KÍ NI a lè ṣe láti mú inú Ọlọ́run dùn? Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí a lè fún un?— Jèhófà sọ pé: “Tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó.” Ó tún sọ pé: “Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà.” (Sáàmù 24:1; 50:10; Hágáì 2:8) Síbẹ̀, ohun kan wà tí a lè fún Ọlọ́run. Kí ni?—

Jèhófà fún wa láyè pé kí á yàn bóyá a óò sin òun tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kò fipá mú wa láti ṣe ohun tó ń fẹ́ kí á máa ṣe. Jẹ́ ká wo ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa lọ́nà tí a óò fi lè yàn yálà láti sìn ín tàbí láti má ṣe sìn ín.

Ó ṣeé ṣe kí o mọ kiní kan tí wọ́n ń pè ní róbọ́ọ̀tì. Ẹ̀rọ ni. Wọ́n ṣe àwọn ẹ̀rọ yẹn lọ́nà tí wọ́n á fi lè máa ṣe ohunkóhun tí ẹni tó ṣe wọ́n bá ń fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Torí náà, àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń pè ní róbọ́ọ̀tì kì í fúnra wọn yan ohun tí wọ́n ń ṣe. Nígbà tí Jèhófà dá wa, tó bá fẹ́, ì bá ṣe gbogbo wa bí ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì. Ì bá ti dá wa lọ́nà tó jẹ́ pé kìkì ohun tó bá fẹ́ kí á máa ṣe náà la ó máa ṣe. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á?— Ṣé o rí i, bí ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì ni àwọn ohun ìṣeré kan ṣe rí. Tí a bá tẹ kiní kan lára àwọn ohun ìṣeré yìí, wọ́n á ṣe nǹkan kan, àmọ́ wọn ò lè dá nǹkan mìíràn ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ẹni tó ṣe wọ́n ń fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Ǹjẹ́ o ti rí irú ohun ìṣeré bẹ́ẹ̀ rí?— Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ohun ìṣeré bẹ́ẹ̀ kì í pẹ́ sú  àwọn èèyàn tí wọ́n bá ti fi ṣeré fún ìgbà díẹ̀ torí pé oríṣi eré kan ni ohun ìṣeré náà máa ń ṣe ṣáá. Ọlọ́run ò fẹ́ kí á máa sin òun bíi pé a jẹ́ ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì tí a ti ṣe pa láti máa sìn ín láìronú. Jèhófà ń fẹ́ kó jẹ́ pé ńṣe ni a nífẹ̀ẹ́ òun tí a fi ń sin òun àti pé ńṣe ló wá tí a fi ń ṣègbọràn sí òun.

Nígbà tí Ọlọ́run dá wa, kí nìdí tí kò fi ṣe wá bí ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì yìí?

Báwo ni o rò pé ó ṣe máa ń rí lára Bàbá wa ọ̀run nígbà tí a bá ṣègbọràn sí i nítorí pé ó wù wá láti ṣe é?— Ó dára, sọ fún mi ná, báwo ni ọ̀nà tí o gbà ń hùwà ṣe máa ń rí lára àwọn òbí rẹ?— Bíbélì sọ pé ọlọ́gbọ́n ọmọ máa “ń mú kí baba [rẹ̀] yọ̀” ṣùgbọ́n arìndìn ọmọ “ni ẹ̀dùn-ọkàn ìyá rẹ̀.” (Òwe 10:1) Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí pé tí o bá ṣe ohun tí ìyá tàbí bàbá rẹ sọ pé kí o ṣe, inú wọn máa ń dùn?— Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ inú wọn máa ń dùn tí o bá ṣàìgbọràn sí wọn?—

Báwo ni o ṣe lè mú inú Jèhófà àti inú àwọn òbí rẹ dùn?

Wàyí o, jẹ́ ká wá ronú nípa Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run. Ó sọ fún wa nípa bí a ṣe lè mú inú òun dùn. Jọ̀wọ́ ṣí Bíbélì rẹ sí Òwe 27:11. Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ níbẹ̀ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” Ǹjẹ́ o mọ ìtumọ̀ pé kí á ṣáátá ẹnì kan?— Ṣé o rí i, ẹnì kan lè ṣáátá rẹ nípa fífi ọ́ rẹ́rìn-ín, kí ó máa sọ fún ọ pé o ò lè ṣe ohun tí o sọ pé wàá ṣe. Báwo ni Sátánì ṣe ṣáátá Jèhófà?— Jẹ́ ká wò ó ná.

Rántí pé a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Orí 8 nínú ìwé yìí pé Sátánì ń fẹ́ jẹ́ ọ̀gá pátápátá ní ayé àti ọ̀run, ó sì ń fẹ́ jọ̀gá lé ẹni gbogbo lórí. Sátánì sọ  pé ohun tó ń mú kí àwọn èèyàn máa sin Jèhófà kò ju torí pé kí wọ́n lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà lọ́wọ́ Jèhófà lọ. Lẹ́yìn tí Sátánì ti mú kí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, Sátánì tún pe Ọlọ́run níjà. Ó sọ fún Ọlọ́run pé: ‘Ohun tó ń mú kí àwọn èèyàn máa sìn ọ́ ni pé wọ́n ti mọ̀ pé àwọn yóò rí nǹkan kan gbà lọ́wọ́ rẹ. Ìwọ sáà gbà mí láyè, èmi yóò sì yí gbogbo èèyàn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.’

Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, báwo ni Sátánì ṣe pe Jèhófà níjà?

Lóòótọ́ o, kì í ṣe bí a ṣe kọ ọ̀rọ̀ Sátánì yìí síbí gẹ́lẹ́ ló ṣe wà nínú Bíbélì o. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ka ìtàn ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù nínú Bíbélì, a óò rí i dájú pé Sátánì sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí Ọlọ́run. Ńṣe ni Sátánì bá Jèhófà jiyàn pé Jóòbù kò ní jẹ́ olódodo sí Ọlọ́run rárá. Jẹ́ kí á ṣí Bíbélì wa sí Jóòbù orí kìíní àti ìkejì kí á rí ohun tó ṣẹlẹ̀.

Kíyè sí i pé ní Jóòbù orí kìíní Sátánì wà láàárín àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run nígbà tí àwọn áńgẹ́lì wá síwájú Jèhófà. Nítorí náà, Jèhófà bi Sátánì léèrè pé: “Ibo ni o ti wá?” Sátánì dáhùn pé  òun wá láti ibi tí òun ti ń rìn káàkiri orí ilẹ̀ ayé. Jèhófà wá béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ o ti kíyè sí Jóòbù, pé ó ń sìn mí àti pé kì í hùwà burúkú kankan?’—Jóòbù 1:6-8.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àríwísí. Ó sọ pé: ‘Ohun tó jẹ́ kí Jóòbù máa sìn ọ́ ni pé kò tíì ní ìṣòro kankan. Tí o kò bá dáàbò bò ó mọ́, yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.’ Nítorí náà Jèhófà dáhùn pé: ‘Ó dára, Sátánì, o lè fi ohunkóhun tí o bá fẹ́ ṣe é, ṣùgbọ́n o kò gbọ́dọ̀ ṣe Jóòbù fúnra rẹ̀ léṣe o.’—Jóòbù 1:9-12.

Kí ni Sátánì ṣe?— Ó mú kí àwọn èèyàn wá jí àwọn màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Jóòbù lọ, kí wọ́n sì pa àwọn darandaran tó ń dà wọ́n. Lẹ́yìn náà, ààrá sán, ó sì pa àwọn àgùntàn àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń ṣọ́ wọn. Ó tún ṣe díẹ̀, àwọn èèyàn kan wá jí àwọn ràkúnmí rẹ̀ lọ wọ́n sì pa àwọn tó ń tọ́jú wọn. Níkẹyìn, Sátánì mú kí ìjì kan jà kí ó sì wó ilé tí àwọn ọmọ mẹ́wàá tí Jóòbù bí wà, kí ó sì pa gbogbo wọn. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, síbẹ̀ ó ṣì ń sin Jèhófà.—Jóòbù 1:13-22.

Nígbà tí Jèhófà tún padà rí Sátánì, Jèhófà sọ fún un pé Jóòbù ṣì jẹ́ olódodo o. Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí, ó ní: ‘Tí o bá gbà kí èmi ṣe òun fúnra rẹ̀ léṣe, yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.’ Nítorí náà, Jèhófà gbà kí  Sátánì ṣe Jóòbù fúnra rẹ̀ léṣe, ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún Sátánì pé kò gbọ́dọ̀ pa Jóòbù o.

Kí ni Jóòbù fara dà, kí sì nìdí tí èyí fi mú inú Ọlọ́run dùn?

Sátánì wá mú kí àrùn kọlu Jóòbù, tó fi jẹ́ pé gbogbo ara rẹ̀ kún fún egbò. Egbò ara Jóòbù wá ń rùn gan-an débi pé kò sí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ láti sún mọ́ ibi tó wà. Kódà aya Jóòbù sọ fún Jóòbù pé: “Bú Ọlọ́run, kí o sì kú!” Àwọn kan tó ṣe bí ẹni pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Jóòbù wá láti kí Jóòbù, wọ́n sì tún dá kún ìṣòro rẹ̀ nípa sísọ pé ó ní láti jẹ́ pé Jóòbù ti hu àwọn ìwà burúkú kan tó mú kó máa jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo bí Sátánì ṣe fìyà jẹ Jóòbù tí ó sì kó wàhálà bá a tó, Jóòbù ṣì ń bá a lọ láti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà.—Jóòbù 2:1-13; 7:5; 19:13-20.

Bí Jóòbù ṣe jẹ́ olódodo yìí, báwo ló rò pé ó ṣe rí lára Jèhófà?— Inú rẹ̀ dùn, nítorí pé Jèhófà lè sọ fún Sátánì pé: ‘Wo Jóòbù! Ohun tó jẹ́ kí ó máa sìn mí ni pé ó ú láti sìn mí.’ Ṣé ìwọ yóò dà bí Jóòbù, kí o jẹ́ ẹnì kan tí Jèhófà lè tọ́ka sí pé ó jẹ́ ara àpẹẹrẹ àwọn tó fi hàn pé Sátánì jẹ́ òpùrọ́?— Dájúdájú, àǹfààní ló jẹ́ fún wa pé a lè járọ́ Sátánì pé òun lè yí ẹnikẹ́ni padà kúrò nínú sísin Jèhófà. Ó dájú pé Jésù kà á sí àǹfààní pẹ̀lú.

Olùkọ́ Ńlá náà ò gba Sátánì láyè rárá kí ó mú òun ṣe ohun tí kò dára. Ìwọ sáà ronú nípa bí àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ ṣe mú inú Bàbá rẹ̀ dùn tó! Jèhófà lè tọ́ka sí Jésù, kí ó sì fún Sátánì lésì pé: ‘Wo Ọmọ mi! Ohun tó mú kí ó jẹ́ olóòótọ́ sí mi pátápátá ni pé ó nífẹ̀ẹ́ mi!’ Sì tún ronú nípa bí inú Jésù ṣe dùn tó pé òun ṣe ohun tó mú ọkàn Bàbá òun yọ̀. Ìdùnnú yẹn mú kí Jésù tiẹ̀ fara da ikú lórí igi oró pàápàá.—Hébérù 12:2.

Ṣé ìwọ fẹ́ dà bí Olùkọ́ Ńlá wa kí ìwọ pẹ̀lú mú inú Jèhófà dùn?— Nígbà náà máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí o ṣe, kí o sì máa mú inú rẹ̀ dùn nípa ṣíṣe nǹkan wọ̀nyẹn!

Kà nípa ohun tí Jésù ṣe láti mú inú Ọlọ́run dùn àti ohun tó yẹ kí àwa náà ṣe pẹ̀lú, nínú Òwe 23:22-25; Jòhánù 5:30; 6:38; 8:28; àti 2 Jòhánù 4.