Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 3

Ẹni Tí Ó Dá Ohun Gbogbo

Ẹni Tí Ó Dá Ohun Gbogbo

Ta ló dá gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí?

MO MỌ ohun kan tó yani lẹ́nu. Ṣé kí n sọ fún ọ?— Ó dáa, wo ọwọ́ rẹ. Ká àwọn ìka ọwọ́ rẹ kò. Mú nǹkan kan sókè. Ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè fi ọwọ́ rẹ ṣe tí ọwọ́ rẹ á sì ṣe é dáadáa. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó dá ọwọ́ wa?—

Ẹni tó dá ẹnu wa, tó dá imú àti ojú wa náà ni. Ọlọ́run ni, òun sì ni Bàbá Olùkọ́ Ńlá náà. Inú wa dùn pé Ọlọ́run fún wa ní ojú, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— A lè fi ojú wa rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan. A lè rí òdòdó. A lè rí àwọn koríko tútù àti ojú ọ̀run aláwọ̀ búlúù. A tiẹ̀ tún lè rí àwọn ẹyẹ kéékèèké tó ń jẹ nǹkan kiri bí irú àwọn tó wà nínú àwòrán yìí. Ká sòótọ́, bí a ṣe ń fojú rí àwọn nǹkan wọ̀nyí yani lẹ́nu, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—

Àmọ́, ta ló dá nǹkan wọ̀nyí? Ṣé àwọn èèyàn kan ló dá wọn ni? Rárá o. Èèyàn lè kọ́ ilé. Àmọ́ kò sí èèyàn tó lè dá koríko tó ń hù. Èèyàn ò lè dá ẹyẹ, òdòdó tàbí àwọn ohun ẹlẹ́mìí mìíràn. Ṣé o mọ̀ bẹ́ẹ̀?—

Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ọlọ́run ló dá ọ̀run àti ayé. Òun náà ló dá àwa èèyàn. Òun ló dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Èyí ni ohun tí Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà, fi kọ́ wa.—Mátíù 19:4-6.

Báwo ni Jésù ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá ọkùnrin àti obìnrin? Ṣé Jésù rí Ọlọ́run nígbà tó ń dá wọn ni?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó rí i. Jésù wà  lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà tí Ọlọ́run ń dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Jésù ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá kó tó wá dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Áńgẹ́lì ni Jésù, ó sì ń gbé lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ní ọ̀run nígbà yẹn.

Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run wí pé: “Jẹ́ kí á ṣe ènìyàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Ọlọ́run ń bá sọ̀rọ̀ nígbà náà?— Ọmọ rẹ̀ ló ń bá sọ̀rọ̀. Ọmọ rẹ̀ tó ń bá sọ̀rọ̀ yìí ló wá sí ayé, tí ó sì wá di ẹni tá a mọ̀ sí Jésù.

Èyí dùn mọ́ni, àbí? Ìwọ rò ó wò ná! Bá a bá ń fetí sí Jésù, a jẹ́ pé ẹni tó wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà tí Ọlọ́run ń dá ayé àti gbogbo nǹkan yòókù ló ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ yẹn. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni Jésù ti rí kọ́ bí ó ṣe ń bá Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ ní ọ̀run. Abájọ tí Jésù fi jẹ́ Olùkọ́ Ńlá náà!

Ǹjẹ́ ìwọ rò pé inú Ọlọ́run kò dùn bó ṣe jẹ́ pé òun nìkan ló wà kí ó tó di pé ó dá Ọmọ rẹ̀?— Inú rẹ̀ dùn. Tí inú rẹ̀ bá dùn nígbà  náà, kí ló fà á tó tún fi dá àwọn ohun ẹlẹ́mìí mìíràn?— Ohun tó mú kó dá àwọn ohun ẹlẹ́mìí mìíràn ni pé ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́. Ó fẹ́ káwọn mìíràn wà láàyè kí wọ́n sì gbádùn ayé wọn. Ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó mú ká wà láàyè.

Gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ṣe ló fi ìfẹ́ tí ó ní hàn. Ó dá oòrùn. Oòrùn ń fún wa ní ìmọ́lẹ̀, ó sì ń bá wa lé otútù lọ. Ká ní kò sí oòrùn ni, ńṣe ni ibi gbogbo ì bá tutù nini, kò ní sí ohun alààyè kankan lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ inú rẹ ò dùn pé Ọlọ́run dá oòrùn?—

Ọlọ́run tún ń mú kí òjò rọ̀. Nígbà mìíràn, inú rẹ lè má dùn tí òjò bá ń rọ̀ nítorí pé kó ní jẹ́ kó o lè jáde síta láti ṣeré. Àmọ́ òjò ló ń jẹ́ káwọn òdòdó dàgbà. Nítorí náà, tá a bá rí àwọn òdòdó tó lẹ́wà, ta ló yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀?— Ọlọ́run ni. Ta ló tún yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tá a bá jẹ àwọn èso àtàwọn ewébẹ̀ tó dùn?— Ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí pé oòrùn àti òjò rẹ̀ ló ń mú kí àwọn nǹkan hù.

Ká ní ẹnì kan bi ọ́ pé: ‘Ṣé Ọlọ́run náà ló dá èèyàn àtàwọn ẹranko?’ Báwo lo ṣe máa dá a lóhùn?— Ó yẹ kó o sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ló dá èèyàn àtàwọn ẹranko.” Ṣùgbọ́n tí ẹnì kan bá wá sọ pé kì í ṣe Ọlọ́run ló dá èèyàn ńkọ́? Tí ẹni náà bá tún sọ fún ọ pé ẹranko ló di èèyàn ńkọ́? Bíbélì kò kọ́ wa bẹ́ẹ̀ o. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan tó wà láàyè.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-31.

Níwọ̀n bí ilé kò ti kọ́ ara rẹ̀, tó jẹ́ pé ẹnì kan ló kọ́ ọ, ta ló wá dá àwọn òdòdó, igi àti àwọn ẹranko?

Àmọ́ ẹnì kan lè sọ fún ọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà. Kí lo máa wá sọ fún ẹni náà?— O ò ṣe nawọ́ sí ilé kan, kí o wá béèrè lọ́wọ́ ẹni náà pé: “Ta ló kọ́ ilé yìí?” Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ẹnì kan ló máa kọ́ ilé náà. Ó dájú pé ilé ò ṣáà lè dédé kọ́ ara rẹ̀!—Hébérù 3:4.

Lẹ́yìn náà, fi òdòdó kan han ẹni náà.  Wá bi í pé: “Ta ló dá òdòdó yìí?” Kì í ṣe ènìyàn ló dá a. Gẹ́gẹ́ bí ilé ò ṣe lè dédé kọ́ ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni òdòdó yìí ò ṣe lè dá ara rẹ̀. Ẹnì kan ló dá a. Ọlọ́run ni.

Sọ pé kí ẹni yẹn tiẹ̀ dúró kó gbọ́ ohùn àwọn ẹyẹ tó ń kọrin. Wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ta ló dá àwọn ẹyẹ tó sì kọ́ wọn ní bí wọ́n á ṣe máa kọrin?” Ọlọ́run ni. Ọlọ́run ló dá ayé àti ọ̀run àti gbogbo ohun ẹlẹ́mìí! Òun ló mú kí gbogbo ohun tó ní ẹ̀mí wà láàyè.

Síbẹ̀, ẹnì kan lè sọ pé nǹkan tóun bá fojú rí nìkan lòun gbà gbọ́. Ó lè sọ pé: ‘Bí mi ò bá lè fojú mi rí i, mi ò lè gbà á gbọ́.’ Èyí ló mú kí àwọn èèyàn kan sọ pé àwọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, wọ́n ní àwọn kò rí i sójú.

Ní tòótọ́ a ò lè fojú rí Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: ‘Kò sí ènìyàn tó lè rí Ọlọ́run.’ Kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí ọmọdé èyíkéyìí nínú ayé tó lè rí Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ ya àwòrán Ọlọ́run tàbí kó gbẹ́ ère Ọlọ́run. Kódà, Ọlọ́run pàápàá sọ fún wa pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ère òun. Nítorí náà, inú Ọlọ́run kò ní dùn tá a ba ya àwòrán Ọlọ́run tàbí tá a bá ṣe ère rẹ̀ tá a wá gbé e sínú ilé wa.—Ẹ́kísódù 20:4, 5; 33:20; Jòhánù 1:18.

Àmọ́ nígbà tá ò ti lè rí Ọlọ́run sójú, báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run wà lóòótọ́? Ìwọ rò ó wò ná. Ṣé o lè fojú rí afẹ́fẹ́?— Rárá o. Kò sí ẹni tó lè fojú rí afẹ́fẹ́. Àmọ́ o lè rí àwọn nǹkan tí afẹ́fẹ́ ń ṣe. O lè rí i bí àwọn ewé tó wà lára igi ṣe ń mì síwá sẹ́yìn tí afẹ́fẹ́ bá ń fẹ́. Nítorí náà, o gbà pé afẹ́fẹ́ wà.

Báwo lo ṣe mọ̀ pé afẹ́fẹ́ wà?

Lọ́nà kan náà, o lè rí àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe. Tó o bá rí òdòdó lára ewéko tàbí o rí ẹyẹ, nǹkan tí Ọlọ́run dá lo rí yẹn. Èyí á jẹ́ kó o gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà lóòótọ́.

Ẹnì kan lè bi ọ́ pé, ‘Ta ló dá oòrùn àti ilẹ̀ ayé?’ Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Òótọ́ ni o, Ọlọ́run ló  dá gbogbo àwọn nǹkan tó ń yani lẹ́nu yìí! Ǹjẹ́ nǹkan dáadáa kọ́ ni Ọlọ́run ṣe yẹn—

Ǹjẹ́ kò dára pé a wà láàyè? A lè gbọ́ àwọn orín aládùn táwọn ẹyẹ ń kọ. A lè rí àwọn òdòdó àtàwọn nǹkan mìíràn tí Ọlọ́run dá. A sì tún lè jẹ àwọn oúnjẹ tí Ọlọ́run pèsè fún wa.

Ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó mú ká wà láàyè. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la mọ oore Ọlọ́run, a óò ṣe nǹkan kan. Kí ni ohun tá a ó ṣe?— A ó fetí sí Ọlọ́run, a ó sì ṣe àwọn ohun tó sọ nínú Bíbélì pé ká ṣe. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò fi hàn pé a fẹ́ràn Ẹni náà tó dá ohun gbogbo.

Ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún gbogbo ohun tó ṣe. Lọ́nà wo? Ka ohun tó wà nínú Sáàmù 139:14; Jòhánù 4:23, 24; 1 Jòhánù 5:21; àti Ìṣípayá 4:11.