Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

 ORÍ 26

Ìdí Tó Fi Nira Láti Máa Ṣe Rere

Ìdí Tó Fi Nira Láti Máa Ṣe Rere

NÍGBÀ tí Sọ́ọ̀lù ń ṣe àwọn ohun burúkú ta ni inú rẹ̀ ń dùn?— Sátánì Èṣù ni. Ṣùgbọ́n inú àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù náà dùn pẹ̀lú. Àmọ́ nígbà tí Sọ́ọ̀lù di ọmọ ẹ̀yìn Olùkọ́ Ńlá náà, tí a sì wá ń pè é ní Pọ́ọ̀lù, àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra rẹ̀. Nítorí náà, ṣé o rí ìdí tí ó fi nira fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti máa ṣe rere?—

Ìyà wo ni Pọ́ọ̀lù jẹ torí pé tó ń ṣe ohun rere?

Nígbà kan, àlùfáà àgbà kan tí ó ń jẹ́ Ananíà pàṣẹ pé kí àwọn kan gbá Pọ́ọ̀lù lójú. Ananíà tiẹ̀ gbìyànjú láti rí i pé wọ́n ju Pọ́ọ̀lù sí ẹ̀wọ̀n. Pọ́ọ̀lù jìyà púpọ̀ nígbà tí ó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òṣìkà èèyàn kan na Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì ju òkúta ńláńlá lù ú, wọ́n fẹ́ pa á.—Ìṣe 23:1, 2; 2 Kọ́ríńtì 11:24, 25.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni yóò gbìyànjú láti mú wa ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́. Nítorí náà ronú lórí àwọn ohun pàtàkì yìí: Báwo ni o ṣe fẹ́ràn ohun rere tó? Ǹjẹ́ o fẹ́ràn ohun rere gan-an débi pé o  kò ní jáwọ́ nínú ṣíṣe é kódà bí àwọn èèyàn bá kórìíra rẹ nítorí rẹ̀? Ó gba ìgboyà láti ṣe bẹ́ẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—

O lè máa rò ó lọ́kàn rẹ pé, ‘Kí ló dé tí àwọn èèyàn yóò fi kórìíra wa nítorí pé a ṣe ohun rere? Ṣe bí ó yẹ kí inú wọn máa dùn ni?’ Ńṣe ló yẹ kí inú wọn máa dùn o. Àwọn èèyàn sábà máa ń fẹ́ràn Jésù nítorí àwọn ohun rere tí ó ń ṣe. Ní ìgbà kan, gbogbo èèyàn ìlú kan ló kóra jọ sí ẹnu ọ̀nà ilé kan tí Jésù wà. Wọ́n wá síbẹ̀ nítorí pé Jésù ń mú àwọn aláìsàn lára dá.—Máàkù 1:33.

Ṣùgbọ́n nígbà mìíràn, inú àwọn èèyàn kì í dùn sí ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ni. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ó tọ́ ni Jésù ń kọ́ni, àwọn èèyàn ṣì  kórìíra rẹ̀ gan-an nítorí pé ó ń sọ òtítọ́. Irú èyí ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan ní ìlú Násárétì, ìlú tí Jésù gbé títí ó fi dàgbà. Ó lọ sínú sínágọ́gù, ìyẹn ibi tí àwọn Júù ti máa ń pàdé láti sin Ọlọ́run.

Jésù sọ àsọyé dáradára láti inú Ìwé Mímọ́ níbẹ̀. Inú àwọn èèyàn kọ́kọ́ dùn sí i. Ẹnu yà wọ́n nítorí ọ̀rọ̀ dáradára tí Jésù sọ. Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè gbà gbọ́ pé Jésù yìí ni ọ̀dọ́mọkùnrin tó gbé ìlú wọn yìí dàgbà.

Ṣùgbọ́n Jésù wá sọ nǹkan mìíràn tí ó yàtọ̀. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìgbà tí Ọlọ́run fi ojú rere pàtàkì hàn sí àwọn èèyàn tí kì í ṣe Júù. Nígbà tí Jésù sọ èyí, àwọn tó wà nínú sínágọ́gù bínú gan-an. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á?— Wọ́n rò pé àwọn nìkan ni Ọlọ́run fi ojú rere pàtàkì hàn sí. Wọ́n rò pé àwọn dára ju àwọn èèyàn yòókù lọ. Nítorí náà wọ́n kórìíra Jésù nítorí ohun tí ó sọ. Ǹjẹ́ o sì mọ ohun tí wọ́n gbìyànjú láti fi ṣe é?—

Bíbélì sọ pé: ‘Wọ́n gbá Jésù mú, wọ́n sì yára mú un lọ sí ẹ̀yìn ìlú ńlá náà. Wọ́n mú un lọ sí téńté gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ńlá kan kí wọ́n lè tì í sísàlẹ̀ láti orí òkè náà, kí wọ́n sì pa á! Ṣùgbọ́n Jésù gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ wọn.’—Lúùkù 4:16-30.

Kí ló fà á tí àwọn èèyàn yìí fi fẹ́ pa Jésù?

Tí irú ohun bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ṣé wàá tún padà lọ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run fún àwọn èèyàn yẹn láéláé?— Yóò gba ìgboyà láti ṣe bẹ́ẹ̀, àbí?— Àmọ́, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Jésù tún padà lọ sí Násárétì. Bíbélì sọ pé: “Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn nínú sínágọ́gù wọn.” Jésù kò ṣíwọ́ sísọ òtítọ́. Kò jẹ́ kí àwọn èèyàn tí kò fẹ́ràn Ọlọ́run dẹ́rù ba òun kí òun máà sọ òtítọ́.—Mátíù 13:54.

Ní ọjọ́ kan tó jẹ́ sábáàtì, Jésù wà ní ibì kan, ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ gbẹ tàbí ká kúkú sọ pé tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sì wà níbẹ̀. Jésù ní agbára láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti fi mú ọkùnrin náà lára dá. Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú àwọn ọkùnrin tó wà níbẹ̀ ń gbìyànjú láti yọ Jésù lẹ́nu. Kí ni Olùkọ́ Ńlá náà yóò ṣe?— Ó kọ́kọ́ béèrè pé: ‘Bí ẹ bá ní àgùntàn kan tí ó sì já sínú kòtò ńlá kan lọ́jọ́ Sábáàtì, ṣé ẹ kò ní gbé e jáde?’

 Bẹ́ẹ̀ ni o, wọ́n á gbé àgùntàn náà jáde, àní lọ́jọ́ Sábáàtì, tó jẹ́ ọjọ́ tó yẹ kí wọ́n máa sinmi. Nítorí náà, Jésù sọ pé: ‘Ó tiẹ̀ dára jù bẹ́ẹ̀ lọ láti ṣèrànwọ́ fún èèyàn lọ́jọ́ Sábáàtì, nítorí pé èèyàn ti ṣeyebíye ju àgùntàn lọ!’ Ó mà ṣe kedere o pé ó yẹ kí Jésù ran ọkùnrin yẹn lọ́wọ́, kí ó sì mú un lára dá!

Jésù sọ fún ọkùnrin yẹn pé kí ó na ọwọ́ rẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò. Inú ọkùnrin náà mà dùn púpọ̀ o! Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tó ń yọ Jésù lẹ́nu ńkọ́? Ṣé inú tiwọn náà dùn?— Rárá o. Wọ́n tiẹ̀ tún wá kórìíra Jésù sí i ni. Wọ́n jáde síta wọ́n lọ gbìmọ̀ pọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa pa Jésù!—Mátíù 12:9-14.

Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn ṣe rí láyé òde òní. Kò sí bí a ti lè ṣe dáadáa tó, a ò lè tẹ́ gbogbo èèyàn lọ́rùn. Nítorí náà, a ní láti pinnu ẹni tí a fẹ́ tẹ́ lọ́rùn ní ti gidi. Tí ó bá jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ni, nígbà náà a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí wọ́n bá kọ́ wa nígbà gbogbo. Ṣùgbọ́n tí a bá ń ṣe ohun tí wọ́n kọ́ wa, ta ni yóò kórìíra wa? Ta ni yóò mú kó nira fún wa láti ṣe ohun rere?—

Sátánì Èṣù ni. Àmọ́ ẹlòmíràn wo ni yóò tún mú kí ó nira?— Àwọn tí Èṣù ti tàn jẹ láti gba àwọn ohun tó jẹ́ irọ́ gbọ́ ni. Jésù sọ fún àwọn aṣáájú ìsìn tí ó wà ní ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín.”—Jòhánù 8:44.

Àwọn èèyàn púpọ̀ ló wà tí Èṣù fẹ́ràn. Jésù pè wọ́n ní “ayé.” Kí lo rò pé “ayé” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí jẹ́?— Ó dára, jẹ́ kí á wo Jòhánù orí kẹẹ̀ẹ́dógún [15], ẹsẹ ìkọkàndínlógún [19]. A rí ọ̀rọ̀ Jésù yìí kà níbẹ̀ pé: ‘Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa fẹ́ràn ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.’

Nítorí náà, ayé tí ó kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni gbogbo àwọn  èèyàn tí kì í ṣe ọmọlẹ́yìn Jésù. Kí ló fà á ti ayé fi kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù?— Rò ó wò ná. Ta ni ó ń ṣàkóso ayé?— Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Ẹni burúkú náà ni Sátánì Èṣù.—1 Jòhánù 5:19.

Ǹjẹ́ o wá rí ohun tó fà á tó fi nira gidigidi láti máa ṣe ohun rere?— Sátánì àti ayé tí ó ń ṣàkóso ló jẹ́ kí ó nira. Ṣùgbọ́n ìdí mìíràn tún wà tó fi nira. Ǹjẹ́ o rántí ohun náà?— Ní Orí 23 nínú ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé a bí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ gbogbo wa pátá. Bí ẹ̀ṣẹ̀, Èṣù àti ayé tí Èṣù ń ṣàkóso kò bá sí mọ́ ǹjẹ́ kò ní dùn mọ́ wa gan-an?—

Nígbà tí ayé yìí bá kọjá lọ, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ń ṣe rere?

Bíbélì ṣèlérí pé: “Ayé ń kọjá lọ.” Èyí fi hàn pé gbogbo àwọn tí kì í ṣe ọmọ ẹ̀yìn Olùkọ́ Ńlá náà kò ní sí mọ́. Ọlọ́run ò ní gbà kí wọ́n máa wà láàyè lọ títí láé. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí yóò wà láàyè títí láé?— Ọ̀rọ̀ Bíbélì tẹ̀ síwájú pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Bẹ́ẹ̀ ni o, kìkì àwọn tó bá ń ṣe rere, tí wọ́n ń ṣe “ìfẹ́ Ọlọ́run,” ni yóò wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Nítorí náà, bí ó bá tiẹ̀ nira, a óò fẹ́ láti máa ṣe ohun rere, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—

Jẹ́ kí á jùmọ̀ ka Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí, tó sọ ìdí tí kò fi rọrùn láti máa ṣe ohun rere: Mátíù 7:13, 14; Lúùkù 13:23, 24; àti Ìṣe 14:21, 22.