TÓ BÁ jẹ́ pé ohunkóhun tó wù ẹ́ lo lè ṣe, ṣé inú ẹ máa dùn? Ǹjẹ́ kì í wù ẹ́ nígbà mìíràn pé kí ẹnì kankan má dà ẹ́ láàmú, kí wọ́n fi ẹ́ sílẹ̀ kó o ṣe ohun tó o bá fẹ́? Ó dára, sòótọ́ o, sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ gan-an.—

Kí nìdí tó fi yẹ kó o fetí sí àwọn tó bá jù ẹ́ lọ?

Ṣùgbọ́n, èwo lo rò pé ó dára jù? Ṣé ó bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ pé kó o máa ṣe ohunkóhun tó bá ṣáà ti wù ẹ́? Àbí ìgbà tó o bá ṣe àwọn nǹkan bí bàbá àti màmá rẹ ṣe ní kó o ṣe é ni nǹkan yẹn tó dára?— Ọlọ́run sọ pé o gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sáwọn òbí rẹ lẹ́nu, ó sì ní láti ní ìdí pàtàkì tó fi sọ bẹ́ẹ̀. Jẹ́ ká wò ó bóyá a lè rí ohun tó jẹ́ kó sọ bẹ́ẹ̀.

Ọmọ ọdún mélòó ni ẹ́?— Ṣé o mọ bí bàbá rẹ ṣe dàgbà tó?— Ẹni ọdún mélòó lo rò pé màmá rẹ tàbí màmá màmá rẹ tàbí bàbá màmá rẹ jẹ́?— Wọ́n ti dé ayé tipẹ́ ṣáájú rẹ. Béèyàn bá sì ṣe pẹ́ láyé tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ní àkókò púpọ̀ tó láti fi kọ́ àwọn nǹkan tó pọ̀. Àwọn ohun tí ẹni náà gbọ́ àti àwọn ohun tó rí àti àwọn ohun tó ń ṣe á máa pọ̀ sí i ni ṣáá bí ọdún ti ń gorí ọdún. Nítorí náà, àwọn ọmọdé lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn àgbà.

Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tí kò dàgbà tó ẹ?— Ǹjẹ́ ìwọ kò mọ nǹkan jù ẹni yẹn lọ?— Kí ló mú kí o mọ nǹkan púpọ̀ jù ú lọ?— Ohun tó fà á  ni pé, o ti dé ayé ṣáájú onítọ̀hún. Àkókò tó o ti lò láti fi kọ́ nípa àwọn nǹkan pọ̀ ju ti ẹni tí kò dàgbà tó ọ lọ.

Ta wá ni ẹni tó ti wà tipẹ́tipẹ́ kí ìwọ tàbí èmi tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tó wà?— Jèhófà Ọlọ́run ni. Ó mọ nǹkan púpọ̀ ju ọ́ lọ, ó sì mọ̀ ju èmi náà lọ. Tó bá sọ fún wa pé ká ṣe ohun kan, kí á mọ̀ dájú pé ohun tó tọ́ ló ní ká ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun náà lè ṣòro láti ṣe. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àkókò kan wà tí kò tiẹ̀ rọrùn fún Olùkọ́ Ńlá náà láti ṣègbọràn?—

Nígbà kan, Ọlọ́run sọ pé kí Jésù ṣe ohun kan tó ṣòro. Jésù wá gbàdúrà nípa ohun náà, bí a ṣe ń wò ó nínú àwòrán yìí. Ó gbàdúrà pé: ‘Bí ìwọ bá fẹ́, mú ohun tó ṣòro yìí kúrò fún mi.’ Àdúrà tí Jésù gbà yìí, mú ká rí i pé kì í rọrùn nígbà mìíràn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́, báwo ni Jésù ṣe parí àdúrà rẹ̀? Ǹjẹ́ o mọ̀ ọ́n?—

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àdúrà Jésù?

Ọ̀rọ̀ tí Jésù fi parí rẹ̀ ni pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:41, 42) Ìfẹ́ Ọlọ́run ni Jésù fẹ́ kó di ṣíṣe, kì í ṣe ìfẹ́ tirẹ̀. Ohun tí Ọlọ́run sì ń fẹ́ gan-an ló ṣe, kì í ṣe ohun tí òun fúnra rẹ̀ rò pé ó dára jù lọ.

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí?— A kẹ́kọ̀ọ́ pé nígbà gbogbo, ohun tó dára ni pé ká máa ṣe ohun tí Ọlọ́run bá sọ pé ká ṣe, àní bí kò bá tiẹ̀ rọrùn láti ṣe pàápàá. Àmọ́ a tún kọ́ nǹkan mìíràn o. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà?— A kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe ẹnì kan náà ni Ọlọ́run àti Jésù bí àwọn kan ṣe sọ. Jèhófà Ọlọ́run dàgbà ju Jésù Ọmọ rẹ̀ lọ, ó sì mọ nǹkan púpọ̀ ju Jésù lọ.

Tá a bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ńṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ràn rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ  rẹ̀ mọ́.” (1 Jòhánù 5:3) Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo wa máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ṣé ìwọ náà yóò máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run?—

Ó dáa, jẹ́ ká ṣí Bíbélì wa ká wo ohun tí Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ọmọ máa ṣe. A fẹ́ ka ohun tí Bíbélì sọ nínú ìwé Éfésù orí kẹfà, ẹsẹ ìkíní, ìkejì àti ìkẹta. Ó kà pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo: ‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’”

Ṣé o wá rí i pé Jèhófà Ọlọ́run ló sọ pé kó o máa ṣègbọràn sí bàbá àti màmá rẹ. Kí ló túmọ̀ sí láti “bọlá” fún wọn? Ó túmọ̀ sí pé kó o máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Ọlọ́run sì ṣèlérí pé tó o bá ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ, ‘nǹkan á máa lọ dáadáa fún ọ.’

Jẹ́ kí n sọ ìtàn kan fún ẹ nípa àwọn kan tí a gba ẹ̀mí wọn là nítorí pé wọ́n ṣe ìgbọràn. Ìlú ńlá Jerúsálẹ́mù ni àwọn tí à ń wí yìí ń gbé láyé àtijọ́. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ará ìlú yẹn ń ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Nítorí náà, Jésù kìlọ̀ fún àwọn ará ìlú náà pé Ọlọ́run máa pa ìlú wọn run. Jésù tún sọ fún wọn bí wọ́n ṣe lè sá àsálà bí wọ́n bá fẹ́ ṣe ohun tó tọ́. Ó sọ pé: ‘Nígbà tí ẹ bá rí i pé àwọn ọmọ ogun púpọ̀ wà yí Jerúsálẹ́mù ká, kí ẹ mọ̀ pé ó ti fẹ́ pa run nìyẹn o. Ìgbà náà ni kí àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù sá kúrò níbẹ̀, kí wọ́n sá lọ sórí àwọn òkè.’—Lúùkù 21:20-22.

Báwo ni ìgbọràn sí ohun tí Jésù sọ ṣe gba àwọn èèyàn yìí là?

Lóòótọ́, bí Jésù ṣe sọ ọ́, àwọn ọmọ ogun wá láti bá Jerúsálẹ́mù jà. Àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wá yìí pọ̀ gan-an wọ́n sì yí Jerúsálẹ́mù ká. Àmọ́ lójijì, àwọn ọmọ ogun yìí kàn tún kúrò níbẹ̀ ni. Àwọn èèyàn púpọ̀ jù lọ ní ìlú náà rò pé kò sí ewu mọ́. Wọn ò sì kúrò nínú ìlú náà. Àmọ́ kí lohun tí Jésù sọ pé kí wọ́n ṣe?— Ká ní Jerúsálẹ́mù lò ń gbé ní àkókò náà, kí ni ìwọ ì bá ṣe?— Àwọn tó gba Jésù gbọ́ lóòótọ́ fi ilé wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ sórí àwọn òkè tó jìnnà sí Jerúsálẹ́mù.

Fún odidi ọdún kan, kò sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù. Ọdún kejì  kọjá, nǹkan kan kò ṣẹlẹ̀. Ní ọdún kẹta náà, kò sí ohun tó ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn kan lè máa rò pé ọ̀dẹ̀ làwọn èèyàn tó ti sá kúrò nínú ìlú náà. Àmọ́ nígbà tó di ọdún kẹrin, àwọn ọmọ ogun Róòmù padà wá. Wọ́n tún yí gbogbo Jerúsálẹ́mù ká. Kò wá sí àyè fún ẹnikẹ́ni láti sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀ mọ́. Àwọn ọmọ ogun náà sì pa gbogbo ìlú náà run lọ́tẹ̀ yìí. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wà nínú ìlú náà ló kú, wọ́n sì kó àwọn tó kù lẹ́rú.

Ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ti ṣègbọràn sí Jésù?— Kò sí ohunkóhun tó ṣe wọ́n. Wọ́n ti wà níbi tó jìnnà sí Jerúsálẹ́mù. Nítorí náà, kò sí ìyà kankan tó jẹ wọ́n. Ìgbọràn dáàbò bò wọ́n.

Tí ìwọ náà bá ń ṣègbọràn, ǹjẹ́ o rò pé ìgbọràn lè dáàbò bò ẹ́?— Àwọn òbí rẹ lè sọ fún ẹ pé o kò gbọ́dọ̀ ṣeré lójú títì. Kí ló mú kí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀?— Ohun tó fà á ni pé mọ́tò lè kọlù ẹ́. Àmọ́ ó lè di ọjọ́ kan kó o ronú pé: ‘Kò ṣáà sí mọ́tò kankan lójú títì báyìí. Nǹkan  kan ò ní ṣe mí. Ṣebí àwọn ọmọ mìíràn ń ṣeré lójú títì, mi ò sì tíì rí i kí nǹkan burúkú kan ṣẹlẹ̀ sí wọn rí.’

Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣègbọràn ká tiẹ̀ sọ pé o kò rí ewu kankan?

Bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe ronú náà nìyẹn. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù kọ́kọ́ lọ kúrò ní Jerúsálẹ́mù, ó dà bí ẹni pé kò sí ewu mọ́. Nítorí pé wọ́n rí i pé àwọn èèyàn yòókù kò kúrò nínú ìlú náà, àwọn náà wá dúró. Jésù ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ o, àmọ́ wọ́n ṣàìgbọràn. Èyí sì yọrí sí ikú fún wọn.

Jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ mìíràn. Ǹjẹ́ o ti fi ìṣáná ṣeré rí?— Ó lè máa dùn mọ́ ọ tó o bá ń ṣá ìṣáná tó o sì ń wo bí ìṣáná náà ṣe ń jó. Àmọ́ ohun tó léwu gan-an ni téèyàn bá ń fi ìṣáná ṣeré. Ó lè jó odindi ilé tán pátá, ó tiẹ̀ lè pa ìwọ gan-an pàápàá!

Rántí o, kéèyàn máa ṣègbọràn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kò tó. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lò ń ṣègbọràn, èyí á dáàbò bò ọ́ gan-an ni. Ta sì ni ẹni náà tó sọ fún ẹ pé, “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín”?— Ọlọ́run ni. Sì rántí pé ohun tó mú kó sọ bẹ́ẹ̀ ni pé ó fẹ́ràn rẹ.

Wàyí o, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí tó fi bí ìgbọràn ti ṣe pàtàkì tó hàn: Òwe 23:22; Oníwàásù 12:13; Aísáyà 48:17, 18; àti Kólósè 3:20.