Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 11

Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run

Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run

ÀWỌN kan sọ pé ohun tí àwọn bá lè fojú rí nìkan làwọn máa ń gbà gbọ́. Ṣùgbọ́n ìyẹn ò dára. Àìmọye nǹkan ló wà tá ò tíì fojú wa rí. Ǹjẹ́ o lè dárúkọ ọ̀kan?—

Afẹ́fẹ́ tí à ń mí símú ńkọ́? Tó bá fẹ́ sí wa lára ǹjẹ́ a máa ń mọ̀?— Gbé ọwọ́ rẹ sókè, kí o fẹ́ atẹ́gùn sí i. Ǹjẹ́ ó dà bíi pé kinní kan kàn ọ́ lára?— Ó dà bẹ́ẹ̀, àmọ́ o ò rí atẹ́gùn yẹn, àbí o rí i?—

Níṣàájú a ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹni ẹ̀mí, tó jẹ́ pé a ò lè fojú rí. A kà á nígbà náà pé àwọn ẹni ẹ̀mí kan ń ṣe rere ṣùgbọ́n àwọn mìíràn ń ṣe ohun tó burú. Dárúkọ díẹ̀ lára àwọn ẹni ẹ̀mí rere tá ò lè fojú rí.— Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan, Jésù náà jẹ́ ọ̀kan, àwọn áńgẹ́lì rere sì wà pẹ̀lú. Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì búburú náà wà?— Bíbélì sọ pé wọ́n wà. Sọ ohun tó o mọ̀ nípa wọn fún mi kí n gbọ́.—

Ohun kan tí a mọ̀ ni pé gbogbo áńgẹ́lì ló lágbára jù wá lọ, ì báà jẹ́ áńgẹ́lì rere tàbí búburú. Olùkọ́ Ńlá náà mọ nǹkan púpọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì. Nítorí pé òun náà jẹ́ áńgẹ́lì tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó bí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ sí ayé. Òun pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì yòókù ni wọ́n jọ ń gbé ní ọ̀run tẹ́lẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì tó pọ̀ rẹpẹtẹ ló mọ̀. Ǹjẹ́ gbogbo àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí ní orúkọ?—

Tí o bá rántí, a ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sẹ́yìn pé Ọlọ́run fún àwọn ìràwọ̀ lórúkọ. Nítorí náà ó dájú pé gbogbo àwọn áńgẹ́lì náà ní orúkọ. A sì mọ̀ pé wọ́n máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nítorí pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ‘èdè àwọn áńgẹ́lì.’ (1 Kọ́ríńtì 13:1) Àwọn nǹkan wo lo rò pé àwọn áńgẹ́lì máa ń bá ara wọn sọ? Ǹjẹ́ wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àwa tó wá ní ayé?—

 A mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì Sátánì, ìyẹn àwọn ẹ̀mí èṣù, ń sapá láti mú kí á ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Nítorí náà, ó dájú pé wọ́n á máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí wọ́n máa gbà ṣe é. Wọ́n ń fẹ́ kí á dà bí àwọn ti dà, kí Jèhófà má bàa fẹ́ràn àwa náà pẹ̀lú. Àmọ́ àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ńkọ́? Ǹjẹ́ o rò pé àwọn náà ń sọ̀rọ̀ nípa wa?— Bẹ́ẹ̀ ni. Ó máa ń wù wọ́n láti ràn wá lọ́wọ́. Jẹ́ kí n sọ fún ẹ nípa bí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run kan ṣe ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tó fẹ́ràn Jèhófà tí wọ́n sì ń sìn ín.

Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Dáníẹ́lì, ó ń gbé ní Bábílónì. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà ní ìlú yẹn ni kò fẹ́ràn Jèhófà. Àwọn èèyàn tiẹ̀ ṣe òfin kan pé àwọn yóò fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì ṣì ń gbàdúrà sí Jèhófà ní tiẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọ́n ṣe sí Dáníẹ́lì?—

Ṣe ni àwọn èèyàn burúkú gbé Dáníẹ́lì sọ sínú ihò kìnnìún. Dáníẹ́lì nìkan wá wà níbẹ̀ láàárín àwọn kìnnìún tí ebi ń pa. Ǹjẹ́ o  mọ ohun tó wá ṣẹlẹ̀?— Dáníẹ́lì sọ pé: ‘Ọlọ́run rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.’ Àwọn kìnnìún wọ̀nyẹn ò pa á lára rárá! Àwọn áńgẹ́lì máa ń ṣe ohun ìyanu fún àwọn tó bá ń sin Jèhófà.—Dáníẹ́lì 6:18-22.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe yọ Dáníẹ́lì nínú ewu?

Ìgbà kan tún wà tí Pétérù wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Wàá rántí pé Pétérù jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù Kristi, Olùkọ́ Ńlá náà. Inú àwọn kan ò dùn nígbà tí Pétérù sọ fún wọn pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run. Nítorí náà wọ́n fi Pétérù sí àtìmọ́lé. Àwọn ọmọ ogun, tàbí ṣọ́jà, wá ń ṣọ́ Pétérù torí kó má lè sá lọ. Ǹjẹ́ ẹnì kankan wà tó lè ràn án lọ́wọ́?—

Pétérù sùn sí àárín àwọn ọmọ ogun méjì tó ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì tún fi  ẹ̀wọ̀n de ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé: ‘Wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ kan sì tàn nínú yàrá kótópó inú ẹ̀wọ̀n náà. Áńgẹ́lì náà fọwọ́ lu Pétérù pẹ́pẹ́ ní ẹ̀gbẹ́, láti jí i, ó ní: “Dìde kíákíá!”’

Báwo ni áńgẹ́lì kan ṣe ran Pétérù lọ́wọ́ tó fi jáde kúrò ní àtìmọ́lé?

Ẹ̀wọ̀n ọwọ́ Pétérù kàn já kúrò ni! Áńgẹ́lì náà wá sọ fún un pé: ‘Wọ ẹ̀wù rẹ, wọ bàtà rẹ, kí o sì máa tẹ̀ lé mi.’ Àwọn ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ọ kò lè dá wọn dúró nítorí áńgẹ́lì yìí ni ó ń ran Pétérù lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n wá dé ibi ilẹ̀kùn irin kan, ohun ìyàlẹ́nu kan ṣẹlẹ̀. Ilẹ̀kùn irin náà kàn ṣí fúnra rẹ̀ ni! Àṣé áńgẹ́lì yẹn tú Pétérù sílẹ̀ ni, kí ó tún lè máa wàásù fáwọn èèyàn.—Ìṣe 12:3-11.

Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run lè ran àwa náà lọ́wọ́?— Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. Ṣé pé wọn kò ní jẹ́ ká fara pa rárá?— Bẹ́ẹ̀ kọ́ o, tí a bá fi ìwà òmùgọ̀ lọ ṣe ohun tó lè pa wá lára, áńgẹ́lì kò ní bá wa dá nǹkan yẹn dúró kí ó má pa wá lára o. Ṣùgbọ́n tí a ò bá tiẹ̀ ṣe nǹkan tó jẹ́ ìwà òmùgọ̀, a ṣì lè fara pa o. Ọlọ́run kò sọ fún àwọn áńgẹ́lì pé tá a bá ti fẹ́ fara pa kí wọ́n máa gbé wa kúrò níbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n ṣe.

Bíbélì sọ fún wa nípa áńgẹ́lì kan tó ń sọ fún àwọn èèyàn níbi gbogbo pé kí wọ́n máa sin Ọlọ́run. (Ìṣípayá 14:6, 7) Báwo ni áńgẹ́lì yìí ṣe ń sọ ọ́ fún wọn? Ṣé ó ń pariwo láti ọ̀run ni kí gbogbo èèyàn lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?— Rárá o, dípò ìyẹn, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó wà ní ayé ló ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, àmọ́ àwọn áńgẹ́lì ń darí wọn bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ wọn. Àwọn áńgẹ́lì máa ń rí i dájú pé àwọn tó fẹ́ mọ̀ nípa Ọlọ́run lóòótọ́ ń ní àǹfààní láti gbọ́ nípa rẹ̀. Àwa náà lè ṣe lára iṣẹ́ ìwàásù yìí, àwọn áńgẹ́lì á sì ràn wá lọ́wọ́.

Ṣùgbọ́n tí àwọn tí kò fẹ́ràn Ọlọ́run bá ń bínú sí wa ńkọ́? Bí wọ́n bá fi wá sí àtìmọ́lé ńkọ́? Ṣé àwọn áńgẹ́lì a wá gbà wá sílẹ̀?— Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ o. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Kí ni áńgẹ́lì yìí ń sọ fún Pọ́ọ̀lù?

Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nígbà kan. Lákòókò kan tí ọkọ̀ òkun tí ó wọ̀ ń lọ lójú òkun, ìjì líle burúkú bẹ̀rẹ̀ sí jà. Ṣùgbọ́n àwọn  áńgẹ́lì ò yọ Pọ́ọ̀lù kúrò níbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ohun tó fà á ni pé àwọn èèyàn kan ṣì wà tó yẹ kó gbọ́ nípa Ọlọ́run. Áńgẹ́lì kan sọ pé: “Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù. Ìwọ gbọ́dọ̀ dúró níwájú Késárì.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Pọ́ọ̀lù yóò lọ síwájú Késárì, tó jẹ́ ọba gbogbo ayé nígbà yẹn, láti lè wàásù fún un. Àwọn áńgẹ́lì yìí mọ ibi tí Pọ́ọ̀lù wà nígbà gbogbo, wọ́n sì ń ràn án lọ́wọ́. Wọ́n á ran àwa náà lọ́wọ́ tí a bá ń sin Ọlọ́run dáadáa.—Ìṣe 27:23-25.

Iṣẹ́ ńlá mìíràn tún wà tí àwọn áńgẹ́lì yóò ṣe, àìpẹ́ yìí ni wọ́n sì máa ṣe é. Àkókò tí Ọlọ́run yóò pa àwọn èèyàn burúkú run ti sún mọ́lé gan-an. Gbogbo àwọn tí kò bá sin Ọlọ́run tòótọ́ yóò pa run. Àwọn èèyàn tó sọ pé àwọn ò gbà pé áńgẹ́lì wà nítorí pé àwọn ò fojú rí wọ́n, yóò wá rí i pé àwọn ti ṣe ohun tí kò dáa.—2 Tẹsalóníkà 1:6-8.

Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sí àwa?— Bí a bá jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run, wọ́n yóò ràn wá lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ṣé ọ̀rẹ́ wọn la jẹ́?— Tí a bá ń sin Jèhófà, á óò jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn. Tí a bá sì ń sin Jèhófà, á óò máa sọ fún àwọn èèyàn yòókù pé kí àwọn náà máa sìn ín.

Láti lè mọ̀ púpọ̀ sí i nípa ohun tí àwọn áńgẹ́lì máa ń ṣe láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ka Sáàmù 34:7; Mátíù 4:11; 18:10; Lúùkù 22:43; àti Ìṣe 8:26-31.