Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 37

Bí A Ṣe Lè Rántí Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀

Bí A Ṣe Lè Rántí Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀

KÁ SỌ pé ẹnì kan fún ọ ní ẹ̀bùn pàtàkì kan. Ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn?— Ṣé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni wàá kàn dúpẹ́ mọ lọ́wọ́ ẹni tó fún ọ tí wàá sì gbàgbé nípa ẹni náà? Tàbí wàá máa rántí ẹni náà àti ohun tí ó ṣe fún ọ?—

Jèhófà Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀bùn pàtàkì kan. Ó rán Ọmọ rẹ̀ sí ayé kí ó wá kú fún wa. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù fi ní láti kú fún wa?— Ohun kan tó ṣe pàtàkì pé kí á mọ̀ ni.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kà á ní Orí 23 nínú ìwé yìí, Ádámù dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó rú òfin pípé tí Ọlọ́run fi lélẹ̀. A sì jogún ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ádámù, tí ó jẹ́ bàbá gbogbo wa. Nítorí náà kí ni o rò pé a nílò?— Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, a nílò bàbá tuntun kan, bàbá kan tí ó jẹ́ ẹni pípé jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí ó lò ní ayé. Ta ni o rò pé ó lè ṣe bàbá yìí fún wa?— Jésù ni.

Jèhófà rán Jésù sí ayé kí ó lè dà bí bàbá fún wa dípò Ádámù. Bíbélì sọ pé: “‘Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè ọkàn.’ Ádámù ìkẹyìn di ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè.” Ta ni Ádámù àkọ́kọ́?— Òun ni ẹni tí Ọlọ́run dá látinú ekuru ilẹ̀. Ta ni Ádámù kejì?— Jésù ni. Bíbélì fi èyí hàn nígbà tí ó sọ pé: “Ọkùnrin àkọ́kọ́ [Ádámù] jẹ́ láti inú ilẹ̀, ekuru ni a sì fi dá a; ọkùnrin kejì [Jésù] jẹ́ láti ọ̀run.”1 Kọ́ríńtì 15:45, 47; Jẹ́nẹ́sísì 2:7.

Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti mú ẹ̀mí Jésù láti ọ̀run tí ó sì fi sínú obìnrin tó ń jẹ́ Màríà, Jésù ò jogún ẹ̀ṣẹ̀ kankan láti ọ̀dọ̀ Ádámù. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi jẹ́ ẹni pípé. (Lúùkù 1:30-35) Ìdí sì tún nìyẹn tí  áńgẹ́lì kan fi sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn nígbà tí a bí Jésù, pé: “A bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí.” (Lúùkù 2:11) Ṣùgbọ́n kí Jésù tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí yìí tó lè di Olùgbàlà wa, kí ló ní láti kọ́kọ́ ṣe?— Ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dàgbà di géńdé, gẹ́gẹ́ bí Ádámù ṣe jẹ́ géńdé. Ẹ̀yìn náà ni Jésù yóò tó di ‘Ádámù kejì.’

Jésù, Olùgbàlà wa yóò tún di “Baba Ayérayé” fún wa. Ohun tí a pè é nínú Bíbélì gan-an nìyẹn. (Aísáyà 9:6, 7) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù ẹni pípé lè di bàbá wa dípò Ádámù tó di aláìpé nígbà tí ó dẹ́ṣẹ̀. Lọ́nà yìí a lè yàn láti fi ‘Ádámù kejì’ ṣe bàbá wa. A mọ̀ pé Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́ Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run ṣá o.

Báwo ni Ádámù àti Jésù ṣe jọra, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jọra?

Bí a bá ti mọ Jésù, a ó lè tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà wa. Ǹjẹ́ o rántí ohun tí Jésù fẹ́ gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀?— Bẹ́ẹ̀ ni o, yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. Ìwàláàyè pípé ti Jésù, tí ó fi rúbọ fún wa nígbà tí ó di géńdé ọkùnrin, ni à ń pè ní ìràpadà. Jèhófà pèsè ìràpadà kí a lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà.—Mátíù 20:28; Róòmù 5:8; 6:23.

Dájúdájú, kò yẹ kí á gbàgbé ohun tí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ṣe fún wa, àbí?— Jésù fi ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ kan han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ọ̀nà yẹn yóò sì mú ká máa rántí ohun tí ó ṣe. Jẹ́ kí á sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà yẹn.

Jẹ́ ká sọ pé o wà nínú yàrà òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan ní Jerúsálẹ́mù. Ọwọ́ alẹ́ ni.  Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jókòó síbi tábìlì kan. Ẹran ọ̀dọ́ àgùntàn kan tí wọ́n sun wà lórí tábìlì ọ̀hún, àti àwọn búrẹ́dì pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ pẹ̀lú ọtí wáìnì pupa. Oúnjẹ àkànṣe kan ni wọ́n fẹ́ jẹ. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí wọ́n fi fẹ́ jẹ ẹ́?—

Wọ́n ń fi oúnjẹ yìí ṣe ìrántí ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn ní ọdún tó ti pẹ́ gan-an sẹ́yìn, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èèyàn Jèhófà, jẹ́ ẹrú ní Íjíbítì. Ní ìgbà yẹn Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: ‘Kí ìdílé kọ̀ọ̀kan pa àgùntàn kan, kí ẹ sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara àtẹ́rígbà ilé yín.’ Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: ‘Ẹ wọnú ilé yín lọ kí ẹ sì jẹ ọ̀dọ́ àgùntàn náà.’

Báwo ni ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì?

 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe bẹ́ẹ̀. Ní alẹ́ kan náà yẹn, áńgẹ́lì Ọlọ́run lọ káàkiri ilẹ̀ Íjíbítì. Áńgẹ́lì náà sì pa àwọn àkọ́bí ọmọ tó wà nínú àwọn ilé tó pọ̀ jù lọ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n tí áńgẹ́lì náà bá ti rí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn lára àtẹ́rígbà ilé kan yóò ré ilé náà kọjá. Ọmọ kankan kò sì ní kú nínú ilé náà. Ohun tí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe yìí mú kí ẹ̀rù ba Fáráò ọba Íjíbítì gan-an. Nítorí náà Fáráò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Mo fún yín ní òmìnira, ẹ lè máa lọ. Ẹ jáde kúrò ní Íjíbítì!’ Bí wọ́n ti gbọ́ èyí, wọ́n di ẹrù wọn sórí ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì kúrò níbẹ̀.

Jèhófà kò fẹ́ kí àwọn èèyàn òun gbàgbé bí òun ṣe gbà wọ́n kúrò ní oko ẹrú. Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé: ‘Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ẹ gbọ́dọ̀ máa jẹ irú oúnjẹ tí ẹ jẹ lálẹ́ òní yìí.’ Wọ́n ń pe oúnjẹ àrà ọ̀tọ̀ yìí ní Ìrékọjá. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀?— Ó jẹ́ nítorí pé ní alẹ́ ọjọ́ yẹn áńgẹ́lì Ọlọ́run “ré” àwọn ilé tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí “kọjá.”—Ẹ́kísódù 12:1-13, 24-27, 31.

Jésù àti àwọn àpọ́sítélì ń ronú nípa èyí nígbà tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ Ìrékọjá. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì gidigidi. Ṣùgbọ́n kí ó tó ṣe é, ó jẹ́ kí Júdásì, àpọ́sítélì aláìṣòótọ́ yẹn, jáde. Lẹ́yìn náà Jésù mú ọ̀kan lára búrẹ́dì tó ṣẹ́ kù, ó gbàdúrà sí i, ó bù ú, ó sì pín in fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ jẹ.” Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Búrẹ́dì yìí dúró fún ara mi tí mo máa fi fúnni nígbà tí mo bá kú fún yín.’

Lẹ́yìn náà, Jésù mú aago wáìnì pupa. Lẹ́yìn tí ó tún gbàdúrà ìdúpẹ́ mìíràn, ó gbé e fún gbogbo wọn yí ká, ó sì sọ pé: “Ẹ mu nínú rẹ̀ gbogbo yín.” Ó sì sọ fún wọn pé: ‘Wáìnì yìí dúró fún ẹ̀jẹ́ mi. Láìpẹ́, èmi yóò tú ẹ̀jẹ̀ mi jáde láti fi mú kí ẹ bọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’—Mátíù 26:26-28; 1 Kọ́ríńtì 11:23-26.

Àǹfààní wo ni ẹ̀jẹ̀ Jésù tí ó fi wé ọtí wáìnì, lè ṣe fún wa?

Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé Jésù sọ pé kí àwọn àpọ́sítélì máa ṣe èyí ní  ìrántí òun?— Wọn kò tún ní jẹ oúnjẹ Ìrékọjá mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, lẹ́ẹ̀kan lọ́dún wọn yóò máa jẹ oúnjẹ àkànṣe yìí láti fi rántí Jésù àti ikú tí ó kú. Oúnjẹ yìí ni wọ́n ń pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Lónìí, a sábà máa ń pè é ní Ìṣe Ìrántí. Nítorí kí ni?— Torí pé ó máa ń rán wa létí ohun tí Jésù àti Bàbá rẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run ṣe fún wa ni.

Búrẹ́dì ibẹ̀ yóò mú ká ronú nípa ara Jésù. Ó fi ara rẹ̀ yìí lélẹ̀ fún wa kí á lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Wáìnì pupa wá ńkọ́ o?— Ńṣe ni ìyẹn yóò mú wa rántí bí ẹ̀jẹ̀ Jésù ti ṣe pàtàkì tó. Ó ṣe iyebíye ju ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n pa nígbà Ìrékọjá ní Íjíbítì lọ. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?— Bíbélì sọ pé ẹ̀jẹ̀ Jésù lè mú kí á rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Nígbà tí a bá sì ti mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, a ò ní ṣàìsàn mọ́, a ò ní darúgbó mọ́, a ò sì ní kú mọ́. Ó yẹ kí á máa ronú nípa ìyẹn nígbà tí a bá wá sí Ìṣe Ìrántí.

Ṣé gbogbo èèyàn ni ó lè máa jẹ búrẹ́dì náà, kí wọ́n sì máa mu wáìnì nígbà Ìṣe Ìrántí?— Ṣé o rí i, Jésù sọ fún àwọn tó ń jẹ ẹ́ tí wọ́n sì ń mu ún pé: ‘Ẹ óò kópa nínú ìjọba mi, ẹ óò jókòó sórí ìtẹ́ pẹ̀lú mi ní ọ̀run.’ (Lúùkù 22:19, 20, 30) Èyí túmọ̀ sí pé wọn yóò lọ sí ọ̀run lọ bá Jésù jọba. Nítorí náà, kìkì àwọn tó bá ń retí láti lọ bá Jésù jọba ní ọ̀run nìkan ni kí ó jẹ lára búrẹ́dì kí ó sì mu lára wáìnì náà.

Àmọ́ ṣá o, àwọn tí kò tiẹ̀ ní jẹ búrẹ́dì náà tí wọ́n kò sì ní mu wáìnì náà ní láti wá síbi Ìṣe Ìrántí. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀?— Ó jẹ́ nítorí pé Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún àwa náà pẹ̀lú. Bí a bá ń lọ síbi Ìṣe Ìrántí yìí, à ń fi hàn pé a kò gbàgbé pé Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. À ń rántí ẹ̀bùn pàtàkì tí Ọlọ́run fún wa.

Lára ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé ìràpadà Jésù ṣe pàtàkì ni 1 Kọ́ríńtì 5:7; Éfésù 1:7; 1 Tímótì 2:5, 6; àti 1 Pétérù 1:18, 19.