Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

 ORÍ 20

Ǹjẹ́ O Máa Ń Fẹ́ Jẹ́ Ẹni Àkọ́kọ́ Nígbà Gbogbo?

Ǹjẹ́ O Máa Ń Fẹ́ Jẹ́ Ẹni Àkọ́kọ́ Nígbà Gbogbo?

ǸJẸ́ o mọ ẹnì kan tó máa ń fẹ́ wà ní ipò àkọ́kọ́ ní gbogbo ìgbà?— Ó lè ti ẹlòmíràn kúrò lórí ìlà kí ó lè rí àyè bọ́ síwájú. Ṣé o ti rí ẹni tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ rí?— Olùkọ́ Ńlá náà rí i tí àwọn àgbàlagbà pàápàá ń gbìyànjú láti wà ní ipò àkọ́kọ́ tàbí ibi tó ṣe pàtàkì jù lọ. Inú rẹ̀ kò sì dùn sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀.

Ǹjẹ́ o ti rí ibi tí àwọn èèyàn ti ń gbìyànjú láti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́?

Bíbélì sọ fún wa pé ẹnì kan pe Jésù sí ibi àsè ńlá kan nínú ilé Farisí kan. Farisí yìí jẹ́ aṣáájú pàtàkì kan nínú ìsìn. Nígbà tí Jésù dé ibẹ̀, ó ń wo bí àwọn àlejò yòókù ṣe ń wọlé tí wọ́n ń yan àwọn ibi tó dára jù lọ láti jókòó. Nítorí náà, ó sọ ìtàn kan fún àwọn tí a pè wá náà. Ṣé ìwọ yóò fẹ́ láti gbọ́?—

 Jésù sọ pé: ‘Tí ẹnì kan bá pè ọ́ wá síbi àsè ìgbéyàwó, má ṣe lọ jókòó sí ibi tó dára jù lọ, tàbí ibi tó ṣe pàtàkì jù lọ.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tó mú kí Jésù sọ bẹ́ẹ̀?— Ó ṣàlàyé pé bóyá ó ti pe ẹnì kan tó ṣe pàtàkì jù ọ́ lọ wá síbẹ̀. Nítorí náà, bí o ṣe rí i nínú àwòrán yìí, ẹni tó se àsè yẹn yóò wá yóò sì sọ fún ọ pé: ‘Dìde fún ọkùnrin yìí, kí o lọ jókòó sí ọ̀hún yẹn.’ Báwo ni yóò ṣe rí lára àlejò tí a sọ bẹ́ẹ̀ fún?— Ojú yóò tì í nítorí pé àwọn yòókù tí a pè yóò máa wò ó bí ó ṣe kúrò níbẹ̀ tó ń lọ síbi tó rẹlẹ̀.

Ohun tí Jésù ń fi hàn ni pé kò tọ́ láti máa wá ibi tó ṣe pàtàkì jù lọ. Nítorí náà, ó sọ pé: ‘Tí a bá pè ọ wá síbi àsè ìgbéyàwó, lọ kí o sì jókòó sí ibi rírẹlẹ̀ jù lọ. Nígbà náà, ẹni tí ó pè ọ́ wá lè dé, kí ó sọ fún ọ pé, “Ọ̀rẹ́, gòkè lọ sí ibi tí ó ga.” Nígbà náà, ìwọ yóò ní ọlá níwájú gbogbo àlejò ẹlẹgbẹ́ rẹ.’—Lúùkù 14:1, 7-11.

Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù ń kọ́ wa nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń lọ jókòó sí ìjókòó tó dáa jù lọ tàbí ìjókòó àkọ́kọ́?

Ǹjẹ́ o mọ ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù ń kọ́ wa nínú ìtàn yìí?— Jẹ́ kí á mú àpẹẹrẹ kan wá láti wò ó bóyá o mọ ẹ̀kọ́ náà. Ká sọ pé o fẹ́ wọ inú ọkọ̀ kan tí àwọn èèyàn púpọ̀ fẹ́ wọ̀ pẹ̀lú. Ṣé ó yẹ kí o sáré lọ jókòó sí àyè kan, kí o sì jẹ́ kí àgbàlagbà dìde dúró?— Ṣé inú Jésù máa dùn sí ọ tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀?—

Ẹnì kan lè sọ pé ohun tó wù kí á máa ṣe, Jésù ò tiẹ̀ ní wò ó rárá. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o gbà pé òtítọ́ nìyẹn?— Nígbà tí Jésù wà níbi àsè ńlá ní ilé Farisí yẹn, ó ń kíyè sí àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe ń yan ìjókòó wọn. Ǹjẹ́ o rò pé kò ní máa ṣàkíyèsí ohun tí à ń ṣe lóde òní pẹ̀lú?— Nígbà tí Jésù sì ti wà ní ọ̀run nísinsìnyí, ó dájú pé yóò lè rí wa dáadáa.

 Bí ẹnì kan bá ń gbìyànjú láti wà ní ipò àkọ́kọ́, ó lè dá wàhálà sílẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn máa ń jiyàn, inú sì lè bí ẹlòmíràn lára wọn. Nígbà mìíràn èyí máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọdé púpọ̀ bá jọ fẹ́ wọ ọkọ̀ lọ sí ibì kan. Gbàrà tí ilẹ̀kùn ọkọ́ bá ti ṣí làwọn ọmọ náà yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí sáré láti lè kọ́kọ́ wọlé ṣáájú àwọn tó kù. Wọ́n máa ń du ìjókòó tó dára jù, èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ gíláàsì ọkọ̀. Kí ló lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀?— Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í jà.

Kí èèyàn máa fẹ́ láti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, máa ń fa ọ̀pọ̀ ìṣòro. Ó tilẹ̀ dá wàhálà tó pọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn àpọ́sítélì Jésù. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ́ ọ ní Orí 6 nínú ìwé yìí, wọ́n bá ara wọn jiyàn nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láàárín wọn. Kí ni Jésù wá ṣe?— Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù tọ́ wọn sọ́nà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà náà wọ́n tún bá ara wọn jiyàn. Jẹ́ ká wo bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀.

Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn mìíràn ń bá Jésù rìnrìn àjò tí  wọ́n jọ rìn lọ sí ìlú Jerúsálẹ́mù kẹ́yìn. Jésù ti máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba rẹ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀, nítorí náà Jákọ́bù àti Jòhánù ti ń ronú nípa bí wọn yóò ṣe bá a jọba níbẹ̀. Wọ́n tiẹ̀ ti bá ìyá wọn Sàlómẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Mátíù 27:56; Máàkù 15:40) Nítorí náà, bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, Sàlómẹ̀ lọ bá Jésù, ó tẹrí ba fún un, ó sì tọrọ ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀.

Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Obìnrin náà dáhùn pé òun ń fẹ́ kí Jésù jẹ́ kí àwọn ọmọ òun jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù nínú Ìjọba rẹ̀, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún àti ìkejì ní ọwọ́ òsì. Wàyí o, nígbà tí àwọn àpọ́sítélì mẹ́wàá yòókù gbọ́ ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù sọ pé kí ìyá wọn tọrọ, ǹjẹ́ inú wọn dùn?—

Kí ni Sàlómẹ̀ tọrọ lọ́wọ́ Jésù, ìṣòro wo nìyẹn sì fà?

Ká sòótọ́, wọ́n bínú sí Jákọ́bù àti Jòhánù gan-an. Nítorí náà, Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ìmọ̀ràn tó dára gan-an. Jésù sọ fún wọn pé  àwọn alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè máa ń fẹ́ jẹ́ ẹni ńlá àti èèyàn pàtàkì. Wọ́n máa ń fẹ́ wà ní ipò gíga tí wọn yóò ti máa pa àṣẹ fún gbogbo èèyàn. Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun má ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiwọn. Jésù sọ pé kàkà bẹ́ẹ̀: ‘Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.’ Ìwọ ronú nípa ìyẹn ná!—Mátíù 20:20-28.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ẹrú máa ń ṣe?— Ó máa ń sin àwọn ẹlòmíràn, kò sì ní retí pé kí àwọn ẹlòmíràn máa sin òun. Ipò tí ó rẹlẹ̀ jù lọ ló máa ń wà, kì í ṣe ipò àkọ́kọ́. Kì í ṣe bíi pé òun jẹ́ ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ṣe bí ẹni tó kéré jù lọ. Sì rántí o, Jésù sọ pé ẹni tó bá fẹ́ wà ní ipò kìíní ní láti máa ṣe bí ẹrú fún àwọn yòókù.

Ó dára, kí lo rò pé ìyẹn fi hàn pé ká máa ṣe?— Ṣé ẹrú máa ń bá ọ̀gá rẹ̀ du ipò ẹni tí ó yẹ kí ó wà ní ìjókòó tó dára jù? Tàbí ṣé yóò máa bá a jiyàn nípa ẹni tó yẹ kí ó kọ́kọ́ jẹun nínú wọn? Kí ni èrò rẹ?— Jésù ṣàlàyé pé ẹrú máa ń fi ọ̀gá rẹ̀ ṣáájú ara rẹ̀ nígbà gbogbo.—Lúùkù 17:7-10.

Nítorí náà, kàkà tí a ó fi máa gbìyànjú láti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, kí ló yẹ kí á ṣe?— Bẹ́ẹ̀ ni o, ó yẹ kí á máa ṣe bí ẹrú fún àwọn ẹlòmíràn. Èyí sì túmọ̀ sí pé kí á máa fi àwọn ẹlòmíràn ṣáájú ara wa. Ó túmọ̀ sí pé kí á máa gbà pé àwọn ẹlòmíràn ṣe pàtàkì jù wá lọ. Ǹjẹ́ o lè ronú nípa ọ̀nà tí o lè gbà fi àwọn ẹlòmíràn sí ipò àkọ́kọ́?— O ò ṣe ṣí ìwé rẹ padà sí ojú ìwé ogójì [40] àti ìkọkànlélógójì [41] kí o sì tún padà wo díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí o lè gbà fi àwọn ẹlòmíràn ṣáájú kí o sì sìn wọ́n.

Ìwọ yóò rántí pé Olùkọ́ Ńlá náà fi àwọn ẹlòmíràn ṣáájú ara rẹ̀ ó sì sìn wọ́n. Ní alẹ́ tí òun àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ lò pa pọ̀ kẹ́yìn, ó tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì wẹ ẹsẹ̀ wọn. Bí àwa pẹ̀lú bá ń fi àwọn ẹlòmíràn ṣáájú tí a sì ń sìn wọ́n, a jẹ́ pé à ń ṣe ohun tí inú Olùkọ́ Ńlá náà àti Bàbá rẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run dùn sí.

Jẹ́ kí á ka àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn sí i, tí ó gbà wá níyànjú pé ká máa fi àwọn ẹlòmíràn ṣáájú ara wa: Lúùkù 9:48; Róòmù 12:3; àti Fílípì 2:3, 4.