọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yẹn, ǹjẹ́ kò ní sọ nǹkan kan nípa rẹ̀?— Tí ó bá ṣe pé ọ̀run ló wà, ṣé Jésù yóò tún dá a padà wá sí ayé kúrò ní ibi tó dára yẹn?— Rárá o!

Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé a ọkàn, wọ́n sì sọ pé ọkàn máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú ara. Wọ́n ní ọkàn Lásárù kò kú pé ó wà láàyè ní ibì kan. Ṣùgbọ́n Bíbélì kò sọ bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé Ọlọ́run dá Ádámù ọkùnrin kìíní ní “alààyè ọkàn.” Ádámù jẹ́ ọkàn. Bíbélì sì tún sọ pé nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ó kú. Ó di “òkú ọkàn,” ó sì padà sí ekuru tí Ọlọ́run fi dá a. Bíbélì sì tún sọ pé àtọmọdọ́mọ Ádámù jogún ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n sì ń kú bákan náà.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7; 3:17-19; Númérì 6:6; Róòmù 5:12.

Nítorí náà, ó ṣe kedere pé a kò ọkàn tí ó dá wà yàtọ̀ sí ara wa. Olúkúlùkù wa jẹ́ ọkàn. Nígbà tí àwọn èèyàn sì ti jogún ẹ̀ṣẹ̀  láti ọ̀dọ̀ Ádámù ọkùnrin kìíní, Bíbélì sọ pe: ‘Ọkàn tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ yóò kú.’—Ìsíkíẹ́lì 18:4.

Èé ṣe tí kò fi yẹ kí á máa bẹ̀rù àwọn òkú?

Àwọn èèyàn kan ń bẹ̀rù àwọn òkú. Wọn kì í sún mọ́ ibi tí ibojì wà nítorí pé wọ́n rò pé àwọn òkú ní ọkàn tí ó dá wà yàtọ̀ sí ara wọn, èyí tí ó lè pa alààyè lára. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ òkú lè ṣe ìpalára fún alààyè?— Rárá o.

Àwọn èèyàn kan tiẹ̀ gbà gbọ́ pé òkú lè di ẹ̀mí tí a kò lè rí, tí wọn yóò sì padà wá bẹ alààyè wò. Nítorí náà, wọ́n máa ń gbé oúnjẹ sí ibì kan fún àwọn òkú láti jẹ. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn tó ń ṣe irú ohun bẹ́ẹ̀ kò gba ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn òkú gbọ́. Bí a bá gba ohun tí Ọlọ́run sọ gbọ́, a kò ní bẹ̀rù àwọn òkú rárá. Bí a bá sì mọrírì oore tí Ọlọ́run ṣe fún wa lóòótọ́ tí ó fún wa ní ìwàláàyè, a ó fi èyí hàn nípa ṣíṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń fẹ́.

Ṣùgbọ́n a lè máa rò ó pé: ‘Ǹjẹ́ Ọlọ́run á mú àwọn ọmọdé tí ó ti kú padà wà láàyè bí? Ǹjẹ́ ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́ bí?’ Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìyẹn nísinsìnyí.

Jẹ́ kí á ka ọ̀rọ̀ Bíbélì síwájú sí i nípa ipò tí àwọn òkú wà àti nípa pé èèyàn jẹ́ ọkàn, nínú Sáàmù 115:17; 146:3, 4; àti Jeremáyà 2:34.