ǸJẸ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí pé inú rẹ bà jẹ́ tí ó sì dà bíi pé o wà ní ìwọ nìkan?— Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé bóyá ni ẹnikẹ́ni tiẹ̀ fẹ́ràn rẹ?— Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọdé kan. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣèlérí pé: ‘Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.’ (Aísáyà 49:15) Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ ọ láti gbọ́ èyí bí?— Dájúdájú Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ràn wa gan-an!

Báwo ni o rò pé yóò ti rí lára ọ̀dọ́ àgùntàn kékeré tó sọ nù yìí?

Òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Bí a bá mọ èyí bẹ́ẹ̀, yóò tù wá nínú gan-an àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Kódà Jèhófà sọ fún wa pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. . . . Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.”Aísáyà 41:10.

Àmọ́, nígbà mìíràn Jèhófà máa ń gbà kí Sátánì yọ wá lẹ́nu. Jèhófà tiẹ̀ máa ń gbà kí Sátánì dán àwọn ìránṣẹ́ Òun wò. Nígbà kan, Èṣù mú kí ìyà jẹ Jésù púpọ̀ gan-an tí Jésù fi kígbe pe Jèhófà pé: ‘Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi fi mí sílẹ̀?’ (Mátíù 27:46) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà ń jẹ Jésù, ó mọ̀ pé Jèhófà ṣì fẹ́ràn òun. (Jòhánù 10:17) Ṣùgbọ́n Jésù tún mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń gbà kí Sátánì dán àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ wò, ó sì máa ń gbà kí Sátánì mú kí ìyà jẹ wọ́n. Nínú orí mìíràn níwájú a ó ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi máa ń gbà kí Sátánì ṣe èyí.

Tí a bá jẹ́ ọmọ kékeré, ẹ̀rù tètè máa ń bà wá nígbà mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ìgbà kan wà rí tí o sọ nù láìmọ ọ̀nà mọ́?— Ǹjẹ́ ẹ̀rù ò bà ọ́?— Ẹ̀rù máa ń ba ọ̀pọ̀ ọmọdé nítorí èyí. Nígbà kan, Olùkọ́ Ńlá sọ ìtàn kan nípa ohun tó sọ nù. Kì í ṣe ọmọ ló sọ nù o. Àgùntàn ni.

Ní àwọn ọ̀nà kan ìwọ dà bí àgùntàn. Lọ́nà wo? Àgùntàn kò tóbi  púpọ̀, kò sì lágbára púpọ̀. Wọ́n sì ń fẹ́ ẹni tí yóò máa tọ́jú wọn tí yóò sì dáàbò bò wọ́n. Ẹni tó ń tọ́jú àgùntàn ni à ń pè ní olùṣọ́ àgùntàn.

Nínú ìtàn tí Jésù sọ, ó sọ̀rọ̀ nípa olùṣọ́ àgùntàn tí ó ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àgùntàn náà sọ nù. Ó lè jẹ́ pé àgùntàn náà fẹ́ wo ohun tó wà ní apá kejì òkè tí wọ́n wà. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, àgùntàn náà ti rìn jìnnà réré sí àwọn yòókù rẹ̀. Báwo ni o rò pé ó ṣe máa rí lára àgùntàn náà nígbà tí ó wò yíká tí ó rí i pé òun nìkan ló wà níbẹ̀?—

Kí ni olùṣọ́ àgùntàn náà yóò ṣe nígbà tí kò rí àgùntàn kan yẹn mọ́? Ṣé yóò sọ pé àgùntàn náà ló kó ara rẹ̀ sí ìyọnu, pé òun ò ní ṣe wàhálà kankan nípa rẹ̀? Tàbí yóò fi àgùntàn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] yòókù sílẹ̀ ní ibi ààbò tí yóò sì lọ wá ẹyọ kan ṣoṣo yẹn? Ṣé yóò torí ẹyọ àgùntàn kan ṣoṣo ṣe gbogbo wàhálà yẹn?— Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni àgùntàn tó sọ nù yẹn, ǹjẹ́ ìwọ yóò fẹ́ kí olùṣọ́ àgùntàn náà wá ọ?—

Olùṣọ́ àgùntàn náà fẹ́ràn àgùntàn rẹ̀ dáadáa, àní títí kan èyí tó sọ nù. Nítorí náà ó lọ wá èyí tí kò rí yẹn. Wo bí ó ṣe máa dùn mọ́ àgù

Ta ni ó dà bí olùṣọ́ àgùntàn tí ó yọ àgùntàn rẹ̀ nínú ewu?

ntàn tó sọ nù náà nígbà tó rí i tí olùṣọ́ àgùntàn náà ń bọ̀! Jésù sì sọ pé inú olùṣọ́ àgùntàn náà dùn gan-an pé ó rí àgùntàn rẹ̀ tó sọ nù náà. Ó yọ̀ gan-an nítorí  àgùntàn kan ṣoṣo yìí ju àgùntàn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún yòókù tí kò sọ nù lọ. Wàyí o, ta ni ó dà bí olùṣọ́ àgùntàn tí Jésù sọ nínú ìtàn rẹ̀? Ta ló fẹ́ràn wa tó bí olùṣọ́ àgùntàn náà ṣe fẹ́ràn àgùntàn rẹ̀?— Jésù sọ pé Bàbá òun tí ń bẹ ní ọ̀run ni. Jèhófà sì ni Bàbá rẹ̀.

Jèhófà Ọlọ́run ni Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá fún àwọn èèyàn rẹ̀. Ó fẹ́ràn gbogbo àwọn tó ń sìn ín, títí kan àwọn ọmọdé bíi tìrẹ. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni lára wa fara pa tàbí kí á pa run. Dájúdájú, ó dùn mọ́ni gan-an láti mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn wa bẹ́ẹ̀!—Mátíù 18:12-14.

Ǹjẹ́ o mọ̀ nínú ọkàn rẹ pé Jèhófà jẹ́ ẹni gidi tí ó wà, gẹ́gẹ́ bí o ṣe mọ̀ pé bàbá rẹ tàbí àwọn èèyàn mìíràn wà ní ti gidi?

Ǹjẹ́ o gbà pé Jèhófà Ọlọ́run wà lóòótọ́?— Ǹjẹ́ o mọ̀ nínú ọkàn rẹ pé ó jẹ́ ẹni gidi tí ó wà bí?— Lóòótọ́ a ò lè fi ojú wa rí Jèhófà. Nítorí pé ẹni Ẹ̀mí ni. Irú ara tí ó ní kì í ṣe èyí tí a lè fi ojú wa rí. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ẹni gidi kan tí ó wà, ó sì ń rí wa. Ó mọ ìgbà tí a bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́. A lè bá a sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń bá ara wa sọ̀rọ̀ níhìn-ín ní orílẹ̀-ayé. À ń ṣe èyí nígbà tí a bá gbàdúrà. Jèhófà ń fẹ́ kí á máa bá òun sọ̀rọ̀.

 Nítorí náà, tí inú rẹ bá bà jẹ́ tàbí tí ó bá dà bíi pé o wà ní ìwọ nìkan, kí ni ó yẹ kí o ṣe?— Bá Jèhófà sọ̀rọ̀. Sún mọ́ ọn, yóò tù ọ́ nínú, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Rántí pé Jèhófà fẹ́ràn rẹ, kódà nígbà tó bá dà bíi pé o wà ní ìwọ nìkan. Jẹ́ kí á ṣí Bíbélì wa. Níhìn-ín nínú Sáàmù kẹtàlélógún [23], bẹ̀rẹ̀ láti Sm 23 ẹsẹ kìíní Bíbélì sọ fún wa pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan. Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko; ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa.”

Kíyè sí ohun tí òǹkọ̀wé náà fi kún un ní Sm 23 ẹsẹ ìkẹrin: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.” Bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn. Wọ́n máa ń rí ìtùnú gbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro. Ṣé bí ó ṣe rí lára ìwọ pẹ̀lú nìyẹn?—

Bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ ṣe ń tọ́jú agbo àgùntàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe ń tọ́jú àwọn èèyàn rẹ̀ dáadáa. Ó ń fi ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà hàn wọ́n, wọ́n sì máa ń fi inú dídùn tẹ̀ lé e. Àní bí wàhálà bá tiẹ̀ wà yí wọn ká, wọn kì yóò bẹ̀rù. Olùṣọ́ àgùntàn máa ń lo ọ̀pá rẹ̀ tàbí ọ̀pá ìdaran rẹ̀ láti fi dáàbò bo àgùntàn kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹranko tó lè pa wọ́n lára. Bíbélì sọ ìtàn nípa bí Dáfídì tó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé olùṣọ́ àgùntàn ṣe dáàbò bo àgùntàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ kìnnìún àti béárì  kan. (1 Sámúẹ́lì 17:34-36) Àwọn èèyàn Ọlọ́run sì mọ̀ pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn pẹ̀lú. Ọkàn wọn lè balẹ̀ nítorí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn.

Nígbà tí a bá wà nínú wàhálà, ta ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tí ń dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀?

Jèhófà fẹ́ràn àwọn àgùntàn rẹ̀ gan-an ni, ó sì ń tọ́jú wọn pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. Bíbélì sọ pé: ‘Bí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò ṣe olùṣọ́ agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ pọ̀.’—Aísáyà 40:11.

Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ ọ láti mọ̀ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà jẹ́?— Ǹjẹ́ o fẹ́ láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgùntàn rẹ̀?— Àgùntàn máa ń fetí sí ohùn olùṣọ́ àgùntàn. Wọ́n máa ń rìn sún mọ́ ọn. Ṣé o máa ń fetí sí Jèhófà?— Ǹjẹ́ ò ń rìn sún mọ́ ọn?— Nígbà náà, kò ní sí ìdí tó fi yẹ kí o máa bẹ̀rù. Jèhófà yóò wà pẹ̀lú rẹ.

Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tọ́jú àwọn tó ń sìn ín. Jẹ́ kí á jùmọ̀ ka ohun tí Bíbélì sọ nípa èyí, nínú Sáàmù 37:25; 55:22; àti Lúùkù 12:29-31.