Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 17

Bí A Ṣe Lè Ní Ayọ̀

Bí A Ṣe Lè Ní Ayọ̀

Kí ló mú kí Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀”?

GBOGBO wa ló fẹ́ máa ní ayọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Ṣùgbọ́n àwọn tó ní ayọ̀ tòótọ́ kò pọ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á?— Ohun tó fà á ni pé wọn ò tíì mọ àṣírí bí èèyàn ṣe ń ní ayọ̀. Wọ́n rò pé bí èèyàn bá ti ní àwọn nǹkan tó pọ̀ yóò ní ayọ̀. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá ní nǹkan wọ̀nyí tán, ayọ̀ wọn kì í wà pẹ́ títí.

Àṣírí pàtàkì náà nìyí. Olùkọ́ Ńlá náà sọ pé: ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ní nǹkan ju èyí tí ó wà nínú rírí nǹkan gbà lọ.’ (Ìṣe 20:35) Nítorí náà, kí ni èèyàn lè ṣe láti lè ní ayọ̀?— Ó dára, ohun tí èèyàn lè ṣe ni pé kó máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan, kó sì máa ṣe àwọn nǹkan fún wọn. Ǹjẹ́ o mọ̀ bẹ́ẹ̀?—

Jẹ́ ká ronú nípa èyí síwájú sí i. Ǹjẹ́ Jésù sọ pé ẹni tí ó gba ẹ̀bùn kò ní láyọ̀?— Rárá, kò sọ bẹ́ẹ̀. Ó wù ọ́ kí o máa gba ẹ̀bùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Gbogbo èèyàn ló ń fẹ́ máa gba ẹ̀bùn. A máa ń láyọ̀ tí a bá gba àwọn nǹkan tó dára.

 Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé tí a bá ń fúnni ní nǹkan, ayọ̀ wa yóò tún pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ta ni o máa sọ pé ó tíì fúnni ní nǹkan púpọ̀ ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ?— Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run ni.

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” Ó ń fún wa ní òjò láti ọ̀run àti oòrùn pẹ̀lú, kí àwọn ewéko lè dàgbà kí á lè rí oúnjẹ jẹ. (Ìṣe 14:17; 17:25) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀”! (1 Tímótì 1:11) Fífún àwọn ẹlòmíràn ní nǹkan jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń mú Ọlọ́run láyọ̀. Tí àwa pẹ̀lú bá fún àwọn ẹlòmíràn ní nǹkan, a lè ní ayọ̀.

Kí lo lè fi kéèkì rẹ ṣe tó lè mú ọ láyọ̀ ju pé kí ìwọ nìkan dá jẹ gbogbo rẹ̀?

Wàyí o, kí ni a lè fún àwọn ẹlòmíràn? Dárúkọ wọn kí n gbọ́?— Nígbà mìíràn, tí a bá fẹ́ fúnni ní ẹ̀bùn, ó máa ń náni lówó. Tó bá jẹ́ pé ilé ìtajà lo ti rí ẹ̀bùn yẹn, owó lo máa fi rà á. Nítorí náà, tí o bá fẹ́ fúnni ní irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀, wàá kọ́kọ́ máa tọ́jú owó pa mọ́ títí yóò fi pọ̀ tó láti ra ẹ̀bùn náà.

Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ẹ̀bùn la máa ń rà o. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ tí ooru bá mú, ife omi tútù máa ń tuni lára gan-an. Tí o bá fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ ní irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀, o lè ní ayọ̀ torí pé o ti fúnni ní nǹkan.

Bóyá lọ́jọ́ kan, ìwọ àti ìyá rẹ lè dín àkàrà. Ó máa ń dùn mọ́ni gan-an. Ṣùgbọ́n kí lo lè fi díẹ̀ nínú àkàrà yẹn ṣe kí o sì láyọ̀ ju pé kí ìwọ nìkan jẹ gbogbo rẹ̀?— Ó dára, o lè fún ọ̀rẹ́ rẹ kan lára rẹ. Ṣé ìwọ yóò fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ kan?—

Olùkọ́ Ńlá náà àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ ayọ̀ tó wà nínú fífúnni  ní nǹkan. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọ́n fún àwọn èèyàn?— Ohun tó dára jù lọ ní ayé ni! Wọ́n mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, wọ́n sì fi ayọ̀ sọ ìhìn rere yẹn fún àwọn èèyàn. Wọ́n ń ṣe èyí láìjẹ́ kí àwọn èèyàn fún wọn ní owó nítorí ohun tí wọ́n ń fúnni.

Lọ́jọ́ kan, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lúùkù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù pàdé obìnrin kan. Obìnrin náà fẹ́ ní ayọ̀ látinú fífúnni. Etí odò kan ni wọ́n ti rí obìnrin náà. Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù lọ síbẹ̀ torí pé wọ́n gbọ́ pé ó jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń gbàdúrà. Bí wọ́n ṣe dé ibẹ̀ wọ́n bá àwọn obìnrin kan tó ń gbàdúrà lóòótọ́.

Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí sọ ìhìn rere nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ fún àwọn obìnrin yìí. Lìdíà ni orúkọ ọ̀kan lára wọn, ó sì fetí sílẹ̀ dáadáa. Lẹ́yìn náà Lìdíà fẹ́ ṣe ohun kan láti fi hàn pé inú òun dùn gan-an sí ìhìn rere tí òun gbọ́. Nítorí náà, ó bẹ Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù pé: ‘Bí ẹ bá gbà pé mo jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ẹ wọ ilé mi, kí ẹ sì dúró níbẹ̀.’ Ó bẹ̀ wọ́n títí, wọ́n sì lọ sílé rẹ̀.—Ìṣe 16:13-15.

Kí ni Lìdíà ń sọ fún Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù?

Lìdíà láyọ̀ gan-an pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí wá sínú ilé òun. Ó fẹ́ràn wọn torí pé wọ́n kọ́ ọ nípa Jèhófà àti Jésù àti nípa bí èèyàn ṣe lè wà láàyè títí láé. Inú rẹ̀ dùn pé òun lè fún Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù ní oúnjẹ láti jẹ àti ibi tí wọ́n lè sùn sí. Bí Lìdíà ṣe fún wọn ní nǹkan torí pé ó wu òun fúnra rẹ̀ láti fún wọn jẹ́ kí ó láyọ̀. Ohun kan nìyẹn tó yẹ kí á máa rántí. Ẹnì kan lè sọ fún wa pé ká fún àwọn èèyàn ní ẹ̀bùn. Ṣùgbọ́n bí kò bá wu àwa fúnra wa láti fúnni, a ò ní láyọ̀ pé a fúnni ní ẹ̀bùn.

Kí ló mú kí inú Lìdíà dùn láti fún Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù ní nǹkan?

Bí àpẹẹrẹ, kí á sọ pé o ní súìtì mélòó kan tó o fẹ́ lá, tí mo bá sọ pé kí o fún ọmọ kékeré mìíràn lára rẹ̀, ṣé inú rẹ yóò dùn láti fún un?— Ṣùgbọ́n kí lo máa ṣe ká sọ pé o ní súìtì mélòó kan, tí o sì rí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o fẹ́ràn gan-an? Tí ó bá jẹ́ pé fúnra rẹ lo ronú tí o sì fún ọ̀rẹ́ rẹ ní díẹ̀ lára rẹ̀, ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn?—

 Nígbà mìíràn, a máa ń fẹ́ràn ẹnì kan gan-an tí a óò fẹ́ láti fún un ní gbogbo ohun tí a fẹ́ fún un, tí a kò sì ní ṣẹ́ ohunkóhun kù fún ara wa. Bí ìfẹ́ tí a ní sí Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i, ohun tó yẹ kí ó máa wù wá láti ṣe fún Ọlọ́run nìyẹn.

Kí ló mú kí obìnrin aláìní yìí láyọ̀ láti fún Ọlọ́run ní gbogbo owó tó ní?

Olùkọ́ Ńlá náà mọ obìnrin kan tó ṣe bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run. Ó rí obìnrin náà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Obìnrin náà ní owó ẹyọ wẹ́wẹ́ méjì péré; gbogbo owó tí ó sì ní nìyẹn. Ṣùgbọ́n ó sọ owó méjì náà sínú àpótí, ó fi ṣe ọrẹ, tàbí ẹ̀bùn, fún iṣẹ́ tẹ́ńpìlì. Kò sí ẹni tó fipá mú obìnrin yìí láti sọ ọ́ síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà níbẹ̀ kò tiẹ̀ mọ ohun tí obìnrin náà ṣe. Ó sọ ọ́ síbẹ̀ nítorí pé ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀, àti pé ó fẹ́ràn Jèhófà dáadáa. Ó sì láyọ̀ nítorí pé ó fún Ọlọ́run ní ẹ̀bùn.—Lúùkù 21:1-4.

Àwọn ọ̀nà tí a lè gbà fúnni ní nǹkan pọ̀ gan-an. Ǹjẹ́ o lè sọ díẹ̀ fún mi?— Tí a bá fúnni ní nǹkan torí pé àwa fúnra wa fẹ́ láti fúnni, a óò ní ayọ̀. Ìdí nìyẹn tí Olùkọ́ Ńlá náà fi sọ pé: ‘Ẹ máa fúnni ní nǹkan nígbà gbogbo.’ (Lúùkù 6:38) Tí a bá ń fúnni ní nǹkan nígbà gbogbo, a ó máa mú àwọn èèyàn láyọ̀. A ó sì jẹ́ ẹni tí ó ní ayọ̀ púpọ̀ jù lọ!

Jẹ́ kí á kà síwájú sí i nípa bí fífúnni ní nǹkan ṣe ń múni láyọ̀, nínú Mátíù 6:1-4; Lúùkù 14:12-14; àti 2 Kọ́ríńtì 9:7.